Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Àṣìṣe

Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Àṣìṣe

Don àti Margaret * gbádùn bí ọmọbìnrin wọn àti ìdílé rẹ̀ ṣe wá kí wọn. Nígbà tí wọ́n fẹ́ máa lọ, Margaret, tó jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí oúnjẹ sísè àmọ́ tó ti wá fẹ̀yìn tì, pinnu láti se oúnjẹ aládùn kan fún wọn, ìyẹn màkàrónì àti ṣíìsì, tó jẹ́ oúnjẹ táwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ fẹ́ràn jù.

Gbogbo wọn ti wà lórí ìjókòó, Margaret gbé oúnjẹ náà wọlé, ó sì gbé e sórí tábìlì. Ó ṣí ọmọrí sókè, sí ìyàlẹ́nu rẹ̀ ó rí i pé omi ọbẹ̀ ṣíìsì nìkan ló wà nínú abọ́. Margaret ò rántí láti da màkàrónì tó dìídì fẹ́ sè sí i! *

Gbogbo wa la máa ń ṣe àṣìṣe, láìka ọjọ́ orí wa àti ìrírí tá a ní sí. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tá a sọ láìronú tàbí ká ṣe ohun kan lásìkò tí ò yẹ, ó sì lè jẹ́ pé ńṣe la gbójú fo ohun kan tàbí ká gbàgbé rẹ̀. Kí nìdí tá a fi ń ṣàṣìṣe? Kí la lè ṣe nígbà tá a bá ṣàṣìṣe? Ṣé a lè yẹra fún un? Tá a ba mọ irú ojú tó yẹ ká máa fi wo àṣìṣe, á jẹ́ ká lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí.

OJÚ TÍ ỌLỌ́RUN ÀTÀWỌN ÈÈYÀN FI Ń WO ÀṢÌṢE

Tí wọ́n bá yìn wá fún ohun tá a ṣe tó dáa, inú wa máa dùn. Tá a bá sì ṣàṣìṣe, kódà kó jẹ́ pé a ò mọ̀ọ́mọ̀ tàbí pé àwọn míì ò mọ̀ sí i, ṣé kò yẹ ká gba ẹ̀bi wa lẹ́bi? Àmọ́ ó gba pé ká ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.

Tá a bá ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, ó lè mú ká ronú pé àṣìṣe náà kò tó nǹkan, a sì lè yẹ̀ ẹ́ sórí ẹlòmíì tàbí ká tiẹ̀ sọ pé kì í ṣe àwa. Àmọ́ ibi tírú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń já sí kì í dáa. Ìṣòro náà lè má yanjú bọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n fìyà jẹ aláìṣẹ̀. Tí a kò bá tiẹ̀ jìyà àbájáde àṣìṣe wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé bópẹ́ bóyá, “olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”​—Róòmù 14:12.

Ọlọ́run mọ̀ pé a máa ń ṣe àṣìṣe. Ìwé Sáàmù sọ pé Ọlọ́run jẹ́ “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́”; kì í “wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ó mọ̀ pé aláìpé ni wá àti pé a lè ṣàṣìṣe, ó sì máa ń “rántí pé ekuru ni wá.”​—Sáàmù 103:​8, 9, 14.

Torí pé Ọlọ́run jẹ́ Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa, ó fẹ́ káwa ọmọ rẹ̀ máà wo àṣìṣe bí òun ṣe ń wò ó. (Sáàmù 130:3) Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wa ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà tó máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ṣàṣìṣe tàbí táwọn míì bá ṣàṣìṣe.

BÓ ṢE YẸ KÁ ṢE TÁ À BÁ ṢÀṢÌṢE

Lọ́pọ̀ ìgbà tẹ́nìkan bá ṣàṣìṣe, ẹni náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun rẹ̀ láti wá bó sẹ máa yẹ ẹ̀bi náà sórí àwọn míì tàbí kó máa ṣe àwáwí fún ohun tó sọ tàbí ohun tó ṣe. Dípò ìyẹn, tó o bá sọ̀rọ̀ tó dun ẹnì kan, oò ṣe kúkú tọrọ àforíjì kó o sì ṣàtúnṣe tó yẹ kí àjọṣe yín lè máa bá a lọ. Ṣé o ti ṣe ohun kan tí kò dáa tó wá dá wàhálà sílẹ̀ fún ẹ tàbí àwọn ẹlòmíì? Dípò tí wà á fi máa bínú síra ẹ̀ tàbí tí wà á fi máa di ẹ̀bi ru àwọn míì, oò ṣe kúkú wá ọ̀nà láti yanjú ọ̀rọ̀ náà? Tó o bá sẹ́ kanlẹ̀ pé kì í ṣèwọ, ọkàn rẹ kò ní balẹ̀, ńṣe lọ̀rọ̀ náà á sì máa fẹjú sí i. Kúkú kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe rẹ, kó o ṣàtúnṣe, kó sì tán síbẹ̀.

