Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Má Fòyà. Èmi Fúnra Mi Yóò Ràn Ọ́ Lọ́wọ́”

“Má Fòyà. Èmi Fúnra Mi Yóò Ràn Ọ́ Lọ́wọ́”

KÁ SỌ pé ò ń rìn lójú ọ̀nà kan tó dá, ilẹ̀ sì ti ṣú. O wá fura pé ẹnì kan ń tẹ̀ lé ẹ. Lo bá dúró, o wá kíyè sí pé ẹni náà dúró. O tún tẹsẹ̀ mọ́rìn, lẹni náà tún gbá tẹ̀ lé ẹ. Lo bá kúkú ki eré mọ́lẹ̀, ó di ilé ọ̀rẹ́ rẹ kan tó wà nítòsí. Lọ̀rẹ̀ẹ́ rẹ bá ṣí ilẹ̀kùn fún ẹ, o sì wọlé. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ, ó dájú pé ọkàn ẹ máa balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.

Irú nǹkan báyìí lè má ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, àmọ́ àwọn ìṣòro míì wà tó lè máa kó ẹ lọ́kàn sókè. Bí àpẹẹrẹ, ṣó o ti ń sapá láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, àmọ́ tó ṣòro fún ẹ? Ṣó ti tọ́jọ́ mẹ́ta tó o ti ń wáṣẹ́, tó ò sì rẹ́ni gbà ẹ́ láìka gbogbo akitiyan tó o ṣe sí? Ṣé bára ṣe ń dara àgbà, tó o sì ń ronú nípa bí ìlera rẹ ṣe máa rí lọ́la ló ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ? Àbí àwọn nǹkan míì wà tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè?

Ìṣòro yòówù kó o ní, ó dájú pé inú rẹ máa dùn tó o bá rẹ́ni fọ̀rọ̀ lọ̀, tẹ́ni náà sì tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lásìkò tó o nílò rẹ̀. Ǹjẹ́ o ní irú alábàárò bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, o ní! Nínú ìwé Aísáyà 41:8-13, Jèhófà pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ òun. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa dúró ti ìwọ náà. Ní ẹsẹ 10 àti 13, Jèhófà sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́. Nítorí pé èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”

‘ÈMI YÓÒ DÌ Ọ́ MÚ ṢINṢIN NÍ TI TÒÓTỌ́’

Ṣé ọ̀rọ̀ yìí fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀? Fojú inú wo ohun tí Jèhófà ń sọ fún wa níbí. Ẹsẹ Bíbélì yẹn kò sọ pé ìwọ àti Jèhófà jọ ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara yín, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn náà dáa. Ká sọ pé ẹ jọ ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara yín, ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà máa di ọwọ́ òsì tìrẹ mú. Àmọ́ ńṣe ni Jèhófà fi “ọwọ́ ọ̀tún òdodo” rẹ̀ di “ọwọ́ ọ̀tún rẹ” mú, àfi bíi pé ó fẹ́ yọ ẹ́ nínú ìṣòro kan tó mu ẹ́ lómi. Bó ti ń fà ẹ́, ó tún ń fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé: “Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Ǹjẹ́ o gbà pé Jèhófà jẹ́ Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ rẹ àti Ọ̀rẹ́ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá níṣòro? Ọ̀rọ̀ rẹ máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Nígbà tí nǹkan bá le fún ẹ, Jèhófà fẹ́ kọ́kàn rẹ balẹ̀ torí pé ó ní ire rẹ lọ́kàn. Ká sòótọ́, Jèhófà jẹ́ olùrànlọ́wọ́ “tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.”—Sm. 46:1.

Ẹ̀DÙN ỌKÀN TORÍ ÀṢÌṢE TÁ A TI ṢE SẸ́YÌN

Àwọn kan máa ń ro ara wọn pin torí ìwà tí wọ́n ti hù sẹ́yìn, ó sì máa ń ṣe wọ́n bíi pé Ọlọ́run ò tíì dárí jì wọ́n. Tọ́rọ̀ tìẹ náà bá rí bẹ́ẹ̀, o lè ronú nípa ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù tó sọ nípa ‘àwọn ìṣìnà ìgbà èwe rẹ̀.’ (Jóòbù 13:26) Dáfídì náà ní irú ẹ̀dùn ọkàn yìí, ìdí nìyẹn tó fi bẹ Jèhófà pé: “Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi àti àwọn ìdìtẹ̀ mi.” (Sm. 25:7) Torí a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa ‘ti ṣẹ̀, a sì ti kùnà ògo Ọlọ́run.’—Róòmù 3:23.

