Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Jó Rẹ̀yìn Tó O Bá Ń Sìn Nílẹ̀ Àjèjì

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Jó Rẹ̀yìn Tó O Bá Ń Sìn Nílẹ̀ Àjèjì

“Inú ọkàn-àyà mi ni mo fi àsọjáde rẹ ṣúra sí.”​—SM. 119:11.

ORIN: 142, 92

1-3. (a) Ibi yòówù ká wà, kí ló yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa? (b) Ìṣòro wo làwọn tó ń kọ́ èdè tuntun máa ń ní, àwọn ìbéèrè wo la sì máa jíròrò? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù “fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣí. 14:6) Iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ. Èyí ti mú káwọn kan lára wa kọ́ èdè tuntun. Àwọn míì ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, nígbà táwọn míì ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ nílẹ̀ àjèjì. Àwọn míì sì ti dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè míì nílùú ìbílẹ̀ wọn.

2 Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run, ká sì tún rí i pé ìdílé wa ń ṣe déédéé nípa tẹ̀mí. (Mát. 5:3) Àmọ́ nígbà míì ọwọ́ wa máa ń dí débi pé a lè má fi bẹ́ẹ̀ ráyè láti dá kẹ́kọ̀ọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì tún ní àwọn ìṣòro míì.

3 Yàtọ̀ sí pé àwọn tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì máa ń kọ́ èdè tuntun, wọ́n tún ní láti rí i dájú pé àwọn ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (1 Kọ́r. 2:10) Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọn ò bá gbọ́ èdè ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́? Kí sì nìdí tó fi pọn dandan pé káwọn òbí rí i dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń dọ́kàn àwọn ọmọ wọn?

OHUN TÓ LÈ PA ÌJỌSÌN WA LÁRA

4. Kí ló lè pa ìjọsìn wa lára? Sọ àpẹẹrẹ kan.

4 Téèyàn bá lọ sìn nílẹ̀ àjèjì, àmọ́ tí kò gbédè ibẹ̀ dáadáa, ó lè ṣòro fún un láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn sì lè pa ìjọsìn rẹ̀ lára. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó ká Nehemáyà lára nígbà tó gbọ́ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ Júù kò gbọ́ èdè Hébérù. (Ka Nehemáyà 13:23, 24.) Àìgbédè àwọn ọmọ yẹn kò jẹ́ kí wọ́n lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn sì mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà yingin.​—Neh. 8:2, 8.

5, 6. Kí làwọn òbí kan tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì rí i pé ó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ wọn, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

5 Àwọn òbí kan tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì ti rí i pé ìfẹ́ táwọn ọmọ wọn ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti ń tutù. Ìdí ni pé àwọn ọmọ yẹn ò lóye ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé, ohun tí wọ́n sì ń kọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kì í wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Arákùnrin Pedro, [1] tó ṣí lọ sílẹ̀ Ọsirélíà láti South America sọ pé: “Téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ohun tó ń kọ́ gbọ́dọ̀ wọ̀ ọ́ lọ́kàn dáadáa kó tó lè ṣe ohun tó tọ́.”​—Lúùkù 24:⁠32.

6 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lédè àjèjì, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ wọ̀ wá lọ́kàn bíi kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ lédè abínibí rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ gbédè, ó lè jẹ́ kí nǹkan tètè sú wa, ó sì lè mú kí ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn. Torí náà, bá a ṣe ń sìn lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì, ó ṣe pàtàkì pé ká sa gbogbo ipá wa kí iná ìgbàgbọ́ wa má bàa jó rẹ̀yìn.​—Mát. 4:4.

WỌ́N MỌYÌ ÀJỌṢE WỌN PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN

7. Kí làwọn ará Bábílónì ṣe láti mú kí Dáníẹ́lì dọmọ ìbílẹ̀, kó sì máa bọ òrìṣà wọn?

7 Nígbà tí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wà nígbèkùn ní Bábílónì, àwọn èèyàn ibẹ̀ kọ́ wọn lédè wọn kí wọ́n lè di ọmọ ìbílẹ̀. Bákan náà, aṣojú ọba tó ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ tún fún wọn lórúkọ Bábílónì. (Dán. 1:3-7) Ohun tó bẹ̀rẹ̀ orúkọ tí wọ́n fún Dáníẹ́lì ni Bẹli, ìyẹn sì ni orúkọ òrìṣà tó lágbára jù táwọn èèyàn Bábílónì ń bọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Ọba Nebukadinésárì fẹ́ kí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbà pé òrìṣà táwọn ń bọ ní Bábílónì lágbára ju Jèhófà Ọlọ́run wọn.​—Dán. 4:8.

8. Kí ni Dáníẹ́lì ṣe tó mú kí àárín òun àti Jèhófà gún régé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ àjèjì ló wà?

