Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àfiwé Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Ṣe

Àfiwé Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Ṣe

ṢÉ KRISTẸNI ni ẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé o wà lára àwọn èèyàn tó lé ní bílíọ̀nù méjì tó sọ pé ọmọlẹ́yìn Kristi làwọn, ìyẹn ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta èèyàn tó wà láyé. Lóde òní, àwọn ẹ̀yà ìsìn tó ń pe ara wọn ní Kristẹni pọ̀ lọ súà, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ wọn àti èrò wọn kò dọ́gba rárá. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ lè yàtọ̀ sí tàwọn míì tó pe ara wọn ní Kristẹni. Ṣó tiẹ̀ ṣe pàtàkì kó o gbé ohun tó o gbà gbọ́ yẹ̀wò? Bẹ́ẹ̀ ni. Torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ kó o lè ṣe ẹ̀sìn Kristẹni tí Bíbélì fọwọ́ sí.

“Kristẹni” làwọn èèyàn mọ àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi sí. (Ìṣe 11:26) Kò sídìí láti tún fi orúkọ míì pè wọ́n torí pé, kò sí àwọn míì tó tún jẹ́ Kristẹni nígbà yẹn. Àwọn Kristẹni máa ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Olùdásílẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni, ìyẹn Jésù Kristi. Ṣọ́ọ̀ṣì tó ò ń lọ ńkọ́? Ṣé ó dá ẹ lójú pé ẹ̀kọ́ Kristi ni wọ́n fi ń kọ́ni níbẹ̀, ìyẹn ẹ̀kọ́ tí àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi gbà gbọ́? Báwo ló ṣe lè dá ẹ lójú? Ọ̀nà kan ṣoṣo tó o lè gbà mọ̀ ni pé, kó o ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ.

Ronú nípa èyí ná: Jésù Kristi ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ìwé Mímọ́ pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò fara mọ́ àwọn tó ń bomi la ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń gbé àṣà àwọn èèyàn lásán lárugẹ. (Máàkù 7:9-13) Ó yẹ ká gbà pé orí Bíbélì làwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ máa gbé ìgbàgbọ́ wọn kà. Torí náà, ó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé ohun tí wọ́n ń kọ́ mi ní ṣọ́ọ̀ṣì ba Bíbélì mu?’ Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ó máa dáa kó o fi ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ fi ń kọ́ni wéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ?

Jésù sọ pé ìjọsìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ dá lórí òtítọ́, inú Bíbélì sì ni òtítọ́ yẹn wà. (Jòhánù 4:24; 17:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ pé, ká tó lè rí ìgbàlà a gbọ́dọ̀ ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Fún ìdí yìí, ó ṣe pàtàkì pé kí ìgbàgbọ́ wa dá lórí òtítọ́ Bíbélì, láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ a ò lè ní ìgbàlà!

BÁ A ṢE LÈ FI ÌGBÀGBỌ́ WA WÉRA PẸ̀LÚ BÍBÉLÌ

A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, kó o sì kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn. Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí, kó o sì ronú lórí àwọn ìdáhùn náà. Kó o wá bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ mi ní ṣọ́ọ̀ṣì bá ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ mu?’

Àwọn ìbéèrè yìí máa mú kó o ṣe àfiwé tó dára jù lọ tó o lè ṣe. Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ láti fi àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì rẹ míì wéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì. Ó ò ṣe ní kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? O sì lè lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo.