Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tá ò fi fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé àwọn ìtẹ̀jáde wa sórí ìkànnì míì tàbí sórí ìkànnì àjọlò?

Torí pé a máa ń fún àwọn èèyàn láwọn ìtẹ̀jáde wa láìsí pé à ń díye lé e, àwọn kan ronú pé kò sóhun tó burú táwọn bá ṣe ẹ̀dà àwọn ìtẹ̀jáde yìí, táwọn sì gbé e sórí àwọn ìkànnì míì tàbí sórí ìkànnì àjọlò. Àmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ti rú òfin, bó ṣe wà nínú Àdéhùn Lílo Ìkànnì àti Àṣẹ Láti Lo Ìkànnì * wa, irú ìwà yìí sì ti fa ọ̀pọ̀ ìṣòro. Bó ṣe wà nínú Àdéhùn Lílo Ìkànnì wa, a kò gba ẹnikẹ́ni láyè láti “gbé ohun tó wà lórí ìkànnì yìí sórí íńtánẹ́ẹ̀tì (ìkànnì èyíkéyìí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, ìkànnì téèyàn ti lè wa ìsọfúnni láìgbàṣẹ tàbí ìkànnì àjọlò).” Kí nìdí tọ́rọ̀ náà fi le tó bẹ́ẹ̀?

A ò gba ẹnikẹ́ni láyè láti gbé àwọn ìtẹ̀jáde wa sórí ìkànnì èyíkéyìí

Gbogbo ìtẹ̀jáde tó wà lórí ìkànnì wa ló ní Ẹ̀tọ́ Àdàkọ. Ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí mú kó ṣe kedere pé ètò Ọlọ́run nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀dà àwọn ìtẹ̀jáde wa àti pé kò sẹ́lòmíì tó lè ṣe bẹ́ẹ̀ láìgbàṣẹ. Àmọ́, àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn alátakò ti ń gbé àwọn ìtẹ̀jáde wa sórí ìkànnì wọn láti dọ́gbọ́n tan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì jẹ. Wọ́n tún máa ń gbé àwọn ohun kan sórí ìkànnì wọn káwọn èèyàn lè máa ṣiyèméjì nípa ètò Ọlọ́run. (Sm. 26:4; Òwe 22:5) Àwọn míì máa ń lo àwọn ohun tó wà nínú ìtẹ̀jáde wa tàbí àmì jw.org láti polówó ọjà. Wọ́n máa ń tẹ àmì náà sórí àwọn nǹkan tí wọ́n ń tà, wọ́n sì tún máa ń lò ó lórí ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà tàbí fóònù. Torí pé a ní Ẹ̀tọ́ àdàkọ, a lè gbé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ lọ sílé ẹjọ́. (Òwe 27:12) Tá a bá wá mọ̀ọ́mọ̀ gba àwọn ará wa tàbí àwọn míì láyè láti ṣe ẹ̀dà àwọn ìtẹ̀jáde wa kí wọ́n sì gbé e sórí ìkànnì míì, ilé ẹjọ́ kò ní gba ẹjọ́ wa rò. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá jẹ́ káwọn èèyàn máa fi àmì jw.org polówó ọjà tàbí kí wọ́n máa tẹ̀ ẹ́ sórí àwọn nǹkan tí wọ́n ń tà.

Àwọn ìkànnì yìí nìkan ni ètò Jèhófà ń lò láti fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí:

Ó léwu tẹ́ ẹ bá wa àwọn ìtẹ̀jáde wa jáde lórí àwọn ìkànnì tó yàtọ̀ sí ìkànnì jw.org. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” nìkan ni Jèhófà gbéṣẹ́ fún pé kó máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa. (Mát. 24:45) Ìkànnì www.pr418.com, tv.pr418.com, [tá a ti máa ń wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW] àti wol.pr418.com [ìyẹn Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì] nìkan ni àwọn ìkànnì tí “ẹrú” náà ń lò láti gbé oúnjẹ tẹ̀mí jáde fún wa. Tó bá sì kan ètò ìṣiṣẹ́ orí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù, mẹ́ta péré la ní, ìyẹn JW Language®, JW Library® àti JW Library Sign Language®. Ọkàn wa balẹ̀ pé kò sí ìpolówó ọjà lórí àwọn ìkànnì tí ètò Ọlọ́run ń lò yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sáyè láti gbé ìgbékúgbèé sórí ẹ̀. Ó ṣe kedere nígbà náà pé tẹ́nì kan bá wá oúnjẹ tẹ̀mí lọ sórí àwọn ìkànnì míì yàtọ̀ sí ti ètò Ọlọ́run, kò sí ẹ̀rí pé ojúlówó oúnjẹ tẹ̀mí lonítọ̀hún máa rí.​—Sm. 18:26; 19:8.

Bákan náà, àwọn ìkànnì kan wà táwọn èèyàn ti máa ń lóhùn sí ìjíròrò. Tẹ́nì kan bá gbé àwọn ìtẹ̀jáde wa sórí àwọn ìkànnì bẹ́ẹ̀, ó lè mú káwọn apẹ̀yìndà àtàwọn alárìíwísí sọ ohun tí kò tọ́ nípa ètò Jèhófà, ìyẹn sì lè mú ká máa ṣiyèméjì nípa ètò Jèhófà. Àwọn ará wa kan ti dá sí àríyànjiyàn lórí àwọn ìkànnì bẹ́ẹ̀, èyí sì ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Àwọn ìkànnì yẹn kì í ṣe ibi tó yẹ ká ti máa báwọn èèyàn jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, torí pé wọn kì í ṣe ibi tá a ti lè “fún àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù.” (2 Tím. 2:​23-25; 1 Tím. 6:​3-5) A tún kíyè sí pé àwọn kan ti fi orúkọ ètò Ọlọ́run, orúkọ Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà ṣí ìkànnì àjọlò àtàwọn ìkànnì míì. Àmọ́ o, a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé kò sí ìkankan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ní ìkànnì ara ẹni tàbí tó wà lórí ìkànnì àjọlò èyíkéyìí.

Tá a bá ń darí àwọn èèyàn lọ sórí ìkànnì wa, wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ gbọ́ “ìhìn rere” Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) Ìgbà gbogbo là ń mú káwọn ìtẹ̀jáde wa tó wà lórí ẹ̀rọ sunwọ̀n sí i. À ń lo àwọn ìtẹ̀jáde yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa torí pé a fẹ́ kó ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Torí náà, o lè fi àwọn ìtẹ̀jáde wa ránṣẹ́ sí ẹlòmíì nípasẹ̀ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ìyẹn e-mail tàbí kó o fi ìlujá àwọn ìtẹ̀jáde táá gbé wọn lọ sórí ìkànnì jw.org ránṣẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò tẹ òfin Àdéhùn Lílo Ìkànnì wa lójú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń darí wọn sí ibì kan ṣoṣo tí wọ́n ti lè rí oúnjẹ tẹ̀mí, ìyẹn ọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”

^ ìpínrọ̀ 1 Ẹ máa rí ìlujá tó máa gbé yín lọ sínú Àdéhùn Lílo Ìkànnì wa tẹ́ ẹ bá wo ọwọ́ ìsàlẹ̀ ojúde ìkànnì jw.org, gbogbo ìtẹ̀jáde tó wà lórí àwọn ìkànnì wa lọ̀rọ̀ yìí sì kàn.