Ǹjẹ́ O “Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ara Rẹ”?
“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”
ORIN: 73, 36
1, 2. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó?
ÌFẸ́ ni olórí ànímọ́ Jèhófà Ọlọ́run. (1 Jòh. 4:16) Jésù ni Jèhófà kọ́kọ́ dá, ó sì ti wà pẹ̀lú Ọlọ́run fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún, torí náà ó ti ní láti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ ṣe nǹkan. (Kól. 1:15) Nínú gbogbo ohun tí Jésù ń ṣe títí kan ìgbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun mọ Jèhófà sí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, òun náà sì ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Torí náà, ó dá wa lójú pé ìfẹ́ ni Jèhófà àti Jésù máa fi ṣàkóso wa títí láé.
2 Nígbà tí ẹnì kan bi Jésù pé èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin, Jésù sọ fún un pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’”
3. Ta ni “aládùúgbò” wa?
3 Kíyè sí i pé Jésù ní ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. Èyí jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fìfẹ́
hàn sí gbogbo èèyàn. Àmọ́, ta ni “aládùúgbò” wa? Tó o bá ti ṣègbéyàwó, ọkọ tàbí aya rẹ ni aládùúgbò rẹ tó sún mọ́ ẹ jù lọ. Àwọn aládùúgbò wa tó tún sún mọ́ wa ni àwọn tá a jọ ń sin Ọlọ́run tòótọ́. Àwọn aládùúgbò wa míì tún ni àwọn tá à ń wàásù fún. Báwo ló ṣe yẹ kí àwa tá à ń sin Jèhófà tá a sì ń fi ẹ̀kọ́ Jésù sílò máa fìfẹ́ hàn sáwọn aládùúgbò wa?NÍFẸ̀Ẹ́ ỌKỌ TÀBÍ AYA RẸ
4. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, kí ló lè mú kí ìgbéyàwó wa yọrí sí rere?
4 Jèhófà ló dá Ádámù àti Éfà, ó sì so wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Ó fẹ́ kí wọ́n láyọ̀, kí ìgbéyàwó wọn wà pẹ́ títí, kí wọ́n sì fi ọmọ kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:
5. Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé kí tọkọtaya máa fìfẹ́ hàn síra wọn?
5 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ká sì máa láyọ̀. Bó ṣe rí nínú ìgbéyàwó náà nìyẹn. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Kọ́r. 13:
6, 7. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa ipò orí? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ máa ṣe sí ìyàwó rẹ̀?
6 Ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an nínú ètò Ọlọ́run torí pé ìlànà ipò orí là ń tẹ̀ lé. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni 1 Kọ́r. 11:3) Àmọ́, kò yẹ káwọn tó wà ní ipò orí jẹ́ apàṣẹwàá. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà tó jẹ́ orí fún Kristi jẹ́ onínúure, kì í sì í ṣe onímọtara ẹni nìkan, ìyẹn sì mú kí Jésù bọ̀wọ̀ fún Baba rẹ̀. Ó mọyì bí Ọlọ́run ṣe ń lo ipò orí rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòh. 14:31) Ó dájú pé Jésù ò ní sọ ohun tó sọ yìí ká ní Jèhófà ti sọ ara rẹ̀ di apàṣẹwàá tàbí tó ń le koko mọ́ Jésù.
Ọlọ́run.” (7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ ni orí aya, Bíbélì sọ pé kí àwọn ọkọ máa “fi ọlá fún” àwọn aya wọn. (1 Pét. 3:7) Ọ̀kan lára ọ̀nà táwọn ọkọ lè gbà bọlá fún àwọn aya wọn ni pé kí wọ́n mọ ohun tí aya wọn nílò kí wọ́n sì máa gba tiwọn rò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfé. 5:25) Kódà, Jésù fẹ́ràn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ débi pé ó kú fún wọn. Tí ọkọ kan bá ń fìfẹ́ lo ipò orí rẹ̀ bí Jésù ti ṣe, ó máa túbọ̀ rọrùn fún aya rẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un, kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó sì tẹrí ba fún un.
NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ
8. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn ará wa?
8 Kárí ayé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń kéde orúkọ Jèhófà, tí wọ́n sì ń sọ ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fáwọn èèyàn. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10; ka Róòmù 12:10.) Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ gaara nípa ìgbọràn yín sí òtítọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.” Ó tún sọ pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”
9, 10. Kí ló mú kí àwa èèyàn Ọlọ́run wà ní ìṣọ̀kan?
9 Ètò Jèhófà ṣàrà ọ̀tọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sáwọn tá a jọ jẹ́ ará. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà a sì ń ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀, ó ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Èyí ló mú kí gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé wà ní ìṣọ̀kan.
