Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Wàá Fọkàn sí Àwọn Ohun Tá A Ti Kọ Sílẹ̀?

Ṣé Wàá Fọkàn sí Àwọn Ohun Tá A Ti Kọ Sílẹ̀?

‘Nǹkan wọ̀nyí la kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin ètò àwọn nǹkan dé bá.’1 KỌ́R. 10:11.

ORIN: 11, 61

1, 2. Kí nìdí tá a fi máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọba mẹ́rin Júdà?

TÓ O bá ń rìn lọ, tó o wá rí i pé ẹnì kan yọ̀ ṣubú níwájú ẹ, ṣé wàá kàn gbabẹ̀ kọjá láìbìkítà àbí wàá rọra kọjá níbẹ̀? Wọ́n ṣáà máa ń sọ pé àgbà tó jìn sí kòtò, ó kọ́ ará yòókù lọ́gbọ́n. Bó ṣe rí náà nìyẹn tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọsìn wa. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè kọ́ látinú àṣìṣe àwọn míì, títí kan àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú Bíbélì.

2 Àwọn ọba Júdà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú fi ọkàn tó pé pérépéré sin Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n ṣe àwọn àṣìṣe tó rinlẹ̀. Kí la rí kọ́ nínú àṣìṣe wọn, kí la sì lè ṣe tá ò fi ní ṣe irú ẹ̀? Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àpẹẹrẹ yìí, àá jàǹfààní gan-an torí pé ìtọ́ni wa làwọn ohun tá a ti kọ sílẹ̀ nígbà ìṣáájú yẹn wà fún.Ka Róòmù 15:4.

TÁ A BÁ GBÁRA LÉ ÒYE ÈÈYÀN, ÌGBẸ̀YÌN RẸ̀ KÌ Í DÁA

3-5. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn tó pé pérépéré ni Ásà fi sin Jèhófà, àṣìṣe wo ló ṣe? (b) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Ásà fi gbára lé èèyàn nígbà tí Bááṣà gbéjà ko Júdà?

3 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Ásà, àá sì rí bá a ṣe lè jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí wa. Ásà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tí mílíọ́nù kan ọmọ ogun Etiópíà gbéjà ko ilẹ̀ Júdà, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí Bááṣà ọba Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Rámà, ìyẹn ìlú kan tó pààlà pẹ̀lú àgbègbè tí Ásà ti ń ṣàkóso. (2 Kíró. 16:1-3) Òye ara rẹ̀ ni Ásà gbára lé nínú ọ̀rọ̀ ti Bááṣà, ìdí nìyẹn tó fi bẹ Bẹni-hádádì ọba Síríà lọ́wẹ̀ pé kó lọ bá Bááṣà jà. Ṣé ọgbọ́n tí Ásà dá yẹn gbè é? Bíbélì sọ pé: “Gbàrà tí Bááṣà gbọ́ nípa èyí, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó jáwọ́ nínú kíkọ́ Rámà, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró.” (2 Kíró. 16:5) Tá a bá wò ó lóréfèé, ó lè dà bíi pé ọgbọ́n tí Ásà dá yẹn gbè é!

4 Àmọ́, ojú wo ni Jèhófà fi wo ohun tí Ásà ṣe yẹn? Ọlọ́run rán wòlíì Hánáánì pé kó bá Ásà wí torí pé kò gbára lé Jèhófà. (Ka 2 Kíróníkà 16:7-9.) Hánáánì sọ fún un pé: “Láti ìsinsìnyí lọ ogun yóò máa jà ọ́.” Lóòótọ́ Bááṣà dẹ̀yìn, àmọ́ ogun ò yé ja Ásà àtàwọn èèyàn rẹ̀ jálẹ̀ ọdún yòókù tó fi ṣàkóso.

