Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà

Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà

“Ìgbàgbọ́ ni . . . ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.”​—HÉB. 11:1.

ORIN: 54, 125

1. Ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú ìgbàgbọ́ tá a ní?

ÀNÍMỌ́ tó ṣe pàtàkì ni ìgbàgbọ́. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló nígbàgbọ́. (2 Tẹs. 3:⁠2) Bó ti wù kó rí, Jèhófà ń fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ń sìn ín ní “ìwọ̀n ìgbàgbọ́” tí wọ́n nílò. (Róòmù 12:3; Gál. 5:22) Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ mọyì ohun tí wọ́n ní.

2, 3. (a) Ìbùkún wo làwọn tó nígbàgbọ́ máa rí gbà? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?

2 Jésù Kristi sọ pé Jèhófà ń fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ òun. (Jòh. 6:​44, 65) Tá a bá nígbàgbọ́ nínú Jésù, àá rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ìyẹn á sì jẹ́ ká ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà títí lọ gbére. (Róòmù 6:23) Ìbùkún ńlá mà nìyẹn o! Àmọ́, ṣé á lẹ́tọ̀ọ́ sí i? Rárá, ìdí ni pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ikú ló sì tọ́ sí wa. (Sm. 103:10) Àmọ́ Jèhófà rí i pé a ṣì lè ṣe ohun tó dáa. Torí bẹ́ẹ̀, ó fojúure hàn sí wa, ó sì mú ká tẹ́tí sí ìhìn rere. Ìyẹn ló mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, a sì nírètí àtigbé títí láé nínú ayé tuntun.​—Ka 1 Jòhánù 4:​9, 10.

3 Àmọ́, kí ni ìgbàgbọ́? Ṣé téèyàn bá ti mọ àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí fún wa, ṣó ti nígbàgbọ́ nìyẹn? Ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù ni pé, àwọn ọ̀nà wo la lè gbà lo ìgbàgbọ́?

‘LO ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ỌKÀN RẸ’

4. Ṣàlàyé ìdí tí ìgbàgbọ́ fi kọjá kéèyàn kàn lóye àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe.

4 Ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ kọjá kéèyàn kàn lóye àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ téèyàn ní láá mú kó máa wù ú láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ tá a ní pé Ọlọ́run máa gba aráyé là máa ń mú ká wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Bí ìwọ bá polongo ‘ọ̀rọ̀ yẹn tí ń bẹ ni ẹnu ìwọ alára’ ní gbangba, pé Jésù ni Olúwa, tí o sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú, a ó gbà ọ́ là. Nítorí ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.”​—Róòmù 10:​9, 10; 2 Kọ́r. 4:⁠13.

5. Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ fi ṣe pàtàkì, kí la sì lè ṣe láti mú kó túbọ̀ lágbára? Ṣàpèjúwe.

5 Ó ṣe kedere pé tá a bá máa ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, ó ṣe pàtàkì ká nígbàgbọ́, ìgbàgbọ́ ọ̀hún ò sì gbọ́dọ̀ kú. A lè fọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ wé òdòdó téèyàn máa ń bomi rin. Tá a bá ń bomi rin òdòdó, á máa jà yọ̀yọ̀ á sì máa rú sí i, àmọ́ tá ò bá bomi rin ín, á bẹ̀rẹ̀ sí í rọ, tó bá sì yá, á kú. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ rí. Tá ò bá ṣọ́ra, ìgbàgbọ́ wa lè kú. (Lúùkù 22:32; Héb. 3:12) Àmọ́, tá a bá ń kíyè sí bí ìgbàgbọ́ wa ṣe rí, àá máa ṣe ohun táá jẹ́ kó lágbára, ìgbàgbọ́ wa máa “gbèrú,” àá sì jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.”​—2 Tẹs. 1:3; Títù 2:⁠2.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÌGBÀGBỌ́

6. Orí nǹkan méjì wo ni Hébérù 11:1 sọ pé ìgbàgbọ́ dá lé?

6 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Hébérù 11:1. (Kà á.) Ó jẹ́ ká mọ̀ pé orí ohun méjì tí a kò lè fojú rí ni ìgbàgbọ́ dá lé: (1) “Ohun tí a ń retí.” Lára rẹ̀ ni àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àmọ́ tí kò tíì ṣẹlẹ̀, bí ìgbà tí Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà búburú, táá sì sọ ayé di Párádísè. (2) “Àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” Nínú ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìfihàn gbangba-gbàǹgbà” túmọ̀ sí “àwọn ẹ̀rí tó dáni lójú” pé àwọn ohun tá ò lè fojú rí wà lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, a gbà pé Jèhófà Ọlọ́run, Jésù Kristi àtàwọn áńgẹ́lì wà, bẹ́ẹ̀ náà la sì gbà pé Ìjọba Ọlọ́run wà lẹ́nu iṣẹ́. (Héb. 11:⁠3) Báwo la ṣe lè fi hàn pé ohun tá à ń retí ṣì wà lọ́kàn wa digbí àti pé a gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ bá ò tiẹ̀ rí àwọn nǹkan ọ̀hún? Kì í ṣe pé ká kàn sọ pé a nígbàgbọ́, àmọ́ ó tún gbọ́dọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa.

7. Báwo ni àpẹẹrẹ Nóà ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí ìgbàgbọ́ jẹ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

7 Hébérù 11:7 sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ Nóà. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, [Nóà] fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.” Nóà fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nígbà tó kan ọkọ̀ áàkì. Kò sí àní-àní pé àwọn aládùúgbò rẹ̀ á máa béèrè ìdí tó fi ń kan ọkọ̀ gàgàrà yẹn lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣé Nóà kàn dákẹ́ ni àbí ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má yọ òun lẹ́nu? Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀! Torí pé ó nígbàgbọ́, ó fìgboyà wàásù fún wọn, ó sì kìlọ̀ fún wọn nípa ìdájọ́ Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jèhófà ṣe sọ ọ̀rọ̀ náà fún Nóà lòun náà ṣe sọ ọ́ fáwọn èèyàn pé: “Òpin gbogbo ẹlẹ́ran ara ti dé iwájú mi, nítorí tí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nítorí wọn . . . Èmi yóò mú àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé láti run gbogbo ẹran ara tí ipá ìyè ń ṣiṣẹ́ nínú wọn lábẹ́ ọ̀run. Ohun gbogbo tí ó wà ní ilẹ̀ ayé yóò gbẹ́mìí mì.” Ó dájú pé Nóà tún máa sọ ohun táwọn èèyàn náà gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Á sọ fún wọn pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ wọnú áàkì náà.’ Ohun tí Nóà ṣe yìí mú kó túbọ̀ fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Abájọ tí Bíbélì fi pè é ní “oníwàásù òdodo.”​—Jẹ́n. 6:​13, 17, 18; 2 Pét. 2:⁠5.

8. Kí ni Jákọ́bù sọ nípa ìgbàgbọ́?

8 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tí ìgbàgbọ́ jẹ́ nínú ìwé Hébérù ni Jákọ́bù kọ lẹ́tà rẹ̀. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, Jákọ́bù náà ṣàlàyé pé ìgbàgbọ́ kọjá kéèyàn kàn gba nǹkan gbọ́, èèyàn gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ tì í. Jákọ́bù wá sọ pé: “Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí láìsí àwọn iṣẹ́, èmi yóò sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.” (Ják. 2:18) Jákọ́bù tún jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín kéèyàn kàn gba nǹkan gbọ́ àti kéèyàn lo ìgbàgbọ́. Ó ṣe tán, àwọn ẹ̀mí èṣù náà gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ wọn ò nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Dípò kí wọ́n lo ìgbàgbọ́, ṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n á ṣe dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́. (Ják. 2:​19, 20) Àmọ́ nígbà tí Jákọ́bù máa sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù, ó sọ pé: “A kò ha polongo Ábúráhámù baba wa ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́ lẹ́yìn tí ó ti fi Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ? Ẹ̀yin rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àti nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀ a sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé.” Kó lè túbọ̀ ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn, Jákọ́bù sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.”​—Ják. 2:​21-23, 26.

9, 10. Báwo ni àpọ́sítélì Jòhánù ṣe jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa lo ìgbàgbọ́?

9 Ohun tó lé lọ́gbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Jòhánù kọ ìwé Ìhìn rere àtàwọn lẹ́tà rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ohun tí Jòhánù kọ nípa ìgbàgbọ́ bá ohun táwọn tó ti kọ̀wé ṣáájú rẹ̀ kọ mu. Nínú gbogbo àwọn tó lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “lo ìgbàgbọ́,” Jòhánù ló lo ọ̀rọ̀ náà jù nínú Bíbélì.

10 Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” (Jòh. 3:36) Torí náà, ẹni tó bá nígbàgbọ́ nínú Jésù gbọ́dọ̀ máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jòhánù máa ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Jésù tó fi hàn pé a ò gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ láti máa lo ìgbàgbọ́.​—Jòh. 3:16; 6:​29, 40; 11:​25, 26; 14:​1, 12.

11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì òtítọ́?

11 A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú ká lóye òtítọ́, ẹ̀mí mímọ́ yìí ló sì jẹ́ ká gba ìhìn rere náà gbọ́. (Ka Lúùkù 10:21.) Ṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó mú wa wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù, ẹni tí Bíbélì pè ní “Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.” (Héb. 12:⁠2) Ká lè fi hàn pé a mọyì ohun bàǹtà-banta tí Jèhófà ṣe yìí, ó yẹ ká máa gbàdúrà, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ìgbàgbọ́ wa lè túbọ̀ lágbára.​—Éfé. 6:18; 1 Pét. 2:⁠2.

O lè fi hàn pé o nígbàgbọ́ tó o bá ń wàásù fáwọn èèyàn nígbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Àwọn nǹkan wo ló máa fi hàn pé à ń lo ìgbàgbọ́?

