Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run Máa Tó Mú Gbogbo Ìyà Kúrò

Ọlọ́run Máa Tó Mú Gbogbo Ìyà Kúrò

“Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́? Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là?” (Hábákúkù 1:2, 3) Hábákúkù ló sọ ọ̀rọ̀ yìí, èèyàn dáadáa ni, Jèhófà sì fẹ́ràn rẹ̀. Ṣé ohun tó sọ yìí fi hàn pé kò nígbàgbọ́? Rárá o. Ọlọ́run fi dá Hábákúkù lójú pé òun ti yan àkókò kan tí òun máa mú ìyà kúrò.​—Hábákúkù 2:2, 3.

Tí ìyà bá ń jẹ àwa tàbí èèyàn wa kan, kì í pẹ́ rárá tá a fi máa ń sọ pé: ‘Ìwọ Ọlọ́run, ibo lojú ẹ wà? Kí ló dé tó ò ń wò wá níran? Ìyà yìí ti pọ̀ jù!’ Àmọ́, Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”​—2 Pétérù 3:9.

ÌGBÀ WO NI ỌLỌ́RUN MÁA MÚ ÌYÀ KÚRÒ?

Kò ní pẹ́ mọ́! Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ìran kan wà tó máa fojú rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó máa fi hàn pé a ti wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn “ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3-42) Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó ń ṣẹ báyìí fi hàn pé kò ní pẹ́ mọ́ rárá tí Olọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ aráyé. a

Àmọ́ báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú gbogbo ìyà kúrò? Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn nǹkan tó ṣe fi hàn pé Ọlọ́run ní agbára láti mú gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.

Ìjábá: Nígbà tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń rìnrìn-àjò nínú ọkọ̀ ojú omi lórí Òkun Gálílì, ìjì ńlá kan jà tó fẹ́ mú kí ọkọ̀ wọn rì. Àmọ́ Jésù fi hàn pé kò sí ìjábá náà tí apá òun àti Baba rẹ̀ ò ká. (Kólósè 1:15, 16) Ńṣe ni Jésù kàn sọ pé: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.”​—Máàkù 4:35-39.

Àìsàn: Àwọn èèyàn mọ Jésù dáadáa pé ó máa ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ó la ojú afọ́jú, ó mú arọ lára dá, ó mú àwọn tó ní wárápá àti ẹ̀tẹ̀ lára dá, tó fi mọ́ oríṣiríṣi àwọn àìsàn míì. Jésù yanjú ìṣòro gbogbo àwọn tó ń jìyà.​—Mátíù 4:23, 24; 8:16; 11:2-5.

Àìtó Oúnjẹ: Jésù lo agbára tí Baba rẹ̀ fún un láti sọ oúnjẹ díẹ̀ di púpọ̀. Nígbà tí Jésù wà láyé, ìgbà méjì ni Bíbélì ròyìn pé ó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn.​—Mátíù 14:14-21; 15:32-38.

Ikú: Àwọn mẹ́ta ni Bíbélì ròyìn pé Jésù jí dìde, ẹ̀rí tó ṣe kedere sì nìyẹn jẹ́ pé Jèhófà lágbára láti mú ikú kúrò. Ẹnì kan tiẹ̀ wà tó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin kí Jésù tó jí i dìde.​—Máàkù 5:35-42; Lúùkù 7:11-16; Jòhánù 11:3-44.

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, wo ẹ̀kọ́ 32 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde, o sì lè wà á jáde lọ́fẹ̀ẹ́ lórí ìkànnì www.pr418.com/yo.