Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Ní Ọrọ̀ Tòótọ́

Bá A Ṣe Lè Ní Ọrọ̀ Tòótọ́

“Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo.”​LÚÙKÙ 16:9.

ORIN: 32, 154

1, 2. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kò sígbà tá ò ní láwọn tálákà nínú ayé yìí?

ỌRỌ̀ AJÉ tó dẹnu kọlẹ̀ ti mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn nílé lóko. Àwọn ọ̀dọ́ tó ń wáṣẹ́ kiri ló kún ìgboro. Ọ̀pọ̀ ló sì ń fi ẹ̀mí wọn wewu torí àtilọ sáwọn ilẹ̀ tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Kò síbi táwọn tálákà kò sí, kódà wọ́n wà láwọn ilẹ̀ tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn olówó túbọ̀ ń lówó, táwọn mẹ̀kúnnù sì túbọ̀ ń tòṣì. Àwọn kan tó ṣèwádìí lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé tí gbogbo èèyàn tó wà láyé bá jẹ́ ọgọ́rùn-ún, ìdá kan péré ló lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, owó tí ìdá kan yìí sì ní ju àpapọ̀ owó táwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún yòókù ní lọ. Bá ò tilẹ̀ rídìí ọ̀rọ̀ yìí délẹ̀délẹ̀, ohun kan tó dájú ni pé akúṣẹ̀ẹ́ lèyí tó pọ̀ jù láyé nígbà tí ìwọ̀nba díẹ̀ sì ní owó tí ìrandíran wọn ò lè ná tán. Ọ̀rọ̀ yìí bá ohun tí Jésù sọ mu, pé: “Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo.” (Máàkù 14:7) Kí ló fà á tí nǹkan fi rí bẹ́ẹ̀?

2 Jésù mọ̀ pé bí ọrọ̀ ajé ṣe máa nira nìyẹn títí Ìjọba Ọlọ́run á fi dé. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ètò ìṣèlú, ẹ̀sìn èké àti ètò ìṣòwò tí Ìṣípayá 18:3 pè ní “àwọn olówò arìnrìn-àjò” jẹ́ apá kan ayé Sátánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn Ọlọ́run kì í lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣèlú tàbí ẹ̀sìn èké, kò sí bí ọ̀pọ̀ wa ṣe lè yẹra pátápátá fún ìṣòwò nínú ayé Sátánì yìí.

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?

3 Ó yẹ káwa Kristẹni ronú nípa ojú tá a fi ń wo ọ̀rọ̀ ìṣòwò ayé yìí, ká bi ara wa pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè lo àwọn ohun ìní mi lọ́nà táá fi hàn pé mo jólóòótọ́ sí Jèhófà? Kí ni mo lè ṣe tí mi ò fi ní tara bọ ọ̀rọ̀ ìṣòwò ayé yìí? Àwọn ìrírí wo làwa èèyàn Jèhófà ní tó fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá lásìkò tí nǹkan nira yìí?’

ÀKÀWÉ ÌRÍJÚ TÓ JẸ́ ALÁÌṢÒDODO

4, 5. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìríjú inú àkàwé Jésù? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Jésù gbà wá?

4 Ka Lúùkù 16:​1-9. Ó yẹ ká ronú lórí àkàwé tí Jésù ṣe nípa ìríjú tàbí ìránṣẹ́ aláìṣòdodo. Lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn kan ìránṣẹ́ náà pé ó ń fi àwọn ohun ìní ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò, ìránṣẹ́ náà dọ́gbọ́n sọ́rọ̀ ara rẹ̀, ó “yan àwọn ọ̀rẹ́” tó lè ràn án lọ́wọ́ tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. * Àmọ́ o, kì í ṣe pé Jésù ń rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà wọn nínú ayé yìí. Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé “àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí” ló máa ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ ó fi àkàwé yẹn kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan.

5 Jésù mọ̀ pé nǹkan lè nira fáwa ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó ṣe rí fún ìránṣẹ́ inú àkàwé yẹn, àá sì wá bá a ṣe máa gbọ́ bùkátà ara wa nínú ayé yìí. Torí náà, Jésù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo, kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá kùnà, wọn [ìyẹn Jèhófà àti Jésù] yóò lè gbà yín sínú àwọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.” Kí la rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn tí Jésù gbà wá yìí?

6. Báwo la ṣe mọ̀ pé ọ̀rọ̀ káràkátà kò sí nínú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé?

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò sọ ìdí tó fi pe ọrọ̀ ní “àìṣòdodo,” Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ káràkátà kò sí lára ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé. Ó ṣe tán, gbogbo ohun tí Ádámù àti Éfà nílò ni Jèhófà fún wọn lọ́pọ̀ yanturu nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 2:​15, 16) Bákan náà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ẹ̀mí mímọ́ darí àwọn Kristẹni ìgbà yẹn tó fi jẹ́ pé “kò tilẹ̀ sí ẹni tí ń sọ pé èyíkéyìí lára àwọn ohun tí òun ní jẹ́ tòun; ṣùgbọ́n wọ́n ní ohun gbogbo ní àpapọ̀.” (Ìṣe 4:32) Wòlíì Aísáyà tiẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn máa gbádùn gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá sáyé. (Aísá. 25:​6-9; 65:​21, 22) Àmọ́ ní báyìí ná, àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní láti máa fọgbọ́n lo àwọn “ọrọ̀ àìṣòdodo” tá a ní nínú ayé yìí bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà.

BÁ A ṢE LÈ FỌGBỌ́N LO ỌRỌ̀ WA

7. Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Lúùkù 16:​10-13?

7 Ka Lúùkù 16:​10-13. Torí àǹfààní ara rẹ̀ ni ìríjú tó wà nínú àkàwé Jésù ṣe yan àwọn ọ̀rẹ́. Àmọ́ Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bá òun àti Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́ torí pé èyí á ṣe àwọn àtàwọn míì láǹfààní. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé àkàwé tí Jésù ṣe jẹ́ ká rí i pé bá a bá ṣe lo “ọrọ̀ àìṣòdodo” tá a ní máa fi hàn bóyá a jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ohun tí Jésù fẹ́ fàyọ ni pé a lè ‘fi ara wa hàn ní olùṣòtítọ́’ nínú bá a ṣe ń lo ọrọ̀ tá a ní. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

8, 9. Sọ àpẹẹrẹ báwọn kan ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń lo ọrọ̀ àìṣòdodo tí wọ́n ní.

8 Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ nínú bá a ṣe ń lo ọrọ̀ wa? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀. (Mát. 24:14) Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kékeré kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà ní kóló kékeré kan, ó sì máa ń fowó sínú rẹ̀ lóòrèkóòrè, kódà ó máa ń fi owó tó yẹ kó fi ra nǹkan ìṣeré sínú kóló náà. Nígbà tí kóló náà kún, ọmọbìnrin náà fi gbogbo owó inú rẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Arákùnrin míì lórílẹ̀-èdè Íńdíà ní oko àgbọn. Ìgbà kan wà tó kó àgbọn rẹpẹtẹ wá sí ọ́fíìsì àwọn tó ń túmọ̀ èdè Malayalam, ó mọ̀ pé wọ́n máa ń nílò àgbọn, tóun bá sì fún wọn lágbọn, ìyẹn á dín ìnáwó wọn kù. Ká sòótọ́, ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ làwọn tá a sọ yìí lò. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará nílẹ̀ Gíríìsì máa ń fi òróró ólífì, wàràkàṣì àtàwọn oúnjẹ míì ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì.

9 Arákùnrin kan wà tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Sri Lanka àmọ́ tó ti kó lọ sórílẹ̀-èdè míì. Ó ní ilé àti ilẹ̀ ní Sri Lanka, ó sì yọ̀ǹda ẹ̀ fáwọn ará kí wọ́n lè máa ṣèpàdé àtàwọn àpéjọ níbẹ̀, ó tún gbà káwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa gbébẹ̀. Arákùnrin náà lè máa fi ilé àti ilẹ̀ náà pawó, àmọ́ bó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀ fáwọn ará tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó mú kí nǹkan rọrùn fún wọn gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ní ilẹ̀ kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn ará máa ń yọ̀ǹda ilé wọn fún ìpàdé, èyí sì ti jẹ́ kó rọrùn fáwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn míì tí ò fi bẹ́ẹ̀ lówó láti máa ríbi ṣe ìpàdé láìsan owó kankan.

10. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùkún tá a máa rí tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́?

10 Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń fi hàn pé àwọn jẹ́ “olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù,” ìyẹn bí wọ́n ṣe ń lo ohun ìní wọn. Ó ṣe tán, ọrọ̀ tẹ̀mí níye lórí ju ohun ìní èyíkéyìí lọ. (Lúùkù 16:10) Báwo ló ṣe rí lára àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà pé àwọn ń lo owó àtohun ìní wọn fún Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀? Wọ́n mọ̀ pé táwọn bá jẹ́ ọ̀làwọ́, àwọn máa ní ọrọ̀ ‘tòótọ́.’ (Lúùkù 16:11) Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó máa ń fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù déédéé sọ àwọn ìbùkún tó ti rí, ó ní: “Bí mo ṣe máa ń fowó ṣètìlẹ́yìn ti jẹ́ kí n túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Mo rí i pé bí mo ṣe ń fowó ṣètìlẹ́yìn ti jẹ́ kí n túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Mo túbọ̀ ń dárí jini, mo túbọ̀ ń ní sùúrù, mo túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń mú nǹkan mọ́ra, mo sì máa ń gbàmọ̀ràn.” Ọ̀pọ̀ ti rí i pé báwọn ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́ ti mú káwọn ní ọrọ̀ tẹ̀mí.​—Sm. 112:5; Òwe 22:9.

11. (a) Tá a bá ń fi owó ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn, báwo nìyẹn ṣe fi hàn pé a ní ọgbọ́n tó gbéṣẹ́? (b) Báwo ni ọrẹ tá à ń ṣe ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

11 Bá a ṣe ń fi owó ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn tún fi hàn pé a ní ọgbọ́n tó gbéṣẹ́. Ó jẹ́ ká lè máa lo owó wa láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó lówó lọ́wọ́ àmọ́ tí wọn ò lè ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tàbí lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ máa ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń fowó ti iṣẹ́ ìwàásù náà lẹ́yìn. (Òwe 19:17) Owó tá a fi ń ṣètìlẹ́yìn ni ètò Ọlọ́run ń lò láti jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn ìtẹ̀jáde wa dé àwọn ilẹ̀ tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù, àmọ́ táwọn èèyàn ibẹ̀ ń wá sínú ètò Ọlọ́run gan-an. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ilẹ̀ bíi Kóńgò, Madagásíkà àti Rùwáńdà, ìgbà kan wà táwọn ará wa máa ń pebi mọ́nú kí wọ́n lè ní Bíbélì. Ìdí sì ni pé Bíbélì wọ́nwó gan-an, kódà owó iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kan tàbí owó oṣù kan ni wọ́n á tù jọ kí wọ́n tó lè ra Bíbélì. Àmọ́ ní báyìí, àwọn ọrẹ tá à ń ṣe ti mú kí “ìmúdọ́gba” wà, èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fún ètò Ọlọ́run láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè wọn kí wọ́n sì pín in fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìdílé títí kan àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:​13-15.) Nípa báyìí, àwọn tó ń fúnni àtàwọn tí wọ́n ń fún ti wá di ọ̀rẹ́ Jèhófà.

MÁ ṢE TARA BỌ ‘ÀWỌN ÌṢÒWÒ ÌGBÉSÍ AYÉ’

12. Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run?

12 Ọ̀nà míì tá a lè gbà bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́ ni pé ká má ṣe tara bọ ètò ìṣòwò ayé yìí, dípò bẹ́ẹ̀, ká máa fayé wa àtohun tá a ní wá ọrọ̀ tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù, bàbá ìgbàgbọ́ fi ilẹ̀ Úrì tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù sílẹ̀, ó sì ń gbé nínú àgọ́ bí Jèhófà ṣe sọ fún un, ìyẹn sì mú kó dọ̀rẹ́ Jèhófà. (Héb. 11:​8-10) Ọlọ́run ló gbẹ́kẹ̀ lé, kò sì fìgbà kan wá bó ṣe máa kó ọrọ̀ jọ torí tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run nìyẹn. (Jẹ́n. 14:​22, 23) Irú ìgbàgbọ́ yẹn ni Jésù rọ̀ wá pé ká ní nígbà tó ń sọ fún ọ̀dọ́kùnrin kan tó lówó pé: “Bí ìwọ bá fẹ́ jẹ́ pípé, lọ ta àwọn nǹkan ìní rẹ, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” (Mát. 19:21) Ọ̀dọ́kùnrin yẹn kò nírú ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní. Àmọ́ àwọn míì wà tó nírú ìgbàgbọ́ yẹn.

13. (a) Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún Tímótì? (b) Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò lónìí?

13 Tímótì náà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù pe Tímótì ní “ọmọ ogun àtàtà ti Kristi Jésù,” Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Kò sí ènìyàn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí ń kó wọnú àwọn iṣẹ́ òwò ìgbésí ayé, kí ó bàa lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ẹni tí ó gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun.” (2 Tím. 2:​3, 4) Lónìí, gbogbo àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò, títí kan àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Wọn ò jẹ́ kí onírúurú ìpolówó ọjà àtàwọn nǹkan míì táyé ń gbé lárugẹ mú kí wọ́n máa lépa ọrọ̀, wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí sọ́kàn pé: ‘Ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.’ (Òwe 22:7) Ohun tí Sátánì fẹ́ ká ṣe ni pé ká máa fi gbogbo ayé wa lépa bá a ṣe máa rí towó ṣe. Ohun táwọn kan ṣe ti mú kí wọ́n tọrùn bọ gbèsè tó gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọdún láti san. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń yáwó ní báǹkì fi kọ́lé, àwọn míì sì ń yáwó fi lọ sílé ìwé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì ń yáwó torí kí wọ́n lè ra mọ́tò olówó gọbọi tàbí kí wọ́n lè ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó táyé gbọ́ tọ́run mọ̀. A lè fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n tá a bá jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, tá ò tọrùn bọ gbèsè, tá a sì ń ra kìkì ohun tá a nílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé Ọlọ́run là ń sìnrú fún kì í ṣe ètò ìṣòwò inú ayé yìí.​—1 Tím. 6:10.

14. Tá a bá máa jẹ́ kóhun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, kí ló yẹ ká ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan.

14 Téèyàn bá máa jẹ́ kóhun díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ó gbọ́dọ̀ fi ohun tó ṣe pàtàkì jù sípò àkọ́kọ́. Wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan tó níléeṣẹ́ ńlá kan. Ó wu tọkọtaya yìí pé kí wọ́n pa dà sínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, torí náà wọ́n ta iléeṣẹ́ wọn, ọkọ̀ ojú omi wọn àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ní. Lẹ́yìn náà, wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó kọ́ oríléeṣẹ́ wa tuntun nílùú Warwick, New York. Ayọ̀ wọn ò lẹ́gbẹ́ nígbà táwọn míì nínú ìdílé wọn wá ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, òbí arákùnrin náà lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé yẹn. Bákan náà, ọmọbìnrin wọn àti ọkọ rẹ̀ náà wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan nílùú Colorado, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń fọjọ́ mélòó kan láàárín ọ̀sẹ̀ ṣiṣẹ́ ní báǹkì kan. Àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ gan-an débi pé wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó máa fi ojoojúmọ́ ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì máa san ìlọ́po mẹ́ta owó oṣù rẹ̀ fún un. Àmọ́ torí pé iṣẹ́ tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ yìí máa pa iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lára, torí náà kò gbà. Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí báwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń lo ara wọn fún Jèhófà. Àwọn tó ń fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wọn fi hàn pé àwọn mọyì jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, wọ́n sì gbà pé ọrọ̀ tẹ̀mí ṣe pàtàkì ju ohunkóhun téèyàn lè rí nínú ayé yìí lọ.

NÍGBÀ TÍ ỌRỌ̀ BÁ KÙNÀ

15. Kí ló máa mú kí Jèhófà bù kún wa?

15 Ọ̀pọ̀ máa ń rò pé Ọlọ́run ló bù kún àwọn tó lówó lọ́wọ́, àmọ́ kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Àwọn tó jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà” ni Jèhófà máa ń bù kún. (Ka 1 Tímótì 6:​17-19.) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Arábìnrin Lucia * gbọ́ pé wọ́n nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Alibéníà, ó ṣí lọ síbẹ̀ láti orílẹ̀-èdè Ítálì lọ́dún 1993. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́, ó gbà pé Jèhófà máa bójú tó òun. Ó kọ́ èdè ilẹ̀ náà débi pé ó ran àwọn tó lé lọ́gọ́ta [60] lọ́wọ́ láti wá sin Jèhófà. Lóòótọ́, ibi tí èyí tó pọ̀ jù lára wa ti ń wàásù lè má méso jáde bíi ti arábìnrin yẹn, síbẹ̀ gbogbo ohun tá a bá ṣe láti mú káwọn míì rí ọ̀nà ìyè kí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ Jèhófà máa fún wa láyọ̀ tí ò lẹ́gbẹ́.​—Mát. 6:20.

16. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ètò ìṣòwò ayé yìí lọ́jọ́ iwájú? (b) Kí ló yẹ ká ṣe ní báyìí tá a ti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

16 Jésù sọ pé: ‘Nígbà tí irúfẹ́ ọrọ̀ àìṣòdodo bẹ́ẹ̀ bá kùnà,’ kì í ṣe bóyá ó máa kùnà, ohun tí Jésù sọ mú kó dájú pé ó máa kùnà ni. (Lúùkù 16:9) Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ báǹkì ló ń kógbá sílé tí ọrọ̀ ajé sì ń dẹnu kọlẹ̀, àmọ́ kékeré lèyí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ètò ìṣòwò lọ́jọ́ iwájú. Láìpẹ́ gbogbo ètò Sátánì máa forí ṣánpọ́n, ì báà jẹ́ ti ìṣèlú, ẹ̀sìn èké tàbí ètò ìṣòwò. Wòlíì Ìsíkíẹ́lì àti Sefanáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wúrà àti fàdákà, ìyẹn ohun táwọn oníṣòwò kà sí pàtàkì kò ní wúlò mọ́ tó bá yá. (Ìsík. 7:19; Sef. 1:18) Báwo ló ṣe máa rí lára wa tó bá jẹ́ pé “ọrọ̀ àìṣòdodo” la fi gbogbo ayé wa kó jọ àmọ́ tá a wá pàdánù ọrọ̀ tòótọ́ nígbẹ̀yìn? Ṣe ló máa dà bí ẹni tó fi gbogbo ayé rẹ̀ ṣiṣẹ́ kó lè kówó jọ tìrìgàngàn àmọ́ tó wá rí i pé ayédèrú owó lòun ti fi gbogbo ayé òun kó jọ. (Òwe 18:11) Ohun tó dájú ni pé irú ọrọ̀ bẹ́ẹ̀ máa kùnà láìpẹ́. Torí náà, lo owó tó o ní láti bá Jèhófà àti Jésù dọ́rẹ̀ẹ́. Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé kò sóhun tá a ṣe láti kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run tó máa gbé, torí ohun tó máa jẹ́ ká ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà nìyẹn.

17, 18. Kí làwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú?

17 Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, a ò ní yálé gbé, a ò sì ní yáwó kọ́lé mọ́. Oúnjẹ máa wà lọ́pọ̀ yanturu, a ò sì ní náwó sórí àìsàn mọ́. Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà láyé máa gbádùn gbogbo ohun tó wà láyé yìí. A ò ní kó wúrà, fàdákà àtàwọn nǹkan iyebíye míì jọ torí pé a fẹ́ fi wọ́n ṣòwò, kàkà bẹ́ẹ̀ ìṣaralóge ni wọ́n máa wà fún. Igi, òkúta àtàwọn ohun ìkọ́lé míì tó jẹ́ ojúlówó máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti kọ́ àwọn ilé tó rẹwà. Àwọn ọ̀rẹ́ wa máa bá wa kọ́lé torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, kì í ṣe torí pé wọ́n fẹ́ gba owó lọ́wọ́ wa. Ṣe làá máa gbádùn gbogbo nǹkan tó wà láyé, a ó sì máa ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú ara wa.

18 Díẹ̀ rèé nínú gbogbo nǹkan táwọn tó bá Jèhófà àti Jésù dọ́rẹ̀ẹ́ máa gbádùn. Ṣe layọ̀ gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé máa kún nígbà tí wọ́n bá gbọ́ tí Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.”​—Mát. 25:34.

^ ìpínrọ̀ 4 Jésù ò sọ bóyá òótọ́ lẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ìránṣẹ́ náà. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí fẹ̀sùn kàn nínú Lúùkù 16:1 ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe làwọn kan fẹ́ bà á lórúkọ jẹ́. Àmọ́, ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ ká kọ́ ni ohun tí ìránṣẹ́ náà ṣe, kì í ṣe ohun tó fà á tí wọ́n fi fẹ́ lé e lẹ́nu iṣẹ́.

^ ìpínrọ̀ 15 Ìtàn ìgbésí ayé Arábìnrin Lucia Moussanett wà nínú Jí! July 8, 2003, ojú ìwé 24 sí 28.