Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!

“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!

“Ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.”—LÚÙKÙ 21:28.

ORIN: 133, 43

1. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé ní ọdún 66 Sànmánì Kristẹni? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

KÁ SỌ pé o wà lára àwọn Kristẹni tó gbé ní ìlú Jerúsálẹ́mù ní ọdún 66 Sànmánì Kristẹni. Ó dájú pé wàá máa rí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká rẹ. Lákọ̀ọ́kọ́, gómìnà ọmọ ilẹ̀ Róòmù tó ń jẹ́ Florus fi ipá gba tálẹ́ńtì owó ẹyọ mẹ́tàdínlógún nínú àpótí ọrẹ mímọ́ tó wà ní tẹ́ńpìlì. Lójú ẹsẹ̀, àwọn Júù dìde ogun wọ́n sì pa àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wà ní Jerúsálẹ́mù nípakúpa, wọ́n wá kéde pé àwọn ò sí lábẹ́ ilẹ̀ Róòmù mọ́. Àmọ́ àwọn ọmọ ogun ìlú Róòmù náà yára gbéjà kò wọ́n pa dà. Kò ju oṣù mẹ́ta lọ lẹ́yìn náà tí Cestius Gallus, gómìnà ilẹ̀ Róòmù tó ń ṣàkóso ilẹ̀ Síríà, fi kó àwọn ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] wọ ìlú Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọmọ ogun náà ya wọ gbogbo ìlú tó wà ní àgbègbè Jerúsálẹ́mù, àwọn Júù ọlọ̀tẹ̀ náà sì sá pa dà lọ sí àgbègbè ibi tí tẹ́ńpìlì wà láti lọ fara pa mọ́. Lẹ́yìn yẹn, àwọn ọmọ ogun Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ ìdí ògiri tó yí tẹ́ńpìlì ká. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba gbogbo àwọn tó wà nínú ìlú. Báwo ni gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ṣe máa rí lára rẹ?

2. Kí ló pọn dandan pé kí àwọn Kristẹni ṣe ní ọdún 66 Sànmánì Kristẹni? Kí ló mú kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀?

2 Ó dájú pé wàá rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, èyí tí òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Lúùkù ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ó ní: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:20) Àmọ́, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni tó tẹ̀ lé ìkìlọ̀ náà?’ Jésù tún sọ pé: “Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:21) Báwo ni wàá ṣe kúrò ní Jerúsálẹ́mù, nígbà tí ọ̀pọ̀ ọmọ ogun ti yí i ká? Wàyí o, ohun kan tó jẹ́ ìyàlẹ́nu ṣẹlẹ̀. Ṣàdédé lo rí i tí àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣẹ́rí pa dà kúrò ní Jerúsálẹ́mù! Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a “ké” àtakò wọn “kúrú.” (Mát. 24:22) O wá láǹfààní láti tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jésù fún ẹ. Lójú ẹsẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn Kristẹni olóòótọ́ yòókù tí wọ́n wà ní ìlú náà àti àgbègbè rẹ̀ sá lọ sórí àwọn òkè tó wà ní òdìkejì Odò Jọ́dánì. * Lẹ́yìn náà, ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù míì forí lé Jerúsálẹ́mù wọ́n sì pa ìlú náà run. Àmọ́, o là á já torí pé o tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù.

3. Ipò tó fara jọ èyí wo ni àwọn Kristẹni máa tó dojú kọ? Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Láìpẹ́ láìjìnnà, olúkúlùkù wa máa dojú kọ ipò tó fara jọ ìyẹn. Yàtọ̀ sí pé Jésù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, ó tún lo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yẹn láti ṣàlàyé bí ohun tó jọ ọ́ ṣe máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí “ìpọ́njú ńlá” bá bẹ̀rẹ̀ lójijì. (Mát. 24:3, 21, 29) Ìròyìn ayọ̀ ló jẹ́ pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” máa la àjálù tó máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé náà já. (Ka Ìṣípayá 7:9, 13, 14.) Kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ náà? Ó yẹ kó wù wá gan-an láti rí ìdáhùn ìbéèrè yìí torí pé ìgbàlà wa wé mọ́ ọn. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò bí àwọn ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú yìí ṣe máa kan gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

BÍ ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ ṢE MÁA BẸ̀RẸ̀

4. Báwo ni ìpọ́njú ńlá ṣe máa bẹ̀rẹ̀, kí ló sì máa mú kó rí bẹ́ẹ̀?

4 Báwo ni ìpọ́njú ńlá ṣe máa bẹ̀rẹ̀? Ìwé Ìṣípayá dáhùn ìbéèrè yìí fún wa nípa ṣíṣe àpèjúwe ìparun “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣí. 17:5-7) Ẹ sì wo bó ṣe bá a mu wẹ́kú pé a fi gbogbo ìsìn èké wé aṣẹ́wó! Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti bá àwọn aṣáájú inú ayé burúkú yìí ṣe ìṣekúṣe. Dípò kí wọ́n máa kọ́wọ́ ti Jésù àti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn, àwọn alákòóso ayé ni wọ́n ń gbárùkù tì. Kí wọ́n lè rọ́wọ́ mú ní agbo òṣèlú, wọn ò fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Ọlọ́run tó yẹ kí àwa Kristẹni máa tẹ̀ lé. Wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ẹni mímọ́, tí wọ́n sì tún jẹ́ wúńdíá. (2 Kọ́r. 11:2; Ják. 1:27; Ìṣí. 14:4) Àmọ́ ta ló máa pa ètò tó dà bí aṣẹ́wó náà run? Jèhófà Ọlọ́run máa fi “ìrònú” rẹ̀ sínú ọkàn “ìwo mẹ́wàá” ti “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà. Àwọn ìwo náà ṣàpẹẹrẹ gbogbo agbára òṣèlú tó ń ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lẹ́yìn. “Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà sì ṣàpẹẹrẹ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè.—Ka Ìṣípayá 17:3, 16-18.

5, 6. Kí ló mú ká gbà pé ìparun Bábílónì Ńlá kọ́ ló máa mú òpin dé bá gbogbo àwọn tó ti wà nínú ẹ̀sìn èké rí?

5 Ṣó wá yẹ ká gbà pé ìgbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run náà ni gbogbo àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn èké máa pa run? Bóyá ni. Ọlọ́run mí sí wòlíì Sekaráyà láti ṣe àkọsílẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Nígbà tí àkọsílẹ̀ náà ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó ti wà nínú ìsìn èké rí, ó ní: “Òun yóò sì wí dájúdájú pé, ‘Èmi kì í ṣe wòlíì. Ọkùnrin tí ń ro ilẹ̀ ni mí, nítorí pé ará ayé ni ó gbà mí síṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ Ẹnì kan yóò sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ wo ni ìwọ̀nyí lára rẹ láàárín ọwọ́ rẹ?’ Òun yóò sì wí pé, ‘Ìwọ̀nyí ni a dá sí mi lára ní ilé àwọn olùfẹ́ mi.’” (Sek. 13:4-6) Torí náà, ó jọ pé, àwọn kan lára àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì á jáwọ́ nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe, wọ́n á sì sẹ́ pé àwọn ò dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀sìn èké yẹn rí.

6 Báwo ni nǹkan á ṣe rí fún àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà yẹn? Jésù ṣàlàyé pé: “Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé a ké ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là; ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́, a óò ké ọjọ́ wọnnì kúrú.” (Mát. 24:22) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, ní ọdún 66 Sànmánì Kristẹni, a “ké” ìpọ́njú náà “kúrú.” Èyí mú kí “àwọn àyànfẹ́,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró, sá kúrò nínú ìlú náà àti ní gbogbo àyíká rẹ̀. Bákan náà, a máa “ké” apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ “kúrú” nítorí “àwọn àyànfẹ́.” Jèhófà ò ní gba “ìwo mẹ́wàá” tó ṣàpẹẹrẹ gbogbo agbára òṣèlú náà láyè láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdádúró díẹ̀ máa wà.

ÀKÓKÒ ÌDÁNWÒ ÀTI ÌDÁJỌ́

7, 8. Àǹfààní wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run tó bá jẹ́ olóòótọ́ máa ní lẹ́yìn ìparun àwọn ètò ìsìn èké? Báwo ni wọ́n á ṣe dá yàtọ̀ nígbà yẹn?

7 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìparun gbogbo ètò ìsìn èké? Àkókò yẹn ni ohun tó wà lọ́kàn wa máa fara hàn kedere. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ààbò lọ sọ́dọ̀ àwọn àjọ tó dà bí “àpáta orí òkè” ìyẹn àwọn àjọ tí àwọn èèyàn dá sílẹ̀. (Ìṣí. 6:15-17, Bíbélì Mímọ́) Àmọ́, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa sá lọ síbi ààbò tí Jèhófà pèsè. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àkókò díẹ̀ tí àwọn Kristẹni ní láti fi sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù kì í ṣe àkókò láti sọ gbogbo àwọn Júù di Kristẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, àkókò tí àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ kí wọ́n sì ṣègbọràn ni. Bákan náà, a ò lè retí pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ní àkókò tí ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ fi máa dáwọ́ dúró díẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn á ní àǹfààní láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n á sì máa kọ́wọ́ ti àwọn arákùnrin Kristi.—Mát. 25:34-40.

8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò ìdánwò yẹn, a mọ̀ pé ó máa gba pé ká yááfì àwọn ohun kan. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni ní láti fi gbogbo ohun ìní wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fara da ọ̀pọ̀ ìnira kí wọ́n lè là á já. (Máàkù 13:15-18) Ká bàa lè jẹ́ olóòótọ́, ǹjẹ́ a ṣe tán láti pàdánù àwọn ohun ìní wa? Ṣé a máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? Ẹ tiẹ̀ wo bó ṣe máa rí nígbà yẹn, bíi ti wòlíì àtijọ́ náà, Dáníẹ́lì, àwa nìkan la ó máa sin Ọlọ́run nìṣó, láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí!—Dán. 6:10, 11.

9, 10. (a) Kí ni àwa èèyàn Ọlọ́run á máa kéde rẹ̀ nígbà yẹn? (b) Kí ni ọ̀tá àwa èèyàn Ọlọ́run máa ṣe?

9 Ìgbà yẹn kọ́ ni àkókò láti wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run. Àkókò ìwàásù á ti kọjá. Àkókò “òpin” ohun gbogbo á ti sún mọ́lé. (Mát. 24:14) Ó dájú pé gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ làwa èèyàn Ọlọ́run á máa kéde rẹ̀. Ó ṣeé ṣe ká máa polongo pé ayé búburú Sátánì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin pátápátá. Bíbélì fi ìkéde yìí wé àwọn òkúta yìnyín nígbà tó sọ pé: “Yìnyín ńláǹlà, tí òkúta rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìwọ̀n tálẹ́ńtì kan sì bọ́ láti ọ̀run sórí àwọn ènìyàn náà, àwọn ènìyàn náà sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu àjàkálẹ̀ yìnyín náà, nítorí ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀ pọ̀ lọ́nà kíkàmàmà.”—Ìṣí. 16:21.

10 Àwọn ọ̀tá wa máa rí i nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀. Ọlọ́run mí sí wòlíì Ìsíkíẹ́lì láti ṣàlàyé ohun tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, ìyẹn àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè, máa ṣe. Ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé àwọn nǹkan yóò wá sí ọkàn-àyà rẹ, dájúdájú, ìwọ yóò sì gbìrò ìpètepèrò tí ń ṣeni léṣe; ìwọ yóò sì wí pé: “Èmi yóò gòkè lọ gbéjà ko ìgbèríko gbalasa. Èmi yóò wá sórí àwọn tí kò ní ìyọlẹ́nu, àwọn tí ń gbé ní ààbò, tí gbogbo wọn ń gbé láìsí ògiri, tí wọn kò sì ní ọ̀pá ìdábùú àti àwọn ilẹ̀kùn pàápàá.” Yóò jẹ́ láti kó ohun ìfiṣèjẹ rẹpẹtẹ àti láti piyẹ́ ohun púpọ̀, kí o bàa lè yí ọwọ́ rẹ padà sórí àwọn ibi ìparundahoro tí a tún ti ń gbé inú wọn àti sára àwọn ènìyàn kan tí a kó jọpọ̀ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè, èyí tí ń kó ọlà àti dúkìá jọ rẹpẹtẹ, àwọn tí ń gbé ní àárín ilẹ̀ ayé.’” (Ìsík. 38:10-12) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ṣe ló máa dà bíi pé àwọn èèyàn Ọlọ́run dá yàtọ̀ “ní àárín ilẹ̀ ayé.” Ara àwọn orílẹ̀-èdè ò ní gbà á mọ́. Torí náà, wọ́n á fẹ́ gbéjà ko àwọn ẹni àmì òróró Jèhófà àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn.

11. (a) Kí ló yẹ ká rántí nípa bí àwọn nǹkan ṣe máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra nígbà ìpọ́njú ńlá? (b) Kí ni àwọn èèyàn máa ṣe nígbà tí wọ́n bá rí àwọn àmì tó fara hàn ní ọ̀run?

11 Bá a ṣe ń gbé àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà yẹ̀ wò, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Bíbélì kò sọ fún wa bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe máa wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan á wọnú ara wọn. Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparí ètò àwọn nǹkan, ó sọ pé: “Àwọn àmì yóò wà nínú oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, àti lórí ilẹ̀ ayé làásìgbò àwọn orílẹ̀-èdè, láìmọ ọ̀nà àbájáde nítorí ìpariwo omi òkun àti ìrugùdù rẹ̀, nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé; nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì. Nígbà náà ni wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.” (Lúùkù 21:25-27; ka Máàkù 13:24-26.) Ṣé àwọn àmì tí ń dẹ́rù bani àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a lè fojú rí ní ọ̀run máa wà nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá ṣẹ? Ó dìgbà náà ká tó mọ̀. Bó ti wù kó rí, àwọn àmì náà máa mú kí ẹ̀rù ba àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ìdí wọn á sì domi.

A ò ní mikàn, torí ó dá wa lójú pé a máa là á já! (Wo ìpínrọ̀ 12, 13)

12, 13. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá wá “pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá”? (b) Kí ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ṣe nígbà yẹn?

12 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá dé “pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá”? Ìgbà yẹn ló máa san èrè fún àwọn olóòótọ́ tó sì máa fi ìyà jẹ àwọn aláìṣòótọ́. (Mát. 24:46, 47, 50, 51; 25:19, 28-30) Bí Mátíù ṣe sọ, àmì kan tó ní oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ nínú ni Jésù fi parí àkàwé tó ṣe nípa àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́. Ó ní: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Yóò sì fi àwọn àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.” (Mát. 25:31-33) Ìdájọ́ wo ló máa kéde sórí àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́? Ó parí àkàwé náà pé: “Àwọn wọ̀nyí [àwọn ewúrẹ́] yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mát. 25:46.

13 Kí ni àwọn ewúrẹ́ máa ṣe tí wọ́n bá rí i pé “ìkékúrò àìnípẹ̀kun” ló ń dúró de àwọn? Wọ́n máa “lu ara wọn nínú ìdárò.” (Mát. 24:30) Ṣùgbọ́n kí ni àwọn arákùnrin Kristi àti àwọn olóòótọ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn máa ṣe nígbà yẹn? Torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, wọ́n á ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa fún wọn pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) A ò ní mikàn, torí ó dá wa lójú pé a máa là á já.

WỌ́N Á MÁA TÀN YÒÒ NÍNÚ ÌJỌBA NÁÀ

14, 15. Ìkójọpọ̀ wo ló máa wáyé lẹ́yìn tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run? Kí ni ìkójọpọ̀ náà?

14 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run? Ohun kan náà ni Mátíù àti Máàkù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Wọ́n ní: “[Ọmọ ènìyàn] yóò sì rán àwọn áńgẹ́lì jáde, yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ilẹ̀ ayé títí dé ìkángun ọ̀run.” (Máàkù 13:27; Mát. 24:31) Ìkójọpọ̀ wo ni Jésù ń sọ níbí? Kì í ṣe ìgbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ẹni àmì òróró jọ ló ń sọ, kì í sì í ṣe ìgbà tá a fi èdìdì ìkẹyìn di àwọn ẹni àmì òróró yòókù. (Mát. 13:37, 38) Kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀ ni èdìdì yẹn á ti wáyé. (Ìṣí. 7:1-4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń sọ nípa àkókò tí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa gba èrè wọn ní ọ̀run. (1 Tẹs. 4:15-17; Ìṣí. 14:1) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì máa wáyé lẹ́yìn tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìsík. 38:11) Lẹ́yìn náà ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí máa ṣẹ. Ó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.”Mát. 13:43. *

15 Ṣé ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé a máa “gba” àwọn ẹni àmì òróró “lọ” sí ọ̀run? Bí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò yìí ṣe yé ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sí nìyẹn. Wọ́n gbà pé a máa gba àwọn Kristẹni lọ sọ́run nínú ẹran ara. Àti pé lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ojúyòójú rí Jésù nígbà ìpadàbọ̀ rẹ̀ láti wá máa ṣàkóso ayé. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé “àmì Ọmọ ènìyàn” máa fara hàn ní ọ̀run, Jésù yóò sì máa bọ̀ “lórí àwọsánmà ọ̀run.” (Mát. 24:30) Ohun tí gbólóhùn méjèèjì yìí túmọ̀ sí ni pé a kò ní lè fi ojúyòójú rí Jésù. Ní àfikún sí ìyẹn, “ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run.” Torí náà, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ “yí” àwọn tá a máa mú lọ sọ́run “padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn.” * (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:50-53.) Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù ni a óò sì kó jọpọ̀ lójú ẹsẹ̀.

16, 17. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ kí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà tó wáyé ní ọ̀run?

16 Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] bá ti wà ní ọ̀run, ìmúrasílẹ̀ tó kẹ́yìn fún ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn lè wá bẹ̀rẹ̀. (Ìṣí. 19:9) Ṣùgbọ́n ohun mìíràn máa ṣẹlẹ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ yẹn tó wáyé. Rántí pé, kí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó lọ sí ọ̀run, Gọ́ọ̀gù máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìsík. 38:16) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ó máa dà bíi pé àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé kò ní olùgbèjà. Wọ́n máa ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn nígbà ayé Ọba Jèhóṣáfátì, pé: “Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín. Ìwọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà.” (2 Kíró. 20:17) Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́run? Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí gbogbo àwọn ẹni àmì òróró á ti wà ní ọ̀run, Ìṣípayá 17:14 sọ nípa ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run pé: “Àwọn wọ̀nyí yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, ṣùgbọ́n, nítorí pé òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀.” Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n máa bá a ṣàkóso ní ọ̀run máa wá láti gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé.

17 Èyí máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. Ogun yìí á sì gbé orúkọ mímọ́ Jèhófà ga. (Ìṣí. 16:16) Nígbà yẹn, gbogbo àwọn tó bá jẹ́ ewúrẹ́ máa “lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, gbogbo ìwà ibi á ti di àwátì, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá á sì la apá tó kẹ́yìn lára ìpọ́njú ńlá náà já. Lẹ́yìn tí gbogbo ìmúrasílẹ̀ bá ti parí, ìwé Ìṣípayá á wá dé ìparí rẹ̀, ìyẹn ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. (Ìṣí. 21:1-4) * Gbogbo àwọn tó la ìpọ́njú ńlá náà já lórí ilẹ̀ ayé á máa yọ̀ torí pé wọ́n rí ojúure Ọlọ́run, wọ́n sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ìfẹ́ tó fi hàn sí wọn. Àsè ìgbéyàwó yẹn á mà kàmàmà o! Ǹjẹ́ kò máa ṣe wá bíi pé kí ọjọ́ náà ti dé?—Ka 2 Pétérù 3:13.

18. Bá a ti ń fojú sọ́nà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá yìí, kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

18 Bá a ti ń fojú sọ́nà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá yìí, kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe báyìí? Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti kọ̀wé pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, . . . Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí, ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.” (2 Pét. 3:11, 12, 14) Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé a óò máa wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí, a ó sì máa ti Ọba Àlàáfíà náà lẹ́yìn.

^ ìpínrọ̀ 15 Àwọn ẹni àmì òróró tó wà láàyè kò ní gbé ara ìyára wọn lọ sí ọ̀run. (1 Kọ́r. 15:48, 49) Ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run palẹ̀ ara wọn mọ́ ní ọ̀nà kan náà tó gbà palẹ̀ òkú Jésù mọ́.

^ ìpínrọ̀ 17 Sáàmù 45 pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe máa wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ọba máa kọ́kọ́ jagun, lẹ́yìn yẹn ni ìgbéyàwó náà á wáyé.