Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Sọ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ

Bíbélì Sọ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ

KÁ SỌ pé ò ń rìn lọ nínú òkùnkùn lálẹ́ ọjọ́ kan, ọkàn ẹ sì balẹ̀ torí pé o ní iná tọ́ọ̀ṣì kan tó mọ́lẹ̀ dáadáa lọ́wọ́. Tó o bá tàn án sílẹ̀, wàá rí ohun tó wà níwájú ẹ gangan. Tó o bá sì tàn án sí ọ̀ọ́kán, iná tọ́ọ̀ṣì tó mọ́lẹ̀ kedere yẹn máa jẹ́ kó o rí ohun tó wà ní ọ̀nà jíjìn gan-an.

Láwọn ọ̀nà kan, a lè fi Bíbélì wé iná tọ́ọ̀ṣì. Bá a ṣe sọ nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tó wà níwájú wa, ìyẹn àwọn ìṣòro tí à ń dojú kọ lójoojúmọ́ nínú ayé burúkú yìí. Àmọ́ Bíbélì tún ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó tún máa ń tànmọ́lẹ̀ sáwọn ohun tó wà lọ́jọ́ iwájú, èyí máa ń jẹ́ ká rí ọ̀nà tó máa jẹ́ ká láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ká sì máa rìn ní ọ̀nà náà. (Sáàmù 119:105) Lọ́nà wo?

Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà méjì tí Bíbélì ti fún wa ní ìrètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la: 1 Ó jẹ́ káyé wa ní ìtumọ̀, àti 2 ó kọ́ wa ní ohun tó máa jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dàá wa títí láé.

1 ÌGBÉSÍ AYÉ TÓ NÍTUMỌ̀

Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò nípa bá a ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro wa, àmọ́ Bíbélì kì í ṣẹgbẹ́ àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa bí èèyàn ṣe lè fúnra ẹ̀ yanjú ìṣòro. Dípò tí Bíbélì á fi gbà wá níyànjú láti máa ronú nípa ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn nìkan, ńṣe ló kọ́ wa pé ká ronú nípa ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé. Ìyẹn ló máa jẹ́ kí ayé wa ní ìtumọ̀ gidi.

Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ṣé o lè ronú nípa ìgbà kan tó o ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan tó ṣaláìní? Tàbí ìgbà tó o tẹ́tí sílẹ̀ bí ọ̀rẹ́ rẹ kan ṣe ń sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún ẹ? Ṣé inú ẹ kì í dùn torí pé o ṣe ohun tó ṣàǹfààní fún àwọn ẹlòmíì?

Ayọ̀ wa máa ń kún tá a bá ṣoore tí a ò sì retí pé kẹ́ni náà san án pa dà fún wa. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Tá a bá fúnni ní nǹkan, tí a ò sì ronú pé kí wọ́n san án pa dà fún wa, ó dájú pé ìlọ́po ẹ̀ la máa fi gbà pa dà tó bá yá.” Àgàgà tó bá jẹ́ pé àwọn tí kò lágbára láti san oore pa dà la ṣoore fún, ó dájú pé a máa rí èrè níbẹ̀. Ó fi hàn pé a fìwà jọ Ọlọ́run. Kódà, ṣe là ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa fúnra rẹ̀, tó ń wo irú oore bẹ́ẹ̀ bí ìgbà tá a yá òun ní nǹkan. (Òwe 19:17) Ó mọyì oore tá a ṣe fáwọn aláìní, Ó sì ṣèlérí pé òun máa fi ìyè àìnípẹ̀kun san wá lẹ́san nígbà tí gbogbo ayé bá di Párádísè, ìyẹn sì jẹ́ ìlérí ọjọ́ iwájú tí à ń fojú sọ́nà fún!​—Sáàmù 37:29; Lúùkù 14:​12-14. *

Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé Bíbélì kọ́ wa pé ìgbésí ayé wa á túbọ̀ nítumọ̀ tá a bá sin Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká máa yìn ín, ká máa bọlá fún un, ká sì máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu. (Oníwàásù 12:13; Ìṣípayá 4:11) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ wa máa tẹ ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, ìyẹn ni pé a máa ṣe ohun tó máa múnú Ẹlẹ́dàá wa dùn. Kódà, ó rọ̀ wá pé ká ‘jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ká sì mú ọkàn-àyà òun yọ̀.’ (Òwe 27:11) Rò ó wò ná, tó o bá fọgbọ́n ṣe àwọn ìpinnu tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu, inú Baba wa ọ̀run máa dùn sí ẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ ká tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà òun káyé wa lè dáa. (Aísáyà 48:​17, 18) Ká sòótọ́, kò sí ohun tó lè mú káyé wa dáa ju pé ká máa sin Ọba Aláṣẹ láyé àti lọ́run, ká sì máa fi ayé wa ṣe ohun tó máa múnú rẹ̀ dùn?

2 BÁ A ṢE LÈ DI Ọ̀RẸ́ ẸLẸ́DÀÁ WA

Bíbélì tún kọ́ wa pé ká mú Ẹlẹ́dàá wa lọ́rẹ̀ẹ́. Ó sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé ṣé lóòótọ́ la lè di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dàá tó ga jù lọ. Àmọ́ Bíbélì mú kó dá wa lójú pé tá a bá “wá Ọlọ́run,” a máa “rí i ní ti gidi” torí pé “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Tá a bá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run bí Bíbélì ṣe gbà wá nímọ̀ràn, a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Lọ́nà wo?

Wo àpẹẹrẹ yìí: Kò sí bá a ṣe lè gbìyànjú tó, kò sóhun tá a lè ṣe tí ikú tó jẹ́ olórí ọ̀tá wa kò fi ní pa wá. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Àmọ́, Ọlọ́run wà títí láé. Kò ní kú láéláé, ó sì fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà wà láàyè títí láé. Bíbélì lo ọ̀rọ̀ tó rọrùn tó sì dáa yìí láti ṣàlàyé ohun tí Jèhófà fẹ́ fún gbogbo àwọn tó ń wá a, ó ní: “Kí ọkàn-àyà yín wà láàyè títí láé.”​—Sáàmù 22:26.

Báwo lo ṣe lè ní irú àjọṣe tó máa wà títí láé bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run? Máa bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Jòhánù 17:3; 2 Tímótì 3:16) Bẹ Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye Ìwé Mímọ́. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé tá a bá ń fi tọkàntọkàn béèrè ọgbọ́n “lọ́wọ́ Ọlọ́run,” ó máa dáhùn ìbéèrè wa. * (Jákọ́bù 1:5) Lákòótán, sapá láti máa fi ohun tó o kọ́ ṣèwà hù, jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa jẹ́ “fìtílà fún ẹsẹ̀ [rẹ]” àti “ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà [rẹ]” nísinsìnyí àti títí láé.​—Sáàmù 119:105.

^ ìpínrọ̀ 8 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè tí Ọlọ́run ṣe, ka orí 3 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 13 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí, a rọ̀ ẹ́ pé kó o wo fídíò tá a pè ní Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Wàá rí i lórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo.

Ọlọ́run wà títí láé, ó sì fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà wà láàyè títí láé