Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Máa Láyọ̀ Tá A Bá Jẹ́ Ọ̀làwọ́

A Máa Láyọ̀ Tá A Bá Jẹ́ Ọ̀làwọ́

“Ayọ̀ . . . wà nínú fífúnni.”​—ÌṢE 20:35.

ORIN: 76, 110

1. Báwo ni àwọn nǹkan tí Jèhófà dá ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀làwọ́ ni?

KÍ JÈHÓFÀ tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan, òun nìkan ló dá wà. Síbẹ̀ Jèhófà ò ro tara ẹ̀ nìkan lásìkò yìí, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fi ìwàláàyè jíǹkí àwọn ẹ̀dá tó wà lọ́run àti láyé. “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì ń fún gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ohun rere. (1 Tím. 1:11; Ják. 1:17) Jèhófà jẹ́ kó ṣe kedere pé táwa náà bá fẹ́ láyọ̀, àfi ká jẹ́ ọ̀làwọ́, ká sì máa fún àwọn míì ní nǹkan.​—Róòmù 1:20.

2, 3. (a) Kí nìdí tá a fi máa láyọ̀ tá a bá ń fúnni? (b) Kí la máa jíròrò?

2 Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́n. 1:27) Ìyẹn ni pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà tá a fi máa gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ yọ. Tá a bá fẹ́ láyọ̀ kí ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀, a gbọ́dọ̀ máa fara wé Jèhófà, ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ wá lọ́kàn, ká sì máa fúnni látọkàn wá. (Fílí. 2:3, 4; Ják. 1:5) Kí nìdí? Ìdí ni pé bí Jèhófà ṣe dá wa nìyẹn. Láìka àìpé wa sí, a lè fara wé Jèhófà, ká sì jẹ́ ọ̀làwọ́.

3 Bíbélì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jẹ́ ọ̀làwọ́. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí kókó yìí. A máa rí i pé tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́, àá rojú rere Jèhófà, àá sì tún rí bí ànímọ́ yìí ṣe lè jẹ́ ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún wa. A tún máa rí i pé tá a bá ń fúnni, a máa láyọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, a máa rí ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ jẹ́ ọ̀làwọ́.

BÁ A ṢE LÈ RÍ OJÚ RERE ỌLỌ́RUN

4, 5. Àpẹẹrẹ wo ni Jèhófà àti Jésù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká jẹ́ ọ̀làwọ́?

4 Jèhófà fẹ́ ká máa fara wé òun, inú rẹ̀ sì máa ń dùn tó bá rí i pé a jẹ́ ọ̀làwọ́. (Éfé. 5:1) Tá a bá wo bí Jèhófà ṣe dá wa àti gbogbo nǹkan rèǹtèrente tó ṣe fún ìgbádùn wa, ó hàn gbangba pé ó fẹ́ káwa èèyàn láyọ̀. (Sm. 104:24; 139:13-16) Torí náà, táwa náà bá ń sapá láti máa ṣe nǹkan táá mú káwọn míì láyọ̀, à ń bọlá fún Jèhófà nìyẹn.

5 Ó tún yẹ káwa Kristẹni tòótọ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi torí pé ó fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mát. 20:28) Pọ́ọ̀lù náà gba àwa Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú . . . Ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀.” (Fílí. 2:5, 7) Á dáa ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mo lè túbọ̀ fara wé Jésù ju bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ?’​—Ka 1 Pétérù 2:21.

6. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fi àpèjúwe ọkùnrin ará Samáríà kọ́ wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

6 A máa rí ojú rere Jèhófà tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tóun àti Jésù fi lélẹ̀ fún wa. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ wá lọ́kàn, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti bójú tó àìní wọn. Nígbà tí ọkùnrin kan tó jẹ́ Júù bi Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Jésù fi àpèjúwe kan nípa ọkùnrin ará Samáríà dá a lóhùn. Nínú àpèjúwe náà, Jésù jẹ́ kó ṣe kedere sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti ran àwọn míì lọ́wọ́ títí kan àwọn tí èdè tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwọn, kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn. (Ka Lúùkù 10:29-37.) Àpèjúwe yẹn jẹ́ ká rí i pé tá a bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà, a gbọ́dọ̀ múra tán láti ran àwọn míì lọ́wọ́ bíi ti ọkùnrin ará Samáríà náà.

7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣe nǹkan ló dáa jù? Ṣàlàyé.

7 Ó yẹ káwa Kristẹni sapá gan-an láti jẹ́ ọ̀làwọ́, ká má sì máa ro tara wa nìkan. Bí àpẹẹrẹ, ìmọtara-ẹni-nìkan ni Sátánì fi dẹkùn mú Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Sátánì sọ pé nǹkan máa sàn fún Ádámù àti Éfà àti gbogbo aráyé lápapọ̀ tá a bá ń ro tara wa nìkan, dípò ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ó wu Éfà náà láti dà bí Ọlọ́run torí pé tara ẹ̀ nìkan ló ń rò. Dípò kí Ádámù náà fi ti Ọlọ́run ṣáájú, ìmọtara-ẹni-nìkan mú kó máa wá bó ṣe máa tẹ́ Éfà lọ́rùn. (Jẹ́n. 3:4-6) Lónìí, gbogbo wa là ń fojú ara wa rí àbájáde burúkú tó tẹ̀yìn ìpinnu wọn yọ. Torí náà, ìmọtara-ẹni-nìkan kì í fúnni láyọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ìbànújẹ́ ló máa ń fà. Àmọ́ tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́, tá ò sì ro tara wa nìkan, ṣe là ń fi hàn pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣe nǹkan ló dáa jù.

ṢE IṢẸ́ TÍ ỌLỌ́RUN GBÉ FÁWỌN ÈÈYÀN RẸ̀

8. Kí nìdí tó fi yẹ kí Ádámù àti Éfà ro tàwọn míì mọ́ tiwọn?

8 Ká sọ pé Ádámù àti Éfà ronú nípa ìtọ́ni tí Jèhófà fún wọn ni, wọ́n á rí i pé Jèhófà fẹ́ káwọn máa ro tàwọn míì mọ́ tiwọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì nìkan ló wà nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà bù kún wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì ṣèkáwọ́ rẹ̀. (Jẹ́n. 1:28) Bí ire àwọn tí Jèhófà dá ṣe jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó yẹ kí ire àwọn ọmọ tí Ádámù àti Éfà máa bí lọ́jọ́ iwájú náà jẹ wọ́n lọ́kàn. Jèhófà fẹ́ kí wọ́n sọ gbogbo ayé di Párádísè fún àǹfààní àwọn ọmọ wọn. Iṣẹ́ ńlá nìyẹn, á sì gba pé kí Ádámù àti Éfà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ wọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kíyẹn lè ṣeé ṣe.

9. Báwo layọ̀ wọn ì bá ti pọ̀ tó ká ní wọ́n sọ ayé di Párádísè?

9 Àwọn ẹni pípé máa ní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jèhófà kí wọ́n tó lè sọ ayé di Párádísè kí wọ́n sì mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run. (Héb. 4:11) Ẹ fojú inú wo bí ayọ̀ wọn á ṣe pọ̀ tó lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó dájú pé wọ́n á gbádùn ẹ̀ dọ́ba! Ká sòótọ́, Jèhófà ò bá ti bù kún wọn gan-an ká sọ pé wọn lo ara wọn fún àǹfààní àwọn míì, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n láyọ̀.

10, 11. Kí ló máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

10 Lónìí, Jèhófà ti fún àwa èèyàn rẹ̀ níṣẹ́ pàtàkì kan. Ó ní ká máa wàásù, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn. Ká tó lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ire àwọn míì máa jẹ wá lọ́kàn. Ohun kan tí kò ní jẹ́ ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.

11 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù sọ pé òun àtàwọn míì tí wọ́n jọ ń wàásù jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” torí pé wọ́n ń fún irúgbìn èso Ìjọba náà, wọ́n sì ń bomi rin irúgbìn náà. (1 Kọ́r. 3:6, 9) Lónìí, táwa náà bá ń lo okun wa, àkókò wa àti gbogbo ohun tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà gbé fún wa, àwa náà á di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà nìyẹn jẹ́ o!

À ń láyọ̀ bá a ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

(Wo ìpínrọ̀ 12)

12, 13. Èrè wo la máa rí tá a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

12 Tá a bá ń lo àkókò àti okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, a máa láyọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó láwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, inú wa máa ń dùn tá a bá rí i pé àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń lóye òtítọ́, ìgbàgbọ́ wọn sì túbọ̀ ń lágbára. Bá a sì ṣe ń rí i tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà, tí wọ́n sì ń sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ fún àwọn míì máa mú ká túbọ̀ láyọ̀. Jésù náà láyọ̀ gan-an nígbà táwọn àádọ́rin [70] tó rán jáde “padà dé pẹ̀lú ìdùnnú” torí àṣeyọrí tí wọ́n ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà.​—Lúùkù 10:17-21.

13 Kárí ayé, inú àwọn akéde máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí i tí òtítọ́ ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Anna, ìyẹn arábìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ tó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ní Ìlà-Oòrùn Yúróòpù. * Ó sọ pé: “Inú mi dùn gan-an torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbí. Iṣẹ́ yìí sì ń fún mi láyọ̀ torí pé tí mo bá dé láti òde ẹ̀rí, dípò kí n máa ronú nípa àwọn ìṣòro tèmi, ọ̀rọ̀ àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń gbà mí lọ́kàn. Màá wá máa ronú nípa ohun tí mo lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Èyí ti jẹ́ kí n rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé, ‘ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.’ ”​—Ìṣe 20:35.

Tá ò bá fo ilé kankan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, à ń fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà

(Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí ló ń fún wa láyọ̀ táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ tẹ́tí sí ìwàásù wa?

14 A máa láyọ̀ tá a bá ń gbìyànjú láti bá gbogbo èèyàn sọ̀rọ̀ kódà táwọn kan ò bá fẹ́ gbọ́. Ó ṣe tán, ohun tí Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì ló fẹ́ káwa náà ṣe lónìí, ó sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: ‘Kí o sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́.’ (Ìsík. 2:7; Aísá. 43:10) Táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ mọyì ohun tá à ń ṣe, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà mọyì gbogbo ìsapá wa. (Ka Hébérù 6:10.) Arákùnrin kan fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé: “A ti gbìn, a sì ti bomi rin, àdúrà wa ni pé kí Jèhófà jẹ́ kó dàgbà.”​—1 Kọ́r. 3:6.

BÁ A ṢE LÈ LÁYỌ̀

15. Ṣé àwọn tó bá moore nìkan ló yẹ ká lawọ́ sí? Ṣàlàyé.

15 Jésù mọ̀ pé tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́, a máa láyọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń mọyì ohun tí ẹlòmíì bá ṣe fún wọn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín. Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín. Nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.” (Lúùkù 6:38) Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa mọyì ohun tá a bá ṣe fún wọn, síbẹ̀ àwọn míì máa ń moore, èyí sì lè mú káwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í lawọ́ sáwọn míì. Torí náà, táwọn kan ò bá tiẹ̀ moore, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan látọkàn wá. O ò lè sọ ohun tí oore kan tó o ṣe lónìí máa dà lọ́jọ́ iwájú.

16. Àwọn wo ló yẹ ká lawọ́ sí, kí sì nìdí?

16 Ohun kan ni pé àwọn tó bá lawọ́ kì í fúnni torí ohun tí wọ́n máa rí gbà pa dà. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá se àsè, ké sí àwọn òtòṣì, amúkùn-ún, arọ, afọ́jú; ìwọ yóò sì láyọ̀, nítorí tí wọn kò ní nǹkan kan láti fi san án padà fún ọ.” (Lúùkù 14:13, 14) Òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olójú àánú [tàbí ọ̀làwọ́] ni a ó bù kún.” Òmíràn sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀.” (Òwe 22:9; Sm. 41:1) Ó dájú pé, a máa láyọ̀ tá a bá ń fún àwọn míì ní nǹkan.

17. Tá a bá fẹ́ láyọ̀, àwọn nǹkan wo la lè fún àwọn míì?

17 Kì í ṣe àwọn nǹkan tara nìkan ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó fa ọ̀rọ̀ Jésù yọ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” Àwọn nǹkan míì tún wà tá a lè fún àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a lè fún àwọn míì ní ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ìṣe 20:31-35) Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí kókó yìí. Ohun tó sọ àti ohun tó ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa lo àkókò wa àti okun wa fáwọn míì, ká máa fìfẹ́ hàn sí wọn, ká sì máa tẹ́tí gbọ́ wọn.

18. Kí làwọn olùṣèwádìí kan sọ nípa fífúnni?

18 Àwọn kan tó máa ń ṣèwádìí nípa ìwà ẹ̀dá sọ pé àwọn tó bá ń fúnni máa láyọ̀. Àpilẹ̀kọ kan sọ pé àwọn èèyàn máa ń láyọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ohun tó dáa fún àwọn míì. Kódà, àwọn olùṣèwádìí sọ pé téèyàn bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́, ìgbésí ayé rẹ̀ á nítumọ̀. Ìdí nìyẹn táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan fi sọ pé ó dáa kéèyàn máa yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìlú. Wọ́n sọ pé téèyàn bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á láyọ̀, ìlera ẹ̀ á sì túbọ̀ dáa sí i. Ohun tí wọ́n sọ yìí ò yà wá lẹ́nu torí pé ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ti sọ nínú Bíbélì pé fífúnni máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀.​—2 Tím. 3:16, 17.

MÁA LAWỌ́ SÍ ÀWỌN MÍÌ

19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ ọ̀làwọ́?

19 Kò rọrùn láti jẹ́ ọ̀làwọ́ nínú ayé yìí torí pé àwọn onímọtara-ẹni-nìkan ló yí wa ká, èyí sì lè mú kí ṣíṣe oore súni nígbà míì. Àmọ́ Jésù sọ pé àṣẹ méjì tó tóbi jù ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, èrò wa àti okun wa àti pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. (Máàkù 12:28-31) Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà, Jésù náà sì lawọ́. Àwọn méjèèjì jẹ́ ká mọ̀ pé táwa náà bá jẹ́ ọ̀làwọ́, a máa ní ayọ̀ tòótọ́. Tá a bá ń fi tọkàntọkàn fún Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa láwọn nǹkan tá a ní, ṣe là ń mú ìyìn wá fún Jèhófà, a sì máa ṣe ara wa àtàwọn míì láǹfààní.

20 Kò sí àní-àní pé ìwọ náà ń sapá láti lo ara rẹ fáwọn míì, ní pàtàkì àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. (Gál. 6:10) Tó o bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀ torí pé àwọn èèyàn máa mọyì rẹ, wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ rẹ. Òwe 11:25 sọ pé: “A óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra, ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.” Nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a máa láyọ̀ tá a bá ń fi inúure hàn sáwọn míì, tá à ń lo ara wa fún wọn, tá a sì jẹ́ ọ̀làwọ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 13 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.