Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ta ni bàbá Jósẹ́fù?

Jósẹ́fù tó jẹ́ káfíńtà nílùú Násárétì ni bàbá tó gba Jésù tọ́. Àmọ́, ta ni bàbá Jósẹ́fù? Ìlà ìdílé Jésù, bó ṣe wà nínú ìwé Ìhìn Rere Mátíù fi hàn pé Jékọ́bù ni bàbá Jósẹ́fù, ṣùgbọ́n Lúùkù sọ pé Jósẹ́fù jẹ́ “ọmọkùnrin Hélì.” Kí ló fa ìyàtọ̀ yìí?—Lúùkù 3:23; Mátíù 1:16.

Àkọsílẹ̀ Mátíù kà pé: “Jékọ́bù Jósẹ́fù.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níbí jẹ́ ká mọ̀ pé Jékọ́bù ni bàbá tó bí Jósẹ́fù. Torí náà, Mátíù to ìlà ìdílé Jósẹ́fù, ìyẹn ìlà ìdílé Dáfídì ọba. Ìlà ìdílé yìí ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tí ọba tọ́ sí, èyí fi hàn pé ọba tọ́ sí Jésù tí Jósẹ́fù gbà ṣọmọ.

Lọ́wọ́ kejì, àkọsílẹ̀ Lúùkù pé Jósẹ́fù ní “ọmọkùnrin Hélì.” Ọ̀rọ̀ náà, “ọmọkùnrin,” tún lè túmọ̀ sí “ọkọ ọmọ.” Ohun tó fara jọ èyí wà nínú Lúùkù 3:27, níbi tó ti pe Ṣéálítíẹ́lì ní “ọmọkùnrin Nẹ́rì,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jekonáyà ni bàbá rẹ̀. (1 Kíróníkà 3:17; Mátíù 1:12) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ṣéálítíẹ́lì fẹ́ ọmọbìnrin Nẹ́rì tí a kò dárúkọ, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọkọ ọmọ Nẹ́rì. Irú ọ̀nà yìí ni Jósẹ́fù gbà jẹ́ “ọmọkùnrin” Hélì, torí pé ó fẹ́ Màríà tó jẹ́ ọmọ Hélì. Torí náà, Lúùkù to ìlà ìdílé Jésù “lọ́nà ti ẹran ara,” nípasẹ̀ Màríà tó jẹ́ ìyá rẹ̀. (Róòmù 1:3) Bíbélì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ìlà ìdílé méjì tí Jésù ti wá.

Irú àwọn aṣọ àti aró wo ló wà láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

Wọ́n rí òwú tí wọ́n pa láró yìí ní hòrò kan nítòsí Òkun Òkú, ó sì ti wà ṣáájú ọdún 135 Sànmánì Kristẹni

Nígbà yẹn, irun tí wọ́n rẹ́ lára àwọn àgùntàn ni wọ́n sábà máa ń fi ṣe aṣọ láwọn agbègbè tó yí ilẹ̀ Ísírẹ́lì ká, wọ́n sì tún máa ń lo irun ara ewúrẹ́ àti ti ràkúnmí. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àgùntàn àti rírẹ́ irun àgùntàn. (1 Sámúẹ́lì 25:⁠2; 2 Àwọn Ọba 3:⁠4; Jóòbù 31:20) Ilẹ̀ Íjíbítì àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni wọ́n ti ń gbin igi ọ̀gbọ̀ tí wọ́n fi ń ṣe aṣọ ọ̀gbọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 41:42; Jóṣúà 2:⁠6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì kì í gbin òwú, àmọ́ Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé òwú wà lára ohun tí wọ́n ń lò ní ilẹ̀ Páṣíà. (Ẹ́sítérì 1:⁠6) Aṣọ tí wọ́n bá fi Sílí ìkì ṣe máa ń wọ́n gan-⁠an, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn oníṣòwò arìnrìn-àjò ló máa ń kó o wá láti apá Ìlà Oòrùn Éṣíà.​—Ìṣípayá 18:​11, 12.

Ìwé kan tó ń jẹ́ Jesus and His World sọ pé: “Onírúurú àwọ̀ ni òwú máa ń ní, ó lè funfun gbòò tàbí kó jẹ́ àwọ̀ ilẹ̀ tó ní àwọn àwọ̀ mí ì lára.” Bákan náà, wọ́n máa ń pa òwú láró. Aró aláwọ̀ àlùkò máa ń wọ́n gan-⁠an tórí pé ara ìṣáwùrú òkun tàbí lára onírúurú igi, gbòǹgbò igi, ewé àtàwọn kòkòrò ni wọ́n ti máa ń rí àwọn aró mí ì tí wọ́n máa ń lò. Lára àwọn àwọ̀ táwọn aró yìí máa ń mú jáde ni àwọ̀ pupa, àwọ̀ yẹ́lò, àwọ̀ búlúù àti àwọ̀ dúdú.