Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń Darí Àwọn Èèyàn Rẹ̀

Jèhófà Ń Darí Àwọn Èèyàn Rẹ̀

“Jèhófà yóò máa ṣamọ̀nà rẹ nígbà gbogbo.”​AÍSÁ. 58:11.

ORIN: 152, 22

1, 2. (a) Báwo làwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yàtọ̀ sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn yòókù? (b) Àwọn nǹkan wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?

“TA NI aṣáájú yín?” Ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń bi àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn. Kò sì yà wá lẹ́nu torí pé ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló jẹ́ pé ọkùnrin tàbí obìnrin kan ló máa ń jẹ́ aṣáájú tàbí ọ̀gá wọn. Àmọ́ ní tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú wa máa ń dùn láti sọ pé kì í ṣe èèyàn aláìpé ni Aṣáájú wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù Kristi tí Ọlọ́run jí dìde ló ń darí wa, Jèhófà Baba rẹ̀ ló sì ń darí òun náà.​—Mát. 23:10.

2 Síbẹ̀, àwọn ọkùnrin mélòó kan wà tá a lè fojú rí tí Bíbélì pè ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tó ń múpò iwájú láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí. (Mát. 24:45) Torí náà, báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà gan-an ló ń darí wa nípasẹ̀ Jésù Kristi ọmọ rẹ̀ bá ò tiẹ̀ fojú rí i? Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti máa ń lo àwọn èèyàn kan láti múpò iwájú. Nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì, a máa jíròrò àwọn ohun mẹ́ta tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni Aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀, àti pé òun ló ń darí àwọn ọkùnrin tó ń múpò iwájú láàárín wọn láyé ìgbà yẹn àti lóde òní.​—Aísá. 58:11.

Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ ỌLỌ́RUN FÚN WỌN LÁGBÁRA

3. Kí ló fún Mósè lágbára láti darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

3 Ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn aṣojú Ọlọ́run lágbára. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ló yan Mósè ṣe aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí ló mú kó lè bójú tó ojúṣe ńlá yẹn? Bíbélì sọ pé Jèhófà “fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sínú rẹ̀.” (Ka Aísáyà 63:​11-14.) Bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ló tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún Mósè lágbára, ó ṣe kedere pé Jèhófà ló ń darí àwọn èèyàn rẹ̀.

4. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí Mósè? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

4 Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn ò lè fojú rí ẹ̀mí mímọ́, báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí Mósè? Ẹ̀mí mímọ́ mú kí Mósè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, ó sì mú kó kéde orúkọ Jèhófà fún Fáráò. (Ẹ́kís. 7:​1-3) Ẹ̀mí mímọ́ tún mú kí Mósè jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́, ọlọ́kàn tútù àti onísùúrù, àwọn ànímọ́ yìí ló sì mú kó lè darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ ò rí i pé Mósè yàtọ̀ pátápátá sáwọn aṣáájú àwọn orílẹ̀-èdè míì, tí wọ́n jẹ́ amúnisìn àti onímọtara-ẹni-nìkan! (Ẹ́kís. 5:​2, 6-9) Ọ̀rọ̀ náà ṣe kedere pé Jèhófà ló yan Mósè láti jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

5. Ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe fún àwọn ọkùnrin míì lágbára láti darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

5 Nígbà tó yá, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà fún àwọn ọkùnrin míì tí Jèhófà yàn lágbára kí wọ́n lè darí àwọn èèyàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ‘Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n.’ (Diu. 34:9) “Ẹ̀mí Jèhófà” bà lé Gídíónì. (Oníd. 6:34) Bákan náà, ‘ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lára Dáfídì.’ (1 Sám. 16:13) Gbogbo àwọn ọkùnrin yẹn gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ẹ̀mí mímọ́ náà sì mú kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan àgbàyanu tí wọn ò lè fagbára wọn ṣe. (Jóṣ. 11:​16, 17; Oníd. 7:​7, 22; 1 Sám. 17:​37, 50) Torí náà, Jèhófà ni ìyìn yẹ fún gbogbo iṣẹ́ ribiribi táwọn èèyàn náà ṣe.

6. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣègbọràn sáwọn tó ń darí wọn?

6 Kí ló yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà tó ṣe kedere sí wọn pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló fún àwọn ọkùnrin yẹn lágbára? Ṣe ló yẹ kí wọ́n ṣègbọràn sí wọn. Nígbà táwọn èèyàn náà ń kùn sí Mósè, Jèhófà bi Mósè pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ènìyàn yìí yóò máa hùwà àìlọ́wọ̀ sí mi?” (Núm. 14:​2, 11) Kò sí àní-àní, Jèhófà ni Aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì yan Mósè, Jóṣúà, Gídíónì àti Dáfídì láti ṣojú òun. Torí náà, táwọn èèyàn náà bá ṣègbọràn sáwọn ọkùnrin yẹn, Jèhófà tó jẹ́ Aṣáájú wọn ni wọ́n ń ṣègbọràn sí.

ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́

7. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ran Mósè lọ́wọ́?

7 Àwọn áńgẹ́lì ran àwọn aṣojú Ọlọ́run lọ́wọ́. (Ka Hébérù 1:​7, 14.) Jèhófà lo àwọn áńgẹ́lì láti gbéṣẹ́ fún Mósè kí wọ́n sì tọ́ ọ sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run rán Mósè “gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso àti olùdáǹdè láti ọwọ́ áńgẹ́lì tí ó fara hàn án nínú igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún.” (Ìṣe 7:35) Jèhófà tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì fún Mósè láwọn Òfin táá fi máa tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà. (Gál. 3:19) Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: “Ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn náà lọ sí ibi tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀. Wò ó! Áńgẹ́lì mi yóò lọ ṣáájú rẹ.” (Ẹ́kís. 32:34) Bíbélì kò sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fojú rí àwọn áńgẹ́lì nígbà tí wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ yẹn. Àmọ́ bí Mósè ṣe ń darí wọn, tó sì ń tọ́ wọn sọ́nà mú kó ṣe kedere pé àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń ràn án lọ́wọ́.

8. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ran Jóṣúà àti Hesekáyà lọ́wọ́?

8 Lẹ́yìn ikú Mósè, áńgẹ́lì kan tí Bíbélì pè ní “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà” fún Jóṣúà lágbára láti ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sójú ogun nígbà tí wọ́n ń bá àwọn ọmọ Kénáánì jà. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló sì ṣẹ́gun. (Jóṣ. 5:​13-15; 6:​2, 21) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọba Hesekáyà kojú àwọn àkòtagìrì ọmọ ogun Ásíríà tí wọ́n wá gbógun ja Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo, “áńgẹ́lì Jèhófà tẹ̀ síwájú láti jáde lọ, ó sì ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] balẹ̀.”​—2 Ọba 19:35.

9. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣojú Ọlọ́run jẹ́ aláìpé, kí ni Jèhófà retí pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe?

9 Ohun kan ni pé ẹni pípé làwọn áńgẹ́lì tó ran àwọn ọkùnrin yẹn lọ́wọ́, àmọ́ àwọn ọkùnrin náà kì í ṣe ẹni pípé. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Mósè kò gbógo fún Jèhófà. (Núm. 20:12) Jóṣúà kò wádìí lọ́wọ́ Jèhófà kó tó bá àwọn ará Gíbéónì dá májẹ̀mú. (Jóṣ. 9:​14, 15) Ìgbà kan wà tí Hesekáyà gbéra ga. (2 Kíró. 32:​25, 26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn ọkùnrin yẹn, Jèhófà retí pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣègbọràn sí wọn. Jèhófà ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti máa ran àwọn aṣojú rẹ̀ lọ́wọ́. Ó ṣe kedere pé Jèhófà ló ń darí àwọn èèyàn rẹ̀.

