Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Wàá Yanjú Èdèkòyédè Kí Àlàáfíà Lè Jọba

Ṣé Wàá Yanjú Èdèkòyédè Kí Àlàáfíà Lè Jọba

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN rọ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ká máa wá àlàáfíà, ká sì jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Tí gbogbo wa bá lẹ́mìí àlàáfíà, kò ní sí gbọ́nmi-si-omi-ò-to nínú ìjọ, àlàáfíà sì máa jọba. Ìyẹn á mú kó máa wu àwọn míì láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọ.

Bí àpẹẹrẹ, babaláwo kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa lórílẹ̀-èdè Madagásíkà kíyè sí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá sọ pé, ‘Tí n bá máa ṣe ẹ̀sìn kankan, ajẹ́rìí ni màá ṣe.’ Nígbà tó yá, kò ṣe babaláwo mọ́, ó ṣe àwọn àtúnṣe tó gbà á lóṣù mélòó kan kí ìgbéyàwó rẹ̀ lè bófin mu, ó sì di olùjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run àlàáfíà.

Bíi ti ọkùnrin yẹn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló ń di Ẹlẹ́rìí lọ́dọọdún, tí wọ́n sì ń gbádùn àlàáfíà tí wọ́n ti ń wá lójú méjèèjì. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé tá a bá gba “owú kíkorò àti ẹ̀mí asọ̀” láyè, ó lè da àárín wa rú, kó sì fa wàhálà nínú ìjọ. (Ják. 3:14-16) Inú wa dùn pé Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tá a lè fi sílò tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò fi ní ṣẹlẹ̀, tí àárín wa sì máa túbọ̀ gún régé. Ká lè mọ bá a ṣe lè fi àwọn ìmọ̀ràn náà sílò, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ará kan yẹ̀ wò.

ÌṢÒRO ÀTI BÍ WỌ́N ṢE YANJÚ RẸ̀

“Èmi àti arákùnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ kì í gbọ́ ara wa yé. Lọ́jọ́ kan, ṣe la bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo mọ́ ara wa, bí àwọn méjì kan ṣe wọlé nìyẹn.”—CHRIS.

“Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí arábìnrin kan tá a jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí ṣàdédé lóun ò bá mi jáde mọ́. Kódà, kò bá mi sọ̀rọ̀ mọ́. Mi ò sì mọ ohun tó fà á.”—JANET.

“Àwa mẹ́ta la jọ ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Nígbà tó yá, ọ̀kan lára wa dágbére fún wa, mo sì rò pé ó ti kúrò. Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa fún ẹnì kejì, láìmọ̀ pé onítọ̀hún kò tíì gbé fóònù sílẹ̀.”—MICHAEL.

“Nínú ìjọ wa, aáwọ̀ kan ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì. Ni ọ̀kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ sí èkejì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín wọn yẹn kò dùn mọ́ àwọn ará nínú rárá.”—GARY.

O lè ronú pé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kò tó nǹkan. Síbẹ̀, tí wọn ò bá wá nǹkan ṣe sí wọn, ó lè dá wàhálà tí kì í tán bọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó sì lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àmọ́, a dúpẹ́ pé àwọn ará yìí fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, wọ́n sì yanjú èdèkòyédè wọn ní ìtùnbí-ìnùbí. Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo lo rò pé wọ́n lò tọ́rọ̀ náà fi yanjú?

“Ẹ má ṣe dá ara yín lágara [tàbí bínú] síra yín lójú ọ̀nà.” (Jẹ́n. 45:24) Jósẹ́fù ló fún àwọn arákùnrin rẹ̀ nímọ̀ràn yìí nígbà tí wọ́n ń pa dà sọ́dọ̀ bàbá wọn. Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn yẹn mọ́gbọ́n dání! Bí ẹnì kan bá tètè máa ń bínú, tí kì í sì í kó ara rẹ̀ níjàánu, ó lè múnú bí àwọn míì. Chris rí i pé ìgbéraga ló ń da òun láàmú àti pé òun ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ohun tóun máa ṣe fóun. Ó wù ú kó ṣàtúnṣe, torí náà ó bẹ arákùnrin tí wọ́n jọ pariwo mọ́ra wọn pé kó má bínú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kó ara rẹ̀ níjàánu. Ẹnì kejì rẹ̀ rí bí Chris ṣe ń sapá, òun náà sì ṣàtúnṣe. Ní báyìí, wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe jọ ń sin Jèhófà.

“Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Janet gbà pé òun lọ̀rọ̀ yẹn bá wí, òun sì gbọ́dọ̀ fi í sílò. Torí náà, ó pinnu pé òun máa bá arábìnrin kejì sọ̀rọ̀, káwọn jọ finúkonú. Nígbà tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀, Janet rọ arábìnrin náà pé kó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an tó fi pa òun tì. Ọ̀rọ̀ yẹn ò kọ́kọ́ rọrùn, àmọ́ bí wọ́n ṣe jọ ń fi pẹ̀lẹ́tù bára wọn sọ̀rọ̀ lọ̀rọ̀ náà ń níyanjú. Arábìnrin kejì wá rí i pé òun lòun ṣi Janet lóye àti pé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà kò kan Janet rárá. Torí náà, ó bẹ Janet, àwọn méjèèjì sì tún pa dà jọ ń lọ sóde ẹ̀rí.

“Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ.” (Mát. 5:23, 24) Inú Ìwàásù Lórí Òkè ni Jésù ti fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn yìí. Inú Michael bà jẹ́ gan-an nígbà tó rí i pé ohun tóun sọ nípa arákùnrin náà ò dáa rárá. Àmọ́, ó pinnu pé òun máa wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin náà. Ó lọ bá a, ó sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Michael sọ pé: “Ó dárí jì mí, ọ̀rọ̀ náà sì tán nínú rẹ̀.” Ní báyìí, wọ́n ti pa dà di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.

“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.” (Kól. 3:12-14) Nínú ọ̀rọ̀ tàwọn aṣáájú-ọ̀nà onírìírí méjì yẹn, alàgbà kan bi wọ́n láwọn ìbéèrè tó mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀, àwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé ó yẹ ká jẹ́ kí àìgbọ́ra-ẹni-yé tá a ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn míì? Ṣé a nídìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tá ò fi lè dárí ji ara wa ká sì jọ máa sin Jèhófà pa pọ̀ ní àlàáfíà?’ Wọ́n gba ìmọ̀ràn tí alàgbà náà fún wọn, wọ́n sì fi í sílò. Ní báyìí, àárín wọn ti gún, wọ́n sì ń bára wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.

Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ ọ́, á dáa kó o fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Kólósè 3:12-14 sílò. Èyí gba kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ọ̀pọ̀ sì ti rí i pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń mú kó rọrùn fáwọn láti dárí ji ẹni náà kọ́rọ̀ náà sì tán nínú wọn. Àmọ́ o, tó o bá rí i pé ọ̀rọ̀ náà ò tán nínú rẹ, ṣé o lè fi ìlànà tó wà nínú Mátíù 18:15 sílò? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo tẹ́nì kan ṣẹ ẹnì kejì rẹ̀ ni Jésù ń sọ nínú ẹsẹ yẹn, síbẹ̀ á dáa kó o fi ìlànà inú rẹ̀ sílò. Torí náà, lọ bá arákùnrin tàbí arábìnrin náà, kẹ́ ẹ sì fi pẹ̀lẹ́tù yanjú ọ̀rọ̀ náà.

Bíbélì tún sọ àwọn nǹkan míì tá a lè ṣe. Ohun tó dáa jù tá a lè ṣe ni pé ká máa fi “èso ti ẹ̀mí” ṣèwà hù. Àá tipa bẹ́ẹ̀ ní “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gál. 5:22, 23) Bí gírísì ṣe máa ń jẹ́ kí maṣíìnì kan ṣiṣẹ́ dáadáa, tá a bá ń fi àwọn ànímọ́ yìí ṣèwà hù, á rọrùn fún wa láti gbé ìgbésẹ̀ táá jẹ́ kí àárín wa máa lọ geerege.

ÀWỌN ÀNÍMỌ́ TÓ YÀTỌ̀ SÍRA MÁA Ń MÚ KÍ ÌJỌ DÙN

Ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ní, èyí sì lè mú kó rọrùn fún wa láti bára wa ṣọ̀rẹ́. Àmọ́ tá ò bá ṣọ́ra, ó tún lè fa wàhálà. Alàgbà kan tó nírìírí ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí, ó ní: “Ẹni tó máa ń tijú lè má fi bẹ́ẹ̀ gba ti ẹni tó máa ń yá mọ́ àwọn èèyàn. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn méjèèjì lè má fi bẹ́ẹ̀ jọni lójú, síbẹ̀ ó lè fa wàhálà.” Àmọ́ ṣé o rò pé tí ìwà ẹni méjì bá ti yàtọ̀ síra, wọn ò lè rẹ́? Ó dáa, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì méjì kan. Irú ẹni wo lo rò pé Pétérù jẹ́? O lè ronú pé ẹni tó máa ń sọ̀rọ̀ gan-an tó sì máa ń kù gìrì ṣe nǹkan ni. Àmọ́ Jòhánù ńkọ́? O lè wò ó pé á jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó sì máa ń ṣọ́ra ṣe. Ó lè nídìí tó o fi ronú bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó jọ pé ìwà wọn yàtọ̀ síra gan-an. Síbẹ̀, àwọn méjèèjì jọ ṣiṣẹ́ pọ̀. (Ìṣe 8:14; Gál. 2:9) Torí náà, ó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni tí ìwà wọn yàtọ̀ síra lè jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀.

