Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | NÍGBÀ TÍ ẸNI TÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ BÁ KÚ

Àwọn Òkú Máa Jíǹde!

Àwọn Òkú Máa Jíǹde!

Ṣé o rántí Gail tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó ń rò ó pé bóyá ni òun máa lè gbé ikú ọkọ òun kúrò lọ́kàn. Àmọ́, ó ń retí ọjọ́ tó máa rí Rob ọkọ rẹ̀ nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Gail sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì tí mo fẹ́ràn jù ni Ìṣípayá 21:3, 4.” Ó kà pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Gail sọ pé: “Ìlérí yìí tuni nínú. Mo káàánú àwọn kan tí èèyàn wọn ti kú, àmọ́ tí wọn kò mọ̀ pé àwọn ṣì tún lè rí wọn pa dà nígbà àjíǹde.” Gail wá ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú ohun tó gbà gbọ́, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. Ó ń sọ ìlérí Ọlọ́run fún àwọn aládùúgbò rẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú kan tí ‘ikú kì yóò sí mọ́.’

Ó dá Jóòbù lójú pé òun máa jíǹde

Ó ṣeé ṣe kí èyí yà ẹ́ lẹ́nu! Ṣùgbọ́n jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù yẹ̀ wò. Àìsàn burúkú kan kọ lù ú. (Jóòbù 2:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ronú pé ó sàn kí òun kú, síbẹ̀ ó ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run lágbára láti jí òun dìde pa dà sí ayé. Ó fi ìdánilójú sọ pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù [Sàréè] . . . Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:13, 15) Ó dá Jóòbù lójú pé Ọlọ́run kò ní gbàgbé òun, á sì fẹ́ láti jí òun dìde.

Láìpẹ́, Ọlọ́run máa jí Jóòbù àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì dìde, nígbà tó bá sọ ayé yìí di Párádísè. (Lúùkù 23:42, 43) Bíbélì mú un dá wa lójú nínú ìwé Ìṣe 24:15 pé: “Àjíǹde . . . yóò wà.” Jésù fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Jóòbù máa rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí wọ̀nyẹn. Nígbà tó bá rí i pé òun pa dà ní “okun inú ti ìgbà èwe” tí “ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe.” (Jóòbù 33:24, 25) Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tó bá fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè fún wa, ìyẹn ni bó ṣe máa jí àwọn òkú dìde pa dà sí ayé.

Tí ìwọ náà bá ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn rẹ kan tó kú, àwọn ohun tá a ti jíròrò yìí lè má gbé ìbànújẹ́ náà kúrò lọ́kàn rẹ pátápátá. Àmọ́ tó o bá ń ronú lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì, wà á nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, wàá sì lókun láti máa fara dà á nìṣó.—1 Tẹsalóníkà 4:13.

Ṣé wà á fẹ́ mọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè fara da ìbànújẹ́? Tàbí o ní àwọn ìbéèrè míì tó fara pẹ́ ẹ, irú bí “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi àti ìjìyà?” Jọ̀ọ́ lọ sórí ìkànnì wa, www.pr418.com/yo, kó o sì rí bí Bíbélì ṣe fún wa ní ìdáhùn tó tuni nínú, tó sì gbéṣẹ́ lónìí.