ỌLỌ́RUN FI Ọ̀RỌ̀ RẸ̀ RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́

10. Báwo ni Òfin Ọlọ́run ṣe tọ́ Mósè sọ́nà?

10 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ àwọn aṣojú Ọlọ́run sọ́nà. Bíbélì pe Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní “Òfin Mósè.” (1 Ọba 2:3) Síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹni tó fún wọn lófin, Mósè alára náà sì gbọ́dọ̀ pa Òfin yẹn mọ́. (2 Kíró. 34:14) Lẹ́yìn tí Jèhófà ti sọ bí wọ́n ṣe máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn, Ìwé Mímọ́ sọ pé ‘Mósè ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.’​—Ẹ́kís. 40:​1-16.

11, 12. (a) Kí ni Jèhófà sọ pé kí Jóṣúà àtàwọn ọba tó jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì máa ṣe? (b) Àǹfààní wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe àwọn tó darí àwọn èèyàn Ọlọ́run?

11 Àtìgbà tí Jóṣúà ti ń darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ti ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọọ́lẹ̀. Jèhófà sọ fún un pé: ‘Kí o máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀.’ (Jóṣ. 1:8) Nígbà tó yá, àwọn ọba tó jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì náà ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ka Òfin náà lójoojúmọ́, kí wọ́n ṣe ẹ̀dà rẹ̀, kí wọ́n sì ‘máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin náà àti ìlànà inú rẹ̀ mọ́ nípa títẹ̀lé wọn.’​—Ka Diutarónómì 17:​18-20.

12 Àǹfààní wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe àwọn ọkùnrin tó darí àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà yẹn? Àpẹẹrẹ kan ni Ọba Jòsáyà. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàwárí ìwé kan tó ní Òfin Mósè nínú, akọ̀wé Jòsáyà kà á sí i létí. * Kí ni ọba náà wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé òfin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya.” Àmọ́, ohun tó ṣe jùyẹn lọ. Jòsáyà jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ òun sọ́nà, torí náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà run, òun àtàwọn aráàlú sì ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá, irú èyí tẹ́nì kan ò ṣe rí. (2 Ọba 22:11; 23:​1-23) Torí pé Jòsáyà àtàwọn aṣáájú míì tó bẹ̀rù Jèhófà gbà kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà, kíá ni wọ́n ṣàtúnṣe sí bí wọ́n ṣe ń darí àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn àtúnṣe yẹn sì mú káwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

13. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn ọba tó jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtàwọn aṣáájú ilẹ̀ abọ̀rìṣà?

13 Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín àwọn ọba rere tó jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtàwọn aṣáájú ilẹ̀ yòókù. Ìdí sì ni pé ọgbọ́n èèyàn lásánlàsàn ló ń darí àwọn aṣáájú ilẹ̀ yòókù. Gbogbo ìwàkíwà ayé yìí ló kún ọwọ́ àwọn ọmọ Kénáánì àtàwọn aṣáájú wọn, àwọn ìwà bíi bíbá ìbátan ẹni lòpọ̀, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, bíbá ẹranko lòpọ̀, fífi ọmọ rúbọ àti ìbọ̀rìṣà. (Léf. 18:​6, 21-25) Bákan náà, àwọn aṣáájú ilẹ̀ Bábílónì àti Íjíbítì kò ní àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìmọ́tótó. (Núm. 19:13) Àmọ́ ní tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn aṣáájú rere fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn jẹ́ mímọ́ nínú àti lóde, wọn ò hu ìwàkiwà, wọn ò sì ṣe ohun tó lè ba ìjọsìn wọn jẹ́. Ó dájú háún pé Jèhófà ló ń darí wọn.