12 Ó yẹ ká túbọ̀ máa lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà. A sì gbọ́dọ̀ ṣe èyí lọ́nà tó máa hàn kedere sáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ máa wàásù nìṣó, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. A tún gbọ́dọ̀ máa ṣe “ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10) Bákan náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀,” ká má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.​—Kól. 3:​5, 8-10.

ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ỌLỌ́RUN ṢE PÀTÀKÌ

13. Báwo ni ‘ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run’ ti ṣe pàtàkì tó? Kí ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀, kí sì nìdí?

13 Bíbélì sọ pé: ‘Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.’ (Héb. 11:⁠6) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ‘ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run’ wà lára “ìpìlẹ̀,” ìyẹn ohun tẹ́nì kan máa kọ́kọ́ nílò kó tó lè di Kristẹni tòótọ́, kó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ. (Héb. 6:⁠1) Lórí ìpìlẹ̀ yìí, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ fi àwọn ànímọ́ pàtàkì míì “kún ìgbàgbọ́ [wa],” ká lè dúró “nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”​—Ka 2 Pétérù 1:​5-7; Júúdà 20, 21.

14, 15. Kí nìdí tí ìfẹ́ fi ṣe pàtàkì bá a bá tiẹ̀ nígbàgbọ́?

14 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà làwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì mẹ́nu kan ìgbàgbọ́ ká lè mọ bí ànímọ́ yìí ti ṣe pàtàkì tó. Kò sí ànímọ̀ míì tí wọ́n mẹ́nu kàn tó bẹ́ẹ̀. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ìgbàgbọ́ ni ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ?

15 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fi ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wéra, ó sọ pé: ‘Bí mo bá ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè ńláńlá nípò pa dà, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.’ (1 Kọ́r. 13:⁠2) Jésù náà jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an nígbà tó dáhùn ìbéèrè táwọn kan bi í pé: “Èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?” (Mát. 22:​35-40) Ìfẹ́ kó ọ̀pọ̀ ànímọ́ míì mọ́ra, títí kan ìgbàgbọ́. Bíbélì sọ pé ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́.” Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká gba ohun tí Ọlọ́run sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́.​—1 Kọ́r. 13:​4, 7.

16, 17. Báwo làwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ ṣe lo ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ pa pọ̀? Èwo ló ṣe pàtàkì jù, kí sì nìdí?

16 Torí pé ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì lo àwọn ànímọ́ yìí pa pọ̀ kódà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan náà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n “gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀.” (1 Tẹs. 5:⁠8) Pétérù sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí [Jésù] rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i sójú nísinsìnyí, síbẹ̀ ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (1 Pét. 1:⁠8) Jákọ́bù bi àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Ọlọ́run yan àwọn tí í ṣe òtòṣì ní ti ayé láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́ àti ajogún ìjọba náà, èyí tí ó ṣèlérí fún àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àbí kò ṣe bẹ́ẹ̀?” (Ják. 2:⁠5) Jòhánù náà sọ pé: “Èyí ni àṣẹ [Ọlọ́run], pé kí a ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi, kí a sì máa nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”​—1 Jòh. 3:⁠23.

17 Lóòótọ́ ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì, àmọ́ lọ́jọ́ iwájú, kò ní sídìí láti nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run mọ́ torí pé wọ́n á ti ṣẹ. Nígbà yẹn, ayé tuntun tá à ń retí á ti dé. Àmọ́, títí ayé làá ṣì máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Nísinsìnyí, bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àwọn mẹ́ta wọ̀nyí; ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.”​—1 Kọ́r. 13:⁠13.

A NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÓ LÁGBÁRA

18, 19. Kí ni ìgbàgbọ́ tó lágbára tá a ní mú kó ṣeé ṣe, ta sì ni ọpẹ́ yẹ?

18 Lóde òní, àwa èèyàn Jèhófà ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Èyí ti mú káwa èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ, tá à ń gbé níbi gbogbo láyé máa gbé nínú Párádísè tẹ̀mí. Ìdí sì ni pé à ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí wa nínú Párádísè tẹ̀mí yìí. (Gál. 5:​22, 23) Kò sí àní-àní pé ìgbàgbọ́ tó lágbára àti ìfẹ́ tòótọ́ ló so wá pọ̀!

19 Kò sí ẹ̀dá èèyàn tó lè sọ pé òun lọpẹ́ tọ́ sí fún ohun tá à ń gbádùn yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run lọpẹ́ yẹ torí pé òun ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Èyí ti mú káwọn èèyàn túbọ̀ mọ̀ nípa Jèhófà, ó sì tún jẹ́ “àmì fún àkókò tí ó lọ kánrin tí a kì yóò ké kúrò.” (Aísá. 55:13) A dúpẹ́ pé Ọlọ́run máa “gbà [wá] là nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.” Kò sí àní-àní pé “ẹ̀bùn Ọlọ́run” ni. (Éfé. 2:⁠8) Ńṣe ni Párádísè tẹ̀mí yìí á túbọ̀ máa gbilẹ̀ títí dìgbà tí gbogbo olódodo máa di pípé, tí wọ́n á máa fayọ̀ sin Jèhófà, tí wọ́n á sì máa yin orúkọ rẹ̀ títí ayé. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà!