Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Gbé Àkópọ̀ Ìwà Tuntun Wọ̀, Tá Ò sì Ní Bọ́ Ọ Sílẹ̀ Mọ́

Bá A Ṣe Lè Gbé Àkópọ̀ Ìwà Tuntun Wọ̀, Tá Ò sì Ní Bọ́ Ọ Sílẹ̀ Mọ́

‘Ẹ fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.’​—KÓL. 3:10.

ORIN: 43, 106

1, 2. (a) Kí ló mú kó dá wa lójú pé àwa èèyàn lè ní àkópọ̀ ìwà tuntun? (b) Àwọn ànímọ́ wo ni Kólósè 3:​10-14 mẹ́nu kàn?

NÍNÚ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ẹ̀ẹ̀mejì ni ọ̀rọ̀ náà “àkópọ̀ ìwà tuntun” fara hàn. (Éfé. 4:24; Kól. 3:10) Ó ń tọ́ka sí àwọn ìwà tó bá “ìfẹ́ Ọlọ́run” mu, ó sì dájú pé àwa èèyàn lè ní àwọn ànímọ́ yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé, Jèhófà dá wa ní àwòrán rẹ̀, èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ.​—Jẹ́n. 1:26, 27; Éfé. 5:1.

2 Torí pé a ti jogún àìpé látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, èyí máa ń mú ká ṣàṣìṣe. Nígbà míì sì rèé, ibi tá a gbé dàgbà máa ń nípa lórí wa. Síbẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè di irú ẹni tí Jèhófà fẹ́ ká jẹ́. Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ nínú àwọn ìwà tuntun tó yẹ ká gbé wọ̀. (Ka Kólósè 3:10-14.) A tún máa ṣàyẹ̀wò bá a ṣe lè máa lo àwọn ànímọ́ yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa.

‘Ọ̀KAN ṢOṢO NI GBOGBO YÍN’

3. Kí ni kò yẹ ká máa ṣe?

3 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé ká gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, ó tẹnu mọ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ànímọ́ tó yẹ ká ní, ìyẹn ni pé ká má ṣe ojúsàájú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Kò sí Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, Síkítíánì, ẹrú tàbí òmìnira.’ * Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ka ara wa sí pàtàkì ju àwọn míì lọ nínú ìjọ, bóyá torí ẹ̀yà wa, orílẹ̀-èdè wa tàbí ipò wa láwùjọ? Ìdí ni pé ‘ọ̀kan ṣoṣo ni gbogbo’ àwa ọmọlẹ́yìn Kristi.​—⁠Kól. 3:11; Gál. 3:⁠28.

4. (a) Báwo ló ṣe yẹ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ṣe sáwọn míì? (b) Kí ló lè mú kó ṣòro fún àwa Kristẹni láti wà níṣọ̀kan?

4 Tá a bá gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, àá máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn láìka ipò wọn láwùjọ tàbí ibi tí wọ́n ti wá sí. (Róòmù 2:11) Àmọ́ èyí kì í rọrùn láwọn ilẹ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè South Africa, ìjọba ṣètò pé kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni kò mọ àwọn ará míì tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwọn. Kí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè yìí lè mọ ara wọn dáadáa, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ètò àkànṣe kan ní October 2013. (2 Kọ́r. 6:13) Kí ni wọ́n ṣe?

5, 6. (a) Ètò wo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe kí àwọn ará tó wà ní orílẹ̀-èdè kan lè wà níṣọ̀kan? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ló yọrí sí?

5 Wọ́n ṣètò pé kí ìjọ méjì tí èdè wọn yàtọ̀ síra jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ láwọn òpin ọ̀sẹ̀ kan. Àwọn ará láti ìjọ méjèèjì jọ máa lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n á jọ ṣèpàdé, wọ́n á sì gba ara wọn lálejò. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìjọ ló kópa nínú ètò yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará sì kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì láti dúpẹ́ fún ètò náà, títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àlùfáà kan wò títí, ó sọ pé: “Mi kì í ṣe Ẹlẹ́rìí o, àmọ́ kí n má parọ́, bí ẹ ṣe ṣètò ìwàásù yín ṣàrà ọ̀tọ̀, ẹ sì tún wà níṣọ̀kan láìka ẹ̀yà tẹ́ ẹ ti wá sí.” Báwo ni ètò yìí ṣe ran àwọn ará lọ́wọ́?

6 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Arábìnrin Noma yẹ̀ wò. Ìjọ tó ń sọ èdè Xhosa ló wà, àmọ́ kò yá a lára láti pe àwọn òyìnbó tó wà níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè òyìnbó wá sílé rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tí òun àtàwọn òyìnbó kan jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tí wọ́n sì tún ṣe é lálejò nílé wọn, ó ní: “Èèyàn bíi tiwa làwọn náà ṣá!” Nígbà tó wá di pé kí ìjọ tó ń sọ èdè Xhosa gba àwọn tó wà níjọ òyìnbó lálejò, Noma se oúnjẹ, ó sì pe àwọn kan wá sílé rẹ̀. Òyìnbó kan tó jẹ́ alàgbà wà lára àwọn tó wá. Noma sọ pé, “Ẹnu yà mí nígbà tí mo rí i tí òyìnbó yìí jókòó sórí àpótí oníke.” Ọpẹ́lọpẹ́ ètò tó ń lọ lọ́wọ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará ni wọ́n ti mọ ara wọn dáadáa báyìí, tí wọ́n sì ti pinnu pé nǹkan kan ò ní ya àwọn.

‘ÌFẸ́NI ONÍJẸ̀LẸ́ŃKẸ́ TI ÌYỌ́NÚ ÀTI INÚ RERE’

7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú?

7 Níwọ̀n ìgbà tá a ṣì wà nínú ayé Sátánì yìí, kò sígbà tá ò ní máa ní ìṣòro. Nígbà míì, a lè má níṣẹ́ lọ́wọ́, a lè máa ṣàìsàn tó le gan-an, wọ́n lè máa ṣe inúnibíni sí wa, a lè pàdánù àwọn nǹkan ìní wa tàbí kí àjálù tiẹ̀ dé bá wa. Torí náà, tá a bá fẹ́ ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Ìfẹ́ tá a ní sí wọn á mú ká máa ṣe inú rere sí wọn. (Éfé. 4:32) Àwọn ànímọ́ yìí máa jẹ́ ká fara wé Ọlọ́run, àá sì lè tu àwọn míì nínú.​—2 Kọ́r. 1:3, 4.

8. Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, kí ló máa yọrí sí? Sọ àpẹẹrẹ kan.

8 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì àtàwọn tó níṣòro nínú ìjọ? A gbọ́dọ̀ bá irú wọn dọ́rẹ̀ẹ́, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì wọn àti pé wọ́n wúlò láàárín wa. (1 Kọ́r. 12:22, 25) Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dannykarl, tó kó lọ sórílẹ̀-èdè Japan láti orílẹ̀-èdè Philippines. Níbi tó ti ń ṣiṣẹ́, wọn kì í ṣe dáadáa sí i torí pé kì í ṣe ọmọ ilẹ̀ Japan. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, ó lọ sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá sọ pé, “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ni ọmọ ilẹ̀ Japan, síbẹ̀, wọ́n kí mi dáadáa àfi bíi pé a ti mọra tipẹ́.” Kò mọ síbẹ̀ o, àwọn ará fìfẹ́ hàn sí i, ìyẹn sì jẹ́ kó tẹ̀ síwájú. Ní báyìí, ó ti ṣèrìbọmi, ó sì ti di alàgbà. Àwọn alàgbà ìjọ tí Dannykarl àti ìyàwó rẹ̀ Jennifer wà sọ pé, ṣe ni Jèhófà fi wọ́n bù kún ìjọ àwọn. Àwọn alàgbà yẹn sọ pé: “Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn méjèèjì, torí pé wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ire Ìjọba Ọlọ́run ló gbawájú láyé wọn, wọ́n sì jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn.”​—Lúùkù 12:31.

9, 10. Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ará fi ìfẹ́ àti inú rere hàn sáwọn èèyàn lóde ẹ̀rí.

9 Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe “ohun rere sí gbogbo ènìyàn” ni pé ká máa wàásù ìhìn rere fún wọn. (Gál. 6:10) Ọ̀pọ̀ àwọn ará ti kọ́ èdè tuntun kí wọ́n lè ran àwọn àjèjì lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 9:23) Èyí sì ti mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. Bí àpẹẹrẹ, aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Tiffany nílẹ̀ Ọsirélíà lọ kọ́ èdè Swahili kó lè ṣèrànwọ́ fún ìjọ tó ń sọ èdè yẹn nílùú Brisbane. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn rárá fún Tiffany láti kọ́ èdè yẹn, Jèhófà ti bù kún rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu. Ó sọ pé: “Tó o bá fẹ́ gbádùn iṣẹ́ ìsìn rẹ, ṣe ni kó o lọ sìn níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Ṣe ló dà bíi pé o wà nílẹ̀ òkèèrè bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ò kúrò nílé rẹ. Á túbọ̀ ṣe kedere sí ẹ pé ìṣọ̀kan wà láàárín wa, wàá sì rí i pé lóòótọ́ ni ìfẹ́ so wá pọ̀.”

Kí ló máa ń mú káwọn Kristẹni ran àwọn àjèjì lọ́wọ́? (Wo ìpínrọ̀ 10)

10 Tún wo àpẹẹrẹ ìdílé kan lórílẹ̀-èdè Japan. Ọmọ wọn obìnrin tó ń jẹ́ Sakiko sọ pé: “Láwọn ọdún 1990, a máa ń pàdé àwọn ọmọ ilẹ̀ Brazil lóde ẹ̀rí. Tá a bá wá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan fún wọn nínú Bíbélì èdè Potogí, irú bí Ìṣípayá 21:3, 4 tàbí Sáàmù 37:10, 11, 29, wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀, kódà wọ́n tiẹ̀ máa ń da omi lójú nígbà míì.” Ìdílé náà wá ronú nípa báwọn ṣe lè ran àwọn àjèjì yìí lọ́wọ́. Sakiko sọ pé: “Nígbà tá a rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Potogí nínú ìdílé wa.” Nígbà tó yá, ìdílé yìí ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ kan tó ń sọ èdè Potogí sílẹ̀, wọ́n sì ti ran ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì tó ṣí wá sí orílẹ̀-èdè wọn lọ́wọ́. Sakiko tún sọ pé: “Kò rọrùn láti kọ́ èdè Potogí, àmọ́ àwọn ìbùkún tá a rí tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó mú kí àwọn nǹkan yìí ṣeé ṣe.”​—Ka Ìṣe 10:34, 35.

‘Ẹ FI ÌRẸ̀LẸ̀ ÈRÒ INÚ WỌ ARA YÍN LÁṢỌ’

11, 12. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká ní èrò tó tọ́ nípa fífi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ? (b) Kí láá jẹ́ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

11 Ó yẹ ká ní èrò tó tọ́ nípa fífi àkọ́pọ̀ ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ. Kò yẹ kó jẹ́ torí káwọn èèyàn lè máa yìn wá la ṣe ń gbé àkọ́pọ̀ ìwà tuntun wọ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ torí àtibọlá fún Jèhófà. Ẹ rántí pé áńgẹ́lì pípé kan di aláìṣòótọ́ torí pé ó jẹ́ kí ìgbéraga wọ òun lẹ́wù. (Fi wé Ìsíkíẹ́lì 28:17.) Tí áńgẹ́lì pípé kan bá lè di agbéraga, ẹ ò rí i pé ó máa gba ìsapá gan-an fáwa èèyàn aláìpé láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Síbẹ̀, a lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara wa láṣọ. Kí láá jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀?

12 Ká lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. (Diu. 17:18-20) Ní pàtàkì, ó yẹ ká máa ronú lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wa àti bó ṣe fi hàn pé òun ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. (Mát. 20:28) Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tó wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. (Jòh. 13:12-17) Tá a bá ń ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ, ó yẹ ká gbàdúrà pé kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn.​—Gál. 6:3, 4; Fílí. 2:3.

13. Àwọn ìbùkún wo la máa rí tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

13 Ka Òwe 22:4. Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, èyí sì máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan máa wà nínú ìjọ, Jèhófà sì máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Gbogbo yín, ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”​—1 Pét. 5:5.

‘Ẹ FI ÌWÀ TÚTÙ ÀTI ÌPAMỌ́RA WỌ ARA YÍN LÁṢỌ’

14. Ta ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká níwà tútù, ká sì ní sùúrù?

14 Nínú ayé lónìí, ojú ọ̀dẹ̀ làwọn èèyàn fi ń wo ẹni tó bá níwà tútù, tó sì ní sùúrù. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Jèhófà Ẹni tó lágbára jù láyé àtọ̀run ló fún wa láwọn ànímọ́ yìí. Òun ló níwà tútù jù, òun ló sì ní sùúrù jù. (2 Pét. 3:9) Ẹ rántí bí Jèhófà ṣe fi sùúrù dá Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì lóhùn nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń bi í níbèérè. (Jẹ́n. 18:22-33; 19:18-21) Bákan náà, ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọdún ni Jèhófà fi ní sùúrù fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ya ọlọ̀tẹ̀.​—Ìsík. 33:11.

15. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ tó bá di pé ká níwà tútù, ká sì ní sùúrù?

15 “Onínú tútù” ni Jésù. (Mát. 11:29) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa ń ṣàṣìṣe, síbẹ̀ Jésù fi sùúrù bá wọn lò. Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ṣe làwọn aṣáájú ìsìn máa ń ṣàríwísí rẹ̀. Síbẹ̀, Jésù ò jẹ́ kíyẹn yí irú ẹni tóun jẹ́ pa dà, ó ṣì jẹ́ onísùúrù títí táwọn ọ̀tá fi pa á. Kódà nígbà tí Jésù ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró, ó gbàdúrà pé kí Bàbá rẹ̀ dárí ji àwọn tó fẹ́ pa á torí pé “wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” (Lúùkù 23:34) Àbí ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká níwà tútù, ká sì ní sùúrù kódà láwọn ipò tí kò rọgbọ.​—Ka 1 Pétérù 2:21-23.

16. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ oníwà tútù, a sì ní sùúrù?

16 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ oníwà tútù, a sì ní sùúrù? Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kól. 3:13) A gbọ́dọ̀ ní sùúrù ká sì níwà tútù ká tó lè ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ. Tá a bá ń dárí jini, ìṣọ̀kan á túbọ̀ máa gbilẹ̀ nínú ìjọ.

17. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ níwà tútù, ká sì ní sùúrù?

17 Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ níwà tútù, ká sì ní sùúrù. Ìdí ni pé àwọn ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì tá a bá máa rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Mát. 5:5; Ják. 1:21) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àwọn ànímọ́ yìí máa ń jẹ́ ká lè bọlá fún Jèhófà, ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—Gál. 6:1; 2 Tím. 2:24, 25.

“Ẹ FI ÌFẸ́ WỌ ARA YÍN LÁṢỌ”

18. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, báwo nìyẹn ò ṣe ní jẹ́ ká máa ṣe ojúsàájú?

18 Gbogbo àwọn ànímọ́ tá a ti sọ̀rọ̀ wọn pátá ló so mọ́ ìfẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọmọlẹ́yìn náà Jákọ́bù bá àwọn Kristẹni kan wí torí pé wọ́n ń ka àwọn olówó sí ju àwọn tálákà lọ. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ tako ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Ó wá fi kún un pé à ń dẹ́ṣẹ̀ bí a bá ń ṣe ojúsàájú. (Ják. 2:8, 9) Lọ́wọ́ kejì, ìfẹ́ ò ní jẹ́ ká máa ka àwọn kan sí ju àwọn míì lọ bóyá torí ipò wọn láwùjọ, ẹ̀yà wọn tàbí torí pé wọ́n kàwé. Kò yẹ ká máa díbọ́n bíi pé gbogbo èèyàn la nífẹ̀ẹ́. Ṣe ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn láìṣe ojúsàájú.

19. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fìfẹ́ wọ ara wa láṣọ?

19 Bákan náà, ìfẹ́ máa ń ní ‘ìpamọ́ra àti inú rere, kì í sì í wú fùkẹ̀.’ (1 Kọ́r. 13:4) Ó gba pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká jẹ́ onínúure, ká sì ní sùúrù ká tó lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó. (Mát. 28:19) Àwọn ànímọ́ yìí sì tún máa ń mú kó rọrùn fún wa láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ. Ìbùkún wo la máa rí tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará? Ó máa jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ, èyí á bọlá fún Jèhófà, á sì mú káwọn míì wá sínú ètò Ọlọ́run. Bí Bíbélì ṣe parí ọ̀rọ̀ nípa àkópọ̀ ìwà tuntun bá a mu wẹ́kú, ó ní: “Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”​—Kól. 3:14.

“Ẹ DI TUNTUN”

20. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa, kí sì nìdí? (b) Àkókò wo là ń fojú sọ́nà fún?

20 Ó yẹ kí gbogbo wa bi ara wa pé, ‘Kí ni mo tún lè ṣe kí n lè bọ́ àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀ kí n má sì gbé wọn wọ̀ mọ́?’ Ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, ká sì ṣiṣẹ́ kára láti borí ìwà èyíkéyìí tó lè mú ká má jogún Ìjọba Ọlọ́run. (Gál. 5:19-21) A tún gbọ́dọ̀ bi ara wa pé, ‘Ṣé mò ń sapá láti máa fi àwọn ànímọ́ tuntun tí mo kọ́ ṣèwà hù?’ (Éfé. 4:23, 24) Kì í ṣe ọjọ́ kan la máa gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, díẹ̀díẹ̀ láá máa mọ́ wa lára títí tá a fi máa lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní kíkún. Fojú inú wo bí ayé ṣe máa dùn tó tí gbogbo wa bá gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, tá a sì di pípé!

^ ìpínrọ̀ 3 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn aráàlú Síkítíánì.