14. Kí nìdí tí Jèhófà fi bá àwọn kan lára àwọn aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀ wí?

14 Kì í ṣe gbogbo àwọn ọba tó ṣàkóso àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́ ló pa òfin Ọlọ́run mọ́. Àwọn tó ṣàìgbọràn sí Jèhófà kọtí ikún sí ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Jèhófà bá àwọn kan lára wọn wí, ó rọ àwọn kan lóye, ó sì fàwọn míì rọ́pò wọn. (1 Sám. 13:​13, 14) Nígbà tí àsìkò sì tó lójú Jèhófà, ó yan ẹnì kan tó lọ́lá ju gbogbo àwọn tó tíì jẹ́ aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀ lọ.

JÈHÓFÀ YAN ẸNI PÍPÉ ṢE AṢÁÁJÚ ÀWỌN ÈÈYÀN RẸ̀

15. (a) Báwo làwọn wòlíì ṣe fi hàn pé Ọlọ́run máa yan aṣáájú tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀? (b) Ta ni aṣáájú tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ náà?

15 Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun máa yan aṣáájú kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fáwọn èèyàn òun. Bí àpẹẹrẹ, Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Wòlíì kan láti àárín ìwọ fúnra rẹ, ní àárín àwọn arákùnrin rẹ, bí èmi, ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbé dìde fún ọ, òun ni kí ẹ̀yin fetí sí.” (Diu. 18:15) Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ẹni yẹn máa jẹ́ “aṣáájú àti aláṣẹ.” (Aísá. 55:4) Lábẹ́ ìmísí, Dáníẹ́lì pe ẹni yẹn ní “Mèsáyà Aṣáájú.” (Dán. 9:25) Níkẹyìn, Jésù Kristi pe ara rẹ̀ ní “Aṣáájú” àwa èèyàn Ọlọ́run. (Ka Mátíù 23:10.) Tinútinú làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi tẹ̀ lé e, wọ́n sì tún jẹ́rìí sí i pé òun ni Jèhófà yàn ṣe aṣáájú. (Jòh. 6:​68, 69) Kí ló jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jésù Kristi ni Jèhófà yàn láti máa darí àwa èèyàn rẹ̀?

16. Kí ló fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ fún Jésù lágbára?

16 Ẹ̀mí mímọ́ fún Jésù lágbára. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, Jòhánù tó batisí rẹ̀ rí i “tí ọ̀run ń pínyà, àti pé, bí àdàbà, ẹ̀mí bà lé e.” Lẹ́yìn ìyẹn, “ẹ̀mí sún un láti lọ sínú aginjù.” (Máàkù 1:​10-12) Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run fún un lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà lára rẹ̀. (Ìṣe 10:38) Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ mú kí Jésù ní ìfẹ́, ayọ̀ àti ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó sì lo àwọn ànímọ́ yìí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Jòh. 15:9; Héb. 12:2) Jésù nìkan ló fi àwọn ànímọ́ yìí hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Èyí sì fi hàn kedere pé òun ni Jèhófà yàn ṣe aṣáájú àwa èèyàn Ọlọ́run.

Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ran Jésù lọ́wọ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi? (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ran Jésù lọ́wọ́?

17 Àwọn áńgẹ́lì ran Jésù lọ́wọ́. Kò pẹ́ sígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, “àwọn áńgẹ́lì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìránṣẹ́ fún un.” (Mát. 4:11) Wákàtí mélòó kan kí wọ́n tó pa á, “áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara hàn án, ó sì fún un lókun.” (Lúùkù 22:43) Ó dá Jésù lójú pé Jèhófà máa rán àwọn áńgẹ́lì láti ran òun lọ́wọ́ nígbàkigbà tóun bá nílò wọn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.​—Mát. 26:53.

18, 19. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ òun sọ́nà nínú ohun tó ń ṣe àti ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni?

18 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ Jésù sọ́nà. Àtìgbà tí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló ti ń jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ máa tọ́ òun sọ́nà. (Mát. 4:4) Kódà, ó ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ débi pé ó gbà kí wọ́n pa òun lórí òpó igi oró. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kó tó kú wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹ sí Mèsáyà lára. (Mát. 27:46; Lúùkù 23:46) Àmọ́ ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn máa ń da ọwọ́ bo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí kò bá ti bá àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn mu. Jésù sọ ohun tí wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn yẹn pé: “Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè [wọn] bọlá fún mi, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́.” (Mát. 15:​7-9) Ṣé irú àwọn èèyàn yẹn ni Jèhófà máa wá yàn ṣe aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀?

