Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Kan Tó Jẹ́ Ẹ̀rí Pé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Péye

Ohun Kan Tó Jẹ́ Ẹ̀rí Pé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Péye

ẸNU Ọ̀NÀ GÌRÌWÒ KAN WÀ NÍLÙÚ RÓÒMÙ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ ÍTÁLÌ TÍ WỌ́N FI Ń RÁNTÍ Ọ̀GÁGUN TITUS, Ó SÌ TI DI ÌRAN ÀPÉWÒ FÚN Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN KÁRÍ AYÉ.

Wọ́n gbẹ́ àwọn àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa sára òpó méjèèjì ẹnu ọ̀nà gìrìwò yìí. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ̀ pé ẹnu ọ̀nà gìrìwò yìí jẹ́ ká mọ ohun kan nípa Bíbélì. Ó jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì péye.

JERÚSÁLẸ́MÙ MÁA PA RUN

Ní ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, abẹ́ ìjọba Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Gọ́ọ̀lù (tá a wá mọ̀ sí Faransé) wà títí kan ilẹ̀ Íjíbítì. Nǹkan ń lọ dáadáa ní gbogbo àgbègbè náà, àyàfi ìlú kan tó ń jẹ́ Jùdíà tí kò fẹ́ fi ara rẹ̀ sábẹ́ àkóso ilẹ̀ Róòmù.

Ìwé Encyclopedia of Ancient Rome sọ pé: “Nínú gbogbo ìlú tó wà lábẹ́ àkóso Róòmù, díẹ̀ péré ló dà bíi Jùdíà tí nǹkan kò lọ dáadáa láàárín àwọn àti Róòmù. Àwọn Júù kórìíra àwọn ará Róòmù tó ń ṣàkóso lórí wọn torí pé wọn kò bọ̀wọ̀ fún àṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Róòmù kórìíra àwọn Júù torí pé wọ́n lágídí.” Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù fi ń retí mèsáyà kan tó jẹ́ alágbára olóṣèlú tó máa bá wọn lé àwọn ará Róòmù dà nù, tí ìgbà ọ̀tun á sì dé bá ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àmọ́ ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wọn bí Jésù ṣe sọ pé Jerúsálẹ́mù máa pa run láìpẹ́.

Jésù sọ pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé bá ọ, nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká, wọn yóò sì ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo, wọn yóò sì fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tí ń bẹ nínú rẹ mọ́lẹ̀, wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ.”​—Lúùkù 19:​43, 44.

Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ya àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́nu. Abájọ tó fi jẹ́ pé ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, bí wọ́n ṣe ń wo tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Olùkọ́, wò ó! àwọn òkúta àti ilé wọ̀nyí mà kàmàmà o!” Lóòótọ́, ìwádìí fi hàn pé àwọn òkúta kan wà lára èyí tí wọ́n fi kọ́ tẹ́ǹpìlì yẹn tó gùn ju mítà mọ́kànlá lọ, wọ́n fẹ̀ tó mítà márùn-ún, wọ́n sì ga tó mítà mẹ́ta! Síbẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Ní ti nǹkan wọ̀nyí tí ẹ ń wò, àwọn ọjọ́ yóò dé nínú èyí tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín, tí a kì yóò wó palẹ̀.”​—Máàkù 13:1; Lúùkù 21:6.

Jésù tún sọ fún wọn pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:​20, 21) Ṣé ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ?

BÍ JERÚSÁLẸ́MÙ ṢE PA RUN

Ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ yẹn, síbẹ̀ àwọn Júù ṣì wà lábẹ́ àkóso ìjọba Róòmù. Àmọ́ lọ́dún 66 Sànmàní Kristẹni, Gessius Florus tó jẹ́ agbowó orí fún ìjọba Róòmù ní Jùdíà lọ mú lára owó tó wà nínú àpótí ọrẹ inú tẹ́ńpìlì, ni àwọn Júù bá gbaná jẹ. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn ọmọ ogun Júù ti ya wọnú ìlú Jerúsálẹ́mù, wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wà níbẹ̀, wọ́n sì kéde pé àwọn ò sí lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù mọ́.

Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ọ̀gágun Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun Róòmù tó lé ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] lọ sí Jerúsálẹ́mù láti paná ọ̀tẹ̀ yẹn. Gbàrà táwọn ọmọ ogun Róòmù dé Jerúsálẹ́mù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ ògiri tẹ́ńpìlì. Àmọ́ láìsí ìdí kan pàtó, ṣe làwọn ọmọ ogun yẹn kẹ́rù wọn, wọ́n sì pa dà sí Róòmù. Inú àwọn ọlọ̀tẹ̀ Júù yẹn dùn, ni wọ́n bá tún lé àwọn ọmọ ogun Róòmù láti bá wọn jà. Bí àwọn Kristẹni ṣe rí i pé ìjà yẹn ti rọlẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Jésù, wọ́n sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì lọ sáàárín àwọn òkè ní ìkọjá Odò Jọ́dánì.​—Mátíù 24:​15, 16.

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ ogun Róòmù tún pa dà wá sí Jùdíà lákọ̀tun. Lọ́tẹ̀ yìí, ọ̀gágun Vespasian àti ọmọkùnrin rẹ̀ Titus ló kó wọn wá. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Olú Ọba Nero kú ní 68 Sànmánì Kristẹni, Vespasian pa dà sí Róòmù láti lọ gbàkóso. Ó wá ní kí Titus àti nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] ọmọ ogun Róòmù mú ìlú Jùdíà balẹ̀.

Nígbà tó di June, ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, Titus sọ pé kí àwọn ọmọ ogun gé gbogbo igi tó wà ní ìgbèríko kí wọ́n fi ṣe àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn tó máìlì mẹ́rin àtààbọ̀, kí wọ́n sì fi yí Jerúsálẹ́mù ká. Nígbà tó fi máa di oṣù September, àwọn ọmọ ogun Róòmù ti mú wọn balẹ̀, wọ́n sì fi iná sun ìlú náà títí kan tẹ́ńpìlì. Bí Jésù ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí, wọn ò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú ìlú náà. (Lúùkù 19:​43, 44) Ìròyìn kan tiẹ̀ sọ pé “ó kéré tán, nǹkan bíi 500,000 èèyàn ló bá ogun náà lọ.”

AYẸYẸ ÌṢẸ́GUN ŃLÁ

Lọdún 71 Sànmánì Kristẹni, Titus pa dà sí Ítálì, àwọn ará ìlú sì fi ìlù àti ijó kí i káàbọ̀. Gbogbo ará ìlú ló péjú pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ìṣẹ́gun náà, òun sì ni ayẹyẹ ìṣẹ́gun tó gbayì jù tí wọ́n ṣe nílùú Róòmù.

Àwòyanu làwọn aráàlú ń wo àwọn ohun iyebíye táwọn ọmọ ogun Róòmù kó bọ̀ láti Jerúsálẹ́mù. Inú wọn ń dùn ṣìkìn bí wọ́n ṣe ń wo àwọn ọkọ̀ òkun ńlá àtàwọn ohun tí wọ́n ṣe lọ́sọ̀ọ́ tó ń ṣàfihàn bójú ogun ṣe rí, tó fi mọ́ àwọn ohun tí wọ́n kó nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù.

Lọ́dún 79 Sànmánì Kristẹni, Vespasian tó jẹ́ olú ọba kú, Titus ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ ọdún méjì lẹ́yìn náà Titus kú, Domitian àbúrò rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Òun ló ṣe ẹnu ọ̀nà gìrìwò yẹn kí wọ́n lè máa fi rántí Titus.

KÍ LÈRÒ RẸ NÍPA ẸNU Ọ̀NÀ GÌRÌWÒ YẸN?

Ẹnu Ọ̀nà Gìrìwò Tí Wọ́n Fi Ń Rántí Ọ̀gágun Titus Nílùú Róòmù

Lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló máa ń ṣèbẹ̀wò sí ìlú Róòmù lọ́dọọdún láti lọ wo ẹnu ọ̀nà gìrìwò tí wọ́n ṣe ní ìrántí ọ̀gágun Titus. Àwọn kan kà á sí iṣẹ́ ọnà tó kàmàmà, àwọn míì kà á sí ohun àyẹ́sí pàtàkì tó jẹ́rìí sí agbára ìjọba Róòmù, àwọn míì sì fi ń rántí ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀.

Àmọ́ fún àwọn tó ń fara balẹ̀ ka Bíbélì, ẹnu ọ̀nà gìrìwò yìí jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì péye, ó ṣeé gbára lé àti pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà.​—2 Pétérù 1:​19-21.