Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Bíbélì Ṣì Ń Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Pa Dà?

Ǹjẹ́ Bíbélì Ṣì Ń Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Pa Dà?

“Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà.”—RÓÒMÙ 12:2.

ORIN: 61, 52

1-3. (a) Àwọn ìyípadà wo ló lè ṣòro fún wa láti ṣe lẹ́yìn tá a ṣèrìbọmi? (b) Tó bá ṣòro fún wa láti ṣe àwọn ìyípadà, àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

NÍGBÀ tí Kevin [1] kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kò sóhun míì tó wù ú bíi kó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Àmọ́, kó tó di Kristẹni ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ta tẹ́tẹ́, tó ń mu sìgá, tó ń mu ọtí àmuyíràá, tó sì ń lo ògùn olóró. Ó wá di dandan pé kí Kevin jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó lòdì sí Ìwé Mímọ́ yìí kó lè rójú rere Ọlọ́run. Ó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó sì gbà kí Bíbélì tó lágbára láti yí ìgbésí ayé ẹni pa dà yí òun pa dà, nípa bẹ́ẹ̀ ó jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò dáa yìí.—Héb. 4:12.

2 Ṣé Kevin wá dẹ́kun àtimáa ṣe ìyípadà nígbèésí ayé rẹ̀ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi? Rárá, ìdí ni pé ó ṣì ní láti máa kọ́ bó ṣe lè máa hùwà tó yẹ Kristẹni, kí ìwà rẹ̀ sì máa sunwọ̀n sí i. (Éfé. 4:31, 32) Bí àpẹẹrẹ, ó yà á lẹ́nu pé ó ṣòro fún òun láti kápá ìbínú òun. Ó sọ pé: “Mo sapá gan-an kí n tó lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà pálapàla tí mò ń hù tẹ́lẹ̀, àmọ́ bí mo ṣe máa kápá ìbínú mi yìí ló wá le jù!” Àdúrà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó jíire ló ran Kevin lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ.

3 Bíi ti Kevin, ọ̀pọ̀ lára wa ló ti ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì kan ká tó ṣèrìbọmi ká lè máa gbé ìgbé ayé tó bá ìlànà Bíbélì mu. Lẹ́yìn tá a ṣèrìbọmi, a rí i pé ó ṣì yẹ ká máa ṣe àwọn ìyípadà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan ká lè túbọ̀ máa fìwà jọ Ọlọ́run àti Jésù. (Éfé. 5:1, 2; 1 Pét. 2:21) Bí àpẹẹrẹ, a lè ti kíyè sí pé a máa ń ṣàríwísí àwọn èèyàn ṣáá, a máa ń ṣòfófó tàbí ká máa sọ̀rọ̀ àwọn míì láìdáa. Ó lè ṣòro fún wa láti ṣe ohun tó tọ́ torí ìbẹ̀rù èèyàn, a sì lè ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ míì. Ṣé àtiṣe àwọn ìyípadà lórí àwọn kòkó yìí ṣòro fún wa ju bá a ṣe rò lọ? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, o lè wá máa bi ara rẹ pé: ‘Lẹ́yìn tí mo ti jáwọ́ nínú gbogbo àwọn àṣà pálapàla, kí nìdí tó fi wá ṣòro fún mi láti ṣe àwọn ìyípadà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ yìí? Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ jẹ́ kí Bíbélì máa tún ìgbésí ayé mi ṣe?’

MÁ ṢE RO ARA Ẹ PIN

4. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn fún wa láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́?

4 Tọkàntọkàn ló máa ń wu àwa tá a mọ Jèhófà tá a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti máa ṣe ohun táá múnú rẹ̀ dùn. Àmọ́, bó ti wù kó máa wù wá tó, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn fún wa láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ torí pé aláìpé ni wá. Ṣe lọ̀rọ̀ wa dà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ pé: “Agbára àti-fẹ́-ṣe wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí.”Róòmù 7:18; Ják. 3:2.

5. Àwọn ìwà wo la ti fi sílẹ̀ ká tó ṣèrìbọmi, àmọ́ àwọn ìwà wo ló lè ṣòro fún wa láti borí?

