Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Jèhófà Dá Mi Lọ́lá Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Ọmọ Tálákà

Jèhófà Dá Mi Lọ́lá Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Ọmọ Tálákà

Inú ilé pákó kan ni wọ́n bí mi sí nílùú kékeré kan tó ń jẹ́ Liberty, ìpínlẹ̀ Indiana lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ẹ̀gbọ́n mẹ́ta ni mo ní, ọkùnrin kan àti obìnrin méjì. Nígbà tó yá, màámi tún bí ọmọ mẹ́ta míì, ọkùnrin méjì àti obìnrin kan.

Ilé pákó tí wọ́n bí mi sí

MO RÁNTÍ pé lágbègbè wa, àwọn tá a jọ bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé náà la jọ parí ẹ̀. Kódà mo fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ orúkọ gbogbo àwọn tó ń gbé ìlú wa, àwọn náà sì mọ orúkọ mi.

Àwa méje làwọn òbí wa bí, àtikékeré sì ni mo ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń dáko

Àwọn oko kéékèèké ló wà nílùú wa, oko àgbàdo ló sì pọ̀ jù nínú wọn. Àgbẹ̀ kan ni bàbá mi ń ṣiṣẹ́ fún nígbà tí wọ́n bí mi. Torí náà, kí n tó pé ọmọ ogún ọdún ni mo ti mọ bí wọ́n ṣe ń wa katakata, mo sì tún mọ àwọn iṣẹ́ oko míì ṣe.

Bàbá mi ti dàgbà nígbà tí wọ́n bí mi, kódà ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] ni wọ́n nígbà yẹn, màmá mi sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì [35]. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ò fi bẹ́ẹ̀ lára, síbẹ̀ ìlera wọn dáa, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì kọ́ gbogbo wa pé káwa náà máa ṣiṣẹ́ kára. Ìwọ̀nba owó díẹ̀ ló ń wọlé fún wọn, síbẹ̀ wọ́n rí i pé à ń ríbi sùn, à ń ráṣọ wọ̀, a sì ń rí oúnjẹ jẹ. Kí n sòótọ́, bàbá mi gbìyànjú fún wa gan-an. Ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93] ni wọ́n nígbà tí wọ́n kú, màmá mi sì kú lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86]. Kò sí èyí tó sin Jèhófà nínú àwọn méjèèjì, àmọ́ àbúrò mi kan wà tó sin Jèhófà, kódà láti nǹkan bí ọdún 1970 ló ti di alàgbà.

ÌGBÀ TÍ MO WÀ NÍ KÉKERÉ

Màmá mi ò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá. Torí náà, wọ́n máa ń kó gbogbo wa lọ sí Ìjọ Onítẹ̀bọmi ní gbogbo ọjọ́ Sunday. Ìgbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá ni mo kọ́kọ́ gbọ́ nípa Mẹ́talọ́kan. Ọ̀rọ̀ yẹn rú mi lójú, mo wá bi màmá mi pé: “Báwo ni Jésù ṣe lè jẹ́ Ọmọ, kó sì tún jẹ́ Bàbá lẹ́sẹ̀ kan náà?” Mo rántí ìdáhùn tí wọ́n fún mi, wọ́n ní: “Ọmọ, àdììtú lọ̀rọ̀ yẹn. Kò lè yé wa.” Ọ̀rọ̀ yẹn ò sì yé mi lóòótọ́. Síbẹ̀, mo ṣèrìbọmi nínú odò kan nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, mo tiẹ̀ rántí pé ẹ̀ẹ̀mẹta ni wọ́n rì mí bọ odò yẹn torí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Mẹ́talọ́kan.

1952 Èmi rèé lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kí wọ́n tó pè mí fún iṣẹ́ ológún

Nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ girama, mo lọ́rẹ̀ẹ́ kan tó máa ń kan ẹ̀ṣẹ́, ó sì ní kémi náà wá kọ́ bí wọ́n ṣe ń kan ẹ̀ṣẹ́. Bí èmi náà ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, mo tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn tó ń kan ẹ̀ṣẹ́ tí wọ́n ń pè ní Golden Gloves. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi jáwọ́ torí mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ẹ̀ṣẹ́ kàn. Nígbà tó yá, wọ́n pè mí fún iṣẹ́ ológún, wọ́n sì rán mi lọ sílẹ̀ Jámánì. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, àwọn ọ̀gá mi sọ pé mo mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan. Ni wọ́n bá rán mi lọ sí Noncommissioned Officers Academy, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ àwọn ológun kémi náà lè di ọ̀gá nínú iṣẹ́ ológun. Àmọ́ iṣẹ́ ológun ò wù mí mọ́, torí náà lẹ́yìn ti mo parí ọdún méjì tí wọ́n pè mí fún, mo pa dà sílé lọ́dún 1956. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun míì tó yàtọ̀ pátápátá.

1954-1956 Mo lo ọdún méjì lẹ́nu iṣẹ́ ológun

ÌGBÉSÍ AYÉ MI YÍ PA DÀ

Lásìkò yìí, ohun táyé ń gbé lárugẹ nínú àwọn fíìmù àti láwọn ibòmíì ni pé kéèyàn ní iṣan lápá, kó sì máa ganpá kiri káwọn èèyàn má bàa fojú pa á rẹ́. Ohun témi náà sì ń ṣe nìyẹn, kódà ojú sùẹ̀gbẹ̀ ni mo fi ń wo àwọn tó ń wàásù. Àmọ́ mo kọ́ àwọn nǹkan tó yí ìgbésí ayé mi pa dà. Lọ́jọ́ kan tí mò ń wa mọ́tò mi kiri ìgboro, àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì kan juwọ́ sí mi. Mo mọ̀ wọ́n dáadáa, àbúrò ọkọ ẹ̀gbọ́n mi ni wọ́n, wọ́n sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ti fún mi ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! nígbà kan rí, àmọ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn kí n máa ka Ilé Ìṣọ́ torí pé lójú mi, ó ti le jù. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n ní kí n wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí wọ́n ń ṣe nílé wọn. Mo sọ fún wọn pé màá lọ rò ó, ni wọ́n bá rẹ́rìn-ín sí mi, wọ́n ní kí n ṣèlérí pé màá wá, lèmi náà bá sọ pé màá wá.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wù mí kí n lọ rárá, síbẹ̀ mo lọ lálẹ́ ọjọ́ yẹn torí pé mo ti ṣèlérí fún wọn. Nígbà tí mo débẹ̀, ẹnu yà mí nígbà tí mo rí bí àwọn ọmọdé ṣe ń ṣàlàyé Bíbélì. Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé gbogbo ọjọ́ Sunday la máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ohun tí mo mọ̀ nínú Bíbélì ò tó nǹkan. Èyí ló mú kí n pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì ní kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Lára ohun tí mo kọ́kọ́ mọ̀ ni pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Mo rántí pé nígbà kan tí mo bi màmá mi pé kí ni wọ́n mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n kàn sọ fún mi pé, “Ṣáwọn yẹn, bàbá arúgbó kan tó ń jẹ́ Jèhófà ni wọ́n ń sìn.” Àmọ́ ní báyìí, mo ti wá mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an.

Mo tẹ̀ síwájú gan-an torí mo mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́. Ní March 1957, ìyẹn oṣù mẹ́sàn-án péré lẹ́yìn tí mo kọ́kọ́ wá sípàdé, mo ṣèrìbọmi. Ìgbésí ayé mi wá yí pa dà. Tí mo bá ronú nípa bí mo ṣe ń hùwà tẹ́lẹ̀, inú mi máa ń dùn pé mo kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin pípé ni Jésù, ó lókun, ó sì lágbára débi pé kò sí ọkùnrin míì tá a lè fi wé e. Síbẹ̀ Jésù kì í jà, kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà “kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́,” bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Aísá. 53:​2, 7) Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ẹni tó bá máa jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ “jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.”​—2 Tím. 2:24.

Ọdún tó tẹ̀ lé e ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn ní 1958. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró fúngbà díẹ̀. Ìdí ni pé mo fẹ́ fẹ́yàwó, Gloria tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì tó pè mí wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lọ́jọ́sí ni mo sì fẹ́ fẹ́. Mi ò kábàámọ̀ ìpinnu tí mo ṣe yẹn torí pé Gloria ṣeyebíye ju iyùn lọ nígbà tí mo fẹ́ ẹ, bó sì ṣe rí títí dòní nìyẹn. Ìṣúra iyebíye tí ò ṣeé fowó rà ni Gloria jẹ́ fún mi, inú mi sì dùn pé òun ni mo fi ṣaya. Ẹ jẹ́ kóun náà sọ díẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún yín:

“Ọmọ mẹ́tàdínlógún [17] làwọn òbí mi bí. Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni mọ́mì mi, àmọ́ wọ́n kú nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá. Ẹ̀yìn ìyẹn ni dádì mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tí mọ́mì mi kú, dádì mi lọ rí ọ̀gá ilé ìwé wa. Nígbà yẹn, ẹ̀gbọ́n mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jáde ilé ẹ̀kọ́ girama. Dádì bẹ ọ̀gá ilé ìwé wa pé kó jẹ́ kí èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin máa pín ọjọ́ tá a máa wá sílé ìwé. Témi bá lọ lónìí, ẹ̀gbọ́n mi á lọ lọ́la. Ọ̀gá ilé ìwé wa gbà, ohun tá a sì ṣe nìyẹn títí ẹ̀gbọ́n mi fi jáde nílé ìwé. Ẹni tó bá wà nílé nínú àwa méjèèjì ló máa tọ́jú àwọn àbúrò wa, á sì se oúnjẹ alẹ́ tí gbogbo wa máa jẹ kí Dádì tó dé láti ibiṣẹ́. Àwọn ìdílé méjì ló máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, mọ́kànlá nínú àwa ọmọ sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo gbádùn kí n máa lọ sóde ẹ̀rí gan-an bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú máa ń tì mí. Inú mi dùn pé ọkọ mi ti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè borí ìtìjú yìí.”

Èmi àti Gloria ṣègbéyàwó ní February 1959. A sì jọ gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ní July ọdún yẹn kan náà, a gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì torí pé ó wù wá láti sìn ní oríléeṣẹ́ wa. Arákùnrin àtàtà kan tó ń jẹ́ Simon Kraker ló fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò, ó sì sọ fún wa pé wọn ò gba àwọn tọkọtaya sí Bẹ́tẹ́lì nígbà yẹn. Síbẹ̀, a ò jẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì kúrò lọ́kàn wa, àmọ́ ó pẹ́ gan-an kọ́wọ́ wa tó tẹ àǹfààní yìí.

A wá kọ̀wé sí oríléeṣẹ́ pé kí wọ́n rán wa lọ sí ibi tí àìní wà. Nígbà tí wọ́n dá wa lóhùn, ibì kan ṣoṣo ni wọ́n fún wa, ìyẹn Pine Bluff, ní ìpínlẹ̀ Arkansas. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ìjọ méjì ló wà ní Pine Bluff, àwọn aláwọ̀ funfun ló wà níjọ àkọ́kọ́, àwọn aláwọ̀ dúdú ló sì wà níjọ kejì. Ìjọ táwọn aláwọ̀ dúdú wà ni wọ́n rán wa lọ, nǹkan bí akéde mẹ́rìnlá ló sì wà níjọ yẹn.

KẸ́LẸ́YÀMẸ̀YÀ GBILẸ̀ GAN-AN

Ẹ lè máa ronú pé kí ló dé táwọn aláwọ̀ funfun àtàwọn aláwọ̀ dúdú ò fi jọ da nǹkan pọ̀ nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣẹ́ ẹ rí i, nígbà yẹn lọ́hùn-ún kò sóhun tá a lè ṣe sí i. Torí pé ìjọba dìídì ṣòfin pé àwọn aláwọ̀ funfun àtàwọn aláwọ̀ dúdú ò gbọ́dọ̀ da nǹkan pọ̀, táwọn èèyàn bá sì rí wọn pa pọ̀, gbẹgẹdẹ lè gbiná. Ìdí nìyẹn táwọn ará fi ń bẹ̀rù pé táwọn aláwọ̀ funfun àtàwọn aláwọ̀ dúdú bá jọ ń ṣèpàdé, àwọn jàǹdùkú lè ba Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn jẹ́, irú ẹ̀ sì ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Kódà, táwọn aláwọ̀ dúdú bá lọ wàásù níbi táwọn aláwọ̀ funfun ń gbé, ṣe ni wọ́n máa fi ọlọ́pàá mú wọn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n lù wọ́n nílùkulù. Torí náà ká lè wàásù láìsí wàhálà, ṣe la tẹ̀ lé òfin yẹn, a sì nírètí pé nǹkan ṣì máa yí pa dà.