5 Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Ọlọ́run yẹ ọkàn Ásà wò, ó sì rí i pé ọkàn tó pé pérépéré ló fi ń sin òun. (1 Ọba 15:14) Lójú Ọlọ́run, Ásà ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. Síbẹ̀, ó ní láti jìyà ìwà àìgbọ́n tó hù. Kí wá nìdí tí Ásà fi gbára lé ara rẹ̀ àti Bẹni-hádádì dípò Jèhófà? Ṣó ronú pé tóun bá ṣe àdéhùn ọlọ́rẹ̀ẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ọba Síríà tàbí tí Síríà bá gbèjà òun, ìyẹn á gbe òun ju kóun gbára lé Jèhófà lọ? Ṣó lè jẹ́ pé ìmọ̀ràn burúkú tí wọ́n gbà á ló jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀?

6. Kí la rí kọ́ lára àṣìṣe tí Ásà ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan.

6 Kí la rí kọ́ lára Ásà táá jẹ́ ká yẹ ọkàn wa wò? Tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro tó kà wá láyà, ó máa ń yá wa lára láti bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ kí la máa ń ṣe tó bá kan àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan? Ṣé a kì í gbára lé òye ara wa, ká sì wá bá a ṣe máa dá yanjú ìṣòro náà? Àbí ṣe la máa ń wo inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká lè fi ìlànà inú rẹ̀ sílò, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Jèhófà la gbára lé? Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan nínú ìdílé rẹ lè gbógun tì ẹ́ nígbà míì pé kó o má lọ sípàdé tàbí àpéjọ. O ò ṣe bẹ Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe? Ká sọ pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ, tí iṣẹ́ míì ò sì tètè yọjú ńkọ́? Ká wá sọ pé ìwọ àti ẹlòmíì tó fẹ́ gbà ẹ́ síṣẹ́ jọ ń sọ̀rọ̀, ṣé wàá lè sọ fún un pé á máa fún ẹ láyè láti lọ sípàdé àárín ọ̀sẹ̀? Ìṣòro yòówù ká ní, ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ inú Sáàmù sọ́kàn, pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.”Sm. 37:5.

KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ TÓ O BÁ KÓ ẸGBẸ́ BÚBURÚ?

7, 8. Àwọn àṣìṣe wo ni Jèhóṣáfátì ṣe, kí ló sì yọrí sí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

7 Kí la rí kọ́ lára Jèhóṣáfátì ọmọ Ásà? Ó láwọn ànímọ́ tó dáa. Ọ̀pọ̀ nǹkan dáadáa ló sì ṣe torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Àmọ́, àwọn ìgbà kan wà tó ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, ó bá Áhábù dána, ìyẹn ọba burúkú tó ṣàkóso ẹ̀yà Ísírẹ́lì mẹ́wàá tó wà ní àríwá. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbà kan tún wà tí Jèhóṣáfátì tẹ̀ lé Áhábù lọ gbéjà ko àwọn ará Síríà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wòlíì Mikáyà kìlọ̀ fún wọn. Díẹ̀ ṣíún báyìí ló kù kí wọ́n pa Jèhóṣáfátì lójú ogun, lẹ́yìn náà ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù. (2 Kíró. 18:1-32) Nígbà tó délé, wòlíì Jéhù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Ṣé èèyàn burúkú ni ó yẹ kí o ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣé àwọn tí ó kórìíra Jèhófà sì ni ó yẹ kí o nífẹ̀ẹ́?’Ka 2 Kíróníkà 19:1-3.

8 Ṣé Jèhóṣáfátì kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Lóòótọ́, ó ṣì ń fìtara ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ ó jọ pé kò kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sóun àti Áhábù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fi ìkìlọ̀ Jéhù sọ́kàn. Jèhóṣáfátì tún kó wọnú àjọṣe tí kò bọ́gbọ́n mu pẹ̀lú ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn Ọba Ahasáyà tó jẹ́ ọmọ Áhábù. Àwọn méjèèjì jọ dòwò pọ̀, wọ́n jọ kan àwọn ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n á fi máa ṣòwò. Àmọ́, pàbó ló já sí torí pé gbogbo ọkọ̀ náà ló fọ́ bà jẹ́.2 Kíró. 20:35-37.

9. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí kò sin Jèhófà?

9 Àpẹẹrẹ Jèhóṣáfátì tá a jíròrò tán yìí yẹ kó mú ká ṣàyẹ̀wò ọkàn wa. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ohun kan ni pé, ọba dáadáa ni Jèhóṣáfátì. Ó ṣe ohun tó tọ́, ó sì “fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ wá Jèhófà.” (2 Kíró. 22:9) Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí àwọn èèyàn búburú má kó èèràn ràn án tó bá bá wọn kẹ́gbẹ́. Rántí ohun tí ìwé Òwe sọ, pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Torí pé Jèhóṣáfátì bá Áhábù ṣọ̀rẹ́, ó rí láburú, kódà ẹ̀mí rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ lọ sí i. Ohun tó dáa ni tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè wá sin Jèhófà. Àmọ́, ó léwu gan-an tó bá di pé à ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí kò sin Jèhófà.

10. (a) Kí la rí kọ́ lára Jèhóṣáfátì tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó? (b) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tó bá di pé ká máa bá àwọn tí kò sin Jèhófà ṣọ̀rẹ́?

10 Báwo la ṣe lè fi ohun tá a kọ́ lára Jèhóṣáfátì sílò? Bí àpẹẹrẹ, ọkàn Kristẹni kan lè máa fà sẹ́ni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kó máa ronú pé òun ò rẹ́ni fẹ́ láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run. Àwọn ẹbí tí kì í ṣe Kristẹni lè máa sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé kó ‘tètè wá ẹnì kan fẹ́ kó tó pẹ́ jù.’ Àwọn míì sì lè máa ronú bíi ti arábìnrin kan tó sọ pé: “Gbogbo wa ló máa ń wù pé káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, ká sì láwọn ọ̀rẹ́ torí bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wa nìyẹn.” Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, á dáa kí Kristẹni kan ṣàṣàrò lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jèhóṣáfátì. Ó máa ń bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. (2 Kíró. 18:4-6) Àmọ́ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá Áhábù tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kẹ́gbẹ́, kò tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Ó yẹ kí Jèhóṣáfátì rántí pé Jèhófà máa ń wá àwọn tó ń fi ọkàn tó pé pérépéré sin òun. Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí náà nìyẹn torí Bíbélì sọ pé ojú Jèhófà “ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé,” àti pé Jèhófà ṣe tán láti “fi okun rẹ̀ hàn” nítorí wa. (2 Kíró. 16:9) Ó mọ ipò wa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ṣó dá lójú pé Jèhófà máa jẹ́ kó o láwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn tó máa nífẹ̀ẹ́ rẹ dénú? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, á ṣe bẹ́ẹ̀ fún ẹ!

Ronú lórí ewu tó wà nínú kéèyàn kó wọnú ìfẹ́ pẹ̀lú ẹni tí kò sin Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 10)

MÁ ṢE DI AGBÉRAGA

11, 12. (a) Báwo ni Hesekáyà ṣe fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ hàn? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi pinnu pé òun ò ní fìyà jẹ Hesekáyà?

11 Ìtàn Hesekáyà jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa ṣọ́ ọkàn wa. Ìgbà kan wà tí Olùṣàyẹ̀wò ọkàn fún Hesekáyà láǹfààní pé kó fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ hàn. (Ka 2 Kíróníkà 32:31.) Nígbà tí Hesekáyà ń ṣàìsàn, Ọlọ́run fún un ní àmì kan tó jẹ́ kó mọ̀ pé ó máa gbádùn. Àmì náà ni pé Jèhófà jẹ́ kí òjìji pa dà sẹ́yìn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí àmì yẹn làwọn ọmọ aládé Bábílónì fi rán àwọn aṣojú sí Hesekáyà. (2 Ọba 20:8-13; 2 Kíró. 32:24) Bíbélì sọ pé Jèhófà “fi í sílẹ̀,” ìyẹn ni pé Jèhófà ò sọ ohun tó yẹ kí Hesekáyà ṣe fáwọn ará Bábílónì náà. Ohun tí Hesekáyà wá ṣe ni pé ó mú àwọn ará Bábílónì yẹn rìn yíká, ó sì fi “gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀” hàn wọ́n. Ó ṣe kedere pé ìwà òmùgọ̀ yẹn ló fi “ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà” Hesekáyà hàn.

12 Bíbélì ò sọ ohun tó fà á tí Hesekáyà fi di agbéraga. Ṣó ṣeé ṣe kó jẹ́ tìtorí pé ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Ásíríà àbí torí pé Ọlọ́run wò ó sàn lọ́nà ìyanu? Ṣó lè jẹ́ torí pé ó ní “ọrọ̀ àti ògo” tó pọ̀ gan-an? Ohun yòówù kó jẹ́, torí pé Hesekáyà gbéra ga, kò mọyì àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ṣe fún un. Ó mà ṣe o! Lóòótọ́ ọkàn tó pérépéré ni Hesekáyà fi sin Jèhófà, síbẹ̀ ìgbà kan wà tó ṣe ohun tí kò tọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, “Hesekáyà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,” Jèhófà sì pinnu pé òun ò ní fìyà jẹ Hesekáyà àtàwọn èèyàn rẹ̀.2 Kíró. 32:25-27; Sm. 138:6.

13, 14. (a) Irú ipò wo ni Jèhófà ti lè ‘fi wá sílẹ̀ láti dán wa wò’? (b) Kí ló yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá ń yìn wá torí ohun rere tá a ṣe?

13 Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hesekáyà? Rántí pé kò pẹ́ sígbà tí Jèhófà bá Hesekáyà ṣẹ́gun Senakéríbù tó sì wo àìsàn rẹ̀ sàn ni Hesekáyà di agbéraga. Lónìí, táwa náà bá ṣàṣeyọrí nínú ohun kan, Jèhófà lè ‘fi wá sílẹ̀ láti dán wa wò,’ ká lè fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan ti lè ṣiṣẹ́ kára láti múra àsọyé tó ní, tó sì wá sọ àsọyé náà ní àpéjọ ńlá. Ká sọ pé ọ̀pọ̀ ló gbóríyìn fún un torí pé wọ́n gbádùn àsọyé náà, kí ni arákùnrin náà máa ṣe bí wọ́n ṣe ń yìn ín?

14 Á dáa ká rántí ọ̀rọ̀ Jésù nígbà táwọn èèyàn bá ń yìn wá, ó ní: “Nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn lé yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’ ” (Lúùkù 17:10) Ẹ jẹ́ ká máa rántí àpẹẹrẹ Hesekáyà táwọn èèyàn bá ń yìn wá. Ẹ̀mí ìgbéraga ni kò jẹ́ kí Hesekáyà mọyì àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ṣe fún un. Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe fún wa, a ò ní gbéra ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà la máa gbógo fún. Ó ṣe tán, Jèhófà ló fún wa ní Ìwé Mímọ́, òun náà ló sì ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tì wá lẹ́yìn.

ṢỌ́RA TÓ O BÁ FẸ́ ṢÈPINNU

15, 16. Kí nìdí tí Jèhófà fi pa dà lẹ́yìn Jòsáyà tó sì wá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀?

15 Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jòsáyà tó jẹ́ ọba rere? Ṣó o rántí ohun tó fà á tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀ tí wọ́n sì pa á? (Ka 2 Kíróníkà 35:20-22.) Jòsáyà “jáde lọ láti bá” Nékò ọba Íjíbítì “faga gbága” bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nékò sọ fún Jòsáyà pé òun ò níjà pẹ̀lú rẹ̀. Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ “láti ẹnu Ọlọ́run” ni Nékò sọ fún Jòsáyà. Kí wá nìdí tí Jòsáyà fi lọ bá Nékò jà? Bíbélì ò sọ fún wa.

16 Àmọ́ báwo ni Jòsáyà ṣe máa mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ni Nékò sọ? Ó kéré tán, Jòsáyà lè béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn wòlíì Jèhófà, ìyẹn Jeremáyà. (2 Kíró. 35:23, 25) Àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jòsáyà ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun míì ni pé Kákémíṣì ni Nékò ń lọ láti bá ìlú míì jagun, kì í ṣe Jerúsálẹ́mù tó wà lábẹ́ àkóso Jòsáyà. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ kò kan orúkọ Ọlọ́run, torí pé Nékò kò ṣáátá Jèhófà tàbí àwọn èèyàn Júdà. Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jòsáyà kò ro ọ̀rọ̀ náà jinlẹ̀ kó tó lọ bá Nékò jà. Ǹjẹ́ a rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ìtàn yìí? Tá a bá dojú kọ ìṣòro, á dáa ká wádìí ká lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe sí ìṣòro náà.

17. Tí ìṣòro kan bá yọjú, báwo la ò ṣe ní ṣàṣìṣe bíi ti Jòsáyà?

17 Tí ìṣòro kan bá yọjú, ó yẹ ká wá àwọn ìlànà Bíbélì tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ náà, ká sì fàwọn ìlànà náà sílò bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Nígbà míì, a lè fọ̀rọ̀ lọ àwọn alàgbà. A lè ti ro ọ̀rọ̀ náà sọ́tùn-ún sósì ká sì ti ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn alàgbà lè tọ́ka wa sáwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ míì táá jẹ́ ká túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ náà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kóun máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 4:20) Àmọ́, ká sọ pé lọ́jọ́ kan tó ti pinnu pé òun fẹ́ lọ sóde ẹ̀rí, ọkọ rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ pé òun á fẹ́ kó wà pẹ̀lú òun nílé. Ọkọ náà sọ pé á dáa káwọn jọ wà pa pọ̀ lọ́jọ́ yẹn torí pé ó ti ṣe díẹ̀ táwọn méjèèjì ti jọ wà pa pọ̀. Arábìnrin náà lè ronú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan, bí èyí tó sọ pé ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run àtèyí tó ní ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 5:29) Àmọ́, ó yẹ kó tún ronú lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ pé káwọn aya tẹrí ba fáwọn ọkọ wọn, àtèyí tó sọ pé ká máa gba tàwọn míì rò. (Éfé. 5:22-24; Fílí. 4:5) Ìbéèrè náà ni pé, ṣé ọkọ arábìnrin náà ta kò ó pé òun ò gbọ́dọ̀ rí i kó lọ sóde ẹ̀rí mọ́, àbí ó wulẹ̀ fẹ́ kí wọ́n jọ wà pa pọ̀ lọ́jọ́ yẹn nìkan? Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká máa fi ìlànà Jèhófà sílò bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.

JẸ́ KÍ ỌKÀN RẸ PÉ PÉRÉPÉRÉ KÓ O SÌ MÁA LÁYỌ̀

18. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

18 Torí pé aláìpé ni wá, a lè ṣe irú àṣìṣe táwọn ọba mẹ́rin tá a sọ̀rọ̀ wọn tán yìí ṣe. A lè máa gbára lé òye èèyàn láìfura, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, a lè di agbéraga tàbí ká ṣe àwọn ìpinnu láìkọ́kọ́ wádìí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe. A mà dúpẹ́ o, pé ibi tá a dáa sí ni Jèhófà ń wò, bó ṣe kíyè sí ibi táwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yẹn dáa sí! Jèhófà tún rí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ òun tó àti bó ṣe máa ń wù wá tó láti fi gbogbo ọkàn wa sin òun. Abájọ tó fi fún wa láwọn àpẹẹrẹ yìí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká lè kẹ́kọ̀ọ́, ká má bàa ṣàṣìṣe tó burú jáì. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì, ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa láwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀!