Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojúure Ta Lò Ń Wá?

Ojúure Ta Lò Ń Wá?

“Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”​—HÉB. 6:10.

ORIN: 39, 30

1. Kí ló sábà máa ń wù wá, kí ló sì ní nínú?

BÁWO ló ṣe máa rí lára rẹ tí ẹnì kan tó o mọ̀, tó o sì bọ̀wọ̀ fún bá gbàgbé orúkọ ẹ tàbí tí kò dá ẹ mọ̀? Kó sẹ́ni tírú ẹ̀ máa ṣe tí kò ní dùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé a máa ń fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá, kí wọ́n sì kà wá sí, ó ṣe tán àpọ́nlé lara ń fẹ́. Àmọ́ kì í ṣe irú àpọ́nlé bẹ́ẹ̀ nìkan la máa ń wá, a tún máa ń fẹ́ káwọn èèyàn mọ bá a ṣe jẹ́ kí wọ́n sì yẹ́ wa sí torí ohun tá a ti gbé ṣe.​—Núm. 11:16; Jóòbù 31:6.

2, 3. Tá ò bá ṣọ́ra, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa bá a ṣe ń fẹ́ káwọn èèyàn gba tiwa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

2 Ṣùgbọ́n tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàṣejù torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn mọyì wa. Ìyẹn lè mú ká máa ṣe ohun tí kò tọ́ torí a fẹ́ kí wọ́n gba tiwa. Ẹ̀mí burúkú táyé Sátánì ń gbé lárugẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í ràn wá, débi pé àwa náà lè fẹ́ lókìkí, ká sì lẹ́nu láwùjọ. Tọ́rọ̀ bá ti rí bẹ́ẹ̀, a ò ní lè fún Jèhófà Baba wa ọ̀run ní ìjọsìn tó yẹ ẹ́.​—Ìṣí. 4:11.

3 Nígbà ayé Jésù, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan máa ń fẹ́ káwọn èèyàn kà wọ́n sí. Jésù wá kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n ń fẹ́ láti máa rìn káàkiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì ń fẹ́ ìkíni ní àwọn ibi ọjà àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù àti àwọn ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi oúnjẹ alẹ́.” Ó fi kún un pé: “Àwọn wọ̀nyí yóò gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù.” (Lúùkù 20:​46, 47) Jésù yàtọ̀ sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ó gbóríyìn fún opó aláìní kan tó fi ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú àpótí owó, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kẹ́nì kankan má kíyè sí i. (Lúùkù 21:​1-4) Ó hàn gbangba pé ohun tó ń mú kí Jésù mọyì àwọn èèyàn yàtọ̀ sóhun tó ń mú káwọn míì ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ojúure ẹni tó yẹ ká máa wá, a sì máa rí irú àwọn tí Jèhófà máa ń fojúure hàn sí.

OJÚURE TA LÓ YẸ KÁ MÁA WÁ?

4. Ojúure ta ló yẹ ká máa wá, kí sì nìdí?

4 Ojúure ta ló yẹ ká máa wá? Káwọn kan lè rí ojúure èèyàn, wọ́n máa ń kàwé rẹpẹtẹ tàbí kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe rọ́wọ́ mú nídìí ìṣòwò tàbí lágbo àwọn òṣèré. Àmọ́ àwa kì í ṣe bẹ́ẹ̀, dípò ìyẹn, Pọ́ọ̀lù sọ ojúure ẹni tó yẹ ká máa wá, ó ní: “Nísinsìnyí tí ẹ ti wá mọ Ọlọ́run, tàbí kí a kúkú sọ pé nísinsìnyí tí ẹ ti wá di mímọ̀ fún Ọlọ́run, èé ti rí tí ẹ tún ń padà sẹ́yìn sí àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ aláìlera àti akúrẹtẹ̀, tí ẹ sì ń fẹ́ láti tún padà sìnrú fún wọn?” (Gál. 4:9) Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà nìyẹn o, pé Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run lè mọ̀ wá! Kódà, ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì wù ú pé ká jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tiẹ̀ sọ pé, “ó máa ń pàfiyèsí sí wa kó lè fojúure hàn sí wa.” Torí náà, tá a bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, ó dájú pé ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀.​—Oníw. 12:​13, 14.

5. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà tó lè mọ̀ wá?

5 Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó rí ojú rere Jèhófà ni Mósè. Nígbà kan, ó bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun túbọ̀ mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀, Jèhófà sì dá a lóhùn pé: “Ohun yìí tí ìwọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pẹ̀lú, ni èmi yóò ṣe, nítorí ìwọ ti rí ojú rere lójú mi, mo sì fi orúkọ mọ̀ ọ́.” (Ẹ́kís. 33:​12-17) Ó dájú pé Jèhófà lè mọ àwa náà, kó sì bù kún wa. Àmọ́, kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà tó lè mọ̀ wá? A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì ya ara wa sí mímọ́ fún un.​—Ka 1 Kọ́ríńtì 8:3.