10 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwa Kristẹni nífẹ̀ẹ́ ara wa, ó ní: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:
11. Kí la fi ń dá ètò Jèhófà mọ̀?
11 Ojúlówó ìfẹ́ táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa fi hàn pé àwa là ń ṣe ìjọsìn tòótọ́. Èyí sì bá ohun tí Jésù sọ mu pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:
KÍKÓ “OGUNLỌ́GỌ̀ ŃLÁ” JỌ
12, 13. Kí ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà ń ṣe báyìí? Kí ni Jèhófà máa ṣe fún wọn láìpẹ́?
12 Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n. Wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ [Ọlọ́run] àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù Kristi].” Ta ni wọ́n? “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n sì ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” torí pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” yìí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, “wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.”
13 Láìpẹ́, Ọlọ́run máa pa ayé búburú yìí run nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Mát. 24:21; ka Jeremáyà 25:
14. Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe pọ̀ tó báyìí?
14 Nígbà tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, iye àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà jákèjádò ayé ò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ. Torí ìfẹ́ tí wọ́n ní sáwọn èèyàn àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láìka àtakò sí. Ní báyìí, wọ́n ń kó ogunlọ́gọ̀ ńlá tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé jọ. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́fà ó lé irínwó [115,400] sì ti tó mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000] jákèjádò ayé. A sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ṣèrìbọmi lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2014 lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́tàlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [275,500], tó túmọ̀ sí pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ọ̀ọ́dúnrún lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún [5,300] èèyàn ló ń ṣèrìbọmi.
15. Kí ló ń mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lónìí?
15 Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti rí iye àwọn tó ń gbọ́ ìwàásù wa. Àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì ti wà ní èdè tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700]. Ilé Ìṣọ́ ni ìwé ìròyìn tí ìpínkiri rẹ̀ gbòòrò jù lọ láyé. Ilé Ìṣọ́ tá à ń tẹ̀ lóṣooṣù lé ní mílíọ̀nù méjìléláàádọ́ta [52,000,000], èdè tá a fi ń tẹ̀ ẹ́ sì jẹ́ igba àti mẹ́tàdínláàádọ́ta [247]. Ẹ̀dà ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tó lé ní igba mílíọ̀nù [200,000,000] la ti tẹ̀ jáde lédè tó ju àádọ́talénígba [250].
16. Kí ló ń mú kí ètò Jèhófà máa gbèrú sí i lójoojúmọ́?
16 Ètò Ọlọ́run ń gbèrú sí i nítorí pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, a sì gba Bíbélì gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí. (1 Tẹs. 2:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” kórìíra wa tó sì ń ta kò wá, síbẹ̀ Jèhófà ń bù kún wa.
Ẹ MÁA NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN
17, 18. Báwo ló ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
17 Báwo ló ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn tí kò jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́? Lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, onírúurú èèyàn la máa ń bá pàdé, àwọn kan máa ń gbọ́ ìwàásù wa àwọn míì kì í fẹ́ gbọ́ rárá. Àmọ́, yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó yẹ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ṣe, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kól. 4:6) Nígbàkigbà tá a bá ń gbèjà ìhìn rere níwájú ẹnikẹ́ni tó bá ń béèrè ìdí tá a fi ní ìrètí, ẹ jẹ́ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ “pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa.
18 Kódà tí àwọn tá à ń wàásù fún bá kọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere tàbí tí wọ́n bá fìbínú sọ̀rọ̀ sí wa, ìyẹn ò ní ká má fìfẹ́ hàn sí wọn. Lọ́nà yìí, à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni [Jèhófà] tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pét. 2:23) Yálà a wà pẹ̀lú àwọn ará wa tàbí a wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ó yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká sì máa fi ìmọ̀ràn yìí sílò pé: “Kí ẹ má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre.”
19. Ìlànà wo ni Jésù fún wa nípa àwọn tí ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa?
19 Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa máa ń mú ká tẹ̀ lé ìlànà pàtàkì tí Jésù fún wa. Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, níwọ̀n bí ó ti ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mát. 5:
20. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò máa gbilẹ̀ nínú ayé tuntun? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
20 Nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ máa fi hàn nínú ìwà àti ìṣe pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn kan ò bá tiẹ̀ fetí sí ìwàásù wa, ìyẹn ò ní ká má ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ẹ má ṣe máa jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ẹyọ ohun kan, àyàfi láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; nítorí ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ ti mú òfin ṣẹ. Nítorí àkójọ òfin náà, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò,’ àti àṣẹ mìíràn yòówù kí ó wà, ni a ṣàkópọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yìí, èyíinì ni, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí aládùúgbò ẹni; nítorí náà, ìfẹ́ ni ìmúṣẹ òfin.” (Róòmù 13: