Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà

Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà

“Ẹ má rò pé mo wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé; èmi kò wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀, bí kò ṣe idà.”​—MÁT. 10: 34.

ORIN: 125, 135

1, 2. (a) Àlàáfíà wo là ń gbádùn báyìí? (b) Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó nira láti gbádùn àlàáfíà bá a ṣe fẹ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

GBOGBO wa la fẹ́ àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn. A sì dúpẹ́ pé Jèhófà ń fún wa lóhun tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run.” Àlàáfíà yìí ni kì í jẹ́ ká kọ́kàn sókè nígbà ìṣòro. (Fílí. 4:​6, 7) Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a tún ń gbádùn “àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run,” ìyẹn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.​— Róòmù 5: 1.

2 Àmọ́, kò tíì tó àsìkò tí Ọlọ́run máa mú kí àlàáfíà jọba níbi gbogbo láyé. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń kó wa lọ́kàn sókè láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn ń bá ara wọn jagun, wọn ò sì lẹ́mìí àlàáfíà. (2 Tím. 3:​1-4) Yàtọ̀ síyẹn, àwa Kristẹni náà ń ja ogun tẹ̀mí, à ń bá Sátánì jagun, a sì ń túdìí àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké tó fi ń kọ́ni. (2 Kọ́r. 10:​4, 5) Ṣùgbọ́n ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè jù, tó sì ń mú kó nira fún wa láti sin Jèhófà ni àtakò látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kò sí nínú òtítọ́. Àwọn kan lára wọn máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àwọn míì sì máa ń sọ pé à ń tú ìdílé ká, kódà wọ́n lè halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn á kọ̀ wá tá ò bá fi ẹ̀sìn wa sílẹ̀. Kí la lè ṣe táwọn mọ̀lẹ́bí wa bá ta kò wá? Kí lohun tá a lè ṣe tí àtakò náà kò fi ní ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́?

TÍ ÀWỌN ẸBÍ RẸ BÁ TA KÒ Ẹ́

3, 4. (a) Kí ni ẹ̀kọ́ Jésù máa ń fà láàárín àwọn èèyàn? (b) Ìgbà wo ló lè nira fún ẹnì kan láti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù?

3 Jésù mọ̀ pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa fa ìpínyà láàárín àwọn èèyàn, àti pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa nílò ìgboyà nígbà táwọn èèyàn bá ta kò wọ́n. Àtakò yìí lè fa àìgbọ́ra-ẹni-yé láàárín àwọn tó wà nínú ìdílé. Jésù sọ pé: “Ẹ má rò pé mo wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé; èmi kò wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀, bí kò ṣe idà. Nítorí mo wá láti fa ìpínyà, láti pín ọkùnrin níyà sí baba rẹ̀, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, àti ọ̀dọ́ aya sí ìyá ọkọ rẹ̀. Ní tòótọ́, àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.”​— Mát. 10:​34-36.

4 Nígbà tí Jésù sọ pé “Ẹ má rò pé mo wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀,” ohun tó ní lọ́kàn ni pé á dáa káwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹ̀kọ́ òun máa fa ìpínyà. Àmọ́ o, òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Jésù fi ń kọ́ni, kì í ṣe pé ó fẹ́ kí àárín àwọn èèyàn dàrú. (Jòh. 18:37) Bó ti wù kó rí, ó lè nira fún ẹnì kan láti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù táwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.

5. Kí làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fara dà?

5 Jésù sọ pé lára ohun táwọn ọmọlẹ́yìn òun máa fara dà ni àtakò látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí wọn. (Mát. 10:38) Torí pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi fẹ́ ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, wọ́n fara da ọ̀pọ̀ nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, kódà wọ́n tiẹ̀ kẹ̀yìn sáwọn míì nínú wọn. Síbẹ̀, ohun tí wọ́n rí gbà ti ju ohun tí wọ́n pàdánù lọ fíìfíì.​— Ka Máàkù 10:​29, 30.

6. Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn táwọn mọ̀lẹ́bí wa bá ta kò wá?

6 Táwọn mọ̀lẹ́bí wa bá ta kò wá torí pé à ń jọ́sìn Jèhófà, a kì í foró yaró, kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ rántí pé ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti Kristi ló gbọ́dọ̀ ṣáájú. (Mát. 10:37) Ó tún yẹ ká ṣọ́ra kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn mọ̀lẹ́bí wa má lọ mú ká ṣe ohun tí Jèhófà kò fẹ́, torí pé ohun tí Sátánì fẹ́ gan-an nìyẹn. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ táwọn mọ̀lẹ́bí wa bá ta kò wá àti bá a ṣe lè borí ìṣòro náà.

ỌKỌ TÀBÍ AYA TÍ KÌ Í ṢE ẸLẸ́RÌÍ

7. Irú ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo ọkọ tàbí aya rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

7 Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé àwọn tó ṣègbéyàwó máa “ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́r. 7:28) Tí ọkọ tàbí aya rẹ kò bá sin Jèhófà, ìyẹn lè mú kí nǹkan túbọ̀ nira nínú ìgbéyàwó rẹ. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kó o fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Ti pé ọkọ tàbí aya rẹ kò sin Jèhófà kò túmọ̀ sí pé kẹ́ ẹ pínyà tàbí pé kẹ́ ẹ kọ ará yín sílẹ̀. (1 Kọ́r. 7:​12-16) Lóòótọ́, ọkọ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kò ní lè múpò iwájú nínú ìdílé tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn, síbẹ̀ ó yẹ kí ìyàwó rẹ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un torí pé òun ni olórí ìdílé. Tó bá sì jẹ́ pé aya ni kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, ó yẹ kí ọkọ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí máa gba ti aya rẹ̀ rò, kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú, kó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.​— Éfé. 5:​22, 23, 28, 29.

8. Ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara rẹ tí ọkọ tàbí aya rẹ bá fẹ́ kó o dín bó o ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà kù?

8 Kí ni wàá ṣe tí ọkọ tàbí aya rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá fẹ́ kó o dín bó o ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà kù? Bí àpẹẹrẹ, ọkọ arábìnrin kan sọ àwọn ọjọ́ pàtó tóun lè yọ̀ǹda fún un láti máa lọ sóde ẹ̀rí láàárín ọ̀sẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ohun tó ń sọ ni pé kí n má sin Jèhófà mọ́? Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé mo lè ṣe ohun tó fẹ́?’ Tó o bá ń gba tẹnì kejì rẹ rò, kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí àìgbọ́ra-ẹni-yé láàárín yín.​— Fílí. 4: 5.

9. Báwo ni òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa bọlá fún òbí wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí?

9 Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti kọ́ àwọn ọmọ tí ọ̀kan lára àwọn òbí kò bá jọ́sìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti ṣe ohun tí Bíbélì pa láṣẹ, pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Éfé. 6:​1-3) Kí ni wàá ṣe tí ọkọ tàbí aya rẹ bá ń ṣe ohun tó lòdì sí Bíbélì? Ó yẹ kó o máa bọ̀wọ̀ fún un, káwọn ọmọ rẹ náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan dáadáa tí ọkọ tàbí aya rẹ ń ṣe ni kó o máa sọ, kó o sì máa yìn ín. Má ṣe máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa níṣojú àwọn ọmọ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó yé wọn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa sin Jèhófà tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Táwọn ọmọ rẹ bá ń hùwà rere, ìyẹn lè wú ẹnì kejì rẹ lórí kó sì wá jọ́sìn Jèhófà.

Máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti sọ nípa Jèhófà fáwọn ọmọ rẹ (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Báwo ni òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ tàbí aya rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí?

10 Ọkọ tàbí aya tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lè fi dandan lé e pé káwọn ọmọ lọ́wọ́ sí ayẹyẹ tí kò bá Bíbélì mu tàbí pé òun máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn òun. Yàtọ̀ síyẹn, ọkọ kan lè sọ fún ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pé kò gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ òun lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Síbẹ̀, á dáa kí arábìnrin náà ṣe ohun tó lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ náà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ìṣe 16:1; 2 Tím. 3:​14, 15) Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan lè pinnu pé ìyàwó òun tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí kò gbọ́dọ̀ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbọ́dọ̀ mú wọn lọ sípàdé. Ó ṣe pàtàkì pé kí aya náà bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, síbẹ̀ á máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti sọ nípa Jèhófà fáwọn ọmọ rẹ̀. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ Jèhófà kí wọ́n sì máa hùwà ọmọlúàbí. (Ìṣe 4:​19, 20) Bó ti wù kó rí, àwọn ọmọ fúnra wọn ló máa pinnu bóyá àwọn máa sin Jèhófà tàbí àwọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.​— Diu. 30:​19, 20. *

ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ TÓ TA KÒ WÁ

11. Kí ló lè fa ìṣòro láàárín àwa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí?

11 Ó lè jẹ́ pé a ò sọ fún àwọn ìdílé wa nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ tí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ ń lágbára, a bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún wọn. (Máàkù 8:38) Kí lo lè ṣe táwọn mọ̀lẹ́bí rẹ bá ta kò ẹ́ torí pé o yàn láti sin Jèhófà? A máa jíròrò àwọn ìgbésẹ̀ tó o lè gbé láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn láìjẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.

12. Kí ló lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ta kò wá? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn?

12 Mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú wa dùn pé a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè ronú pé ńṣe làwọn ajẹ́rìí ń tàn wá jẹ tàbí pé wọ́n ti mú wa wọnú ẹgbẹ́ wọn. Wọ́n lè ronú pé a ò nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ́ torí pé a ò bá wọn ṣọdún mọ́. Wọ́n tiẹ̀ lè máa bẹ̀rù pé ẹ̀sìn tá a gbà máa mú wa ṣìnà. Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó ń bà wọ́n lẹ́rù, ìyẹn á jẹ́ ká lóye wọn ká sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. (Òwe 20: 5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sapá láti lóye “ènìyàn gbogbo” kó bàa lè wàásù ìhìn rere fún wọn, ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe nìyẹn.​— 1 Kọ́r. 9:​19-23.

13. Báwo ló ṣe yẹ ká máa bá àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀?

13 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tuni lára. Bíbélì gbà wá níyànjú pé kí “àsọjáde [wa] máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.” (Kól. 4: 6) Á dáa ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó lè darí wa nígbà tá a bá ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí wa sọ̀rọ̀. Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa sọ fún wọn pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ kò tọ̀nà. Tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tí kò dáa sí wa, ẹ jẹ́ ká fara wé àwọn àpọ́sítélì Jésù. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn wa, àwa ń súre; nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń mú un mọ́ra; nígbà tí wọ́n ń bà wá lórúkọ jẹ́, àwa ń pàrọwà.”​— 1 Kọ́r. 4:​12, 13.

14. Kí ló lè yọrí sí tá a bá ń hùwà rere?

14 Máa hùwà rere. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ tútù lè pẹ̀tù sáwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ́kàn, síbẹ̀ ká rántí pé ìwà rere lẹ̀ṣọ́ ènìyàn. (Ka 1 Pétérù 3:​1, 2, 16.) Jẹ́ kí àwọn ẹbí rẹ rí i nínú ìwà rẹ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn ìgbéyàwó wa, à ń tọ́jú àwọn ọmọ wa, a kì í hùwàkiwà, ìgbésí ayé wa sì máa ń nítumọ̀. Kódà báwọn mọ̀lẹ́bí wa kò bá tiẹ̀ di Ẹlẹ́rìí, àá máa láyọ̀ torí pé à ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà.

15. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ di àríyànjiyàn?

15 Ronú ṣáájú nípa ohun tó o máa ṣe. Ronú nípa àwọn nǹkan tó lè fa àìgbọ́ra-ẹni-yé láàárín ìwọ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kó o sì pinnu ohun tó o máa ṣe. (Òwe 12:​16, 23) Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Bàbá ọkọ mi kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an. Nígbàkigbà témi àti ọkọ mi bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ wọn, ṣe la máa ń kọ́kọ́ gbàdúrà ká lè fohùn pẹ̀lẹ́ dá wọn lóhùn tí wọ́n bá fi ìbínú sọ̀rọ̀. A máa ń ronú ohun tá a máa bá wọn sọ tí kò ní bọ́ sápò ìbínú wọn. Torí pé a ò fẹ́ kí ìjíròrò wa débi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tó lè fa àríyànjiyàn, a kì í pẹ́ jù tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀.”

16. Kí lo lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé ìwọ lo fà á táwọn mọ̀lẹ́bí rẹ fi ń gbọ̀rọ̀ rẹ sódì?

16 Ohun kan ni pé, bó ti wù ká ṣe tó, àwọn mọ̀lẹ́bí wa ṣì lè gba ọ̀rọ̀ wa sódì. Ó lè máa ṣe wá bíi pé àwa la fà á, pàápàá torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, a ò sì fẹ́ múnú bí wọn. Tó bá ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀, rántí pé àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà ṣe pàtàkì ju àjọṣe ìwọ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ lọ. Tí wọ́n bá rí ọwọ́ tó o fi mú òtítọ́, wọ́n á mọ̀ pé kò sóhun táwọn lè ṣe láti dí ẹ lọ́wọ́. Bó ti wù kó rí, fi sọ́kàn pé o ò lè fipá mú ẹnikẹ́ni láti di Ẹlẹ́rìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí wọ́n rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa sin Jèhófà nínú ìwà rẹ. Ó ṣe tán, gbogbo èèyàn pátá ni Baba wa onífẹ̀ẹ́ fún láǹfààní láti wá jọ́sìn rẹ̀.​— Aísá. 48:​17, 18.

TÍ ẸNÌ KAN LÁRA ÌDÍLÉ RẸ BÁ FI JÈHÓFÀ SÍLẸ̀

17, 18. Kí láá ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ bá fi Jèhófà sílẹ̀?

17 Ọgbẹ́ ọkàn téèyàn máa ń ní kì í ṣe kékeré tí ẹnì kan nínú ìdílé bá fi ètò Jèhófà sílẹ̀ tàbí tí wọ́n bá yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Kí lo lè ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ?

18 Máa ṣe ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run déédéé. Máa ṣe ohun táá fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun. Bí àpẹẹrẹ, máa ka Bíbélì déédéé, máa múra ìpàdé sílẹ̀ kó o sì máa pésẹ̀ déédéé. Bákan náà, máa wàásù déédéé, kó o sì máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ lókun tí wàá fi lè fara dà á. (Júúdà 20, 21) Àmọ́, tó bá dà bíi pé ọkàn rẹ ò sí nínú àwọn nǹkan tó ò ń ṣe, kí lo lè ṣe? Má jẹ́ kó sú ẹ! Tó o bá tẹra mọ́ ṣíṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, wàá lè pọkàn pọ̀, ọ̀rọ̀ náà ò sì ní ká ẹ lára ju bó ṣe yẹ lọ. O lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹni tó kọ Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin [73]. Ìgbà kan wà tó ṣinú rò tíyẹn sì dà á lọ́kàn rú. Àmọ́ nígbà tó lọ síbi ìjọsìn Jèhófà, èrò tó ní yí pa dà, ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀. (Sm. 73:​16, 17) Nǹkan lè yí pa dà fún ìwọ náà bíi ti onísáàmù yẹn tó o bá ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà nìṣó.

19. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o fara mọ́ ìbáwí Jèhófà?

19 Fara mọ́ ìbáwí Jèhófà. Lóòótọ́, ó máa ń dunni gan-an tí wọ́n bá yọ èèyàn ẹni lẹ́gbẹ́, àmọ́ gbogbo ìdílé pátá ni ìbáwí Jèhófà máa ń ṣe láǹfààní, títí kan ẹni tó dẹ́ṣẹ̀. (Ka Hébérù 12:11.) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé ká “jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀” pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà. (1 Kọ́r. 5:​11-13) Ká sòótọ́ kò rọrùn, àmọ́ kò yẹ ká tún jọ máa ṣe àwọn nǹkan tá a jọ ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Kò yẹ ká jọ máa kàn síra lórí fóònù, nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí àtẹ̀jíṣẹ́, títí kan lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tàbí ìkànnì àjọlò.

20. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká sọ̀rètí nù?

20 Má sọ̀rètí nù. Bíbélì sọ pé ìfẹ́ “a máa retí ohun gbogbo,” lédè míì, kò yẹ ká sọ̀rètí nù pé ẹni tó fi Jèhófà sílẹ̀ lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (1 Kọ́r. 13: 7) Tó o bá kíyè sí i pé ìbátan rẹ náà ti ń yíwà pa dà, o lè gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó lè gbọ́ àrọwà Jèhófà pé: “Padà sọ́dọ̀ mi.”​— Aísá. 44: 22.

21. Kí ló yẹ kó o ṣe táwọn ará ilé rẹ bá ń fìtínà ẹ torí pé o jẹ́ Ẹlẹ́rìí?

21 Jésù sọ pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ èèyàn èyíkéyìí ju òun lọ, a ò ní rí ìtẹ́wọ́gbà òun. Síbẹ̀, ó dá Jésù lójú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa nífẹ̀ẹ́ òun ju ẹnikẹ́ni lọ, kódà lójú àtakò ìdílé. Táwọn ará ilé rẹ bá ń fìtínà ẹ torí pé ò ń tẹ̀ lé Jésù, gbára lé Jèhófà. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á. (Aísá. 41:​10, 13) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àti Jésù mọyì rẹ gan-an, wọ́n á sì san ẹ́ lẹ́san rere bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin.

^ ìpínrọ̀ 10 Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa bó o ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí ọkọ tàbí aya rẹ kò bá sin Jèhófà, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́, August 15, 2002.