Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Fi Kún Ẹwà Párádísè Tẹ̀mí

Bá A Ṣe Lè Fi Kún Ẹwà Párádísè Tẹ̀mí

Èmi yóò sì ṣe àyè ẹsẹ̀ mi gan-an lógo.”—AÍSÁ. 60:13.

ORIN: 102, 75

1, 2. Nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, kí ni ọ̀rọ̀ náà, “àpótí ìtìsẹ̀” túmọ̀ sí?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN sọ pé: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.” Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. (Aísá. 66:1, Bíbélì Mímọ́) Kódà, Ọlọ́run tún sọ nípa “àpótí ìtìsẹ̀” rẹ̀ pé: “Èmi yóò sì ṣe àyè ẹsẹ̀ mi gan-an lógo.” (Aísá. 60:13) Ọ̀nà wo ló máa gbà ṣe é lógo? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ayé tó jẹ́ “àpótí ìtìsẹ̀” Ọlọ́run là ń gbé, kí nìyẹn béèrè pé ká ṣe?

2 Nínú Bíbélì, ayé nìkan kọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, “àpótí ìtìsẹ̀” túmọ̀ sí. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tún lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti ṣàpèjúwe tẹ́ńpìlì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò nígbà àtijọ́. (1 Kíró. 28:2; Sm. 132:7) Ayé ni tẹ́ńpìlì náà wà, ibẹ̀ làwọn èèyàn sì máa ń péjọ sí láti sin Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi lẹ́wà gan-an lójú Jèhófà, wíwà rẹ̀ sì ṣe ayé tó jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ Jèhófà lógo.

3. Kí ni tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Ọlọ́run, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀?

3 Lónìí, àwọn èèyàn ò péjọ láti sin Ọlọ́run tòótọ́ nínú tẹ́ńpìlì tá a fi ọwọ́ kọ́ mọ́. Àmọ́, tẹ́ńpìlì tẹ̀mí kan wà tó ń fi ògo fún Jèhófà ju ilé èyíkéyìí lọ. Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí ni ètò tó mú ká lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ Jésù Kristi tó jẹ́ àlùfáà àti nípasẹ̀ ẹbọ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, tí Jèhófà sì fi ẹ̀mí yàn án gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí náà.—Héb. 9:11, 12.

4, 5. (a) Kí ni Sáàmù 99 sọ pé àwọn tó ń fi òótọ́ sin Jèhófà ń fẹ́ láti ṣe? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

4 Torí pé a mọrírì tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tí Jèhófà ṣètò rẹ̀ yìí, à ń yìn Jèhófà nípa sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀, a sì ń gbé e ga torí pé ó jẹ́ aláàánú, ó sì pèsè ìràpadà fún wa. Ẹ wo bó ti múni lọ́kàn yọ̀ tó pé àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n ń yin Jèhófà lógo báyìí ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ! Àwọn onísìn kan ní èrò tí kò tọ̀nà pé táwọn bá ti kúrò láyé táwọn sì lọ sí ọ̀run làwọn máa tó yin Ọlọ́run. Àmọ́, gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ìsinsìnyí ló yẹ ká máa yin Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé níbí.

5 À ń tipa báyìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí ìwé Sáàmù 99:1-3, 5-7 sọ̀rọ̀ wọn. (Kà á.) Bí sáàmù yẹn ṣe sọ, Mósè, Áárónì àti Sámúẹ́lì kọ́wọ́ ti ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn tòótọ́ nígbà ayé wọn. Kí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ arákùnrin Kristi lóde òní tó lọ sí ọ̀run níbi tí wọ́n á ti di àlùfáà tí wọ́n á sì ṣàkóso pẹ̀lú Jésù, wọ́n á ti kọ́kọ́ sìn láìyẹsẹ̀ nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti orí ilẹ̀ ayé. “Àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n ti di ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù báyìí ń tì wọ́n lẹ́yìn nígbà gbogbo. (Jòh. 10:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìrètí kan náà ni gbogbo wá ní, a jùmọ̀ ń sin Jèhófà ní ayé, tó jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ Rẹ̀. Àmọ́, ó dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń kọ́wọ́ ti ìjọsìn mímọ́ tí Jèhófà ṣètò rẹ̀?’

BÁ A ṢE LÈ MỌ ÀWỌN TÓ Ń SIN ỌLỌ́RUN NÍNÚ TẸ́ŃPÌLÌ TẸ̀MÍ

6, 7. Ìṣòro wo ló wáyé láàárín àwọn Kristẹni àtijọ́? Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà?

6 Kò tíì pé ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ tí ìpẹ̀yìndà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 20:28-30; 2 Tẹs. 2:3, 4) Èyí wá jẹ́ kó ṣòro gan-an láti mọ àwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, àkókò tó fún Jèhófà láti mú kí àwọn nǹkan ṣe kedere nípasẹ̀ Ọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé gorí ìtẹ́, ìyẹn Jésù Kristi.

7 Ní ọdún 1919, àwọn tí Jèhófà fọwọ́ sí, tí wọ́n ń sìn nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ ti fara hàn kedere. A ti yọ́ wọn mọ́ nípa tẹ̀mí kí ìjọsìn wọn lè túbọ̀ ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Aísá. 4:2, 3; Mál. 3:1-4) Lára ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ.

8, 9. Ṣàlàyé apá mẹ́ta tí “párádísè” tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran pín sí.

8 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìran tó rí nínú 2 Kọ́ríńtì 12:1-4. (Kà á.) Ó pe ohun tó rí nínú ìran tó ju ti ẹ̀dá lọ náà ní ìṣípayá. Ìṣípayá náà ò ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀, ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni. Nígbà tí a ‘gba Pọ́ọ̀lù lọ sí ọ̀run kẹta’ nínú ìran náà, “párádísè” wo ló rí? Párádísè tí Pọ́ọ̀lù sọ lè jẹ́ Párádísè nípa tara, Párádísè nípa tẹ̀mí, tàbí “párádísè Ọlọ́run,” tí gbogbo wọ́n máa wà pa pọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó lè jẹ́ Párádísè tá a lè fojú rí ní ilẹ̀ ayé, èyí tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Lúùkù 23:43) Ó tún lè jẹ́ Párádísè tẹ̀mí tá a máa gbádùn ní kíkún nínú ayé tuntun. Ní àfikún sí ìyẹn, ó lè jẹ́ àwọn àǹfààní àgbàyanu nínú “párádísè Ọlọ́run” ní ọ̀run.—Ìṣí. 2:7.

9 Kí wá ló fà á tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé òun “gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kò lè fẹnu sọ, èyí tí kò bófin mu fún ènìyàn láti sọ”? Ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé àkókò ò tíì tó fún un láti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn ohun àgbàyanu tó rí nínú ìran náà. Àmọ́ lónìí, ó bójú mu láti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn!

10. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú “Párádísè tẹ̀mí” àti “tẹ́ńpìlì tẹ̀mí”?

10 Gbólóhùn náà, “Párádísè tẹ̀mí” ti di ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa ń lò nínú ètò Ọlọ́run. Ó túmọ̀ sí àyíká tàbí ipò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó kún fún ọ̀pọ̀ nǹkan tẹ̀mí, tó sì ń fúnni láǹfààní láti gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run àti pẹ̀lú àwọn ará wa. Àmọ́, a ò wá lè torí ìyẹn sọ pé kò sí ìyàtọ̀ láàárín “Párádísè tẹ̀mí” àti “tẹ́ńpìlì tẹ̀mí” o! Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìjọsìn tòótọ́. Ṣùgbọ́n, Párádísè tẹ̀mí ló ń jẹ́ ká mọ àwọn tó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run tí wọ́n sì ń sìn ín nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ lónìí.—Mál. 3:18.

11. Àǹfààní wo ni Párádísè tẹ̀mí mú ká ní báyìí?

11 Ẹ wo bó ti múni lọ́kàn yọ̀ tó pé láti ọdún 1919, Jèhófà ti jẹ́ kí àwọn èèyàn aláìpé máa bá òun ṣiṣẹ́ láti mú àwọn èèyàn wá sínú Párádísè tẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n máa sọ ọ́ dọ̀tun, kí wọ́n sì mú kó máa gbòòrò sí i! Ṣé ìwọ náà ń ṣe ipa tìrẹ nínú iṣẹ́ àgbàyanu yìí? Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ láti máa bá Jèhófà ṣiṣẹ́ kó o lè máa ṣe ‘àyè ẹsẹ̀ rẹ̀’ lógo?

ÈTÒ JÈHÓFÀ Ń RẸWÀ SÍ I

12. Kí ló mú kó dá gbogbo wa lójú pé ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 60:17 máa ṣẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

12 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyípadà àgbàyanu kan tó máa wáyé nínú apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà wà nínú ìwé Aísáyà 60:17. (Kà á.) Àwọn ọ̀dọ́ tàbí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ti ka ọ̀pọ̀ ohun tó jẹ́rìí sí i pé ìyípadà yìí ń wáyé tàbí kí wọ́n ti gbọ́ nípa rẹ̀ látẹnu àwọn míì. Àmọ́ àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí àwọn ìyípadà náà ṣojú wọn. Abájọ tó fi dá wọn lójú pé Jèhófà ń lo Ọba tó gbé gorí ìtẹ́ láti ṣamọ̀nà àwọn tó wà nínú ètò Rẹ̀, ó sì ń lò ó láti darí wọn. Wọ́n mọ̀ pé ẹni tí àwọn gbẹ́kẹ̀ lé ò ní já àwọn kulẹ̀, gbogbo wa la sì ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀. Tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ látọkàn wá, ó máa fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun ó sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà.

13. Iṣẹ́ wo ni Sáàmù 48:12-14 sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe?

13 Bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti wà nínú òtítọ́, ó pọn dandan pé ká máa sọ fún àwọn èèyàn nípa ètò Jèhófà. Ohun ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé Párádísè tẹ̀mí wà nínú ayé búburú tí ìwà ìbàjẹ́ àti àìnífẹ̀ẹ́ ti gbilẹ̀ yìí! A gbọ́dọ̀ fi ayọ̀ ròyìn àwọn ohun tó jẹ́ àgbàyanu nípa ètò Jèhófà, tàbí “Síónì,” àti ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Párádísè tẹ̀mí fún àwọn “ìran ẹ̀yìn ọ̀la.”—Ka Sáàmù 48:12-14.

14, 15. Àwọn ìyípadà wo ló wáyé nínú ètò Ọlọ́run ní ọdún 1970 sí ọdún 1979? Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà ṣe wá láǹfààní?

14 Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, àwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wa ti rí àwọn ìyípadà kan tó wáyé, wọ́n sì tún rí bí àwọn ìyípadà náà ṣe túbọ̀ fi kún ẹwà apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà. Wọ́n rántí ìgbà tí ètò Ọlọ́run ń lo ìránṣẹ́ ìjọ, tí orílẹ̀-èdè máa ń ní ìránṣẹ́ ẹ̀ka, tí ìtọ́ni sì máa ń wá látọ̀dọ̀ ààrẹ Watch Tower Society. Àmọ́ ní báyìí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló ń bójú tó ìjọ, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ló ń bójú tó orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, ìtọ́ni sì ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tá a wá mọ̀ sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ṣeé fiṣẹ́ lé lọ́wọ́ wà tí wọ́n ń ran gbogbo àwọn arákùnrin olùfọkànsìn yìí lọ́wọ́, àwọn nìkan ṣoṣo ni wọ́n ń dá ṣe àwọn ìpinnu nínú ìjọ, ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ní oríléeṣẹ́. Ní ọdún 1970 sí ọdún 1979, àwọn nǹkan yí pa dà, alàgbà kan ṣoṣo ò dá ṣèpinnu mọ́, àwùjọ àwọn alàgbà ló wá ń ṣe ìpinnu.

15 Ǹjẹ́ àwọn ìyípadà yìí ṣe wá láǹfààní? Bẹ́ẹ̀ ni, ó sì bọ́gbọ́n mu láti gbà bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó túbọ̀ ṣe kedere sí wa ló mú ká ṣe àwọn ìyípadà náà. Dípò tí ẹnì kan ṣoṣo á fi máa pàṣẹ, Jèhófà fún wa ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” ètò Ọlọ́run sì ń jàǹfààní látinú ànímọ́ rere tí gbogbo wọ́n ní.—Éfé. 4:8; Òwe 24:6.

Jèhófà ń fún àwọn èèyàn níbi gbogbo ní ìtọ́sọ́nà tí wọ́n nílò (Wo ìpínrọ̀ 16, 17)

16, 17. Àwọn ìyípadà wo ló wáyé láìpẹ́ yìí tó wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, kí sì nìdí?

16 Tún ronú nípa àwọn ìyípadà tó dé bá àwọn ìwé ìròyìn wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí, èyí tó kan bí wọ́n ṣe rí, ohun tó wà nínú wọn àti ọ̀nà tá a gbà ń mú wọn dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. Ẹ sì wo bó ṣe máa ń dùn mọ́ni tó láti lo àwọn ìwé tó wúlò tó sì fani mọ́ra yìí lóde ẹ̀rí! Bá a sì ṣe ń lo àwọn ohun èlò ìgbàlódé bí Ìkànnì jw.org láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn èèyàn níbi gbogbo ń rí i kedere pé Jèhófà fẹ́ láti máa fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tí ọ̀pọ̀ lára wọ́n nílò lójú méjèèjì.

17 Kò yẹ ká gbàgbé ìyípadà tó wáyé tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé tàbí ká ní àkókò púpọ̀ sí i fún ìdákẹ́kọ̀ọ́. A sì tún mọrírì àwọn ìyípadà tó ti dé bá àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè wa. À ń rí i pé ọdọọdún ni wọ́n ń dáa sí i. Ayọ̀ wa sì tún ń pọ̀ sí i bá a ṣe ń rí ìdálẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i gbà ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. Ọwọ́ Jèhófà hàn kedere nínú gbogbo ìyípadà tó ń wáyé náà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ń fi kún ẹwà ètò rẹ̀ àti ti Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE LÁTI FI KÚN ẸWÀ PÁRÁDÍSÈ TẸ̀MÍ

18, 19. Báwo la ṣe lè fi kún ẹwà Párádísè tẹ̀mí?

18 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà yọ̀ǹda fún wa láti fi kún ẹwà Párádísè tẹ̀mí wa. Báwo la ṣe ń fi kún ẹwà Párádísè náà? À ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i di ọmọ ẹ̀yìn. Nígbàkigbà tá a bá ran ẹnì kan lọ́wọ́ tó sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́, a ti mú kí ààlà Párádísè tẹ̀mí náà gbòòrò sí i nìyẹn.—Aísá. 26:15; 54:2.

19 A tún lè fi kún ẹwà Párádísè tẹ̀mí tá a bá ń sapá láti mú kí ìwà wa máa sunwọ̀n sí i. Lọ́nà yẹn, a óò túbọ̀ mú kí Párádísè yìí fa àwọn tí kò tíì wá síbẹ̀ mọ́ra. Ìmọ̀ Bíbélì ní àyè tirẹ̀, àmọ́ ìwà mímọ́ wa àti bá a ṣe ń gbé ní ìrẹ́pọ̀ ló kọ́kọ́ máa ń fa àwọn èèyàn wá sínú ètò Ọlọ́run, á sì wá mú kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà àti Jésù.

O lè kópa nínú mímú kí ààlà Párádísè tẹ̀mí náà gbòòrò sí i (Wo ìpínrọ̀ 18, 19)

20. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 14:35 ṣe sọ, kí ló yẹ kó máa wù wá láti ṣe?

20 Ó dájú pé inú Jèhófà àti Jésù á máa dùn gan-an bí wọ́n ti ń wo Párádísè tẹ̀mí tó rẹwà tá a wà nínú rẹ̀ lónìí. À ń láyọ̀ bá a ṣe ń mú kí Párádísè tẹ̀mí tá a wà nínú rẹ̀ rẹwà sí i. Àmọ́, ìtọ́wò lásán nìyẹn jẹ́ tá a bá fi wé ayọ̀ tá a máa ní nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ayé di Párádísè. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ohun tó wà nínú Òwe 14:35, tó sọ pé: “Ìdùnnú ọba ń bẹ nínú ìránṣẹ́ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà.” Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà bá a ti ń ṣiṣẹ́ kára láti fi kún ẹwà Párádísè tẹ̀mí náà.