Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe àkájọ ìwé, báwo sì ni wọ́n ṣe ń lò ó?

Àkájọ ìwé Ẹ́sítérì tí wọ́n fi awọ ṣe ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún kejìdínlógún

Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé Jésù ṣí àkájọ ìwé Aísáyà, ó sì ká àkájọ ìwé náà pa dà lẹ́yìn tó ka ohun tó wà nínú rẹ̀. Jòhánù sọ lọ́wọ́ ìparí ìwé Ìhìn Rere rẹ̀ pé, gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe kò lè gba inú àkájọ ìwé tí òun kọ.—Lúùkù 4:16-20; Jòhánù 20:30; 21:25.

Báwo ni wọ́n ṣe máa ń ṣe àkájọ ìwé? Awọ tàbí òrépèté ni wọ́n fi ń ṣe àkájọ ìwé, wọ́n á lẹ̀ ẹ́ pọ̀ léteetí títí táá fi gùn. Wọ́n á wá ká a mọ́ ara ọ̀pá kékeré kan, wọ́n á sì kọ ojú ibi tọ́rọ̀ wà sínú. Àárín àwọn ilà gbọọrọ tí wọ́n fà sórí ìwé náà ni wọ́n máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí. Tí àkájọ ìwé náà bá gùn jù, wọ́n á fi ọ̀pá sí ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ìwé náà. Ẹni tó bá fẹ́ kà á máa fi ọwọ́ kan tú u, á sì máa fi ọwọ́ kejì ká a pa dà títí táá fi débi tó ń wá.

Ìwé náà, The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Àǹfààní tó wà nínú àkájọ ìwé ni pé tó bá gùn dáadáa (bíi mítà mẹ́wàá), ó lè gba ohun tó wà nínú ìwé ńlá kan.” Wọ́n fojú bù ú pé àkájọ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù máa gùn tó mítà mẹ́sàn-án ààbọ̀. Láwọn ìgbà míì, wọ́n máa ń gé eteetí àwọn àkájọ ìwé kan, wọ́n á fi òkúta há eteetí yìí kó lè dán, wọ́n á sì pa á láró.

Àwọn wo ló ṣeé ṣe kó wà lára “àwọn olórí àlùfáà” tá a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì?

Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ọkùnrin kan ṣoṣo ló máa ń ṣiṣẹ́ àlùfáà àgbà. Ẹni yìí ló sì máa wà ní ipò yẹn títí tó fi máa kú. (Númérì 35:25) Áárónì ló kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ àlùfáà àgbà. Nígbà tí àlùfáà àgbà bá kú, ọmọkùnrin rẹ̀ tó jẹ́ àkọ́bí ló máa rọ́pò rẹ̀. (Ẹ́kísódù 29:⁠9) Ọ̀pọ̀ lára àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì lọ́kùnrin ló máa ń ṣiṣẹ́ àlùfáà, ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ló di àlùfáà àgbà.

Nígbà táwọn orílẹ̀-èdè mí ì ń ṣàkóso àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn alákòóso ló máa ń yan àwọn àlùfáà àgbà sípò, tí wọ́n á sì tún yọ wọ́n nígbà tí wọ́n bá fẹ́. Wọ́n sábà máa ń yan àwọn tó wá látinú ìdílé tó lẹ́nu láwùjọ, ní pàtàkì láti ìlà ìdílé Áárónì. Àwọn tí wọ́n yàn sínú ẹgbẹ́ “àwọn olórí àlùfáà” ni àwọn tó jẹ́ abẹnugan lára àwọn àlùfáà. Àwọn tó ṣeé ṣe kó wà nínú ẹgbẹ́ àwọn olórí àlùfáà ni àwọn tó jẹ́ olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpín mẹ́rìnlélógún [24] tí wọ́n pín ìdílé àwọn àlùfáà sí, tàbí àwọn tó jẹ́ òléwájú lára ìdílé àlùfáà àgbà, àtàwọn tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ àlùfáà àgbà, irú bí Ánásì.​—1 Kíróníkà 24:1-19; Mátíù 2:4; Máàkù 8:31; Ìṣe 4:6.