Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

Ìtàn Tó Ṣe Pàtàkì

Ìtàn Tó Ṣe Pàtàkì

Bíbélì dá yàtọ̀ nínú àwọn ìwé ìsìn tó wà láyé. Ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run. Bákan náà, kò tíì sí ìwé míì táwọn èèyàn tọ pinpin, tí wọ́n sì ṣàríwísí rẹ̀ bíi Bíbélì.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀mọ̀wé kan ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Bíbélì tá a ní báyìí bá èyí tí wọ́n kọ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mu. Onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìsìn kan tiẹ̀ sọ pé: “Kò dá wa lójú pé ohun tó wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ló wà nínú Bíbélì tòde òní. Ọ̀pọ̀ àṣìṣe tá a fọwọ́ bò mọ́lẹ̀ ló kún inú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ Bíbélì ló sì jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n kọ ọ́, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló sì wà láàárín wọn.”

Torí ìsìn táwọn míì ń ṣe, wọ́n gbà pé kì í ṣe òótọ́ lóhun tó wà nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Faizal. Àwọn òbí rẹ̀ tí kì í ṣe Kristẹni kọ́ ọ pé, ìwé mímọ́ ni Bíbélì, àmọ́ wọ́n ti yí ohun tó wà nínú rẹ̀ pa dà. Ó sọ pé: “Fún ìdí yìí, ara mí kì í balẹ̀ tí ẹnì kan bá fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ó ṣe tán, kì í ṣe ojúlówó Bíbélì ni wọ́n ń gbé kiri. Wọ́n ti yí i pa dà!”

Tó bá jẹ́ pé Bíbélì ti yàtọ̀ sí ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣé a ṣì lè tẹ̀ lé ohun tó bá sọ? Ó dáa, ronú nípa àwọn ìbéèrè yìí ná: Ṣé o lè fọkàn tán àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa ọjọ́ iwájú tí kò bá dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí yẹn wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀? (Róòmù 15:4) Ṣé wàá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu nípa iṣẹ́, ìdílé, tàbí ẹ̀sìn tó bá jẹ́ pé ayédèrú ni Bíbélì tá à ń gbé kiri báyìí?

Òótọ́ ni pé kò sí Bíbélì tí wọ́n kọ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mọ́, síbẹ̀ a ṣì lè rí àwọn míì tí wọ́n dà kọ látìgbà láéláé, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ míì tí wọ́n fọwọ́ kọ. Kí ló fà á tí àwọn ìwé àfọwọ́kọ yẹn kò fi bà jẹ́, tí àwọn alátakò kò fi pa á run, tí kò sì ṣeé ṣe láti yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà? Báwo sì ni bí Bíbélì ṣe wà títí dòní ṣe lè mú kó dá ẹ lójú pé òótọ́ lohun tó wà nínú rẹ̀? Wàá rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú apá tó kàn nínú ìtàn bí Ọlọ́run ṣe pa Bíbélì mọ́ títí di àkókò yìí.