6, 7. Kí ló lè ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́?

6 Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àwa àti Baba wa ọ̀run jẹ́. Bíi tàwọn Kristẹni tó wà ní Gálátíà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí, kò yẹ káwa náà pa dà sídìí “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ aláìlera àti akúrẹtẹ̀” tó wà nínú ayé yìí. (Gál. 4:9) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yìí ti tẹ̀ síwájú gan-an débi pé wọ́n ti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni yìí kan náà ti ń “padà sẹ́yìn” sí àwọn nǹkan tí kò ní láárí. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fún wọn pé: “Ládúrú ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ ti kọ́, kí ló dé tó jẹ́ pé àwọn nǹkan tí kò wúlò tẹ́ ẹ ti fi sílẹ̀ lẹ tún wá ń ṣe?”

7 Ṣé irú ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ sí wa lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè ṣẹlẹ̀. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó lè jẹ́ pé nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, a ti yááfì àwọn àǹfààní kan tó lè sọ wá di gbajúmọ̀ nínú ayé Sátánì. (Ka Fílípì 3:​7, 8.) Bí àpẹẹrẹ, a lè ti yááfì àtilọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tàbí kó jẹ́ pé a kọ ìgbéga kan lẹ́nu iṣẹ́. Ó sì lè jẹ́ pé a yááfì iṣẹ́ tó lè sọ wá dolówó rẹpẹtẹ. Àwọn míì nínú wa ì bá ti di olókìkí torí pé wọ́n lẹ́bùn orin kíkọ tàbí kí wọ́n gbóná nídìí eré ìdárayá, síbẹ̀ wọ́n yááfì àwọn àǹfààní yẹn. (Héb. 11:​24-27) Àṣìṣe ló máa jẹ́ tá a bá lọ ń kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó dáa tá a ṣe nígbà yẹn, tá à ń ronú pé ìgbésí ayé wa máa sàn ká sọ pé a ò yááfì àwọn nǹkan yẹn. Tá a bá ń ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè mú ká pa dà sídìí “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ aláìlera àti akúrẹtẹ̀” tó wà nínú ayé. *

MÁA WÁ OJÚURE JÈHÓFÀ

8. Kí la lè ṣe táá mú kó máa wù wá láti wá ojúure Jèhófà?

8 Kí la lè ṣe táá mú kó máa wù wá láti wá ojúure Jèhófà dípò tí ayé? Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi àwọn kókó pàtàkì méjì yìí sọ́kàn. Àkọ́kọ́, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fojúure hàn sáwọn tó bá ń sìn ín tọkàntọkàn. (Ka Hébérù 6:10; 11:6) Ó mọyì ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lójú rẹ̀, ìwà ‘àìṣòdodo’ ló máa jẹ́ tó bá pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tì. Kódà Bíbélì sọ pé Jèhófà “mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (2 Tím. 2:19) Ó “mọ ọ̀nà àwọn olódodo,” ó sì mọ bó ṣe máa dá wọn nídè nígbà àdánwò.​—Sm. 1:6; 2 Pét. 2:9.

9. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ń fojúure hàn sáwọn èèyàn rẹ̀.

9 Nígbà míì, Jèhófà máa ń fojúure hàn sáwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (2 Kíró. 20:​20, 29) Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bí Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè ní Òkun Pupa nígbà táwọn ọmọ ogun Fáráò ń lépa wọn. (Ẹ́kís. 14:​21-30; Sm. 106:​9-11) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ débi pé àwọn tó ń gbé lágbègbè yẹn ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà lẹ́yìn ogójì [40] ọdún. (Jóṣ. 2:​9-11) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ń jẹ́ ká rí i pé alágbára ni Jèhófà, ó sì nífẹ̀ẹ́, èyí ń jẹ́ kó dá wa lójú pé mìmì kan ò lè mì wá nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà kò wá. (Ìsík. 38:​8-12) Nígbà yẹn ọkàn wa máa balẹ̀ pé ojúure Jèhófà la wá kì í ṣe ti ayé.

10. Kí ni kókó kejì tó yẹ ká fi sọ́kàn?

10 Kókó kejì ni pé: Jèhófà lè fojúure hàn sí wa láwọn ọ̀nà tá ò lérò. Jésù sọ pé tẹ́nì kan bá ń ṣe ohun tó dáa torí káwọn èèyàn lè yẹ́ ẹ sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò lè rí èrè kankan gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ti gba èrè rẹ̀ ní kíkún báwọn èèyàn ṣe ń kan sáárá sí i. (Ka Mátíù 6:​1-5.) Jésù wá fi kún un pé Jèhófà “tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀” ń kíyè sí àwọn tó ń ṣe ohun tó dáa tí wọn ò sì wá káwọn èèyàn yẹ́ wọn sí, á sì san olúkúlùkù wọn lẹ́san. Nígbà míì sì rèé, Jèhófà lè fojúure hàn sí wa láwọn ọ̀nà tá ò lérò. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

JÈHÓFÀ FOJÚURE HÀN SÍ ỌMỌBÌNRIN KAN LỌ́NÀ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀

11. Báwo ni Jèhófà ṣe fojúure hàn sí Màríà?

11 Nígbà tó tó àkókò lójú Jèhófà láti rán ọmọ rẹ̀ wá sáyé, Jèhófà yan Màríà láti jẹ́ ìyá rẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀ ni Màríà, kò sì tíì ní ìbálòpọ̀ rí. Násárétì ló ń gbé, ìyẹn ìlú kan táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí, tó sì jìn sí Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀. (Ka Lúùkù 1:​26-33.) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Màríà ni Jèhófà fún láǹfààní yìí? Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé ó ti “rí ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Ẹni tẹ̀mí ni Màríà, èyí sì hàn nínú ọ̀rọ̀ tó bá Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ̀ sọ. (Lúùkù 1:​46-55) Èyí fi hàn pé Jèhófà kíyè sí Màríà pé olóòótọ́ ni, ìdí nìyẹn tó fi fún Màríà ní àǹfààní bàǹtà-banta tí ò lérò yìí.

12, 13. Báwo ni Jèhófà ṣe yẹ́ Jésù sí nígbà tí wọ́n bí i àti nígbà tí wọ́n gbé e lọ sí tẹ́ńpìlì lẹ́yìn ogójì ọjọ́?

12 Nígbà tí Màríà bí Jésù, Jèhófà ò jẹ́ káwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tàbí àwọn alákòóso tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn áńgẹ́lì fara han àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń bójú tó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní pápá nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Lúùkù 2:​8-14) Àwọn olùṣọ́ àgùntàn yìí ló sì wá kí ọmọ jòjòló náà. (Lúùkù 2:​15-17) Ó dájú pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà yẹ́ Jésù sí máa ya Màríà àti Jósẹ́fù lẹ́nu gan-an. Èyí sì yàtọ̀ pátápátá sí bí Èṣù ṣe ń ṣe nǹkan tiẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Sátánì rán àwọn awòràwọ̀ lọ síbi tí Jésù àtàwọn òbí rẹ̀ wà, gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ní ṣìbáṣìbo bá nígbà tí wọ́n gbọ́ pé a ti bí Jésù. (Mát. 2:3) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló sì ṣokùnfà ikú àìmọye àwọn ọmọ jòjòló lágbègbè náà.​—Mát. 2:16.

13 Lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí Màríà bí Jésù, ó pọndandan kó lọ rúbọ sí Jèhófà ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù bí Òfin ṣe sọ. Èyí gba pé kó rìnrìn-àjò nǹkan bí kìlómítà mẹ́sàn-án láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Lúùkù 2:​22-24) Bó ṣe ń lọ, ó ṣeé ṣe kó máa ronú bóyá àlùfáà tó wà níbẹ̀ máa ṣí àwọn nǹkan kan payá nípa ohun tí Jésù máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Lóòótọ́, wọ́n yẹ́ Jésù sí níbẹ̀, àmọ́ kì í ṣe bí Màríà ṣe lérò. Jèhófà lo ọkùnrin “olódodo àti onífọkànsìn” kan tó ń jẹ́ Síméónì àti wòlíì Ánà, ìyẹn opó tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] láti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọmọ náà ni Mèsáyà tàbí Kristi tá a ṣèlérí.​—Lúùkù 2:​25-38.

14. Àwọn ìbùkún wo ni Jèhófà fún Màríà?

14 Ṣé Jèhófà fojúure hàn sí Màríà fún bó ṣe tọ́jú Jésù títí tó fi dàgbà? Bẹ́ẹ̀ ni. Lára ohun tí Jèhófà ṣe ni pé ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Màríà àtohun tó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Òótọ́ ni pé Màríà ò lè rìnrìn-àjò pẹ̀lú Jésù ní ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ torí pé ó ṣeé ṣe kí ọkọ rẹ̀ ti kú kéyìí sì mú kó pọndandan fún un láti wà ní Násárétì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jésù ṣe ò ṣojú rẹ̀, síbẹ̀ ó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù kú. (Jòh. 19:26) Nígbà tó yá, Màríà náà wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù kí wọ́n tó gba ẹ̀mí mímọ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì. (Ìṣe 1:​13, 14) Ó ṣeé ṣe kóun náà gba ẹ̀mí mímọ́ lọ́jọ́ yẹn. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé òun náà láǹfààní láti wà pẹ̀lú Jésù lọ́run títí láé àti láéláé. Àbí ẹ ò rí i pé Jèhófà ò gbàgbé iṣẹ́ rere tí Màríà ṣe, ó sì san án lẹ́san!

JÈHÓFÀ FOJÚURE HÀN SÍ ỌMỌ RẸ̀

15. Báwo ni Jèhófà ṣe fojúure hàn sí Ọmọ rẹ̀ nígbà tó wà láyé?

15 Jésù ò wá káwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn alákòóso fojúure hàn sóun. Àmọ́ ó dájú pé inú rẹ̀ máa dùn gan-an nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run nígbà mẹ́ta, tó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tí Jésù ṣèrìbọmi nínú Odò Jọ́dánì. Jèhófà sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mát. 3:17) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jòhánù Oníbatisí nìkan ló wà níbẹ̀, tó sì gbọ́ ohùn Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, nǹkan bí ọdún kan kí Jésù tó kú, àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta gbọ́ tí Jèhófà sọ nípa Jésù pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.” (Mát. 17:5) Bákan náà, ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ikú Jésù, Jèhófà tún bá Ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.​—Jòh. 12:28.

Kí lo rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe fojúure hàn sí Ọmọ rẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 15 sí 17)

16, 17. Báwo ni Jèhófà ṣe fojúure hàn sí Jésù lọ́nà tí kò lérò?

16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé àwọn èèyànkéèyàn máa parọ́ mọ́ òun, wọ́n á pe òun ní asọ̀rọ̀ òdì, òun á sì kú ikú ẹ̀sín, síbẹ̀ ó gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ dípò tara rẹ̀. (Mát. 26:​39, 42) Bíbélì sọ pé Jésù ‘fara da òpó igi oró, ó sì tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú’ torí pé ó ń wá ojúure Jèhófà dípò tayé. (Héb. 12:2) Báwo wá ni Jèhófà ṣe fojúure hàn sí Jésù?

17 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún òun ní ògo tóun ní nígbà tóun wà pẹ̀lú rẹ̀ lọ́run. (Jòh. 17:5) Jésù ò wá pé kí Jèhófà fi òun sí ipò ńlá kan tàbí kó fún òun ní ìgbéga àrà ọ̀tọ̀ tóun bá pa dà sí ọ̀run. Àmọ́ kí ni Jèhófà ṣe? Ó fojúure hàn sí Jésù lọ́nà tí kò lérò. Jèhófà jí Jésù dìde, ó sì gbé e sí “ipò gíga” lọ́run. Ó tún fún Jésù lóhun tí kò tíì fún ẹ̀dá kankan rí ṣáájú ìgbà yẹn, ìyẹn àìleèkú! * (Fílí. 2:9; 1 Tím. 6:16) Ẹ ò rí i pé ọ̀nà àgbàyanu ni Jèhófà gbà san Jésù lẹ́san torí ìṣòtítọ́ rẹ̀!

18. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa wá ojúure àwọn èèyàn ayé yìí?

18 Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa wá ojúure àwọn èèyàn ayé yìí? Ẹ jẹ́ ká máa fi sọ́kàn pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fojúure hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, ó sì sábà máa ń san wọ́n lẹ́san láwọn ọ̀nà tí wọn ò lérò. Ta ló mọ ọ̀nà àrà tí Jèhófà máa gbà bù kún wá lọ́jọ́ iwájú? Ní báyìí ná, ìṣòro tàbí àdánwò yòówù ká máa kojú nínú ayé yìí, ẹ jẹ́ ká máa rántí nígbà gbogbo pé ayé yìí àti gbogbo ohun tó ń gbé lárugẹ máa tó kọjá lọ. (1 Jòh. 2:17) Kò sí báwọn èèyàn ṣe lè gbé wa gẹ̀gẹ̀ tó lónìí, gbogbo ẹ̀ á dìtàn lọ́la. Àmọ́, Jèhófà Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ‘kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tí a fi hàn fún orúkọ rẹ̀.’ (Héb. 6:10) Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa fojúure hàn sí wa, kódà ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tá ò lérò!

^ ìpínrọ̀ 7 Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tú ọ̀rọ̀ náà “akúrẹtẹ̀” sí “aláìní,” àwọn míì sì tú u sí “alágbe” tàbí ohun tí kò wúlò.

^ ìpínrọ̀ 17 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìbùkún àìròtẹ́lẹ̀ ni àìleèkú yìí máa jẹ́ fún Jésù torí pé kò síbì kankan tá a ti sọ̀rọ̀ nípa àìleèkú nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.