Àwọn Júù ìgbàanì ni Ọlọ́run dìídì darí ọ̀rọ̀ inú Aísáyà orí 41 sí. Ìwà wọn ti burú débi pé Jèhófà bínú sí wọn, ó sì jẹ́ káwọn ará Bábílónì kó wọn lẹ́rú. (Aísá. 39:6, 7) Tí wọ́n bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa gbà wọ́n là. (Aísá. 41:8, 9; 49:8) Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà máa ń ṣe sáwọn tó bá wù látọkàn láti rí ojú rere rẹ̀ lóde òní.—Sm. 51:1.

Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Takuya * tó máa ń wo àwòrán oníhòòhò, tó sì máa ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀. Ó sapá gan-an kó lè jáwọ́ nínú ìwà yìí, síbẹ̀ ó ṣòro fún un láti jáwọ́. Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀? Ó ní: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò lè rí ojúure Ọlọ́run, àmọ́ tí mo bá gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí jì mí, ńṣe ni Jèhófà máa ń gbé mi ró.” Báwo ni Jèhófà ṣe gbé e ró? Àwọn alàgbà tó wà ní ìjọ tí Takuya wà sọ fún un pé kó sọ fún àwọn nígbàkigbà tó bá tún ti ṣe é. Takuya sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti sọ fún wọn, àmọ́ tí mo bá sọ fún wọn, wọ́n máa ń fún mi níṣìírí.” Lẹ́yìn náà, àwọn alàgbà ṣètò pé kí alábòójútó àyíká ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ Takuya. Alábòójútó àyíká náà sọ fún un pé: “Mi ò ṣèèṣì wá síbí. Àwọn alàgbà ló fẹ́ kí n wá sọ́dọ̀ rẹ. Wọ́n dìídì fẹ́ ká bẹ̀ ọ́ wò.” Takuya sọ pé: “Èmi ni mò ń ṣẹ̀, síbẹ̀ Jèhófà ń lo àwọn alàgbà láti ràn mí lọ́wọ́.” Takuya tẹ̀ síwájú débi tó fi di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ní báyìí, ó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bíi ti Takuya, Ọlọ́run máa gbé ẹ ró tó o bá ṣubú.

Ọ̀RỌ̀ ÀTIJẸ ÀTIMU

Ìṣòro ńlá ni àìníṣẹ́ lọ́wọ́ jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Látìgbà tí iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn kan, wọn ò tíì ríṣẹ́ míì. Wo bó ṣe máa rí lára ẹ tó bá jẹ́ pé gbogbo ibi tó o wáṣẹ́ dé, kò síṣẹ́ ni wọ́n ń sọ fún ẹ. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti mú káwọn kan ro ara wọn pin. Báwo ni Jèhófà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ó lè má pèsè iṣẹ́ tó o fẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ ó lè mú kó o rántí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì Ọba sọ, pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sm. 37:25) Òótọ́ pọ́ńbélé nìyẹn! Torí pé o ṣeyebíye lójú Jèhófà, ó ṣe tán àtifi “ọwọ́ ọ̀tún òdodo” rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní àwọn nǹkan tó o nílò táá jẹ́ kó o máa bá ìjọsìn rẹ nìṣó.

Báwo ni Jèhófà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ?

Sara tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà rí ọwọ́ Jèhófà láyè rẹ̀. Iléeṣẹ́ ńlá kan tó ń sanwó gidi fún un ló ń bá ṣiṣẹ́, àmọ́ iṣẹ́ náà ń gba àkókò rẹ̀ gan-an. Ó wù ú láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, torí náà ó fiṣẹ́ sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kò tètè rí iṣẹ́ tí kò ní gbà á lákòókò, ló bá ṣí ṣọ́ọ̀bù tó ti ń ta áásìkiriìmù. Àmọ́ kò pẹ́ tó fi kógbá wọlé torí pé owó ò wọlé. Sara sọ pé: “Ọdún mẹ́ta gbáko ni mi ò fi rí nǹkan ṣe, àmọ́ mo dúpẹ́ pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fara dà á.” Sara kọ́ béèyàn ṣe ń fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó nílò àti ohun tó kàn wù ú, ó sì tún kọ́ béèyàn ò ṣe ní máa ṣàníyàn. (Mát. 6:33, 34) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọ̀gá rẹ̀ níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ní kó pa dà wá máa ṣiṣẹ́ ní ipò tó wà tẹ́lẹ̀. Sara wá sọ fún un pé ọjọ́ mélòó kan lòun á máa fi ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀, òun á sì máa gbàyè lẹ́nu iṣẹ́ fún ìjọsìn òun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tó ń wọlé fún Sara kò tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́, síbẹ̀ ó ń ráyè iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó ń ṣe. Ó wá sọ pé, ní gbogbo àsìkò tí nǹkan ò rọrùn yẹn, “Mo rí ọwọ́ Jèhófà láyé mi.”

TÁRA BÁ Ń DARA ÀGBÀ

Ohun míì tó tún ń mú kéèyàn ṣàníyàn ni ara tó ń dara àgbà. Tí ọ̀pọ̀ bá ti ń sún mọ́ àtifẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n máa ń ṣàníyàn pé bóyá làwọn á rówó gbọ́ bùkátà dọjọ́ alẹ́. Wọ́n tún máa ń ṣàníyàn nípa bí ìlera àwọn ṣe máa rí báwọn ṣe ń dàgbà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Dáfídì ló bẹ Jèhófà pé: “Má ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó; ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀.”—Sm. 71:9, 18.

Kí ló lè mú kí ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà balẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń dara àgbà? Á dáa kí wọ́n mú kí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára, kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa pèsè ohun tí wọ́n nílò. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ti ń gbádùn ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tẹ́lẹ̀, ní báyìí ó lè gba pé kí wọ́n jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn. Wọ́n lè wá rí i pé jíjẹ “oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè” lè gbádùn mọ́ni ju “akọ màlúù tí a bọ́ yó,” ìyẹn gan-an sì tún máa ṣàǹfààní fún ìlera wọn. (Òwe 15:17) Tó o bá gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà, ó máa pèsè fún ẹ kódà tára bá ti ń dara àgbà.

José àti Rose pẹ̀lú Tony àti Wendy

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí José àti Rose tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún ohun tó lé ní ọdún márùndínláàádọ́rin [65]. Láàárín àkókò yẹn, wọ́n tún tọ́jú bàbá Rose tó nílò kẹ́ni kan dúró tì í ní gbogbo ìgbà. Wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún José torí pé ó lárùn jẹjẹrẹ, èyí ò sì rọrùn rárá. Ṣé Jèhófà wá fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ di àwọn tọkọtaya olóòótọ́ yìí mú? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ lọ́nà wo? Jèhófà lo tọkọtaya kan tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ, ìyẹn Tony àti Wendy. Tọkọtaya yìí fún José àti Rose ní ilé tí wọ́n á máa gbé. Tony àti Wendy ti pinnu pé àwọn aṣáájú-ọ̀nà làwọn máa gbé ilé náà fún láìgbowó. Lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Tony máa ń rí José àti Rose láti ojú wíńdò iléèwé rẹ̀ tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí. Tony nífẹ̀ẹ́ wọn torí ìtara tí wọ́n ní, àpẹẹrẹ wọn sì ran òun náà lọ́wọ́. Nígbà tí Tony àti Wendy rí i pé àwọn tọkọtaya àgbàlagbà yìí ti fi gbogbo ayé wọn sin Jèhófà, èyí mú kí wọ́n gbà wọ́n sílé náà. Ní báyìí, ó ti tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tí wọ́n ti ń ṣèrànwọ́ fún José àti Rose tí wọ́n ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún. Àwọn tọkọtaya àgbàlagbà yẹn gbà pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni Tony àti Wendy jẹ́ fún wọn.

Ọlọ́run ń na “ọwọ́ ọ̀tún òdodo” rẹ̀ sí ìwọ náà. Ṣé ìwọ náà á ṣípá fún Ẹni tó ṣèlérí fún ẹ pé: “Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́”?

^ ìpínrọ̀ 11 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.