Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Ni Yóò Ni Ilẹ̀ Ayé”

“Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Ni Yóò Ni Ilẹ̀ Ayé”

Ọ̀pọ̀ nínú wa ló ti rí bí àwọn èèyàn ṣe ń gbé ẹ̀bi fún aláre tí wọ́n sì ń gbé àre fún ẹlẹ́bi, a tún ń rí bí àwọn ẹni ibi ṣe ń fìyà jẹ aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Ṣé ìgbà kan tiẹ̀ ń bọ̀ tí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ìkà kò ní sí mọ́?

Nínú Bíbélì, Sáàmù 37 dáhùn ìbéèrè yìí, ó sì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an. Gbọ́ ohun tó sọ nípa àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí.

  • Kí ló yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá ń ni wá lára?​—Ẹsẹ 1 àti 2.

  • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni burúkú?Ẹsẹ 10.

  • Báwo ni ọjọ́ ọ̀la àwọn tó ń hùwà rere ṣe máa rí?​—Ẹsẹ 11 àti 29.

  • Kí ló yẹ ká máa ṣe báyìí?​—Ẹsẹ 34.

Ohun tí Ọlọ́run sọ ní Sáàmù 37 jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára fún àwọn tó ‘ní ìrètí nínú Jèhófà, tí wọ́n sì ń pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.’ Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì mọ ohun tó yẹ kó o ṣe kí ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ lè gbádùn ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ yẹn.