Kò rọrùn láti wàásù nígbà yẹn. Nígbà míì tá a bá ń wàásù lágbègbè táwọn aláwọ̀ dúdú ń gbé, a máa kan ilẹ̀kùn míì, a sì máa rí i pé àwọn aláwọ̀ funfun ló ń gbébẹ̀. A ò ní mọ̀ bóyá ká wàásù fún wọn ní ṣókí tàbí ká tọrọ àforíjì, ká sì tètè bá ẹsẹ̀ wa sọ̀rọ̀. Bí nǹkan ṣe rí nìyẹn lásìkò náà.

Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wa lọ. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tá a ṣe ló jẹ́ pé dọ́là mẹ́ta péré ni wọ́n ń san fún wa lóòjọ́. Gloria sábà máa ń bá àwọn èèyàn tọ́jú ilé. Ó tiẹ̀ nílé kan tí wọ́n ti gbà kí n máa ràn án lọ́wọ́ kó lè tètè máa parí iṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n máa ń fún wa lóúnjẹ ọ̀sán, èmi àti Gloria sì jọ máa jẹ ẹ́ ká tó kúrò níbẹ̀. Gloria tún máa ń bá ìdílé kan lọ aṣọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èmi sì máa ń tọ́jú ọgbà wọn, mo máa ń nu wíńdò, mo sì máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ míì. Nílé àwọn aláwọ̀ funfun kan tá a ti ṣiṣẹ́, Gloria máa ń nu wíńdò wọn láti inú ilé, èmi á sì nù ún láti ìta. Iṣẹ́ ọjọ́ kan gbáko niṣẹ́ yẹn, torí náà wọ́n máa ń fún wa lóúnjẹ ọ̀sán. Inú ilé ni Gloria ti máa ń jẹun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í jókòó pẹ̀lú ìdílé náà, èmi sì máa ń jẹun níta. Oúnjẹ yẹn máa ń dùn gan-an, mi ò tiẹ̀ kì í ronú pé ìta ni mo ti ń jẹ ẹ́. Ìdílé yẹn kóni mọ́ra, àmọ́ kò sí nǹkan tí wọ́n lè ṣe sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó gbilẹ̀ nígbà yẹn. Mo rántí ìgbà kan tá a dúró ra epo nílé epo kan. Lẹ́yìn tá a ra epo tán, mo béèrè bóyá ìyàwó mi lè lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn. Ṣe ni ọ̀gbẹ́ni náà fojú burúkú wò mí, ó sì sọ pé: “Wọ́n ti tì í.”

INÚ RERE TÁ Ò LÈ GBÀGBÉ LÁÉ

Láìka gbogbo ìṣòro yẹn sí, a gbádùn àkókò tá a lò pẹ̀lú àwọn ará, a sì gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an. Nígbà tá a kọ́kọ́ dé Pine Bluff, ọ̀dọ̀ arákùnrin tó jẹ́ ìránṣẹ́ ìjọ là ń gbé. Nígbà yẹn, ìyàwó arákùnrin náà kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà Gloria bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́sẹ̀ kan náà, mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọmọbìnrin wọn àti ọkọ rẹ̀. Inú wa dùn pé ìyàwó arákùnrin yẹn àti ọmọbìnrin rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi.

A tún láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà ní ìjọ táwọn aláwọ̀ funfun wà. Nígbà míì, wọ́n máa ń pè wá pé ká wá jẹun nílé wọn, àmọ́ alẹ́ ni wọ́n sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì gbọ́dọ̀ kíyè sára. Ìdí ni pé ẹgbẹ́ kan wà nígbà yẹn tí wọ́n ń pè ní Ku Klux Klan (ìyẹn KKK), ẹgbẹ́ yìí ló ń ṣagbátẹrù kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, torí pé wọ́n kórìíra àwọn aláwọ̀ dúdú gan-an. Mo rántí pé lálẹ́ ọjọ́ kan táwọn èèyàn ń ṣọdún Halloween, mo rí ọkùnrin kan tó jókòó síwájú ilé rẹ̀, tó sì wọ aṣọ funfun àti ìbòjú táwọn ẹgbẹ́ KKK máa ń wọ̀. Láìka gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn sí, àwọn ará ṣì ń fìfẹ́ hàn sí wa. Nígbà kan tá a fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè, a ò lówó tá a lè fi rìnrìn-àjò, arákùnrin kan wá gbà láti ra mọ́tò wa ká lè rówó lọ sí àpéjọ náà. Àmọ́ oṣù kan lẹ́yìn ìyẹn, bá a ṣe ń bọ̀ láti òde ẹ̀rí, ó ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu torí ìrìn àrìnwọ́dìí tá a ti rìn nínú oòrùn. Nígbà tá a máa délé, a rí ohun kan tó yà wá lẹ́nu. A rí mọ́tò wa níwájú ilé wa, a sì rí ìwé pélébé kan tí wọ́n kọ̀rọ̀ sí pé: “Mo mọ̀ pé ẹ nílò mọ́tò yìí, torí náà mo fún yín pa dà. Èmi arákùnrin yín.”

Ẹnì kan tún fi inúure hàn sí mi, mi ò sì lè gbàgbé láé. Lọ́dún 1962, ètò Ọlọ́run pè mí fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ nílùú South Lansing, New York. Oṣù kan gbáko ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí, wọ́n sì ṣètò rẹ̀ fáwọn alábòójútó nínú ìjọ, àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alábòójútó àgbègbè. Lásìkò tí wọ́n pè mí yìí, mi ò níṣẹ́ lọ́wọ́, àtigbọ́ bùkátà ìdílé sì ṣòro díẹ̀ fún mi. Àmọ́, iléeṣẹ́ tẹlifóònù kan wà ní Pine Bluff tó fẹ́ gbà mí síṣẹ́. Tí wọ́n bá gbà mí, èmi ni màá jẹ́ aláwọ̀ dúdú àkọ́kọ́ tí wọ́n máa gbà sílé iṣẹ́ náà. Wọ́n tiẹ̀ sọ fún mi pé àwọn á gbà mí. Kí ni màá ṣe? Mi ò lówó tí mo lè fi rìnrìn-àjò lọ sí New York. Mo wá wò ó pé bóyá máa gba iṣẹ́ yẹn kí n sì pa ilé ẹ̀kọ́ náà tì. Kódà mo ti fẹ́ kọ lẹ́tà sí ètò Ọlọ́run pé mi ò ní lè wá, àmọ́ nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tí mi ò lè gbàgbé láé.

Arábìnrin kan wà ní ìjọ wa tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, arábìnrin yìí wá sílé wa, ó sì fún mi ní àpò ìwé kan. Nígbà tí màá ṣí i, owó ló kúnnú ẹ̀ bámú. Òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ máa ń jí láàárọ̀ kùtù, wọ́n á lọ ṣiṣẹ́ nínú oko tí wọ́n ti ń gbin òwú, wọ́n á sì bá àwọn àgbẹ̀ tu koríko tó ń hù nínú oko yẹn. Ohun tó mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ tu owó jọ fún mi kí n lè rìnrìn-àjò lọ sí New York fún ilé ẹ̀kọ́ náà. Arábìnrin náà sọ fún mi pé: “Mo fẹ́ kó o lọ gbẹ̀kọ́ dáadáa nílé ẹ̀kọ́ yẹn, kó o lè pa dà wá kọ́ wa tó o bá dé!” Mo bá pe iléeṣẹ́ tẹlifóònù tó fẹ́ gbà mí síṣẹ́ pé kí wọ́n fún mi lọ́sẹ̀ márùn-ún kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àmọ́ wọ́n sọ fún mi pé, “Kò sóhun tó jọ ọ́!” Èmi náà ò sì yọ ara mi lẹ́nu torí mo ti pinnu ohun tí màá ṣe. Inú mi dùn pé mi ò gba iṣẹ́ náà, ilé ẹ̀kọ́ ni mo lọ.

Gloria náà sọ bí nǹkan ṣe rí ní Pine Bluff, ó ní: “Mo gbádùn àgbègbè tá a ti wàásù gan-an, kódà mo ní àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó tó mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún. A máa ń lọ sí ilé-dé-ilé láàárọ̀, lẹ́yìn náà, àá lọ sọ́dọ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, nígbà míì a máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ di aago mọ́kànlá alẹ́. A gbádùn iṣẹ́ náà gan-an, ó ń ṣe mí bíi pé ká má kúrò lẹ́nu iṣẹ́ yẹn mọ́, kódà ó kọ́kọ́ ṣe mí bákan nígbà tí ètò Ọlọ́run ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká, àmọ́ Jèhófà mọ ibi tó ti fẹ́ lò wá.”

A BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ

Bá a ṣe ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wa lọ ní Pine Bluff, a kọ lẹ́tà sí ètò Ọlọ́run pé a fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ọkàn wa balẹ̀ pé ètò Ọlọ́run máa fọwọ́ sí i torí pé alábòójútó àgbègbè wa fẹ́ ká lọ ran ìjọ kan lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Texas, ó sì fẹ́ ká di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ká tó lọ síbẹ̀. Ó wu àwa náà gan-an pé ká di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Torí náà, a retí retí, àmọ́ a ò gbọ́ èsì kankan látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run. Gbogbo ìgbà la máa ń lọ wo ibi tí wọ́n ń kó lẹ́tà wa sí, síbẹ̀ a kì í bá nǹkan kan. Àmọ́ lọ́jọ́ kan ní January 1965, a bá lẹ́tà kan nínú àpótí náà, ètò Ọlọ́run ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Mo rántí pé àsìkò yẹn náà ni wọ́n sọ Arákùnrin Leon Weaver di alábòójútó àyíká, àmọ́ ní báyìí, òun ni olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí nígbà tí wọ́n ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí. Ní nǹkan bí ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn, Arákùnrin James A. Thompson, Jr. ti gbé mi yẹ̀ wò bóyá mo tóótun fún iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Ó sì fara balẹ̀ ṣàlàyé àwọn ibi tí mo kù sí àtàwọn ànímọ́ míì tó yẹ kí alábòójútó àyíká ní. Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ni mo rí i pé ìmọ̀ràn tó fún mi nígbà yẹn wúlò gan-an. Inú mi sì dùn pé Arákùnrin Thompson ni alábòójútó àgbègbè tí mo kọ́kọ́ bá ṣiṣẹ́ torí pé ẹni tẹ̀mí ni, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára rẹ̀.

Mo mọrírì bí àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe ràn mí lọ́wọ́

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí alábòójútó àyíká máa ń gbà kì í tó nǹkan. Mo lo ọ̀sẹ̀ kan pẹ̀lú alábòójútó àyíká tó ń dá mi lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó ń bẹ ìjọ kan wò, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, a jọ lọ sí ìjọ tí mo fẹ́ bẹ̀ wò, kó lè wo bí mo ṣe ṣe sí, ó sì fún mi láwọn ìmọ̀ràn tó máa ràn mí lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Mo rántí pé mo sọ fún Gloria pé, “Ṣé kò lè dúró díẹ̀ ni?” Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé kò sígbà tó o nílò ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ò ní gbárùkù tì ẹ́, ìyẹn tó o bá jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Mi ò lè gbàgbé àwọn arákùnrin bíi J. R. Brown tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò nígbà yẹn àti Fred Rusk tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn arákùnrin yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an.

Ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà gbòde kan nígbà yẹn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí ẹgbẹ́ KKK ṣe ìwọ́de ní àgbègbè kan tá à ń bẹ̀ wò ní ìpínlẹ̀ Tennessee. Mo tún rántí ọjọ́ kan tá a jáde òde ẹ̀rí, gbogbo wa sì yà ní ilé oúnjẹ kan ká lè sinmi díẹ̀. Ni mo bá ní kí n sáré lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn, àmọ́ mo kíyè sí i pé ọ̀gbẹ́ni kan dìde, ó sì tẹ̀ lé mi. Ọ̀gbẹ́ni yìí rí wúruwùru, ó sì fín gbogbo ara bíi tàwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ KKK. Àmọ́ arákùnrin kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, bó ṣe tẹ̀ lé wa nìyẹn. Arákùnrin yìí fìrìgbọ̀n ju èmi àti ọ̀gbẹ́ni yẹn lọ, ó wá bi mí pé, “Ṣé kò síṣòro Arákùnrin Herd?” Bí ọ̀gbẹ́ni yẹn ṣe rí arákùnrin yẹn, ṣe ló sáré jáde láìlo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ náà. Ohun kan tí mo ti rí ni pé, kì í ṣe àwọ̀ tẹ́nì kan ní ló ń fa ẹ̀tanú àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Arákùnrin ni arákùnrin á máa jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́ yálà wọ́n jẹ́ aláwọ̀ funfun tàbí dúdú, wọ́n sì ṣe tán láti kú fún ẹ.

JÈHÓFÀ BÙ KÚN MI GAN-AN

Ọdún méjìlá [12] la lò lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká, a sì fi ọdún mọ́kànlélógún [21] ṣe iṣẹ́ alábòójútó àgbègbè, lápapọ̀ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] la lò lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò. A gbádùn iṣẹ́ náà, a sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí tó ń fúnni lókun. Àmọ́ Jèhófà ṣì ní iṣẹ́ míì fún wa. Ní August 1997, ọwọ́ wa tẹ ohun kan tá a ti ń fojú sọ́nà fún. Wọ́n pè wá sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Amẹ́ríkà lẹ́yìn ọdún méjìdínlógójì [38] tá a kọ́kọ́ gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì. Oṣù tó tẹ̀ lé e la sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Mo ronú pé wọ́n kàn fẹ́ kí n wá ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀ ni, àmọ́ ọ̀tọ̀ lohun tí wọ́n ní lọ́kàn.

Gloria ṣeyebíye ju iyùn lọ nígbà tí mo fẹ́ ẹ, bó sì ṣe rí títí dòní nìyẹn

Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ni mo ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ gan-an níbẹ̀. Iṣẹ́ ńlá làwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ ń ṣe torí pé jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ni ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà àtàwọn alábòójútó àyíká ti máa ń fi ìbéèrè ránṣẹ́, ẹ̀ka yìí ló sì ń dáhùn àwọn ìbéèrè náà. Mo mọrírì báwọn arákùnrin yìí ṣe fi sùúrù ràn mí lọ́wọ́ tí wọ́n sì dá mi lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ kí n sòótọ́, tí wọ́n bá tún ní kí n lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀, àfi kí wọ́n tún dá mi lẹ́kọ̀ọ́.

Èmi àti Gloria ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì gan-an. Àtilẹ̀ la ti máa ń tètè jí, èyí sì mú kí nǹkan rọrùn fún wa ní Bẹ́tẹ́lì. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan, mo di ọ̀kan lára àwọn olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó sì dọdún 1999, mo láǹfààní láti di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí, àmọ́ ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù ni pé Jésù Kristi ni orí ìjọ Kristẹni, kì í ṣe èèyàn kankan.

Látọdún 1999 ni mo ti láǹfààní láti wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Tí n bá ronú nípa ìgbésí ayé mi, ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé ọ̀rọ̀ èmi àti wòlíì Ámósì jọra. Jèhófà kíyè sí Ámósì tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ yìí ò jọjú torí pé oúnjẹ tálákà làwọn èèyàn ka ọ̀pọ̀tọ́ sí, síbẹ̀ Ọlọ́run yan Ámósì láti di wòlíì, ó sì dájú pé Jèhófà bù kún un gan-an. (Ámósì 7:​14, 15) Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tèmi náà rí, Jèhófà kíyè sí mi, èmi ọmọ àgbẹ̀ lásánlàsàn nílùú Liberty, ìpínlẹ̀ Indiana, ó sì bù kún mi lọ́pọ̀ yanturu, kódà ìbùkún náà kọjá àfẹnusọ! (Òwe 10:22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé mẹ̀kúnnù ni mo ti wá, síbẹ̀ Jèhófà bù kún mi gan-an, àní sẹ́ àwọn ìbùkún náà kọjá kèrémí!