Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tá ni Èṣù?

Tá ni Èṣù?

Tá ni Èṣù?

ṢÉ WÀÁ SỌ PÉ Èṣù jẹ́ . . .

  • Ẹ̀mí àìrí kan?

  • Èrò ibi tó wà lọ́kàn èèyàn?

  • Tàbí pé kò sí Èṣù?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Èṣù bá Jésù sọ̀rọ̀, ó sì “dẹ ẹ́ wò.” (Mátíù 4:1-4) Èyí fi hàn pé Èṣù kì í ṣe èrò ibi tó wà lọ́kàn èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú kan ni.

OHUN MÍÌ TÁ A LÈ KỌ́ NÍNÚ BÍBÉLÌ

  • Áńgẹ́lì mímọ́ ni Èṣù nígbà tí Ọlọ́run dá a, àmọ́ ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.’ (Jòhánù 8:44) Ó di òpùrọ́, ó sì ta ko Ọlọ́run.

  • Àwọn áńgẹ́lì míì gbè sẹ́yìn Sátánì.—Ìṣípayá 12:9.

  • Èṣù ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé òun kò sí.​—2 Kọ́ríńtì 4:4.

Ṣé Èṣù lè darí àwọn èèyàn?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ ẹ̀tàn lásán ni pé Èṣù lágbára lórí àwọn èèyàn. Àwọn míì sì ń máa ń bẹ̀rù pé kí Èṣù má kó wọnú àwọn. Kí lèrò tiẹ̀?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Èṣù máa ń tan àwọn èèyàn jẹ, àmọ́ kò lè darí gbogbo èèyàn.

OHUN MÍÌ TÁ A LÈ KỌ́ NÍNÚ BÍBÉLÌ

  • Èṣù máa ń díbọ́n kó lè mú káwọn èèyàn gba ohun tó fẹ́.—2 Kọ́ríńtì 11:14.

  • Láwọn ìgbà míì, àwọn ẹ̀mí Èṣù máa ń darí àwọn èèyàn kan.—Mátíù 12:22.

  • Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti “kọ ojú ìjà sí Èṣù.” —Jákọ́bù 4:7.