Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí nìdí tí àwọn èèyàn fi ń hùwà ibi?

Tá ni ẹni tó gbìyànjú láti mú kí Jésù ṣe ohun tí kò dára?—Mátíù 4:8-10

Gbogbo èèyàn ló fẹ́ jẹ́ èèyàn àlááfíà, ọmọlúwàbí àti onínúure. Kí wá ló dé tí ìwà ipá, ìrẹ́jẹ àti ìwà ìkà fi gbòde kan? Ojoojúmọ́ la máa ń gbọ́ ìròyìn burúkú. Ó ní láti jẹ́ pé ẹnì kan ló ń mú kí àwọn èèyàn máa hùwà ibi.—Ka 1 Jòhánù 5:19.

Ṣé Ọlọ́run dá ìwà ibi mọ́ wa ni? Rara o, Jèhófà Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ká lè fara wé ìfẹ́ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Jóòbù 34:10) Ọlọ́run tún buyì kún wa ní ti pé ó fún wa lómìnira láti ṣe bá a ṣe fẹ́. Àmọ́ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn, wọ́n ṣi àǹfààní tí Ọlọ́run fún wọn lò, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀. Ara wọn la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀.—Ka Diutarónómì 32:4, 5.

Ṣé ìwà ibi máa dópin?

Ọlọ́run fẹ́ ká sapá láti máa sá fún ẹ̀ṣẹ̀. (Òwe 27:11) Ìdí nìyẹn tó fi ń kọ́ wa láwọn ọ̀nà tá a lè gbà yẹra fún ohun tí kò dára, tó sì tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè láyọ̀. Ṣùgbọ́n ní báyìí, a kò lè fara wé Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀.—Ka Sáàmù 32:8.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ibi gbòde kan, Ọlọ́run fàyè gbà á fúngbà díẹ̀ ká lè fojú ara wa rí ohun tó máa ń tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. (2 Pétérù 3:7-9) Àmọ́ láìpẹ́, ilẹ̀ ayé á kún fún àwọn èèyàn àlàáfíà tó ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 37:9-11.