Bí àpẹẹrẹ, bóyá ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe ẹnì kan nínú ìjọ rẹ máa ń múnú bí ẹ. Síbẹ̀, ó yẹ kó o rántí pé Kristi kú fún ẹni yẹn náà, ó sì yẹ kó o máa fìfẹ́ hàn sí i. (Jòh. 13:34, 35; Róòmù 5:6-8) Torí náà, kó o tó pinnu pé o ò ní bá ẹni náà ṣọ̀rẹ́ mọ́, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ohun tí ẹni yìí ń ṣe lòdì sí Ìwé Mímọ́? Ṣé ó ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa múnú bí mi ni? Àbí bá a ṣe ń ṣe nǹkan ló wulẹ̀ yàtọ̀?’ Bákan náà, ó ṣe pàtàkì gan-an kó o béèrè pé: ‘Èwo lára àwọn ànímọ́ dáadáa tó ní ni màá fẹ́ fara wé?’

Ó ṣe pàtàkì gan-an kó o ronú lórí ìbéèrè tó kẹ́yìn yẹn. Jẹ́ ká sọ pé ẹnì kan máa ń yá mọ́ àwọn èèyàn, ìwọ sì jẹ́ ẹni jẹ́jẹ́. Ó ṣeé ṣe kí ànímọ́ yẹn mú kó rọrùn fún ẹni yẹn láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí. O ò ṣe bá a ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀? Tó bá sì jẹ́ pé ọ̀làwọ́ lonítọ̀hún, tí ìwọ ò sì fi bẹ́ẹ̀ lawọ́, ìwọ náà ò ṣe máa lawọ́ sáwọn àgbàlagbà, àwọn aláìsàn tàbí àwọn aláìní, kíwọ náà lè nírú ayọ̀ táwọn ọ̀làwọ́ máa ń ní? Ohun tá à ń sọ ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ànímọ́ yín yàtọ̀, ìwọ àti onítọ̀hún lè dọ̀rẹ́ tó o bá gbájú mọ́ ibi tẹ́ni náà dáa sí. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò ní kẹ́ ẹ di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, àmọ́ ẹ̀ẹ́ mọyì ara yín, ọkàn rẹ máa balẹ̀, àlàáfíà sì máa wà nínú ìjọ.

Ó ṣeé ṣe kí Yúódíà àti Síńtíkè ní àwọn ànímọ́ tó yàtọ̀ síra gan-an. Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “ní èrò inú kan náà nínú Olúwa.” (Fílí. 4:2) Ǹjẹ́ kò ní dáa kí gbogbo wa ní èrò inú kan náà nínú Olúwa, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àlàáfíà jọba nínú ìjọ?

Ẹ YANJÚ ÈDÈKÒYÉDÈ TÓ BÁ WÁYÉ

Èpò tàbí koríko lè pa òdòdó téèyàn ò bá fa èpò náà tu. Lọ́nà kan náà, èrò tí kò dáa tá a ní sáwọn míì lè pa wá lára tá ò bá tètè fà á tu kúrò lọ́kàn wa. Yàtọ̀ síyẹn, téèyàn bá jẹ́ kí ìbínú ru bo òun lójú, ó lè ba àlàáfíà ìjọ jẹ́. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará wa, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yanjú èdèkòyédè tá a ní pẹ̀lú àwọn míì, kí àlàáfíà lè jọba láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.

Tó o bá lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, tó o sì yanjú èdèkòyédè tó wáyé, inú rẹ máa dùn gan-an pé o ṣe bẹ́ẹ̀

Tá a bá yanjú èdèkòyédè, tá a sì wá àlàáfíà, inú wa máa dùn gan-an pé a ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan, ó sọ pé: “Ó ṣe mí bíi pé arábìnrin kan ń fojú ọmọdé wò mí. Inú mi ò sì dùn sóhun tó ń ṣe yẹn. Torí bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi, tó bá bá mi sọ̀rọ̀, ṣe ni mo máa ń dá a lóhùn gán-ín. Mo ronú pé, ‘Torí kì í fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí, èmi náà ò ní máa bọ̀wọ̀ fún un.’ ”

Arábìnrin yẹn ronú nípa ìwà tó ń hù. Ó sọ pé: “Mo rí i pé ìwà tí mò ń hù kù díẹ̀ káàtó, inú mi ò sì dùn. Mo wá pinnu pé á dáa kí n yíwà mi pa dà. Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, mo ra ẹ̀bùn kan lọ fún arábìnrin náà, mo sì fi káàdì ìkíni kan kún un. Nínú káàdì yẹn, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì mí. Lẹ́yìn náà, a dì mọ́ra wa, a sì parí ọ̀rọ̀ náà. Látìgbà yẹn, a ò ní èdèkòyédè mọ́.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń wá àlàáfíà lójú méjèèjì, síbẹ̀ tẹ́nì kan kò bá bọ̀wọ̀ fún wọn tàbí tó fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn tí kò sin Jèhófà nìyẹn, àmọ́ ó yẹ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà. Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti sọ pé: “Èmi . . . pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tí ó yẹ ìpè tí a fi pè yín, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́, kí ẹ máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:1-3) “Ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà” yìí ṣe pàtàkì gan-an ni. Torí náà, ká jẹ́ kí ìdè náà túbọ̀ lágbára sí i, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé láàárín wa.