5 Ká tó di Kristẹni, a ti jáwọ́ nínú àwọn àṣà àti ìwà tí kò yẹ Kristẹni. (1 Kọ́r. 6:9, 10) Síbẹ̀ náà, aláìpé ṣì ni wá. (Kól. 3:9, 10) Torí náà, kódà lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi tàbí lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tá a ti wà nínú òtítọ́, kò sí bá ò ṣe ní máa ṣàṣìṣe, a ò rọ́gbọ́n ẹ̀ dá. Nǹkan tí ò dáa lè máa wù wá, a lè ní èrò tí kò tọ́, ó lè sì lè ṣòro fún wa láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. A tiẹ̀ lè máa bá àwọn ìwà búburú kan fà á fún ọ̀pọ̀ ọdún.

6, 7. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa lọ́ tìkọ̀ ká tó bẹ Jèhófà fún ìdáríjì?

6 Àìpé tá a jogún ò ní ká má sin Jèhófà, kò sì ní ká má ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Tiẹ̀ rò ó wò ná, nígbà tí Jèhófà ní ká wá sin òun, ó mọ̀ pé àá máa ṣàṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Jòh. 6:44) Torí pé Jèhófà mọ̀ wá, ó sì mọ ohun tó wà lọ́kàn wa, ó dájú pé ó mọ àwọn ohun táá máa bá wa fínra. Ó sì mọ̀ pé kò sí bá ò ṣe ní máa ṣàṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, Jèhófà ò torí ìyẹn sọ pé òun ò lè bá irú wa ṣọ̀rẹ́.

7 Ìfẹ́ mú kí Ọlọ́run fún wa lẹ́bùn iyebíye kan, ìyẹn ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. (Jòh. 3:16) Tá a bá ronú pìwà dà, tá a sì tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́lá ẹbọ ìràpadà yìí, ọkàn wa á balẹ̀ pé àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà ò yingin. (Róòmù 7:24, 25; 1 Jòh. 2:1, 2) Ṣó wá yẹ ká ro ara wa pin, pé a ò yẹ lẹ́ni tó lè jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà yìí, torí a gbà pé aláìmọ́ ni wá àti pe ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ jù? Rárá, kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀! Ṣe nìyẹn máa dà bí ìgbà tọ́wọ́ wa dọ̀tí, tá a wá lá ò ní fomi fọwọ́ wa. Ó yẹ ká rántí pé gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà ni ẹ̀bùn ìràpadà wà fún. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fún wa lẹ́bùn ìràpadà ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀ bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé.—Ka 1 Tímótì 1:15.

8. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká gbójú fo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa?

8 Lóòótọ́, a kì í gbójú fo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, ká wá máa dẹ́ṣẹ̀ lọ ràì. Tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, àfi ká máa sapá láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run àti Jésù pẹ́kípẹ́kí ká sì jẹ́ irú ẹni tí wọ́n fẹ́ ká jẹ́. (Sáàmù 15:1-5) A tún gbọ́dọ̀ máa sapá láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, kódà ká tiẹ̀ fi wọ́n sílẹ̀ pátápátá bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi ni àbí ó ti pẹ́ tá a ti ṣèrìbọmi, a gbọ́dọ̀ máa “bá a lọ . . . ní gbígba ìtọ́sọ́nàpadà” tàbí ká máa sọ irú ẹni tá a jẹ́ dọ̀tun.—2 Kọ́r. 13:11.

9. Kí ló mú kó dá wa lójú pé a ṣì lè máa sapá láti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀?

9 A gbọ́dọ̀ máa sapá lójoojúmọ́ tá a bá fẹ́ máa sọ irú ẹni tá a jẹ́ dọ̀tun ká sì gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.” Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé, tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ atannijẹ; ṣùgbọ́n kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfé. 4:22-24) Ohun tí Bíbélì sọ yìí pé ká “di tuntun” kì í ṣe ohun téèyàn ń ṣe lẹ́ẹ̀kan táá dáwọ́ dúró, ó gba pé kéèyàn máa sapá lójoojúmọ́. Èyí wúni lórí gan-an. Ìdí sì ni pé ó jẹ́ kó dá wa lójú pé bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti ṣèrìbọmi, a ṣì lè máa sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. Ó dájú pé Bíbélì lè máa tún ìgbésí ayé wa ṣe lójoojúmọ́.

KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢÒRO TÓ BẸ́Ẹ̀?

10. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tún ìgbésí ayé wa ṣe, àwọn ìbéèrè wo la sì lè bi ara wa?

10 A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tún ìgbésí ayé wa ṣe. Àmọ́, kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ sapá tó bẹ́ẹ̀? Bí Jèhófà bá ń mú ká ṣàṣeyọrí láwọn ọ̀nà kan, kí nìdí tí kò fi rọrùn fún wa láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa? Ṣé Jèhófà ò lè ṣe é ni, ká má máa ní èrò tí kò tọ́ táá fi jẹ́ pé a ò tiẹ̀ ní làágùn jìnnà ká tó lè ṣe ohun tó fẹ́?

11-13. Kí nìdí tí Jèhófà fi retí pé ká sapá ká lè borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa?

11 Tá a bá ń ronú nípa ayé tá a wà yìí àti ọ̀run tó lọ salalu, àá rí i pé Jèhófà lágbára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan péré, oòrùn máa ń sọ mílíọ̀nù márùn-ún tọ́ọ̀nù ìtànṣán rẹ̀ di agbára tó ṣeé lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ nínú agbára náà ló ń wá sí ayé wa yìí, síbẹ̀ ó tó láti pèsè àwọn ohun tó máa gbẹ́mìí wa ró. (Sm. 74:16; Aísá. 40:26) Inú Jèhófà máa ń dùn láti fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára tí wọ́n nílò nígbà tí wọ́n nílò rẹ̀. (Aísá. 40:29) Ọlọ́run lè fún wa lágbára tá a lè fi borí gbogbo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa láì làágùn jìnnà. Àmọ́, kí nìdí tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀?

12 Ọlọ́run ti fún wa ní ẹ̀bùn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn òmìnira láti yan ohun tó wù wá. Tá a bá yàn láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ tá a sì ń sapá láti ṣe é, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì fẹ́ múnú rẹ̀ dùn. A tún ń fi hàn pé a gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Sátánì ti sọ pé Jèhófà ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, torí náà tá a bá fínnúfíndọ̀ fi ara wa sábẹ́ Jèhófà tá a sì ń sapá láti ti ìṣàkóso rẹ̀ lẹ́yìn, ó dájú pé inú Jèhófà Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ máa dùn sí wa. (Jóòbù 2:3-5; Òwe 27:11) Àmọ́, tí Jèhófà bá mú kí gbogbo ẹ̀ rọrùn fún wa débi pé a ò tiẹ̀ ní làágùn jìnnà ká tó lè ṣe ohun tó fẹ́, báwo la ṣe lè sọ pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí i àti pé lóòótọ́ la gbà kó máa darí wa?

13 Torí náà, Jèhófà sọ pé ká sapá gidigidi ká lè ní àwọn ànímọ́ tó yẹ Kristẹni. (Ka 2 Pétérù 1:5-7; Kól. 3:12) Ó retí pé ká ṣiṣẹ́ kára ká lè borí àwọn èrò tí kò tọ́ tá a máa ń ní àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. (Róòmù 8:5; 12:9) Tá a bá ṣiṣẹ́ kára láti ṣàtúnṣe tó yẹ tá a sì ṣàṣeyọrí, inú wa máa dùn pé Bíbélì ṣì ń yí ìgbésí ayé wa pa dà.

JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN MÁA YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ PA DÀ

14, 15. Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ ní àwọn ànímọ́ tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí? (Wo àpótí náà “ Bíbélì àti Àdúrà Yí Ìgbésí Ayé Wọn Pa Dà.”)

14 Kí la lè ṣe ká tó lè ní àwọn ànímọ́ Kristẹni ká sì máa ṣe ohun tó ń múnú Jèhófà dùn? A gbọ́dọ̀ máa sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dípò ká máa ronú pé ohun tá a lè dá ṣe fúnra wa ni. Ìwé Róòmù 12:2 sọ pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” Jèhófà máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè fòye mọ ohun tó fẹ́, ká sì ṣe é, ó tún máa ń mú ká lè ṣàtúnṣe tó yẹ ní ìgbésí ayé wa débi tí inú rẹ̀ á fi dùn sí wa. Torí náà, ó yẹ ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, ká sì máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13; Gál. 5:22, 23) Tá a bá ń tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tá a sì ń mú èrò wa bá èrò Jèhófà mu bó ṣe wà nínú Bíbélì, àá túbọ̀ máa fìwà jọ Jèhófà lọ́rọ̀, lérò àti ní ìṣe. Àmọ́ síbẹ̀ náà, a ṣì gbọ́dọ̀ máa sapá láti máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò, kó má di pé ṣe la kàn ṣáà ń ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ kan náà nígbà gbogbo.—Òwe 4:23.

Á dáa ká ṣàkójọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, ká sì máa kà wọ́n látìgbàdégbà (Wo ìpínrọ̀ 15)

15 Láfikún sí Bíbélì kíkà ojoojúmọ́, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtẹ̀jáde wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì ká lè máa rí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fara wé Jèhófà. Ṣe làwọn ará kan máa ń kó àwọn ẹsẹ Bíbélì kan jọ àtàwọn àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! táá mú kí wọ́n lè máa fi àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣèwà hù kí wọ́n sì borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣàkójọ wọn tán, wọ́n máa ń kà á látìgbàdégbà.

16. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tá ò bá tètè ní àwọn ànímọ́ tó yẹ Kristẹni?

16 Tó ò bá tètè ní àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fẹ́, ó yẹ kó o máa rántí pé irú ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀ máa ń gba àkókò. A ò lè ní gbogbo àwọn ànímọ́ yẹn lẹ́ẹ̀kan náà. Ó máa gba pé ká ní sùúrù bá a ṣe ń sapá láti jẹ́ kí Bíbélì tún ìgbésí ayé wa ṣe . Níbẹ̀rẹ̀, ó lè gba pé ká kọ́ ara wa láti máa ṣe ohun tó bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu. Bí èrò àti ìṣe wa ṣe ń bá ti Jèhófà mu bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, á wá rọrùn fún wa láti máa ronú lọ́nà tó yẹ ká sì máa hùwà tó yẹ Kristẹni.—Sm. 37:31; Òwe 23:12; Gál. 5:16, 17.

MÁA RÁNTÍ ỌJỌ́ Ọ̀LA ÀGBÀYANU TÁ A NÍ

17. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, kí la lè máa fojú sọ́nà fún?

17 Láìpẹ́, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa di pípé, wọ́n á sì láǹfààní láti máa jọ́sìn Jèhófà títí láé. Nígbà yẹn, kò ní sí pé a tún ń bá àìpé ẹ̀dá wọ̀yá ìjà, wẹ́rẹ́ báyìí làá máa fàwọn ànímọ́ Kristẹni ṣèwà hù. Àmọ́ ní báyìí ná, a dúpẹ́ pé Jèhófà fún wa lẹ́bùn ìràpadà tó jẹ́ ká lè máa sin Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Kódà ní báyìí tá a ṣì jẹ́ aláìpé, a lè máa sin Ọlọ́run tá a bá ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa yí ìgbésí ayé wa pa dà.

18, 19. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Bíbélì lágbára láti yí ìgbésí ayé wa pa dà?

18 Kevin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣiṣẹ́ kára kó lè kápá ìbínú rẹ̀. Ó ṣàṣàrò lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ó fi wọ́n sílò, ó gbà kí àwọn ará ran òun lọ́wọ́ ó sì fi ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un sílò. Láàárín ọdún díẹ̀, Kevin ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ogún ọdún rèé tó sì ti di alàgbà. Síbẹ̀, ó ṣì ń sapá láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, kí ìwà rẹ̀ àtijọ́ má bàa tún gbérí mọ́.

19 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kevin fi hàn pé Bíbélì ń ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ láti máa ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nínú ìgbésí ayé wọn. Torí náà, ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa bá a nìṣó láti yí ìgbésí ayé wa pa dà, ká sì tún jẹ́ kó mú kí àárín àwa àti Jèhófà túbọ̀ gún régé. (Sm. 25:14) Bí Jèhófà ṣe ń bù kún ìsapá wa, a máa rí ẹ̀rí pé lóòótọ́ ni Bíbélì ń yí ìgbésí ayé wa pa dà.—Sm. 34:8.

^ [1] (ìpínrọ̀ 1) A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.