Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ?

Òótọ́ Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì

Òótọ́ Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì

Ṣé ó wù ẹ́ kó o mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì, irú ẹ̀dá tí wọ́n jẹ́, ibi tí wọ́n ti wá àti ohun tí wọ́n ń ṣe? Kò sí ibòmíì tó o ti lè rí ìdáhùn kọjá inú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí, ìyẹn Bíbélì. (2 Tímótì 3:16) Kí ni Bíbélì sọ nípa wọn?

  • Bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn áńgẹ́lì jẹ́ ẹ̀mí tí a ò lè fojú rí torí pé wọn kò ní “ẹran ara àti egungun.” Ọ̀run ni àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ń gbé, wọ́n sì lè dé ibi tí Ọlọ́run wà.​—Lúùkù 24:39; Mátíù 18:10; Jòhánù 4:24.

  • Àwọn ìgbà kan wà tí àwọn áńgẹ́lì wá sáyé tí wọ́n sì para dà di èèyàn kí wọ́n lè jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn. Àmọ́, tí wọ́n bá ti parí iṣẹ́ wọn, wọ́n á tún para dà di áńgẹ́lì.​—Àwọn Onídàájọ́ 6:​11-23; 13:​15-20.

  • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tí àwọn áńgẹ́lì bá para dà di èèyàn, ìrísí ọkùnrin ni wọ́n máa ń mú, Bíbélì sì máa ń fi hàn pé wọ́n jẹ́ ọkùnrin, àmọ́ kì í ṣe pé àwọn áńgẹ́lì kan jẹ́ ọkùnrin táwọn míì sì jẹ́ obìnrin. Bákan náà, wọ́n kì í gbéyàwó, wọ́n ò sì ń bímọ. Láfikún sí i, kì í ṣe pé àwọn áńgẹ́lì ti máa ń kọ́kọ́ jẹ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, yálà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìkókó, ọmọdé tàbí àgbàlagbà kí wọ́n tó wá lọ di áńgẹ́lì lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà dìídì dá àwọn áńgẹ́lì, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè wọ́n ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́.”​—Jóòbù 1:6; Sáàmù 148:​2, 5.

  • Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ahọ́n ènìyàn àti ti áńgẹ́lì,” èyí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ní èdè tí wọ́n fi ń bára wọn sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti lo àwọn áńgẹ́lì láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ rí, síbẹ̀ kò gbà wá láyè láti máa jọ́sìn wọn tàbí gbàdúrà sí wọn.​—1 Kọ́ríńtì 13:1; Ìṣípayá 22:​8, 9.

  • Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn áńgẹ́lì ló wà, èyí fi hàn pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn áńgẹ́lì ló wà. *​—Dáníẹ́lì 7:10; Ìṣípayá 5:11.

  • Àwọn áńgẹ́lì “tóbi jọjọ nínú agbára” ju àwa èèyàn lọ fíìfíì, orí wọn sì pé lọ́nà tó kàmàmà ju tàwa èèyàn lọ. Wọ́n tún yára gan-an lọ́nà tó bùáyà, èyí sì kọjá òye àwa èèyàn.​—Sáàmù 103:20; Dáníẹ́lì 9:​20-23.

  • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n àti òye àwọn áńgẹ́lì ju tàwa èèyàn lọ fíìfíì, síbẹ̀ ó níbi tágbára wọn mọ àti pé àwọn nǹkan kan ṣì wà tí wọn ò mọ̀.​—Mátíù 24:36; 1 Pétérù 1:12.

  • Àwọn áńgẹ́lì ní àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run dá mọ́ wọn, wọ́n sì tún lómìnira láti yan ohun tí wọ́n bá fẹ́. Torí náà, bíi ti àwa èèyàn, wọ́n lè yàn láti ṣe ohun rere tàbí ohun búburú. Ó dùn wá pé àwọn áńgẹ́lì kan yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.​—Júúdà 6.

^ ìpínrọ̀ 8 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a túmọ̀ sí ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nínú Ìṣípayá 5:​11, fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run lé ní ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù tàbí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù pàápàá!