8 Lóòótọ́ wọ́n rọ Dáníẹ́lì pé kó jẹ àwọn oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, àmọ́ Dáníẹ́lì pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé òun ò ní “sọ ara òun di eléèérí.” (Dán. 1:8) Torí pé Dáníẹ́lì máa ń ka Ìwé Mímọ́ tó wà lédè ìbílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn mú kí àárín òun àti Jèhófà gún régé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ àjèjì ló wà. (Dán. 9:2) Abájọ tó fi jẹ́ pé, lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún tó ti wà ní Bábílónì, orúkọ Hébérù tó ń jẹ́ làwọn èèyàn ṣì mọ̀ ọ́n sí.​—Dán. 5:13.

9. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 119, àǹfààní wo lẹni tó kọ Sáàmù náà rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

9 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fún ẹni tó kọ Sáàmù 119 lókun, tó jẹ́ kó lè dá yàtọ̀ láàárín àwọn ojúgbà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ṣe làwọn kan lára àwọn ọmọ ọba ń fi ẹni tó kọ Sáàmù náà ṣe yẹ̀yẹ́. (Sm. 119:23, 61) Síbẹ̀, inú rẹ̀ máa ń dùn torí pé ó ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Ka Sáàmù 119:11, 46.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ RẸ JÓ RẸ̀YÌN

10, 11. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wá lọ́kàn? Ṣàpèjúwe.

10 Kò sí àní-àní pé ọwọ́ wa máa ń dí bá a ṣe ń ṣe ojúṣe wa nínú ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, síbẹ̀ ká rí i pé à ń wáyè láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé. (Éfé. 5:15, 16) Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé kì í ṣe torí ká lè tètè parí ìwé tá à ń kà la ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ tàbí torí ká lè dáhùn nípàdé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà táá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wá lọ́kàn, táá sì mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára.

11 Kí ohun tá à ń kọ́ tó lè wọ̀ wá lọ́kàn, ó yẹ ká máa ronú nípa bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe kàn wá, kì í ṣe bá a ṣe fẹ́ fi kọ́ àwọn míì nìkan ló yẹ ká máa rò. (Fílí. 1:​9, 10) Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá ń múra òde ẹ̀rí, tá à ń múra ìpàdé tàbí tá à ń múra iṣẹ́ tá a ní nípàdé, a kì í sábà ronú bọ́rọ̀ náà ṣe kàn wá. Wo àpèjúwe yìí ná: Àwọn tó ń se oúnjẹ tà sábà máa ń tọ́ oúnjẹ tí wọ́n ń sè wò. Síbẹ̀, ìtọ́wò yẹn kò tó láti gbẹ́mìí wọn ró. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn náà gbọ́dọ̀ máa jẹun dáadáa tí wọ́n bá máa lókun. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká rí i pé à ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ohun tá à ń kọ́ á fi wọ̀ wá lọ́kàn.

12, 13. Kí nìdí tó fi dáa káwọn tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè abínibí wọn?

12 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì máa ń rí i pé ó máa ṣe àwọn láǹfààní táwọn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè abínibí wọn. (Ìṣe 2:⁠8) Kódà àwọn míṣọ́nnárì náà mọ̀ pé kì í wulẹ̀ ṣe ohun táwọn ń gbọ́ nípàdé nìkan ló máa mú kí ìgbàgbọ́ àwọn fẹsẹ̀ múlẹ̀, àwọn tún gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa.

13 Ó ti tó nǹkan bí ọdún mẹ́jọ tí Arákùnrin Alain ti ń kọ́ èdè Páṣíà, ó wá sọ pé: “Tí mo bá ń múra ìpàdé sílẹ̀ lédè Páṣíà, bí mo ṣe máa kọ́ èdè náà ni mo máa ń gbájú mọ́, torí bẹ́ẹ̀ ẹ̀kọ́ náà kì í fi bẹ́ẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn. Ìdí nìyẹn tí mo fi máa ń wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì lédè abínibí mi.”

JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN WỌ ÀWỌN ỌMỌ RẸ LỌ́KÀN

14. Kí ló yẹ káwọn òbí máa ṣe, kí sì nìdí?

14 Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ rí i dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wọ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn dáadáa. Lẹ́yìn tí Serge àti Muriel ìyàwó rẹ̀ ti sìn fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ta níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì, wọ́n rí i pé ọmọ wọn ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] ò láyọ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Muriel sọ pé: “Inú ọmọ wa máa ń dùn láti wàásù lédè abínibí rẹ̀ tó jẹ́ Faransé níjọ tá a wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí tá a ti wà níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì, a kíyè sí i pé inú rẹ̀ kì í dùn láti lọ sóde ẹ̀rí mọ́.” Serge wá sọ pé: “Nígbà tá a rí i pé ìtara ọmọ wa ti ń dín kù, ṣe la pa dà sí ìjọ tá a wà tẹ́lẹ̀.”

Rí i dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wọ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn (Wo ìpínrọ̀ 14 àti 15)

15. (a) Kí ló lè mú káwọn òbí pinnu pé àwọn á pa dà sí ìjọ tó ń sọ èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Diutarónómì 6:5-7 gba àwọn òbí?

15 Kí ló lè mú káwọn òbí pinnu pé àwọn á pa dà sí ìjọ tó ń sọ èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kí wọ́n wò ó bóyá àwọn máa ráyè kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lédè tí wọ́n lóye, lẹ́sẹ̀ kan náà kí wọ́n sì tún kọ́ wọn lédè àjèjì tí wọ́n ń sọ níbi tí wọ́n ti ń sìn. Ohun kejì ni pé wọ́n lè kíyè sí pé àwọn ọmọ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nítara fún iṣẹ́ ìsìn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n má nífẹ̀ẹ́ sí ibi tí wọ́n ti ń sìn mọ́. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn òbí lè pinnu pé á dáa káwọn pa dà sí ìjọ tó ń sọ èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa títí dìgbà tí òtítọ́ á fi jinlẹ̀ lọ́kàn wọn.​—Ka Diutarónómì 6:5-7.

16, 17. Kí làwọn òbí kan ṣe kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ tó ń sọ èdè àjèjì ni wọ́n wà?

16 Ohun míì táwọn òbí kan máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń fi èdè ìbílẹ̀ wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ tó ń sọ èdè àjèjì ni wọ́n wà. Arákùnrin Charles ní ọmọbìnrin mẹ́ta, èyí tó kéré jù jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, èyí àkọ́bí sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Àwùjọ tó ń sọ èdè Lingala ni wọ́n wà. Arákùnrin Charles sọ pé: “A pinnu pé èdè abínibí wa tí àwọn ọmọ wa gbọ́ làá máa lò nígbà Ìjọsìn Ìdílé wa. Àmọ́ a jọ máa ń gbá àwọn géèmù tó wà lédè Lingala ká lè fìyẹn kọ́ wọ́n lédè yẹn.”

Ẹ máa sapá láti kọ́ èdè ibi tẹ́ ẹ wà, kẹ́ ẹ sì máa dáhùn nípàdé (Wo ìpínrọ̀ 16 àti 17)

17 Arákùnrin Kevin ní ọmọbìnrin méjì tí èyí ẹ̀gbọ́n ò ju ọmọ ọdún mẹ́jọ lọ. Àwọn ọmọ yìí kì í fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé torí pé ìjọ tó ń sọ èdè àjèjì ni wọ́n wà. Bàbá wọn sapá gan-an láti kọ́ wọn kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ lọ́kàn wọn. Ó sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi máa ń kọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ lédè Faransé, torí pé èdè tí wọ́n gbọ́ dáadáa nìyẹn. A tún máa ń rí i dájú pé a lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè Faransé lẹ́ẹ̀kan lóṣù, tá a bá sì tún gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, a máa ń lọ sí àpéjọ àgbègbè lédè ìbílẹ̀ wa.”

18. (a) Ìlànà wo ló wà nínú Róòmù 15:1, 2 táá jẹ́ kó o lè pinnu ohun tó máa ṣe àwọn ọmọ rẹ láǹfààní? (b) Kí làwọn òbí kan sọ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? (Wo àfikún àlàyé.)

18 Ohun kan ni pé, ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tí wọ́n á ṣe kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ wọn má bàa jó rẹ̀yìn. [2] (Gál. 6:5) Muriel tá a mẹ́nu bà lókè sọ pé inú àwọn dùn pé àwọn yááfì ohun táwọn nífẹ̀ẹ́ kí ìgbàgbọ́ ọmọ àwọn lè fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Ka Róòmù 15:1, 2.) Serge ọkọ rẹ̀ náà gbà pé ìpinnu tó dáa làwọn ṣe. Ó sọ pé: “Gbàrà tá a pa dà sí ìjọ tó ń sọ èdè Faransé lọmọ wa ti bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ ìwàásù, ó sì ti ṣèrìbọmi. Ní báyìí, ó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Kódà, ó yà wá lẹ́nu pé òun fúnra rẹ̀ ti ń ronú àtilọ sìn nínú ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì!”

JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RÙN WỌ̀ Ẹ́ LỌ́KÀN

19, 20. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

19 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, torí náà ó jẹ́ ká ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè kí ‘gbogbo onírúurú ènìyàn lè ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’ (1 Tím. 2:4) Ó mọ̀ pé táwọn èèyàn bá ń ka ọ̀rọ̀ òun lédè abínibí wọn, wọ́n á lóye rẹ̀, wọ́n á sì lè túbọ̀ sún mọ́ òun.

20 Ibi yòówù ká wà, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo wa máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ lọ́nà táá mú kí òtítọ́ wọ̀ wá lọ́kàn. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ déédéé lédè abínibí wa, ìgbàgbọ́ wa àti ti ìdílé wa á fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, àá sì fi hàn pé lóòótọ́ la mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Sm. 119:11.

^ [1] (ìpínrọ̀ 5) A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ [2] (ìpínrọ̀ 18) Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ṣe ìdílé rẹ láǹfààní, wo àpilẹ̀kọ náà, “Títọ́ Ọmọ Nílẹ̀ Òkèèrè​—Ìpèníjà àti Èrè Tó Wà Ńbẹ̀” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2002.