Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI ÈRÒ ỌLỌ́RUN NÍPA OGUN?

Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Láyé Ìgbàanì

Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Láyé Ìgbàanì

Àwọn ọmọ Íjíbítì jẹ́ orílẹ̀-èdè alágbára, wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run. Ìyà náà pọ̀ débi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dá àwọn nídè, àmọ́ Ọlọ́run kò dáhùn àdúrà wọn lójú ẹsẹ̀. (Ẹ́kísódù 1:13, 14) Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń rétí pé kí Ọlọ́run gba àwọn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íjíbítì tó ń fìtínà wọn. Nígbà tó yá, àkókò tó lójú Ọlọ́run láti gbèjà wọn. (Ẹ́kísódù 3:7-10) Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló bá àwọn ọmọ Íjíbítì jagun. Ó fi onírúurú àjálù kọ lu àwọn ọmọ Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, ó mú kí ọba Íjíbítì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣègbé sínú Òkun Pupa. (Sáàmù 136:15) Jèhófà Ọlọ́run fi hàn pé òun jẹ́ “akin lójú ogun” nítorí àwọn èèyàn rẹ̀.Ẹ́kísódù 15:3, 4.

Bí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe bá àwọn ọmọ Íjíbítì jagun fi hàn pé àwọn ogun kan wà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. Láwọn ìgbà kan, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n lọ jagun. Bí àpẹẹrẹ, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n bá àwọn ará Kénáánì jagun, torí pé wọ́n ya ìkà lẹ́dàá. (Diutarónómì 9:5; 20:17, 18) Ó tún sọ fún Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì pé kó lọ bá àwọn Filísínì jagun. Kódà, Ọlọ́run kọ́ Dáfídì ní ọgbọ́n tó máa fi ṣẹ́gun wọn.2 Sámúẹ́lì 5:17-25.

Àwọn ìtàn Bíbélì yìí fi hàn pé bí ìyà tàbí ìnira èyíkéyìí bá dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run máa ń fọwọ́ sí i pé kí wọ́n lọ jagun kó lè dáàbò bò wọ́n, kí ìjọsìn tòótọ́ má sì pa run. Àmọ́, kíyè sí àwọn kókó mẹ́ta yìí nínú àwọn ogun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí.

  1. ỌLỌ́RUN NÌKAN LÓ Ń PINNU ÀWỌN TÓ MÁA LỌ JAGUN. Nígbà kan, Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí.” Kí nìdí? Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló máa jà fún wọn. (2 Kíróníkà 20:17; 32:7, 8) Bá a ṣe mẹ́nu kàn-án níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì ni Ọlọ́run jà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Láwọn ìgbà míì, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ja ogun tó fọwọ́ sí. Lára irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ ni èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú bí wọ́n ṣe máa gba Ilẹ̀ Ìlérí àti bí wọ́n ṣe máa dáàbò bo ilẹ̀ náà.Diutarónómì 7:1, 2; Jóṣúà 10:40.

  2. ỌLỌ́RUN NÌKAN LÓ Ń PINNU ÌGBÀ TÍ OGUN MÁA JÀ. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti dúró de àsìkò tí Ọlọ́run bá ni kí wọ́n lọ bá àwọn èèyànkéèyàn tó yí wọn ká jagun. Tí Ọlọ́run kò bá sọ fún wọn pé ó yá, wọn kì í lọ sójú ogun. Tí wọ́n bá wá kù gìrì lọ sojú ogun, Ọlọ́run kì í tì wọ́n lẹ́yìn. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà kan tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ ja ogun tí Ọlọ́run kò rán wọn, àbájáde rẹ̀ kò dáa rárá. *

  3. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run gbógun ja àwọn ọmọ Kénáánì, ó dá àwọn kan sí, bíi Ráhábù àti ìdílé rẹ̀

    ỌLỌ́RUN KÒ FẸ́ IKÚ ẸNIKẸ́NI, TÍTÍ KAN ÀWỌN ẸNI BURÚKÚ. Jèhófà Ọlọ́run ló fún wa lẹ́mìí torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. (Sáàmù 36:9) Torí náà, kò fẹ́ kí àwa èèyàn máa kú. Àmọ́, ó dunni pé àwọn kan ti jingíri sínú ìwà ìkà débi pé wọ́n máa ń pa àwọn ẹlòmíì. (Sáàmù 37:12, 14) Kí Ọlọ́run lè dáwọ́ irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ dúró, ó fọwọ́ sí i pé kí àwọn èèyàn rẹ̀ gbógun ti àwọn ẹni ibi yẹn. Síbẹ̀, ní gbogbo ìgbà tí Ọlọ́run lo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti jagun, ó ṣì máa ń fi hàn pé òun jẹ́ “aláàánú” àti ẹni “tí ń lọ́ra láti bínú” sí àwọn ọ̀tá tó ń gbógun ti àwọn èèyàn rẹ̀. (Sáàmù 86:15) A rí àpẹẹrẹ kan nínú òfin tó fún wọn pé kí wọ́n tó gbógun ja ìlú kan, kí wọ́n kọ́kọ́ “fi ọ̀rọ̀ àlàáfíà lọ̀ ọ́,” kí àwọn aráàlú náà lè láǹfààní láti yíwà pa dà, kí wọ́n má báa bógun lọ. (Diutarónómì 20:10-13) Ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run gbà fi hàn pé òun “kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó.”Ìsíkíẹ́lì 33:11, 14-16. *

Àwọn àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé láyé ìgbàanì, Ọlọ́run máa ń lo ogun láti fòpin sí ìwà burúkú táwọn ẹni ibi ń hù. Ọlọ́run nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ìgbà tí ogun máa wáyé àtàwọn tó máa ja ogun náà, kì í ṣe àwọn èèyàn. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé arógunyọ̀ ni Ọlọ́run, tó kàn ń pa èèyàn bí ẹni pa ẹran? Rárá o. Ọlọ́run kórìíra ìwà ipá. (Sáàmù 11:5) Ǹjẹ́ èrò tí Ọlọ́run ní nípa ogun wá yí pa dà nígbà tí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ wá sáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

^ ìpínrọ̀ 7 Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí àwọn ọmọ Ámálékì àtàwọn ọmọ Kénáánì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ lọ ja ogun náà. (Númérì 14:41-45) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn èyí, Jòsáyà Ọba kù gìrì lọ sójú ogun tí Ọlọ́run kò fọwọ́ sí, ó sì bá ogun náà lọ.2 Kíróníkà 35:20-24.

^ ìpínrọ̀ 8 Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi fọ̀rọ̀ àlàáfíà lọ àwọn ọmọ Kénáánì kí wọ́n tó gbógun jà wọ́n? Ìdí ni pé irinwó [400] ọdún ni Ọlọ́run fi yọ̀ǹda fún àwọn ọmọ Kénáánì láti jáwọ́ nínú àwọn ìwàkiwà wọn. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi máa gbógun dé, àwọn ọmọ Kénáánì yìí ti jingíri sínú ìwà burúkú wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 15:13-16) Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi pàṣẹ pé kí wọ́n pa wọ́n run pátápátá. Àmọ́, àwọn ọmọ Kénáánì kan ronú pìwà dà, wọ́n sì dá wọn sí.Jóṣúà 6:25; 9:3-27.