19 Yàtọ̀ sí pé Jésù jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ òun sọ́nà nínú àwọn nǹkan tó ṣe, ó tún máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn. Nígbà táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń bá a fa ọ̀rọ̀, kò lo ọgbọ́n ara rẹ̀ tàbí ìrírí rẹ̀ láti fún wọn lésì, kàkà bẹ́ẹ̀ Ìwé Mímọ́ ló fi ń dá wọn lóhùn. (Mát. 22:​33-40) Bákan náà, dípò táá fi máa sọ àwọn ìtàn dídùn fáwọn èèyàn nípa bí nǹkan ṣe rí lọ́run àti bóun àti Baba rẹ̀ ṣe dá àgbáálá ayé, ṣe ló “ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.” (Lúùkù 24:​32, 45) Jésù nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì máa ń yá a lára láti fi kọ́ àwọn míì.

20. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé Jèhófà ni ìyìn àti ògo yẹ? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín Jésù àti Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní? Báwo nìyẹn ṣe jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà yan ṣe aṣáájú?

20 Lóòótọ́ àwọn tó tẹ́tí sọ́rọ̀ Jésù gbà pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lárinrin, àmọ́ Jèhófà tó jẹ́ Olùkọ́ rẹ̀ ni Jésù gbógo fún. (Lúùkù 4:22) Nígbà tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan ń yin Jésù, ó pè é ní “Olùkọ́ Rere,” àmọ́ Jésù fìrẹ̀lẹ̀ dáhùn pé: “Èé ṣe tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run.” (Máàkù 10:​17, 18) Ẹ ò rí i pé Jésù yàtọ̀ pátápátá sí Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní tó di ọba tàbí aṣáájú ilẹ̀ Jùdíà ní nǹkan bí ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn ìgbà yẹn! Níbi ìpàdé ìlú kan, Hẹ́rọ́dù gúnwà pẹ̀lú aṣọ aláràbarà. Àwọn èrò tó pé jọ bẹ̀rẹ̀ sí í júbà rẹ̀ pé: “Ohùn ọlọ́run kan ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” Ó dájú pé ńṣe ni inú Hẹ́rọ́dù ń dùn bí wọ́n ṣe ń yìn ín. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Ní ìṣẹ́jú akàn, áńgẹ́lì Jèhófà kọlù ú, nítorí pé kò fi ògo fún Ọlọ́run; àwọn kòkòrò mùkúlú sì jẹ ẹ́, ó sì gbẹ́mìí mì.” (Ìṣe 12:​21-23) Ó ṣe kedere pé kò sí aláròjinlẹ̀ èèyàn kan tó máa sọ pé Jèhófà ló yan Hẹ́rọ́dù ṣe aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé Jèhófà ló yan Jésù, ìgbà gbogbo ló sì máa ń gbógo fún Jèhófà torí ó mọ̀ pé Jèhófà ni Aṣáájú Tó Ga Jù Lọ fún àwa èèyàn rẹ̀.

21. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Kì í ṣe ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ni Jésù fi máa ṣe aṣáájú àwa èèyàn Ọlọ́run. Ìdí sì ni pé lẹ́yìn tó jíǹde, ó sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Ó wá fi kún un pé: “Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:​18-20) Ní báyìí tí Jésù ti pa dà sọ́run, báwo láá ṣe máa darí àwa èèyàn Jèhófà? Àwọn wo ni Jèhófà yàn pé kó máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Kristi, tí wọ́n á sì máa múpò iwájú láàárín àwa èèyàn Jèhófà? Báwo làwa Kristẹni ṣe máa dá àwọn aṣojú Ọlọ́run mọ̀? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 12 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwé tí Mósè fọwọ́ ara rẹ̀ kọ nìyẹn.