Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwọ Lo Máa Pinnu Bí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Ṣe Máa Rí!

Ìwọ Lo Máa Pinnu Bí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Ṣe Máa Rí!

ṢÉ O LÈ PINNU BÍ ỌJỌ́ Ọ̀LA RẸ ṢE MÁA RÍ? Àwọn kan gbà pé gbogbo èèyàn ló ní àyànmọ́ tàbí kádàrá. Torí náà, èrò wọn ni pé kò sẹ́ni tó lè pinnu bí ọjọ́ ọ̀la òun funra rẹ̀ ṣe máa rí. Tí ọwọ́ wọn ò bá tẹ nǹkan tí wọ́n ń wá, ṣe ni wọ́n á gba kámú pé ó ti wà lákọọ́lẹ̀ pé àwọn ò lè ní nǹkan yẹn láé. Wọ́n tún lè sọ pé: “Wọn ò kádàrá ẹ̀ mọ́ mi!”

Ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá àwọn míì tó bá dà bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro tó wà láyé burúkú yìí. Ó lè jẹ́ pé wọ́n ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti mú nǹkan sunwọ̀n sí i àmọ́ tó jẹ́ pé ogun, ìwà ọ̀daràn, oríṣiríṣi àjálù àti àìsàn kò jẹ́ kí akitiyan wọn yọ rárá. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ gba kámú pé kí làwọn ń da ara àwọn láàmú fún?

Ká sòótọ́, àwọn ìṣòro tó wà láyé yìí lè fa ìnira fúnni débi pé ọwọ́ ẹni lè má tẹ nǹkan téèyàn fẹ́ nísinsìnyí. (Oníwàásù 9:11) Àmọ́ níti bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí, ọ̀wọ́ kálukú wa ló wà. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, àwa fúnra wa la máa pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí. Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ.

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jèhófà báwọn sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Mósè tó jẹ́ aṣáájú wọn pé: “Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.”​Diutarónómì 30:​15, 19, 20.

“Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè.” ​—Diutarónómì 30:19

Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè lóko ẹrú Íjíbítì, ó sì jẹ́ kó yé wọn pé ó máa ṣeé ṣe fún wọn láti gbé ní àlàáfíà ní Ilẹ̀ Ìlérí tí òun máa fún wọn. Àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan kí wọ́n tó lè gbádùn àwọn ìbùkún yìí. Wọ́n gbọ́dọ̀ “yan ìyè.” Ìyẹn ni pé, kí wọ́n ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, kí wọ́n fetí sí ohùn rẹ̀, kí wọ́n sì fà mọ́ ọn.’

Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, ìwọ náà gbọ́dọ̀ yan ohun tó o fẹ́, àmọ́ má gbàgbé pé ohun tó o bá yàn báyìí ló máa pinnu bí ọjọ́ ọ̀la rẹ ṣe máa rí. Tó o bá yàn láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí ò ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tó o sì sún mọ́ ọn, ìyè lo ti yàn yẹn, ìyẹn ìyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ báwo lo ṣe lè ṣe àwọn nǹkan yìí?

YÀN LÁTI NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN

Ìfẹ́ ló ta yọ jù lọ nínú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù nípa àṣẹ tó ga jù lọ, ó dáhùn pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Sísún mọ́ Ọlọ́run ju pé kéèyàn máa sọ pé òun bẹ̀rù Ọlọ́run, èèyàn gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?

Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa dà bí ìfẹ́ tí àwọn òbí máa ń ní sí ọmọ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí kì í ṣe ẹni pípé, síbẹ̀ wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n máa ń tọ́ wọn sọ́nà, wọ́n máa ń gbóríyìn fún wọn, wọ́n máa ń tọ́jú wọn, wọ́n sì tún máa ń bá wọn wí nígbà tó bá yẹ. Wọ́n ń ṣe gbogbo èyí kí ayé àwọn ọmọ wọn lè dára, kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí. Àmọ́, kí làwọn òbí ń retí lọ́dọ̀ àwọn ọmọ? Wọ́n fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa gbọ́rọ̀ sí wọn lẹ́nu kí wọ́n lè ṣe ara wọn láǹfààní. Ṣé kò wá bọ́gbọ́n mu tí Baba wa ọ̀run tó jẹ́ ẹni pípé bá retí pé ká nífẹ̀ẹ́ òun, ká sì mọyì gbogbo ohun tó ṣe fún wa?

FETÍ SÍ OHÙN ỌLỌ́RUN

Nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “fetí sí” túmọ̀ sí pé kéèyàn “ṣègbọràn.” Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá sọ fọ́mọ kan pé, “Gbọ́rọ̀ sáwọn òbí ẹ lẹ́nu.” Torí náà, tẹ́nì kan bá máa fetí sílẹ̀ sí ohun tí Ọlọ́run ń sọ, àfi kẹ́ni náà máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, kó sì máa ṣe ohun tí Ọlọ́run bá sọ. Àmọ́ a ò lè gbọ́ ohùn Ọlọ́run bá a ṣe ń gbọ́ ohùn èèyàn, tá a bá fẹ́ gbọ́ ohùn Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì, ká sì máa fi ohun tá à ń kà ṣèwà hù.​—1 Jòhánù 5:3.

Jésù sọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọ́ràn sí Ọlọ́run. Ó ní: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Bó ṣe ṣe pàtàkì pé ká máa jẹun, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì pé ká máa ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òun gan-an ló tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì ṣàlàyé pé: “Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:12) Ìmọ̀ àti ọgbọ́n tí Ọlọ́run bá fún wa lè dáàbò bò wá, ó sì lè jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, ìyẹn àwọn ìpinnu tó máa jẹ́ ká ní ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú.

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Má gbàgbé àpèjúwe Jésù tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, níbi tí Jésù ti sọ pé: “Tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:​13, 14) Tá a bá fẹ́ rin ìrìn àjò lójú ọ̀nà yìí, ó dájú pé a máa nílò ẹnì kan táá máa tọ́ wa sọ́nà, ká lè débi tá à ń lọ, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣé o wá rí i pé ó ṣe pàtàkì ká sún mọ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 16:8) Àmọ́ báwo la ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?

Ojoojúmọ́ la máa ń ní ọ̀pọ̀ nǹkan tá a fẹ́ ṣe, àwọn míì sì wà tó di dandan ká ṣe. Àwọn nǹkan yẹn lè mú kọ́wọ́ wa dí débi pé a ò ní ráyè ronú nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rán wa létí pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfésù 5:​15, 16) Tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, ohun tó yẹ kó gbà wá lọ́kàn jù ni bá a ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.​—Mátíù 6:33.

ỌWỌ́ Ẹ LÓ WÀ

Kò sí ohun tó o lè ṣe nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, àmọ́ ọwọ́ ẹ ni ọjọ́ ọ̀la rẹ wà. O lè yan ọjọ́ ọ̀la tó dára fún ara rẹ àti ìdílé rẹ. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì sọ ohun tó fẹ́ ká máa ṣe. Gbọ́ ohun tí wòlíì Míkà sọ, ó ní:

“Ó ti sọ fún ọ, ìwọ ará ayé, ohun tí ó dára. Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”​Míkà 6:8.

Ọlọ́run ń fìfẹ́ pè ẹ́ pé kó o bá òun rìn, kó o lè gbádùn ìbùkún ayérayé tó máa fún àwọn tó bá gbà láti bá a rìn. Ṣé wàá bá Ọlọ́run rìn? Ọwọ́ ẹ ló wà!