Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mọ Ọ̀tá Rẹ

Mọ Ọ̀tá Rẹ

“Àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn [Sátánì].”​2 KỌ́R. 2:11.

ORIN: 150, 32

1. Kí ni Jèhófà sọ nípa ọ̀tá wa nínú ọgbà Édẹ́nì?

Ó DÁJÚ pé Ádámù mọ̀ pé ejò ò lè sọ̀rọ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó fòye gbé e pé ẹ̀dá ẹ̀mí kan ló lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀. (Jẹ́n. 3:​1-6) Ádámù àti Éfà ò mọ irú ẹni tí ẹ̀dá ẹ̀mí náà jẹ́ rárá. Síbẹ̀, Ádámù fara mọ́ ohun tí ẹ̀dá ẹ̀mí yìí sọ, ó sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Baba rẹ̀ ọ̀run onífẹ̀ẹ́. (1 Tím. 2:14) Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé àwọn ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa ọ̀tá tó tan Ádámù àti Éfà jẹ, ó sì ṣèlérí pé òun máa pa ẹni ibi yìí run. Àmọ́ Jèhófà tún sọ pé kí òun tó pa ọ̀tá yìí run, ọ̀tá yìí máa tako àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.​—Jẹ́n. 3:15.

2, 3. Kí nìdí tí Bíbélì ò fi sọ púpọ̀ nípa ọ̀tá wa ṣáájú kí Mèsáyà tó dé?

2 Jèhófà kò sọ orúkọ áńgẹ́lì tó di ọlọ̀tẹ̀ náà fún wa. * Kódà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] ọdún lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì ni Ọlọ́run tó jẹ́ ká mọ orúkọ tá à ń pe ọ̀tá yẹn lónìí. (Jóòbù 1:6) Kódà, ìwé mẹ́ta péré nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló mẹ́nu kan Sátánì tó túmọ̀ sí “Alátakò.” Àwọn ìwé náà ni Kíróníkà Kìíní, Jóòbù àti Sekaráyà. Kí nìdí tí Bíbélì ò fi sọ púpọ̀ nípa ọ̀tá wa ṣáájú kí Mèsáyà tó dé?

3 Jèhófà ò sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa Sátánì nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó ṣe tán, ìdí pàtàkì tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fi wà lákọọ́lẹ̀ ni pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn dá Mèsáyà mọ̀, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé e. (Lúùkù 24:44; Gál. 3:24) Lẹ́yìn tí Mèsáyà dé, Jèhófà lo òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ láti jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tá a mọ̀ báyìí nípa Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀. * Ìyẹn sì bá a mu gẹ́lẹ́ torí Jésù àtàwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n á jọ ṣàkóso ni Jèhófà máa lò láti pa Sátánì àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ run.​—Róòmù 16:20; Ìṣí. 17:14; 20:10.

4. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù Èṣù?

4 Àpọ́sítélì Pétérù fi Sátánì Èṣù wé “kìnnìún tí ń ké ramúramù,” Jòhánù pè é ní “ejò,” ó sì tún pè é ní “dírágónì.” (1 Pét. 5:8; Ìṣí. 12:9) Ṣùgbọ́n kò sídìí tó fi yẹ ká bẹ̀rù Èṣù, torí pé ó níbi tí agbára rẹ̀ mọ. (Ka Jákọ́bù 4:7.) Ọkàn wa balẹ̀ torí pé Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa gbágbáágbá. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ wọn, a máa borí ọ̀tá wa. Síbẹ̀, ó yẹ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mẹ́ta tó ṣe pàtàkì yìí: Báwo ni agbára Sátánì ṣe pọ̀ tó? Báwo ló ṣe ń dẹkùn mú àwọn èèyàn? Ibo ni agbára rẹ̀ mọ? A máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ níbẹ̀.

BÁWO NI AGBÁRA SÁTÁNÌ ṢE PỌ̀ TÓ?

5, 6. Kí nìdí táwọn ìjọba èèyàn ò fi lè tún ayé yìí ṣe?

5 Àwọn áńgẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Sátánì. Ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Sátánì tan àwọn áńgẹ́lì kan láti bá àwọn ọmọbìnrin èèyàn ṣèṣekúṣe. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tó sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé dírágónì náà wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run pẹ̀lú rẹ̀. (Jẹ́n. 6:​1-4; Júúdà 6; Ìṣí. 12:​3, 4) Àwọn áńgẹ́lì yìí fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì gbà kí Sátánì máa darí àwọn. Kì í ṣe pé àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí kàn ń rìn kiri bí aláìníṣẹ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Jèhófà ṣe gbé Ìjọba ọ̀run kalẹ̀ náà ni Sátánì gbé ìjọba tiẹ̀ náà kalẹ̀. Sátánì fúnra rẹ̀ ló ń darí ìjọba rẹ̀, ó sì ṣètò àwọn ẹ̀mí èṣù sí ìjọba ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó fún wọn ní ọlá àṣẹ, ó sì sọ wọ́n di alákòóso ayé.​—Éfé. 6:12.

6 Sátánì ń fi ìjọba tó gbé kalẹ̀ yìí darí àwọn ìjọba èèyàn. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé Sátánì fi “gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” han Jésù, ó sì sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ yìí àti ògo wọn ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú, nítorí pé a ti fi í lé mi lọ́wọ́, ẹnì yòówù tí mo bá sì fẹ́ ni èmi yóò fi í fún.” (Lúùkù 4:​5, 6) Láìka bí Sátánì ṣe ń lo agbára rẹ̀ lórí ìjọba èèyàn, àwọn ìjọba èèyàn ṣì máa ń ṣe àwọn nǹkan tó dáa déwọ̀n àyè kan fún àwọn aráàlú. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wu àwọn alákòóso kan láti ṣe ohun tó dáa fáwọn èèyàn, àmọ́ kò sí ìjọba tàbí èèyàn èyíkéyìí tó lè tún ayé yìí ṣe.​—Sm. 146:​3, 4; Ìṣí. 12:12.

7. Báwo ni Sátánì ṣe ń lo ìsìn èké àti ètò ìṣòwò láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

7 Kì í ṣe àwọn ìjọba ayé nìkan ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ, ó tún máa ń lo ìsìn èké àti ètò ìṣòwò láti ṣi “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” pátá lọ́nà. (Ìṣí. 12:9) Sátánì máa ń lo ìsìn èké láti tan irọ́ kálẹ̀ nípa Jèhófà. Kì í ṣèyẹn nìkan, Èṣù tún ń sapá gan-an láti mú káwọn èèyàn gbàgbé orúkọ Ọlọ́run. (Jer. 23:​26, 27) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ló ti tàn jẹ torí wọ́n rò pé Ọlọ́run làwọn ń sìn àmọ́ tó jẹ́ pé ẹ̀mí èṣù ni wọ́n ń jọ́sìn. (1 Kọ́r. 10:20; 2 Kọ́r. 11:​13-15) Sátánì tún máa ń lo ètò ìṣòwò láti tan àwọn èèyàn jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ rò pé ó dìgbà táwọn bá lówó tabua, táwọn sì kó nǹkan jọ pelemọ káwọn tó lè láyọ̀. (Òwe 18:11) Àwọn tó gba irọ́ yìí gbọ́ máa ń fi ojoojúmọ́ ayé wọn lépa “Ọrọ̀” dípò kí wọ́n máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mát. 6:24) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ti jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún owó àtàwọn nǹkan tara bo ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run mọ́lẹ̀.​—Mát. 13:22; 1 Jòh. 2:​15, 16.

8, 9. (a) Ẹ̀kọ́ méjì wo la rí kọ́ látinú ohun tí Ádámù, Éfà àtàwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ yẹn ṣe? (b) Àǹfààní wo ló wà nínú bá a ṣe mọ̀ pé Sátánì ló ń darí ayé?

8 Ó kéré tán, ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì wà tá a rí kọ́ lára Ádámù, Éfà àtàwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀. Àkọ́kọ́, kò sáyè fún ṣeku-ṣẹyẹ, nínú ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tàbí ká fi ara wa sábẹ́ àkóso Sátánì. (Mát. 7:13) Ìkejì, àǹfààní díẹ̀ làwọn tó bá tẹ̀ lé Sátánì máa ń rí. Bí àpẹẹrẹ, Ádámù àti Éfà láǹfààní láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fúnra wọn, àwọn ẹ̀mí èṣù náà sì lágbára déwọ̀n àyè kan lórí àwọn ìjọba èèyàn. (Jẹ́n. 3:22) Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tẹ́nì kan bá yàn láti tẹ̀ lé Sátánì, ohun tí Sátánì máa fún un kò ní tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyà tó máa jẹ.​—Jóòbù 21:​7-17; Gál. 6:​7, 8.

9 Àǹfààní wo ló wà nínú bá a ṣe mọ̀ pé Sátánì ló ń darí ayé? Ó ń jẹ́ ká fi àwọn ìjọba èèyàn sí àyè tó yẹ wọ́n, ó sì ń jẹ́ ká máa fìtara kìlọ̀ fáwọn èèyàn. Jèhófà fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. (1 Pét. 2:17) Ó sì tún fẹ́ ká máa ṣègbọràn sí òfin wọn tí kò bá ti tako àwọn ìlànà rẹ̀. (Róòmù 13:​1-4) Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, a ò gbọ́dọ̀ gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí tàbí ká máa gbé alákòóso kan lárugẹ. (Jòh. 17:​15, 16; 18:36) Bákan náà, Sátánì ò fẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, ó sì ń bà á lórúkọ jẹ́, ìdí nìyẹn tá a fi ń sapá láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Inú wa máa ń dùn pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, a sì ń lo orúkọ rẹ̀ torí a mọ̀ pé, tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àǹfààní tá a máa rí á ju àǹfààní èyíkéyìí tí owó tàbí nǹkan tara lè fún wa.​—Aísá. 43:10; 1 Tím. 6:​6-10.

BÁWO NI SÁTÀNÌ ṢE Ń DẸKÙN MÚ ÀWỌN ÈÈYÀN?

10-12. (a) Báwo ni Sátánì ṣe lo ohun tó dà bí ìjẹ láti tan àwọn áńgẹ́lì jẹ? (b) Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn áńgẹ́lì yẹn?

10 Sátánì gbọ́n féfé nínú bó ṣe máa ń tan àwọn èèyàn jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń lo àwọn nǹkan tó dà bí ìjẹ kó lè fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra. Ìgbà míì sì rèé, ṣe ló máa ń halẹ̀ mọ́ wọn kí wọ́n lè ṣe ohun tó fẹ́.

11 Sátánì lo ohun tó dà bí ìjẹ láti fi tan ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì. Á ti máa ṣọ́ wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún kó lè mọ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ táá fi mú wọn. Nígbà tó yá, ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì lò mú wọn, wọ́n sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin, ni wọ́n bá bí àwọn òmìrán tó jẹ́ òǹrorò ẹ̀dá. (Jẹ́n. 6:​1-4) Kò dájú pé ìṣekúṣe nìkan ni Sátánì fi tan àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn, ó tún lè sọ fún wọn pé òun á fún wọn lágbára láti máa darí àwọn èèyàn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Sátánì ò fẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ nípa ‘irú-ọmọ obìnrin náà’ ṣẹ. (Jẹ́n. 3:15) Bó ti wù kó rí, Jèhófà fòpin sí gbogbo ọ̀tẹ̀ yẹn nígbà tó mú Ìkún Omi wá, bí gbogbo ìsapá Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn ṣe já sófo nìyẹn.

Sátánì máa ń lo ìṣekúṣe, ìgbéraga àti ìbẹ́mìílò láti dẹkùn mú wa (Wo ìpínrọ̀ 12, 13)

12 Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn áńgẹ́lì yẹn? A ò gbọ́dọ̀ máa ronú pé a ò lè kó sínú páńpẹ́ ìṣekúṣe àti ìgbéraga. Bí àpẹẹrẹ, àwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ yẹn ti fi ọ̀pọ̀ ọdún sin Jèhófà lọ́run. Síbẹ̀, láìka àǹfààní ńlá tí wọ́n ní yìí, wọ́n jẹ́ kí èròkerò gbà wọ́n lọ́kàn débi tí wọ́n fi kẹ̀yìn sí Jèhófà. Bákan náà, àwa náà lè ti máa sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ tá ò bá ṣọ́ra, èròkerò lè gbà wá lọ́kàn. (1 Kọ́r. 10:12) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká máa yẹ ọkàn wa wò nígbà gbogbo, ká má ṣe fàyè gba èròkerò àti ìgbéraga!​—Gál. 5:26; ka Kólósè 3:5.

13. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì tún máa ń lò, kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kó sínú páńpẹ́ yìí?

13 Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ míì tí Sátánì fi ń mú àwọn èèyàn ni kéèyàn máa wá fìn-ín ìdí kókò nípa ẹgbẹ́ òkùnkùn. Lónìí, Sátánì ń lo ìsìn èké láti gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ, àmọ́ ó tún máa ń lo eré ìnàjú láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìbẹ́mìílò. Àwọn fíìmù, géèmù, ìwé ìròyìn àtàwọn eré orí ìtàgé máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú ìbẹ́mìílò. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kó sínú páńpẹ́ yìí? A ò lè retí pé kí ètò Ọlọ́run to orúkọ àwọn eré ìnàjú tó yẹ ká máa wò àtàwọn tí kò yẹ ká máa wò. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kó lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. (Héb. 5:14) Torí náà, tá a bá ń fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílò pé kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run “wà láìsí àgàbàgebè,” àá máa ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. (Róòmù 12:9) Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé kì í ṣe àwọn eré ìnàjú tí mò ń sọ pé káwọn míì má wò lèmi fúnra mi ń wò? Tí àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn míì bá rí àwọn eré ìnàjú tí mò ń wò, kí ni wọ́n máa rò nípa mi?’ Ká má gbàgbé pé, tí ìwà wa bá bá ohun tá à ń kọ́ àwọn èèyàn mu, a ò ní kó sínú páńpẹ́ Sátánì.​—1 Jòh. 3:18.

Sátánì lè mú kí ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn ọmọléèwé wa lè máa halẹ̀ mọ́ wa, a sì lè dojú kọ àtakò látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wa (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbà halẹ̀ mọ́ wa, kí la lè ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀?

14 Yàtọ̀ sí pé Sátánì máa ń lo àwọn ohun tó dà bí ìjẹ kó lè dẹkùn mú wa, ó tún máa ń halẹ̀ mọ́ wa ká lè fi Jèhófà sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú káwọn aláṣẹ dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró. Ó tún lè mú kí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé wa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé à ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. (1 Pét. 4:4) Bákan náà, ó lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí wa fúngun mọ́ wa ká má bàa lọ sípàdé mọ́. (Mát. 10:36) Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí la lè ṣe? Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé irú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ torí pé Sátánì ló ń bá wa jagun. (Ìṣí. 2:10; 12:17) Lẹ́yìn náà, ká máa rántí pé Sátánì ti fẹ̀sùn kàn wá pé ìgbà tí nǹkan bá dẹrùn fún wa nìkan la máa sin Jèhófà. Ó ní tí ìyà bá jẹ wá, a máa fi Jèhófà sílẹ̀. (Jóòbù 1:​9-11; 2:​4, 5) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí pé òun nìkan ló lè gbà wá lọ́wọ́ Sátánì, ó sì dájú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé!​—Héb. 13:5.

IBO NI AGBÁRA SÁTÁNÌ MỌ?

15. Ṣé Sátánì lè fipá mú ká ṣe ohun tá ò fẹ́? Ṣàlàyé.

15 Sátánì ò lè fipá mú ká ṣe ohun tí kò wù wá. (Ják. 1:14) Àmọ́ torí àìmọ̀kan, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe ohun tí Sátánì fẹ́ láìmọ̀. Tẹ́nì kan bá wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, òun fúnra rẹ̀ á pinnu bóyá ohun tí Sátánì fẹ́ lòun máa ṣe tàbí ohun tí Jèhófà fẹ́. (Ìṣe 3:17; 17:30) Tá a bá pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ la máa ṣe, kò sí ohun tí Sátánì lè ṣe táá mú ká yẹsẹ̀.​—Jóòbù 2:3; 27:5.

16, 17. (a) Àwọn nǹkan míì wo ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò lè ṣe? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù láti gbàdúrà sókè sí Jèhófà?

16 Àwọn nǹkan míì wà tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ pé wọ́n lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Jèhófà àti Jésù nìkan ni Bíbélì sọ pé wọ́n ní agbára yẹn. (1 Sám. 16:7; Máàkù 2:8) Àmọ́ ṣé ó yẹ ká bẹ̀rù pé tá a bá gbàdúrà sókè, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ máa gbọ́ wa, wọ́n á sì dènà àdúrà náà? Rárá o. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹ̀rù kì í bà wá láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà torí à ń ronú pé Èṣù lè rí wa. Bákan náà, kò yẹ ká bẹ̀rù láti gbàdúrà sókè torí à ń ronú pé Èṣù lè gbọ́ wa. Kódà, Bíbélì mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó gbàdúrà sókè, wọn ò sì bẹ̀rù pé Èṣù lè gbọ́ àwọn. (1 Ọba 8:​22, 23; Jòh. 11:​41, 42; Ìṣe 4:​23, 24) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ó dá wa lójú pé bí Èṣù tiẹ̀ pa wá lára, Jèhófà ò ní jẹ́ kó ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́.​—Ka Sáàmù 34:7.

17 Ó yẹ ká mọ ọ̀tá wa, àmọ́ kò sídìí tó fi yẹ ká bẹ̀rù rẹ̀. Lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, àwa èèyàn aláìpé lè ṣẹ́gun Sátánì. (1 Jòh. 2:14) Tá a bá kọjú ìjà sí Èṣù, ó dájú pé ó máa sá kúrò lọ́dọ̀ wa. (Ják. 4:7; 1 Pét. 5:9) Àmọ́ Sátánì máa ń dìídì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀dọ́. Torí náà, kí làwọn ọ̀dọ́ lè ṣe kí wọ́n lè dúró gbọin-in lójú àtakò Èṣù? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn ìbéèrè yìí.

^ ìpínrọ̀ 2 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì kan ní orúkọ. (Oníd. 13:18; Dán. 8:16; Lúùkù 1:19; Ìṣí. 12:7) Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀ ni Jèhófà fún lórúkọ (Sm. 147:4), ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé gbogbo àwọn áńgẹ́lì ló ní orúkọ, tó fi mọ́ áńgẹ́lì tó sọ ara rẹ̀ di Sátánì.

^ ìpínrọ̀ 3 Ìgbà méjìdínlógún [18] péré ni orúkọ náà Sátánì fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, àmọ́ ó lé ní ìgbà ọgbọ̀n [30] tó fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.