Tó bá jẹ́ pé ẹlòmíì ló ṣàṣìṣe, ó rọrùn gan-an fún wa láti fi hàn pé a kò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ṣe. Àmọ́ báwo ni ì bá ṣe dáa tó ká ní a bá lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù Kristi nígbà tó sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Tó o bá ṣe àṣìṣe, kódà kó má tó nǹkan, wàá fẹ́ káwọn míì fi àánú hàn sí ẹ, kí wọ́n sì gbójú fo àṣìṣe tó o ṣe pátápátá. Kí ló dé tíwọ náà ó fi àánú hàn sí àwọn míì?​—Éfésù 4:32.

ÀWỌN ÌLÀNÀ TÓ LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́ LÁTI DÍN ÀṢÌṢE RẸ KÙ

Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ohun tó máa ń fa àṣìṣe ni “kéèyàn má ronú jinlẹ̀, kéèyàn má mọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ tàbí kéèyàn má fọkàn sí ohun tó ń ṣe.” Ó yẹ ká gbà pé gbogbo èèyàn pátá lóhun tá a mẹ́nu kàn yìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Síbẹ̀, àwọn ìlànà pàtàkì kan wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dín àṣìṣe wa kù. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn.

Ọ̀kan lára àwọn ìlànà yẹn wà nínú Òwe 18:​13, ó kà pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” Tá a bá lo àkókò díẹ̀ láti mọ ìdí ọ̀rọ̀ kan, tá a sì ronú lórí ohun tá a máa sọ dáadáa, kò ní jẹ́ ká fi ìwàǹwára hùwà tàbí ká sọ ohun tí kò yẹ ká sọ. Tá a bá fara balẹ̀ ká lè mọ ìdí ọ̀rọ̀ kan, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún sísọ̀rọ̀ láìronú jinlẹ̀, á sì dín àṣìṣe wa kù.

Ìlànà Bíbélì míì sọ pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kó o sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Tó o bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn míì, máa gba tiwọn rò kó o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Bákan náà, máa gbóríyìn fún wọn kó o sì máa fún wọn ní ìṣírí. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa jẹ́ káwọn èèyàn tètè máa dárí jì ẹ́ tó o bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí tó o ṣìwà hù. Tó bá sì jẹ́ àṣìṣe ńlá lo ṣe, ó máa jẹ́ kọ̀rọ̀ náà tètè yanjú.

Tó o bá ṣe àṣìṣe, sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe tó o ṣe. Dípò tí wàá fi máa ṣe àwáwí fún ọ̀rọ̀ tó o sọ tàbí ìwà tó o hù, ńṣe ni kó o wò ó bí ọ̀nà tó o lè gbà mú kí ìwà rẹ túbọ̀ dára sí i. Ṣé o máa nílò pé kó o túbọ̀ máa ṣe sùúrù, kó o jẹ́ onínúure kó o sì máa kó ara rẹ níjàánu? Àbí ó máa gba pé kó o túbọ̀ jẹ́ oníwà tútù, ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kó o sì máa fìfẹ́ hàn? (Gálátíà 5:​22, 23) Ó kéré tán, ó máa jẹ́ kó o mọ ohun tí kò yẹ kó o ṣe nígbà míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kó o gba ẹ̀bi rẹ lẹ́bi, síbẹ̀ má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ náà ká ẹ lára jù. Tó o bá fọ̀rọ̀ náà rẹ́rìn-ín, ó máa jẹ́ kó o tètè gbé e kúrò lọ́kàn.

A MÁA JÀǸFÀÀNÍ TÁ A BÁ NÍ ÈRÒ TÓ TỌ́

Tá a bá ní èrò tó tọ́ nípa àṣìṣe, kò ní jẹ́ ká ṣinú rò nígbà tó bá wáyé. Ó máa jẹ́ ká wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ọkàn wa á sì balẹ̀. Tá a bá sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe wa, ó máa sọ wá di ọlọ́gbọ́n, àwọn èèyàn á sì máa fẹ́ràn wa. Kò ní jẹ́ ká máa kárí sọ, a ò sì ní lérò tí kò tọ́ nípa ara wa. Tá a bá ń rántí pé àwọn míì náà ní àṣìṣe tiwọn tí wọ́n ń fẹ́ borí, ó máa jẹ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ wọn. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a máa rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ láti máa fara wé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run àti bó ṣe máa ń múra tán láti darí jini ní fàlàlà.​—Kólósè 3:13.

Ṣé àṣìṣe Margaret tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí wá ba ayọ̀ wọn jẹ́ lọ́jọ́ náà? Rárá o. Ńṣe ni gbogbo wọn fọ̀rọ̀ náà rẹ́rìn-ín, Margaret pàápàá fira ẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́, gbogbo wọn sì gbádùn oúnjẹ náà láìsí màkàrónì! Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ọmọ Margaret sọ ohun mánigbàgbé tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà fáwọn ọmọ wọn àti bí wọ́n ṣe mọyì àwọn òbí wọn àgbà. Ó ṣe tán, àṣìṣe lásán ni!

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ ìpínrọ̀ 3 Irú oúnjẹ kan ni màkàrónì àti ṣíìsì jẹ́. Wọ́n máa ń se màkàrónì, wọ́n á sì yí i pọ̀ mọ́ ọbẹ̀ tí wọ́n fi ṣíìsì ṣe.