Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ìbùkún Jèhófà Mú Kí Ìgbésí Ayé Mi Túbọ̀ Nítumọ̀

Ìbùkún Jèhófà Mú Kí Ìgbésí Ayé Mi Túbọ̀ Nítumọ̀

ỌDÚN 1927 ni wọ́n bí mi ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Wakaw, lágbègbè Saskatchewan ní orílẹ̀-èdè Kánádà. Ọmọ méje ni àwọn òbí mi bí, ọkùnrin mẹ́rin àti obìnrin mẹ́ta. Torí náà, mo mọ ohun tó túmọ̀ sí láti máa gbé láàárín àwọn èèyàn púpọ̀.

Nígbà tí Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1930 wáyé, tí ọrọ̀ ajé sì dẹnu kọlẹ̀, ìdílé wa náà mọ̀ ọ́n lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lówó lọ́wọ́, oúnjẹ ò wọ́n wa. À ń sin adìyẹ a sì tún ní màlúù kan, torí náà gbogbo ìgbà la máa ń ní ẹyin, wàrà, ọ̀rá wàrà, wàràkàṣì àti bọ́tà. Torí náà, gbogbo wa la ní iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tá à ń ṣe nílé.

Inú mi máa ń dùn tí mo bá ń rántí àwọn ọdún yẹn. Bí àpẹẹrẹ, bí òórùn dídùn èso ápù ṣe máa ń gba inú yàrá kan. Tí Dádì bá ti lọ ta àwọn irè oko nígboro nígbà ìwọ́wé ilẹ̀ Kánádà, wọ́n máa ń gbé ẹ̀kún àpótí ápù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ká wá sílé. Inú wa máa ń dùn torí gbogbo wa ń rí ápù jẹ lójoojúmọ́.

ÌDÍLÉ WA KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

Ọmọ ọdún mẹ́fà ni mí nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ wàásù fún àwọn òbí mi. Ọkùnrin ni àkọ́bí àwọn òbí mi tó ń jẹ́ Johnny, kété lẹ́yìn tí wọ́n bí i ló kú. Èyí sì ba àwọn òbí mi nínú jẹ́, wọ́n wá bi àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wa pé: “Ibo ni Johnny wà?” Àlùfáà náà sọ pé wọn ò tíì ṣe ìsàmì fún un, torí náà kò tíì lọ sọ́run, ṣùgbọ́n ó ṣì wà ní Limbo, ìyẹn ibi tí àwọn Kátólíìkì gbà pé àwọn ọmọdé tí kò tíì ṣèrìbọmi máa ń lọ lẹ́yìn tí wọ́n bá kú. Àlùfáà náà tún sọ fún àwọn òbí mi pé tí wọ́n bá fún òun lówó, òun á gbàdúrà fún Johnny kó lè ti Limbo kọjá lọ sọ́run. Tó bá jẹ́ ìwọ ni, báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára rẹ? Ọ̀rọ̀ náà dun àwọn òbí mi débi pé wọn ò bá àlùfáà náà sọ̀rọ̀ mọ́. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń ṣe kàyéfì nípa ibi tí Johnny wà.

Lọ́jọ́ kan, màmá mi rí ìwé pẹlẹbẹ kan tó ń jẹ́ Where Are the Dead? [Ibo Làwọn Òkú Wà?] tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Ó fìtara kàwé náà. Nígbà tí Dádì dé, tayọ̀tayọ̀ ni Mọ́mì fi sọ fún wọn pé: “Mo ti mọ ibi tí Johnny wà! Ó ń sùn lọ́wọ́ báyìí ni, ó máa jíǹde tó bá yá.” Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn ni Dádì ka ìwé náà tán. Ìtùnú ló jẹ́ fún Dádì àti Mọ́mì láti rí i nínú Bíbélì pé àwọn òkú ń sùn báyìí ni, wọ́n ṣì máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú.Oníw. 9:5, 10; Ìṣe 24:15.

Ohun tí wọ́n kà yìí yí ìgbésí ayé wa pa dà sí rere torí ó tù wá nínú ó sì mú ká láyọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn òbí mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ́n sì ń dara pọ̀ pẹ̀lú ìjọ tó wà ní Wakaw, tí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ukraine pọ̀ sí. Kò sì pẹ́ tí Mọ́mì àti Dádì fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sóde ẹ̀rí.

Kò pẹ́ sígbà yẹn tá a fi kó lọ sí Ẹkùn-ìpínlẹ̀ British Columbia, ìjọ tó wà níbẹ̀ sì gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Inú mi máa ń dùn tí mo bá ń rántí ìgbà tá à ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀ ṣáájú ìpàdé ọjọ́ Sunday. Ìfẹ́ tí gbogbo wa ní fún Jèhófà àti òtítọ́ Bíbélì ń pọ̀ sí i. Mò ń rí bí Jèhófà ṣe ń mú kí ìgbésí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀ àti bó ṣe ń bù kún wa.

Kò rọrùn fún wa nígbà yẹn láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a gbà gbọ́ torí pé ọmọdé ṣì ni wá. Àmọ́, ohun tó ràn wá lọ́wọ́ ni pé èmi àti àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Eva máa ń múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a máa lò lóde ẹ̀rí lóṣù yẹn sílẹ̀, àá sì wá ṣe é ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Ọ̀nà kan tó dára nìyẹn fún wa láti kọ́ bá a ṣe lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú máa ń tì wá. Mo mọrírì ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ wa láti máa wàásù.

Ohun kan tí mi ò jẹ́ gbàgbé nígbà tá a wà ní kékeré ni pé àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún máa ń dé sílé wa. Bí àpẹẹrẹ, inú wa máa ń dùn tí alábòójútó àyíká wa ìyẹn Arákùnrin Jack Nathan, bá wá bẹ ìjọ wa wò tó sì dé sílé wa. * A máa ń gbádùn àìmọye ìtàn tó ń sọ fún wa, bó sì ṣe máa ń gbóríyìn fún wa látọkàn wá ń jẹ́ kó wù wá láti máa fòótọ́ sin Jèhófà.

Mo máa ń ronú pé, “Tí mo bá dàgbà, mo fẹ́ dà bí Arákùnrin Nathan.” Mi ò mọ̀ nígbà yẹn pé ńṣe ni àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ ń múra mi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí màá fi ìgbésí ayé mi ṣe. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo pinnu láti sin Jèhófà. Ní ọdún 1942, èmi àti Eva ṣèrìbọmi.

ÌDÁNWÒ ÌGBÀGBỌ́

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn èèyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn gan-an. Omidan Scott, olùkọ́ wa kan tí kì í gba tẹlòmíì mọ́ tiẹ̀ dá àwọn àbúrò mi obìnrin méjì àti ọkùnrin kan dúró níléèwé, torí pé wọ́n kọ̀ láti kí àsíá. Ó wá pe tíṣà mi pé kó lé èmi náà kúrò níléèwé. Àmọ́ tíṣà mi sọ fún un pé, “Oníkálukú ló láǹfààní láti ṣe ohun tó wù ú lórílẹ̀-èdè yìí, a sì tún ní ẹ̀tọ́ láti má ṣe lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè.” Láìka bí Omidan Scott ṣe ń yọ olùkọ́ mi lẹ́nu sí, ó sọ ní ṣàkó pé, “Èmi ni màá pinnu ohun tí màá ṣe.”

Omidan Scott wá sọ fún un pé: “Rárá, ọwọ́ ẹ kọ́ ni ìpinnu yẹn wà. Màá fẹjọ́ ẹ sùn tó ò bá lé Melita kúrò níléèwé.” Tíṣà mi wá ṣàlàyé fún àwọn òbí mi pé òun ò ní fẹ́ kí iṣẹ́ bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́, torí náà kò sóhun tóun máa ṣe ju pé kí òun lé mi kúrò níléèwé, bí òun tiẹ̀ mọ̀ pé kò yẹ kí òun ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn òbí mi ra àwọn ìwé tá a lè máa fi kẹ́kọ̀ọ́ nílé. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tá a fi kó lọ sí nǹkan bíi kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n [32] síbi tá à ń gbé tẹ́lẹ̀, wọ́n sì gbà wá sí iléèwé míì níbẹ̀.

Ní àwọn ọdún tí ogun fi ń jà, wọ́n fòfin de àwọn ìwé wa; síbẹ̀, a ṣì ń fi Bíbélì wàásù láti ilé dé ilé. Torí náà, ó mọ́ wa lára láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nípa lílo Bíbélì nìkan. Èyí mú kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa, ká sì rí ìtìlẹ́yìn Jèhófà.

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ-KÍKÚN

Mo nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe irun lóge, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ mélòó kan torí ẹ̀

Nígbà tí èmi àti Eva parí iléèwé wa, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Mo ríṣẹ́ sí ilé ìtajà ńlá kan. Nígbà tó yá, mo kọ́ iṣẹ́ ìṣerunlóge fún oṣù mẹ́fà mo sì máa ń ṣe irun nílé. Mo wá ríṣẹ́ míì síbi tí wọ́n ti máa ń ṣe irun, ẹ̀ẹ̀mejì láàárín ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, mo sì máa ń kọ́ àwọn míì ní irun ṣíṣe lẹ́ẹ̀mejì lóṣù. Èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún mi láti máa rówó gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí mò ń ṣe.

Ní ọdún 1955, mo fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè “Ijọba Alayọ Iṣẹgun” tí wọ́n ṣe ní ìlú New York City, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ìlú Nuremberg lórílẹ̀-èdè Jámánì. Àmọ́ kí n tó lọ sí ìlú New York, mo rí Arákùnrin Nathan Knorr tó wá láti oríléeṣẹ́ wa. Òun àti ìyàwó rẹ̀ wá sí àpéjọ àgbègbè kan ní ìlú Vancouver lórílẹ̀-èdè Kánádà. Nígbà tí wọ́n wá sí àpéjọ yẹn, wọ́n ní kí n bá Arábìnrin Knorr ṣe irun. Nígbà tí Arákùnrin Knorr rí irun náà, inú rẹ̀ dùn gan-an ni, ó sì lóun fẹ́ rí mi. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, mo sọ fún un pé mo máa kọ́kọ́ dé ìlú New York kí n tó lọ sí orílẹ̀-èdè Jámánì. Ó wá sọ pé kí n wá ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Brooklyn fún ọjọ́ mẹ́sàn-án.

Ìrìn àjò yẹn ló yí ìgbésí ayé mi pa dà. Nígbà tí mo wà ní ìlú New York, mo pàdé ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Theodore (Ted) Jaracz. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ló bi mí pé, “Ṣé aṣáájú-ọ̀nà ni ẹ́?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbéèrè yẹn yà mí lẹ́nu, mo sọ fún un pé, “Rárá o.” Ìdáhùn yìí ta sí ọ̀rẹ́ mi LaVonne létí, ló bá ní, “Aṣáájú-ọ̀nà ni o!” Ọ̀rọ̀ náà rú Ted lójú, ló bá béèrè lọ́wọ́ LaVonne pé, “Ti ta ni kí n wá gbà gbọ́ nínú ẹ̀yin méjèèjì báyìí?” Mo ṣàlàyé fún un pé mo ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tẹ́lẹ̀ ó sì wù mí kí n pa dà bẹ̀rẹ̀ tí ń bá pa dà sílé láti àpéjọ náà.

ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ GAN-AN NÍNÚ TED

Ọdún 1925 ni wọ́n bí Ted ní ìlú Kentucky lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni nígbà tó ṣèrìbọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́nì kankan nínú ìdílé rẹ̀ tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́dún méjì lẹ́yìn náà. Bí iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún tó ṣe fún nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.

Nígbà tí Ted pé ọmọ ogún ọdún ní July ọdún 1946, ó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì keje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ní ìlú Cleveland, ìpínlẹ̀ Ohio lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, wọ́n ní kí Ted lọ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ẹ̀ka ní ilẹ̀ Ọsirélíà.

Ted wá sí àpéjọ tí wọ́n ṣe ní ìlú Nuremberg ní orílẹ̀-èdè Jámánì, a sì ráyè bára wa sọ̀rọ̀. Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra nìyẹn. Inú mi dùn pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni Ted ń fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn. Ó máa ń fọkàn sí nǹkan, kì í fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú nǹkan, síbẹ̀ ó lọ́yàyà ó sì ń kóni mọ́ra. Mo mọ̀ pé ire àwọn ẹlòmíì ló máa ń fi ṣáájú tiẹ̀. Lẹ́yìn tí àpéjọ náà parí, Ted pa dà sí Ọsirélíà, èmi náà sì pa dà sí Vancouver, ṣùgbọ́n à ń kọ lẹ́tà síra wa.

Lẹ́yìn tí Ted ti lo nǹkan bí ọdún márùn-ún ní ilẹ̀ Ọsirélíà, ó pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sì wá ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Vancouver. Inú mi dùn gan-an pé ìdílé mi fẹ́ràn Ted. Ẹ̀gbọ́n mi tó ń jẹ́ Michael máa ń ṣọ́ mi gan-an, pàápàá tó bá kíyè sí i pé ọkùnrin èyíkéyìí fẹ́ràn mi. Àmọ́, Michael gba ti Ted, ó wá sọ fún mi pé, “Melita, ọkùnrin tó dá a lo rí yìí o. O jẹ́ tọ́jú ẹ̀ dáadáa kó má bàa bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́.”

Lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó lọ́dún 1956, a jọ gbádùn iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún fún ọ̀pọ̀ ọdún

Ìfẹ́ Ted ti wá gbà mí lọ́kàn. A ṣègbéyàwó ní December 10 ọdún 1956. A jọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Vancouver, lẹ́yìn náà a lọ sí ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, látibẹ̀ wọ́n ní kí Ted lọ máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ní ìpínlẹ̀ Missouri àti Arkansas. Fún nǹkan bí ọdún méjìdínlógún [18] tá a fi wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ilé tá à ń gbé ń yí pa dà. A ní ìrírí tó lárinrin lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó gbé wa dé ibi tó pọ̀ jù lọ lórílẹ̀-èdè náà, a sì máa ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti máa ṣí kúrò láti ibì kan sí ibòmíràn, a gbádùn iṣẹ́ arìnrìn-àjò wa gan-an.

Ted ò fi àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jèhófà ṣeré rárá, ohun tí mo sì fẹ́ràn jù lára ẹ̀ nìyẹn. Ó mọyì iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe fún Jèhófà Ẹni tó ga jù lágbàáyé. A fẹ́ràn láti máa jùmọ̀ ka Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde wa. Ká tó sùn lálẹ́, àwa méjèèjì á kúnlẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì, Ted á wá gbàdúrà. Lẹ́yìn ìyẹn, àwa méjèèjì á tún wá dá gbàdúrà. Mo máa ń mọ̀ tí ọ̀rọ̀ kan bá ń jẹ Ted lọ́kàn. Ó máa bọ́ọ́lẹ̀ lórí bẹ́ẹ̀dì, á kúnlẹ̀, á sì wá gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ fún àkókò gígùn. Inú mi máa ń dùn bó ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà lórí gbogbo nǹkan.

Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tá a ṣègbéyàwó, Ted ṣàlàyé fún mi pé òun máa bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Ó sọ fún mi pé: “Mo ti gbàdúrà kíkankíkan lórí ọ̀rọ̀ yìí kó lè dá mi lójú pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni mo ṣe.” Kò yà mí lẹ́nu pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín Ọlọ́run fẹ̀mí yan Ted láti wá sìn lọ́run. Mo kà á sí àǹfààní láti máa ṣètìlẹ́yìn fún ọ̀kan lára àwọn arákùnrin Kristi.Mát. 25:35-40.

MO NÍ ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN MÍÌ

Lọ́dún 1974, ó yà wá lẹ́nu pé wọ́n ní kí Ted wá di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ní ká wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Brooklyn. Bí Ted ṣe ń bójú tó ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, èmi ń ṣiṣẹ́ ìtọ́jú ilé tàbí kí n ṣiṣẹ́ níbi ìṣerunlóge.

Ọ̀kan lára iṣẹ́ tí Ted ń ṣe ni pé ó máa ń lọ ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà káàkiri àgbáyé. Inú rẹ̀ máa ń dùn láti rí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń tẹ̀ síwájú pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Nígbà kan tó pọn dandan pé ká lọ fára ní ìsinmi, tá a sì pinnu láti lọ sí orílẹ̀-èdè Sweden, Ted sọ fún mi pé: “Melita, ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa ní orílẹ̀-èdè Poland, mo sì fẹ́ lọ ran àwọn ará tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́.” Torí náà, a gbàwé àṣẹ ìwọ̀lú, a sì lọ sí orílẹ̀-èdè Poland. Ted àti àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè yẹn rìn lọ sí ibi tó jìnnà kí ẹnikẹ́ni má bàa gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Ọjọ́ mẹ́rin gbáko ni wọ́n fi jọ ṣèpàdé, inú Ted dùn pé òun ran àwọn ará yìí lọ́wọ́, èyí sì fún mi láyọ̀.

A tún pa dà lọ sí Poland ní oṣù November ọdún 1977. Ìgbà yẹn ni Arákùnrin F. W. Franz, Daniel Sydlik àti Ted ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè yẹn fún ìgbà àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ṣì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bá àwọn alábòójútó, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àti àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti pẹ́ nínú òtítọ́ sọ̀rọ̀ ní ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ted àtàwọn míì rèé ní Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ nílùú Moscow lẹ́yìn tí ìjọba fún wa láṣẹ láti máa bá iṣẹ́ wa lọ

Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, Milton Henschel àti Ted tún ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Poland, wọ́n sì bá àwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀, ní báyìí wọ́n ti ń fàyè gbà wá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Lọ́dún 1982, ìjọba orílẹ̀-èdè Poland gba àwọn ará láyè láti ṣe àpéjọ ọlọ́jọ́ kan. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ṣe àwọn àpéjọ tó tún tóbi jùyẹn lọ, gbọ̀ngàn tí wọ́n háyà ni wọ́n ti ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú wọn. Lọ́dún 1985, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì lómìnira láti máa wàásù, ìjọba gbà pé ká ṣe àpéjọ àgbègbè mẹ́rin ní àwọn pápá ìṣeré ńlá. Ní oṣù May ọdún 1989, bá a ṣe ń ṣètò àwọn àpéjọ míì tó tún tóbi, ìjọba orílẹ̀-èdè Poland mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ wa kúrò. Inú Ted dùn gan-an nítorí àwọn àṣeyọrí yìí.

Àpéjọ àgbègbè ní orílẹ̀-èdè Poland

TED FARA DA ÀÌSÀN

Ní ọdún 2007, à ń lọ síbi ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì kan ní orílẹ̀-èdè South Africa. Àmọ́ ní orílẹ̀-èdè England, ìfúnpá Ted bẹ̀rẹ̀ sí í ga, torí náà dókítà sọ pé ká sún ìrìn-àjò wa síwájú. Nígbà tí ara Ted balẹ̀ díẹ̀, a pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, Ted ní àrùn rọpárọsẹ̀ tó le gan-an, bí ò ṣe lè gbé apá àti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ mọ́ nìyẹn.

Ara Ted ò tètè yá, kò sì lè lọ síbi iṣẹ́ ní gbogbo ìgbà yẹn. A dúpẹ́ pé àrùn náà kò pa ohùn rẹ̀ lára. Láìka bí àìsàn yẹn ṣe le tó, Ted ṣì máa ń gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun tó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kódà látinú yàrá wa, ó máa ń lóhùn sí ìpàdé tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Ted mọrírì ìtọ́jú tí wọ́n fún un nílé ìwòsàn wa ní Bẹ́tẹ́lì gan-an. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rìn pa dà. Ó máa ń ṣe púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un, ó sì máa ń gbìyànjú láti ṣọ̀yàyà sí gbogbo èèyàn.

Ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn, Ted tún ní àrùn rọpárọsẹ̀, ó wá kú ní Wednesday, June 9, ọdún 2010. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé lọ́jọ́ kan Ted máa parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, síbẹ̀ mi ò lè ṣàlàyé bí ikú rẹ̀ ṣe dùn mí tó, ṣe ló dà bíi pé kí n ṣì máa rí i. Síbẹ̀, ojoojúmọ́ ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìtìlẹ́yìn tí mo fún Ted. Àwa méjèèjì ti jọ gbádùn iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún fún ohun tó ju ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta [53] lọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé Ted ti ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Baba mi ọ̀run. Mo mọ̀ pé iṣẹ́ tuntun tó ní báyìí á ṣì máa fún un láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.

BÍ MO ṢE Ń KOJÚ ÀWỌN ÌṢÒRO TÓ Ń YỌJÚ

Inú mi máa ń dùn púpọ̀ láti ṣiṣẹ́ kí n sì fún àwọn míì ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ níbi ìṣerunlóge ní Bẹ́tẹ́lì

Lẹ́yìn tí mo ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣiṣẹ́ takuntakun pẹ̀lú ọkọ mi tí mo sì ń láyọ̀, kò rọrùn láti kojú àwọn ìṣòro tó ń yọjú. Èmi àti Ted kì í fojú pa àlejò rẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì àti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Nísinsìnyí tí Ted ò sí mọ́, tí ara mi ò sì le bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ìwọ̀nba ni nǹkan tí mo lè ṣe. Síbẹ̀, mo ṣì máa ń gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn ará ní Bẹ́tẹ́lì àti nínú ìjọ. Iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì kò rọrùn àmọ́, inú mi dùn pé mo láǹfààní láti sin Jèhófà lọ́nà yìí. Síbẹ̀ ìfẹ́ tí mo ní fún iṣẹ́ ìwàásù kò dín kù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ mí, ó sì máa ń ṣòro fún mi láti dìde dúró, inú mi máa ń dùn tí mo bá ń jẹ́rìí ní òpópónà tí mo sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Tí mo bá ń ronú lórí gbogbo ohun burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lónìí, inú mi máa ń dùn pé èmi àti Ted ọkọ mi àtàtà la jọ ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà! Mo gbà lóòótọ́ pé ìbùkún Jèhófà ti mú kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ nítumọ̀.Òwe 10:22.

^ ìpínrọ̀ 13 Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Jack Nathan wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1990, ojú ìwé 10 sí 14.