Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’

‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’

“Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín.”​—FÍLÍ. 4:7.

ORIN: 76, 141

1, 2. Kí ló ṣẹlẹ̀ nílùú Fílípì tó sọ Pọ́ọ̀lù àti Sílà dèrò ẹ̀wọ̀n? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

NÍ NǸKAN bí ọ̀gànjọ́ òru, àwọn míṣọ́nnárì méjì ìyẹn Pọ́ọ̀lù àti Sílà wà nínú ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún nílùú Fílípì. Wọ́n de ẹsẹ̀ wọn mọ́ inú àbà, gbogbo ẹ̀yìn sì ń ro wọ́n nítorí lílù tí wọ́n lù wọ́n. (Ìṣe 16:​23, 24) Wẹ́rẹ́ báyìí ni gbogbo ẹ̀ bẹ̀rẹ̀! Láìṣẹ̀ láìrò, àwọn ará ìlú yẹn wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn alákòóso ìlú, wọ́n sì dájọ́ fún wọn láìgbọ́ tẹnu wọn. Wọ́n ya aṣọ mọ́ wọn lára, wọ́n sì fi ọ̀pá lù wọ́n. (Ìṣe 16:​16-22) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni Pọ́ọ̀lù, àmọ́ wọ́n fẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú bí wọn ò ṣe gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ kí wọ́n tó dájọ́ fún un. *

2 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe jókòó sínú ẹ̀wọ̀n tó ṣókùnkùn yẹn, ó ṣeé ṣe kó máa ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ó lè máa ronú nípa àwọn èèyàn tó wà nílùú Fílípì. Wọ́n yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ ìlú tí Pọ́ọ̀lù ti wàásù torí pé kò sí sínágọ́gù àwọn Júù níbẹ̀. Kódà, ẹ̀yìn òde ìlú lẹ́bàá odò kan làwọn Júù máa ń kóra jọ sí. (Ìṣe 16:​13, 14) Kí àwọn Júù tó lè ní sínágọ́gù níbì kan, ó kéré tán àwọn ọkùnrin Júù mẹ́wàá gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀. Ṣé torí pé àwọn ọkùnrin Júù tó wà ní Fílípì ò pé mẹ́wàá ni wọn ò ṣe ní sínágọ́gù ni? Ó jọ pé àwọn ọmọ ìlú Fílípì máa ń yangàn torí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù. (Ìṣe 16:21) Bóyá ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fojú pa Pọ́ọ̀lù àti Sílà rẹ́ pé Júù ni wọ́n, wọn ò tiẹ̀ ronú ẹ̀ pé wọ́n lè jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù láé. Èyí ó wù kó jẹ́, Pọ́ọ̀lù àti Sílà rèé nínú ẹ̀wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò.

3. Kí ló lè mú kí Pọ́ọ̀lù máa ṣe kàyéfì nígbà tí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n, síbẹ̀ kí ni kò jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sóun?

3 Ó tún ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máa ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn oṣù díẹ̀ sẹ́yìn. Òdìkejì Òkun Aegean ní Éṣíà Kékeré ni Pọ́ọ̀lù wà nígbà yẹn. Àmọ́, ẹ̀mí mímọ́ kò jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù wàásù láwọn àgbègbè kan níbẹ̀. Ṣe ló dà bíi pé ọ̀tọ̀ ni ibi tí ẹ̀mí mímọ́ fẹ́ darí rẹ̀ lọ. (Ìṣe 16:​6, 7) Ibo wá ni ẹ̀mí mímọ́ fẹ́ kó lọ? Pọ́ọ̀lù rí ìran kan nígbà tó wà ní Tíróásì, ó sì gbọ́ nínú ìran náà pé: “Rékọjá wá sí Makedóníà.” Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí ìran yìí, ó gbà pé ibi tí Jèhófà fẹ́ kóun lọ nìyẹn, ó sì kọrí síbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Ka Ìṣe 16:8-10.) Àmọ́ kò pẹ́ tí Pọ́ọ̀lù dé Makedóníà ló dèrò ẹ̀wọ̀n. Ó ṣeé ṣe kí èyí mú kí Pọ́ọ̀lù máa ronú pé, kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi? Ìgbà wo ni màá jáde lẹ́wọ̀n yìí? Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí àwọn èrò yìí paná ayọ̀ rẹ̀ tàbí kó mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ yingin. Ṣe lòun àti Sílà bẹ̀rẹ̀ sí í “gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run.” (Ìṣe 16:25) Ó dájú pé àlàáfíà Ọlọ́run ló mú kí ọkàn wọn balẹ̀.

4, 5. (a) Ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ wa lè gbà dà bíi ti Pọ́ọ̀lù? (b) Báwo ni nǹkan ṣe yí pa dà bìrí fún Pọ́ọ̀lù?

4 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti ṣe àwọn ìpinnu kan tó o gbà pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe lo ṣe, àmọ́ tí nǹkan ò wá rí bó o ṣe rò. Bóyá ṣe lo kan ìṣòro tàbí ohun kan ló ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé rẹ pa dà pátápátá. (Oníw. 9:11) O lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kí ló máa jẹ́ kó o gbà pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká pa dà sórí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Sílà.

5 Bí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣe ń kọrin ìyìn sí Jèhófà, àwọn nǹkan tí wọn ò lérò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀. Lójijì, ìmìtìtì ilẹ̀ kan ṣẹlẹ̀, ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà sì ṣí sílẹ̀ gbayawu. Gbogbo ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi de àwọn méjèèjì já. Nígbà tí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó fẹ́ pa ara rẹ̀, àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí mú kí ẹ̀ṣọ́ náà àti ìdílé rẹ̀ ṣèrìbọmi. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn agbófinró ìlú rán àwọn ẹ̀ṣọ́ pé kí wọ́n lọ dá Pọ́ọ̀lù àti Sílà sílẹ̀, wọ́n sì ní kí wọ́n máa bá ọ̀nà wọn lọ. Àmọ́ nígbà táwọn agbófinró náà rí i pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà àti pé àwọn ti fìyà jẹ wọ́n láìtọ́, ṣe ni àwọn agbófinró náà wá sìn wọ́n jáde kúrò nílùú. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà sọ pé káwọn tó lọ, àwọn gbọ́dọ̀ dágbére fún Lìdíà, ìyẹn arábìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi. Wọ́n sì tún lo àǹfààní yẹn láti fún àwọn ará níṣìírí. (Ìṣe 16:​26-40) Àbí ẹ ò rí i bí gbogbo nǹkan ṣe yí pa dà bìrí!

“Ó TA GBOGBO ÌRÒNÚ YỌ”

6. Àwọn nǹkan wo la máa jíròrò?

6 Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àti Sílà? Ohun tá a kọ́ ni pé Jèhófà lè gbọ̀nà àrà ṣe ohun tí a kò lérò, torí náà kò yẹ ká máa ṣàníyàn tá a bá ní ìṣòro. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára, èyí sì hàn nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Fílípì nípa bí àlàáfíà Ọlọ́run ṣe lè mú ká borí àníyàn. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Fílípì 4:​6, 7. (Kà á.) Lẹ́yìn náà, a máa wo àwọn àpẹẹrẹ míì nínú Bíbélì níbi tí Jèhófà ti gbọ̀nà àrà ṣe àwọn nǹkan. Yàtọ̀ síyẹn, a máa jíròrò bí “àlàáfíà Ọlọ́run” ṣe lè mú ká nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro wa.

7. Ẹ̀kọ́ wo ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ káwọn ará ní Fílípì kọ́ nínú lẹ́tà tó kọ sí wọn, ẹ̀kọ́ wo làwa náà sì lè kọ́ nínú ohun tó sọ?

7 Kò sí àní-àní pé táwọn ará ní Fílípì bá ń ka lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn, wọ́n á rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i àti bí Jèhófà ṣe dá òun àti Sílà nídè lọ́nà tí ẹnikẹ́ni ò lérò. Ẹ̀kọ́ wo ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n kọ́? Ẹ̀kọ́ náà ni pé kí wọ́n má ṣàníyàn. Ó ní kí wọ́n gbàdúrà, wọ́n á sì rí àlàáfíà Ọlọ́run. Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé “àlàáfíà Ọlọ́run . . . ta gbogbo ìrònú yọ.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ohun táwọn atúmọ̀ èdè kan tú gbólóhùn yìí sí ni pé àlàáfíà Ọlọ́run “ju ìmọ̀ gbogbo lọ” tàbí pé “ó tayọ òye eniyan.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé “àlàáfíà Ọlọ́run” kọjá gbogbo ohun tá a lè rò lọ. Nígbà míì, àwa fúnra wa lè má rí ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro wa, àmọ́ Jèhófà mọ ọ̀nà àbáyọ, ó sì lè gba ọ̀nà àrà kó wa yọ nínú ìṣòro náà.​—Ka 2 Pétérù 2:9.

8, 9. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fìyà jẹ Pọ́ọ̀lù ní Fílípì, àǹfààní wo nìyẹn mú wá? (b) Kí nìdí táwọn ará ní Fílípì fi máa gbà pé ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán?

8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún mẹ́wàá ti kọjá lẹ́yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àti Sílà, síbẹ̀ báwọn ará tó wà nílùú Fílípì yẹn ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà yẹn máa fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. Òótọ́ ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé ni ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará yẹn. Lóòótọ́ Jèhófà fàyè gba ìyà tó jẹ Pọ́ọ̀lù àti Sílà, síbẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn mú kí wọ́n lè ‘gbèjà ìhìn rere, kí wọ́n sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.’ (Fílí. 1:⁠7) Látìgbà yẹn, ó dájú pé àwọn agbófinró ìlú máa rò ó pé ẹ̀ẹ̀mejì kí wọ́n tó ṣe ohunkóhun sí àwọn Kristẹni tó wà níjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nílùú Fílípì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe ló mú kí Lúùkù tí wọ́n jọ rìnrìn-àjò lè dúró ní Fílípì lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi ibẹ̀ sílẹ̀. Èyí á sì mú kó ṣeé ṣe fún Lúùkù láti fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni nílùú náà lókun.

9 Àwọn ará tó wà ní Fílípì mọ̀ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Pọ́ọ̀lù ti fojú winá àwọn ìṣòro tó lékenkà, kódà àtìmọ́lé ló wà ní Róòmù nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn ará yẹn. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ní “àlàáfíà Ọlọ́run.”​—⁠Fílí. 1:​12-14; 4:​7, 11, 22.

“Ẹ MÁ ṢE MÁA ṢÀNÍYÀN NÍPA OHUNKÓHUN”

10, 11. Kí ló yẹ ká ṣe tí ìṣòro kan bá ń kó ìdààmú ọkàn bá wa, kí la lè máa retí?

10 Kí ni kò ní jẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, táá sì mú ká ní “àlàáfíà Ọlọ́run”? Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Fílípì pé àdúrà lòògùn àníyàn. Nígbà tá a bá ń ṣàníyàn, ṣe ló yẹ ká tú gbogbo ọkàn wa jáde nínú àdúrà. (Ka 1 Pétérù 5:​6, 7.) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó yẹ kó dá wa lójú pé á gbọ́ wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ àwọn oore tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa. Tá a bá ń rántí pé Jèhófà “lè ṣe ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò,” ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ máa túbọ̀ lágbára.​—⁠Éfé. 3:⁠20.

11 Ọ̀nà tí Jèhófà máa gbà dáhùn àdúrà wa lè yà wá lẹ́nu bó ṣe ṣe fún Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní Fílípì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè má ṣe nǹkan àrà fún wa, síbẹ̀ ó dájú pé ohun tá a nílò gan-an láá ṣe. (1 Kọ́r. 10:13) Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a máa fọwọ́ lẹ́rán, àá sì máa retí pé kí Jèhófà bá wa yanjú ìṣòro wa. Ó yẹ káwa náà ṣe ohun tó bá àdúrà wa mu. (Róòmù 12:11) Àwọn ìgbésẹ̀ tá a bá gbé máa jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé lóòótọ́ lọ̀rọ̀ náà ń jẹ wá lọ́kàn, Jèhófà á sì bù kún ìsapá wa. Síbẹ̀, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà lè ṣe ju ohun tá a fẹ́ àti ohun tá a béèrè lọ. Nígbà míì, Jèhófà lè dáhùn àdúrà wa lọ́nà tó máa yà wá lẹ́nu gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì táá jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ pé Jèhófà lè gba ọ̀nà àrà ṣe ohun tí a kò lérò.

ÀWỌN ÌGBÀ TÍ JÈHÓFÀ ṢE NǸKAN ÀRÀ FÁWỌN ÌRÁNṢẸ́ RẸ̀

12. (a) Kí ni Ọba Hesekáyà ṣe nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà gbógun tì í? (b) Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe yanjú ìṣòro yìí?

12 Nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ ìgbà la rí bí Jèhófà ṣe gba ọ̀nà àrà dáhùn àdúrà àwọn èèyàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Hesekáyà ló ń jọba nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà gbógun ja ilẹ̀ Júdà, ó sì ṣẹ́gun gbogbo àwọn ìlú tó yí Jerúsálẹ́mù ká. (2 Ọba 18:​1-3, 13) Lẹ́yìn náà, Senakéríbù gbógun ti ìlú Jerúsálẹ́mù. Kí ni Ọba Hesekáyà ṣe nígbà tó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá yìí ń kógun bọ̀? Ṣe ló gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ wòlíì Aísáyà. (2 Ọba 19:​5, 15-20) Síbẹ̀, Hesekáyà ò jókòó tẹtẹrẹ, ó san ìṣákọ́lẹ̀ tí Senakéríbù bù lé e, kó lè pẹ̀tù sọ́kàn rẹ̀. (2 Ọba 18:​14, 15) Nígbà tó yá, Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún ogun. (2 Kíró. 32:​2-4) Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀ yìí? Jèhófà rán áńgẹ́lì kan láti pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Senakéríbù ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo. Ká sòótọ́, Hesekáyà gan-an ò lè ronú ẹ̀ láé pé ohun tí Jèhófà máa ṣe nìyẹn!​—⁠2 Ọba 19:⁠35.

Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù?​—Jẹ́n. 41:42 (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. (a) Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù? (b) Kí ni nǹkan àgbàyanu tó ṣẹlẹ̀ sí Sárà ìyàwó Ábúráhámù?

13 Àpẹẹrẹ míì ni ti Jósẹ́fù ọmọkùnrin Jékọ́bù. Nígbà tí Jósẹ́fù wà lẹ́wọ̀n ní Íjíbítì, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ lè ronú pé òun máa di igbákejì Fáráò ọba Íjíbítì, tàbí pé Jèhófà máa lo òun láti gba ìdílé òun lọ́wọ́ ìyàn? (Jẹ́n. 40:15; 41:​39-43; 50:20) Ó dájú pé ohun tí Jèhófà ṣe kọjá gbogbo ohun tí Jósẹ́fù lérò. Tún ronú nípa Sárà tó jẹ́ ìyá àgbà fún Jósẹ́fù. Ṣé Sárà gbà pé Jèhófà lè jẹ́ kóun bímọ pẹ̀lú ọjọ́ orí òun, dípò kó jẹ́ pé ọmọ ìránṣẹ́ òun lòun á gbà ṣọmọ? Ká sòótọ́, Sárà ò lè ronú ẹ̀ láé pé Jèhófà lè jẹ́ kóun bímọ.​—⁠Jẹ́n. 21:​1-3, 6, 7.

14. Kí ló dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe?

14 Ohun kan ni pé, a ò retí pé kí Jèhófà gba ọ̀nà àrà mú gbogbo ìṣòro wa kúrò kí ayé tuntun tó dé. Àwa kọ́ la sì máa sọ fún Jèhófà pé kó ṣe iṣẹ́ ìyanu láyé wa. Síbẹ̀, Jèhófà ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ìgbàanì lọ́wọ́ lọ́nà àrà, kò sì tíì yí pa dà. (Ka Aísáyà 43:​10-13.) Torí náà, tá a bá ń ronú nípa èyí, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. Ó dá wa lójú pé Jèhófà lè ṣe ohunkóhun tó bá gbà ká lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 4:​7-9) Kí la rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ tí Bíbélì mẹ́nu kàn yìí? Àpẹẹrẹ Hesekáyà, Jósẹ́fù àti Sárà jẹ́ ká rí i pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, á ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó dà bíi pé kò ṣeé borí.

Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, á ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó dà bíi pé kò ṣeé borí

15. Kí ló máa jẹ́ ká ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” kí ló sì mú kí èyí ṣeé ṣe?

15 Báwo la ṣe lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run” kódà tá a bá níṣòro? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣìkẹ́ àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run wa. Ìràpadà tí “Kristi Jésù” ṣe nìkan ló mú ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fún wa ni bó ṣe pèsè ìràpadà yìí. Jèhófà máa ń tipasẹ̀ ìràpadà dárí jì wá, ìyẹn sì ń jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn, ká sì ní ẹ̀rí ọkàn rere.​—⁠Jòh. 14:6; Ják. 4:8; 1 Pét. 3:21.

YÓÒ MÁA ṢỌ́ ỌKÀN-ÀYÀ YÍN ÀTI AGBÁRA ÈRÒ ORÍ YÍN

16. Kí ni “àlàáfíà Ọlọ́run” máa ń ṣe fún wa? Ṣàpèjúwe.

16 Kí ni “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ” máa ń ṣe fún wa? Ìwé Mímọ́ sọ pé ‘yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa nípasẹ̀ Kristi Jésù.’ (Fílí. 4:7) Àwọn ẹ̀ṣọ́ ni wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “ṣọ́” nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn fún. Ọ̀rọ̀ náà sì ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n máa ń ṣọ́ àwọn ìlú olódi láyé àtijọ́. Fílípì wà lára irú àwọn ìlú bẹ́ẹ̀. Ọkàn àwọn aráàlú Fílípì máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá ń sùn lálẹ́ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ wà tó ń ṣọ́ ibodè ìlú. Lọ́nà kan náà, tá a bá ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ọkàn wa máa balẹ̀, ara sì máa tù wá. A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ káyé wa dùn kó sì lóyin. (1 Pét. 5:10) Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, kì í sì í jẹ́ kí àníyàn bò wá mọ́lẹ̀.

17. Kí láá jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà ìpọ́njú ńlá?

17 Láìpẹ́, aráyé máa dojú kọ ìpọ́njú tó tíì le jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé. (Mát. 24:​21, 22) A ò mọ bí nǹkan ṣe máa rí fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nígbà yẹn, síbẹ̀ kò sídìí fún wa láti máa ṣàníyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ gbogbo ohun tí Jèhófà máa ṣe, síbẹ̀ a mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. A ti rí i nínú àwọn ohun tó ti ṣe sẹ́yìn pé kò sí ohun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá ní lọ́kàn, ó sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà àrà. Gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún wa lọkàn wa máa balẹ̀, a sì máa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”

^ ìpínrọ̀ 1 Ó ṣeé ṣe kí Sílà náà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù.​—Ìṣe 16:37.