Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Jèhófà Bù Kún Ìpinnu Tí Mo Ṣe

Jèhófà Bù Kún Ìpinnu Tí Mo Ṣe

Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1939, a lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Joplin tó wà ní apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Missouri, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ilẹ̀ ò tíì fi bẹ́ẹ̀ mọ́ nígbà tá a lọ ki àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú bọ ẹnu ọ̀nà àwọn èèyàn, ìgbà tílẹ̀ sì fi máa mọ́, a ti ṣe tán. Ìdájí la ti jí kúrò nílé, ó sì lé ní wákàtí kan tá a fi wakọ̀. Lẹ́yìn tá a ṣe tán, a rọra pa dà sínú ọkọ̀, a sì wakọ̀ lọ síbi tá a ti máa ń pàdé ká lè dúró de àwọn ará wa tó kù. Ẹ lè máa wò ó pé kí nìdí tá a fi jí kúrò nílé ní ìdájí, tá a sì tún tètè pa dà sílé. Màá sọ fún yín tó bá yá.

INÚ mi dùn pé Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn làwọn òbí mi. Fred àti Edna Molohan lorúkọ wọn, àtikékeré sì ni wọ́n ti gbin ìbẹ̀rù Ọlọ́run sí mi lọ́kàn. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n (bá a ṣe máa ń pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn), wọ́n sì nítara gan-an. Nígbà tí wọ́n fi máa bí mi lọ́dún 1934, wọ́n ti lo ogún (20) ọdún nínú ètò Ọlọ́run. Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Parsons, tó wà ní apá gúúsù ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Kansas là ń gbé, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ará ìjọ wa ni ẹni àmì òróró. Ìdílé wa máa ń gbádùn bá a ṣe ń lọ sí ìpàdé déédéé àti bá a ṣe ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Gbogbo ọ̀sán Sátidé la sábà máa ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà, bá a ṣe máa ń pe iṣẹ́ ìwàásù níbi térò pọ̀ sí nígbà yẹn. Kí n sòótọ́, ó máa ń rẹ̀ wá àmọ́ Dádì máa ń ra áásìkiriìmù fún wa lẹ́yìn tá a bá parí iṣẹ́.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn akéde ìjọ wa ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tóbi gan-an, bá a ṣe ní àwọn ìlú kéékèèké, bẹ́ẹ̀ náà la ní ọ̀pọ̀ abúlé tó wà nítòsí. Tá a bá lọ wàásù fáwọn àgbẹ̀ lóko tá a sì fún wọn láwọn ìtẹ̀jáde wa, dípò kí wọ́n san owó, wọ́n sábà máa ń fún wa ní ewébẹ̀, ẹyin tí adìyẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ yé kódà wọ́n máa ń fún wa ní odindi adìyẹ nígbà míì. Níwọ̀n bí Dádì ti sanwó fáwọn ìtẹ̀jáde náà tẹ́lẹ̀, ńṣe làwọn oúnjẹ yìí máa ń bọ́ sákòókò gẹ́ẹ́.

IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ ÀKÀNṢE

Àwọn òbí mi ní ẹ̀rọ giramafóònù kan tí wọ́n fi ń wàásù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré láti lo ẹ̀rọ yẹn nígbà tá à ń wí yìí, síbẹ̀ inú mi máa ń dùn láti ran Dádì àti Mọ́mì lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń gbé àwọn ìwàásù Arákùnrin Rutherford sáfẹ́fẹ́ nígbà ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Èmi, Dádì àti Mọ́mì níwájú mọ́tò tá a fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́

Dádì sọ mọ́tò Ford 1936 tá à ń lò di ọkọ̀ tó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ torí náà, wọ́n so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ńlá kan mọ́ orí rẹ̀. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni mọ́tò yìí ṣe torí òun la fi ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nígbà yẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń kọ́kọ́ gbé orin sáfẹ́fẹ́ káwọn èèyàn lè tẹ́tí sí wa, lẹ́yìn náà la máa gbé àwọn ìwàásù tó dá lórí Bíbélì sáfẹ́fẹ́. Tó bá parí, a máa fún àwọn tó bá fẹ́ láwọn ìtẹ̀jáde wa.

Ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Cherryvale ní ìpínlẹ̀ Kansas, àwọn ọlọ́pàá sọ fún Dádì pé kí wọ́n má ṣe gbé mọ́tò tá a fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ sí ọgbà kan tí ọ̀pọ̀ ti ń sinmi láwọn ọjọ́ Sunday, àmọ́ wọ́n lè gbé e síta. Dádì ò jiyàn, ṣe ni wọ́n gbé mọ́tò wọn sí òdìkejì kí àwọn tó wà nínú ọgbà yẹn lè máa gbọ́ ìwàásù. Inú mi máa ń dùn bí mo ṣe ń wà pẹ̀lú Dádì àti ẹ̀gbọ́n mi tó ń jẹ́ Jerry láwọn àkókò yìí.

Nígbà kan láàárín ọdún 1936 sí 1939, a ṣètò àkànṣe ìwàásù kan táá jẹ́ ká tètè kárí àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn èèyàn ti máa ń ta kò wá. Kí ilẹ̀ tó mọ́ la ti máa lọ (bá a ṣe ṣe ní Joplin, ìpínlẹ̀ Missouri), a sì máa rọra ki àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí àwọn ìwé pẹlẹbẹ sẹ́nu ọ̀nà àwọn èèyàn. Tá a bá parí iṣẹ́, a máa pàdé ní ibì kan lẹ́yìn ìlú náà ká lè mọ̀ bóyá ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ àwọn kan lára wa.

Ọ̀nà míì tá à ń gbà wàásù ni pé, a máa ń gbé ìsọfúnni kiri ìgboro. A máa ń gbé àwọn àkọlé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kọ́ ọrùn, a sì máa ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bá a ṣe ń yan kiri àárín ìlú. Mo rántí pé ọjọ́ kan tí àwọn ará ń wàásù ní ìlú wa, wọ́n gbé àkọlé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan sọ́rùn tó ní àkọlé náà, “Ìsìn Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó.” Wọ́n rin nǹkan bíi máìlì kan (1.6 km) kí wọ́n tó pa dà sílé wa. A dúpẹ́ pé kò sẹ́ni tó ta kò wọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn tó pàdé wọn ló nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n kà lára àkọlé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ náà.

ÀWỌN ÀPÉJỌ ÀGBÈGBÈ TÁ A ṢE NÍGBÀ TÍ MO WÀ NÍ KÉKERÉ

Ìdílé wa sábà máa ń rin ìrìn àjò láti Kansas lọ sí àpéjọ àgbègbè ní ìpínlẹ̀ Texas. Ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n ń pè ní Missouri-Kansas-Texas Railroad ni Dádì ń bá ṣiṣẹ́, torí náà a kì í sanwó tá a bá fẹ́ wọ ọkọ̀ ojú irin. Èyí máa ń mú ká lè lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí wa, ká sì jọ lọ sí àpéjọ àgbègbè. Ìlú Temple, ìpínlẹ̀ Texas ni ẹ̀gbọ́n Mọ́mì tó ń jẹ́ Fred Wismar àti ìyàwó rẹ̀, Eulalie ń gbé. Kò pẹ́ lẹ́yìn ọdún 1900 ni Fred kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó sì ṣèrìbọmi. Ọ̀dọ́ ni nígbà yẹn, ó sì sọ àwọn ohun tó ń kọ́ fáwọn àbúrò rẹ̀ títí kan màmá mi. Ṣàṣà ni àwọn ará tí kò mọ̀ ọ́n ní gbogbo àgbègbè Texas torí pé òun ni ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀ àgbègbè nígbà yẹn, (tá a mọ̀ sí alábòójútó àyíká báyìí). Onínúure ni, ó ṣeé sún mọ́, gbogbo ìgbà sì ni inú rẹ̀ máa ń dùn. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń fìtara wàásù, àpẹẹrẹ rẹ̀ sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́.

Lọ́dún 1941, ìdílé wa wọkọ̀ ojú irin lọ sí ìlú St. Louis, ní ìpínlẹ̀ Missouri lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fún àpéjọ ńlá kan. Wọ́n ní kí gbogbo àwa ọmọdé jókòó sí apá ibì kan tí wọ́n dìídì ṣètò fún wa ká lè gbọ́ àsọyé Arákùnrin Rutherford. Àkòrí àsọyé náà ni “Àwọn Ọmọ Ọba Náà.” Níparí àsọyé yẹn, ó yà wá lẹ́nu nígbà tí Arákùnrin Rutherford àtàwọn tó ràn án lọ́wọ́ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní ìwé tuntun náà, Children. Àwa ọmọdé tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ló gba ìwé náà.

Ní April 1943, a lọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Jára Mọ́ṣẹ́,” àpéjọ yẹn wúni lórí gan-an, Coffeyville ní ìpínlẹ̀ Kansas la sì ti ṣe é. Wọ́n dá ilé ẹ̀kọ́ kan tí àá máa ṣe ní gbogbo ìjọ sílẹ̀, ìyẹn Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì tún mú ìwé kékeré tó ní ẹ̀kọ́ méjìléláàádọ́ta (52) tá a máa lò nílé ẹ̀kọ́ náà jáde. Ọdún yẹn náà ni mo kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́ yìí. Ohun míì tó tún mú kí àpéjọ yẹn jẹ́ mánigbàgbé fún mi ni pé, àpéjọ yẹn ni mo ti ṣèrìbọmi pẹ̀lú àwọn méjì míì nínú adágún omi tó wà nínú oko kan nítòsí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé omi yẹn tutù gan-an.

MO FẸ́ SÌN NÍ BẸ́TẸ́LÌ

Ọdún 1951 ni mo parí ilé ẹ̀kọ́ girama, mo sì ní láti ṣe ìpinnu nípa ohun tí màá fí ayé mi ṣe. Jerry ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì nígbà kan, torí náà ó wu èmi náà gan-an láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ni mo bá gba fọ́ọ̀mù, mo sì fi ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì wa ní Brooklyn. Ìgbà tó yá, wọ́n ní kí n máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní March 10, 1952. Ìpinnu tí mo ṣe yìí ló jẹ́ kí n túbọ̀ di ẹni tẹ̀mí.

Ó ti pẹ́ tó ti ń wù mí láti ṣiṣẹ́ ní ibi tí wọ́n ti ń tẹ̀wé kí n lè wà lára àwọn tó ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn wa. Àmọ́, ilé ìjẹun ni wọ́n yàn mí sí, nígbà tó sì yá wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ nílé ìdáná, kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn iṣẹ́ mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń tẹ̀wé títí di báyìí. Síbẹ̀ tí mi ò bá sí níbi iṣẹ́ lọ́sàn-án, mo gbádùn kí n máa kàwé ní yàrá ìkàwé tó wà ní Bẹ́tẹ́lì. Ohun tí mò ń ṣe yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an torí ó ti jẹ́ kí n túbọ̀ di ẹni tẹ̀mí kí ìgbàgbọ́ mi sì lágbára. Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún jẹ́ kí n pinnu pé bíná ń jó bíjì ń jà, mi ò ní fi iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀. Ọdún 1949 ni Jerry kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, ó sì fẹ́ Patricia, àmọ́ ibi tí wọ́n ń gbé kò fi bẹ́ẹ̀ jìn sí Brooklyn. Àwọn méjèèjì ràn mí lọ́wọ́, wọ́n sì fún mi níṣìírí gan-an nígbà tí mo kọ́kọ́ dé Bẹ́tẹ́lì.

Kò pẹ́ tí mo dé Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn arákùnrin tó tóótun tí Bẹ́tẹ́lì á máa rán lọ sọ àsọyé láwọn ìjọ míì. Wọ́n máa ń rán àwọn arákùnrin yìí lọ sáwọn ìjọ tó wà ní ọgọ́rùn-ún méjì máìlì (322 kìlómítà) sí ọ́fíìsì Brooklyn láti sọ àsọyé kí wọ́n sì bá ìjọ náà lọ sóde ẹ̀rí. Mo láǹfààní láti wà lára àwọn tí wọ́n yàn. Àyà mi já nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, tó sì tún jẹ́ pé wákàtí kan la fi ń sọ àsọyé nígbà yẹn. Ọkọ̀ ojú irin ni mo sábà máa ń wọ̀ lọ sáwọn ìjọ tí wọ́n rán mi lọ. Mo rántí pé ní ọ̀sán ọjọ́ kan lásìkò òtútù lọ́dún 1954, mo wọ ọkọ̀ ojú irin kan tó yẹ kó gbé mi dé New York ní ìrọ̀lẹ́ Sunday. Ṣùgbọ́n, ìjì kan jà, yìnyín sì ń jábọ́, òtútù yẹn le débi pé ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà dákú, kò sì ṣiṣẹ́ mọ́. Nǹkan bí aago márùn-ún àárọ̀ ọjọ́ kejì, ìyẹn lọ́jọ́ Monday la tó dé New York City. Nígbà tí mo bọ́ sílẹ̀, mo wọ ọkọ̀ ojú irin míì lọ sí Brooklyn, mo sì gba ilé ìdáná lọ. Ó pẹ́ mi díẹ̀, ó sì ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu torí mi ò sùn rárá tílẹ̀ fi mọ́, àmọ́ láìka gbogbo ohun tójú mi rí láwọn àkókò yìí, inú mi dùn pé mo lè lọ ran àwọn ará lọ́wọ́, ìyẹn sì ń jẹ́ kí n láwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Àsìkò mánigbàgbé ni wọ́n máa ń jẹ́ fún mi.

À ń múra láti gbóhùn sáfẹ́fẹ́ ní ilé iṣẹ́ rédíò WBBR

Lẹ́yìn tí mo lo ọdún díẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n ní kí n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ ní ilé iṣẹ́ rédíò WBBR. Àjà kejì ní 124 Columbia Heights ló wà. Mo wà lára àwọn tó máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń gbé sáfẹ́fẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Arákùnrin A. H. Macmillan, tó ti sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún ní Bẹ́tẹ́lì náà wà lára àwa tá a jọ máa ń ṣe ètò yìí. A sábà máa ń pè wọ́n ní Arákùnrin Mac torí pé tàgbà tèwe ló fẹ́ràn wọn. Àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún àwa ọ̀dọ́ tá a wà ní Bẹ́tẹ́lì torí ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ti fara dà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

A máa ń fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé pélébé yìí kí wọ́n lè máa tẹ́tí gbọ́ ètò wa lórí rédíò WBBR

Nígbà tó di ọdún 1958, wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Èmi ni mo máa ń bá àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege gba ìwé ìgbélùú, màá sì tún ṣètò bí wọ́n ṣe máa dé orílẹ̀-èdè tí wọ́n rán wọn lọ. Nígbà yẹn, owó gọbọi ni wọ́n fi ń wọkọ̀ òfuurufú, torí náà díẹ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ló máa ń wọkọ̀ òfuurufú. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí Áfíríkà àti Éṣíà ló máa ń wọ ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń kẹ́rù. Nígbà tó yá, owó ọkọ̀ òfuurufú ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, torí náà èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló bẹ̀rẹ̀ sí í wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ síbi tí wọ́n bá rán wọn lọ.

Mò ń ṣètò ìwé ẹ̀rí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣáájú ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege

ÀWỌN ÀPÉJỌ TÁ A LỌ KÁRÍ AYÉ

Lọ́dún 1960, iṣẹ́ mi tún pọ̀ sí i nígbà tí wọ́n ní kí n háyà àwọn ọkọ̀ òfuurufú tó máa gbé wa láti Amẹ́ríkà lọ sí Yúróòpù fún àwọn àpéjọ àgbáyé tá a fẹ́ ṣe lọ́dún 1961. Èmi náà bá ọkọ̀ òfuurufú kan lọ, a gbéra láti ìlú New York, ó di ìlú Hamburg lórílẹ̀-èdè Jámánì. Lẹ́yìn tá a parí àpéjọ yẹn, èmi àtàwọn arákùnrin mẹ́ta míì láti Bẹ́tẹ́lì yá mọ́tò kan, a sì lọ sí orílẹ̀-èdè Ítálì ká lè ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní ìlú Róòmù. Àtibẹ̀ la ti lọ sí ilẹ̀ Faransé àtàwọn òkè Pyrenees Mountains. Ìgbà tá a kúrò níbẹ̀, a kọjá sí orílẹ̀-èdè Sípéènì níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. A kó àwọn ìtẹ̀jáde kan fáwọn ará nílùú Barcelona, ṣe la dì í bí ẹni pé ẹ̀bùn la gbé lọ fún wọn, inú wa sì dùn gan-an nígbà tá a rí wọn! Àtibẹ̀ la ti wakọ̀ lọ sí ìlú Amsterdam, a sì wọ ọkọ̀ òfuurufú pa dà sí New York.

Lọ́dún 1962, ètò Ọlọ́run tún ní kí n ṣètò bí àwọn tó máa lọ sí àwọn àkànṣe àpéjọ àgbáyé tá a máa ṣe kárí ayé ṣe máa lọ sí Àpéjọ Àgbáyé “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun” ti ọdún 1963. Ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́tàlélọ́gọ́rin (583) èèyàn ló máa lọ sí àpéjọ yìí ní Yúróòpù, Éṣíà àti Gúúsù Pàsífíìkì, wọ́n á sì parí ìrìn àjò náà sí ìlú Honolulu ní Hawaii àti Pasadena ní California. Wọ́n á tún ṣèbẹ̀wò sí Lẹ́bánónì àti Jọ́dánì kí wọ́n lè rí àwọn ìlú tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ẹ̀ka tí mo wà ní Bẹ́tẹ́lì ló ṣètò àwọn ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n wọ̀, àwọn òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n dé sí àtàwọn ìwé ìgbélùú tí wọ́n nílò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ.

MO NÍ ALÁBÀÁṢIṢẸ́PỌ̀ TUNTUN

Mánigbàgbé lọdún 1963 jẹ́ fún mi. June 29 ọdún yẹn ni mo fẹ́ Lila Rogers tó wá láti Missouri lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àtọdún 1960 ló ti ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, èmi àti ìyàwó mi lọ sáwọn àpéjọ àgbáyé tá a ṣe ní Gíríìsì, Íjíbítì àti Lẹ́bánónì. Láti Beirut, a wọkọ̀ òfuurufú lọ sí Jọ́dánì. Wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa ní Jọ́dánì nígbà yẹn, wọ́n sì ti sọ fún wa pé àwọn aláṣẹ kì í fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níwèé ìgbélùú, torí náà a ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tá a bá débẹ̀. Àmọ́, nígbà tá a dé pápákọ̀ òfuurufú, a rí ọ̀pọ̀ àwọn ará tí wọ́n gbé àkọlé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan dání, ohun tí wọ́n kọ sí i ni pé “Ẹ Káàbọ̀, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà”! Ó yà wá lẹ́nu, kódà téèyàn bá gẹṣin nínú wa kò lè kọsẹ̀ láé! Ẹ ò lè mọ bínú wa ṣe dùn tó nígbà tá a fojú ara wa rí àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì dárúkọ! A dé ibi tí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù gbé, àwọn ilẹ̀ tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ti wàásù àti ibi tí ẹ̀sìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ kó tó tàn dé apá ibi gbogbo láyé.​—Ìṣe 13:47.

Ọdún karùndínlọ́gọ́ta (55) rèé témi àti Lila ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, aya rere ni lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Pọ́túgà láwọn àsìkò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Àá fún àwọn ará wa níṣìírí, àá sì kó àwọn ìtẹ̀jáde àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò fún wọn. A tún ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n nílùú Cádiz ní Sípéènì. Inú mi dùn gan-an pé mo láǹfààní láti sọ àsọyé tó gbé wọn ró nípa tẹ̀mí.

Èmi àti ìyàwó mi pẹ̀lú Jerry Molohan àti ìyàwó rẹ̀, Patricia nígbà tá à ń lọ sí Àpéjọ “Àlááfíà Lórí Ilẹ̀-ayé” lọ́dún 1969

Láti ọdún 1963 ni mo ti ń ṣètò bí àwọn ará láti Bẹ́tẹ́lì ṣe máa lọ sáwọn àpéjọ àgbáyé tá à ń ṣe ní Áfíríkà, Ọsirélíà, Amẹ́ríkà Àárín, Amẹ́ríkà ti Gúúsù, Yúróòpù, Ìlà Oòrùn Éṣíà, Hawaii, New Zealand àti Puerto Rico. Ọ̀pọ̀ àpéjọ lèmi àti Lila jọ lọ, a ò sì lè gbàgbé wọn láé! Ọ̀kan lára irú àwọn àpéjọ bẹ́ẹ̀ ni èyí tá a ṣe nílùú Warsaw, ní Poland lọ́dún 1989. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ní Rọ́ṣíà ló jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa lọ sí àpéjọ nìyẹn. A pàdé ọ̀pọ̀ àwọn ará tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́wọ̀n nígbà ìjọba Soviet Union nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì tí mi ò lè gbàgbé ni bí mo ṣe máa ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kárí ayé àti bí mo ṣe máa ń gbé àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míṣọ́nnárì ró nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ìbẹ̀wò tá a ṣe kẹ́yìn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní South Korea, a dé ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní ìpínlẹ̀ Suwon, a sì bá àádọ́ta (50) lára àwọn arákùnrin wa tó wà lẹ́wọ̀n sọ̀rọ̀. Àwọn arákùnrin wa yìí ò sọ̀rètí nù, wọ́n ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí wọ́n á máa sin Jèhófà láìsí ìdíwọ́ kankan. Ìṣírí gbáà ni wọ́n jẹ́ fún wa!​—Róòmù 1:​11, 12.

ÌBÍSÍ TÓ Ń MÁYỌ̀ WÁ

Mo ti rí bí Jèhófà ṣe bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ láti àwọn ọdún yìí wá. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000) akéde ni gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1943. Àmọ́ ní báyìí, a ti ju mílíọ̀nù mẹ́jọ lọ, a sì ń wàásù ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ogójì (240) lọ. Iṣẹ́ àṣekára táwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì ṣe ló mú ọ̀pọ̀ ìbísí yìí wá. Inú mi dùn gan-an pé mo ti bá ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì yìí ṣiṣẹ́, mo sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sìn!

Mo láyọ̀ pé mo pinnu láti fayé mi sin Jèhófà nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, ìdí sì nìyẹn tí mo fi gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì. Kò sígbà tí mi kì í rí ọwọ́ Jèhófà láyé mi. Yàtọ̀ sí àwọn ìbùkún tí mò ń gbádùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, ọ̀pọ̀ ọdún ni èmi àti Lila ti ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú onírúurú ìjọ ní Brooklyn, àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tá a sì ní ò lóńkà.

Èmi àti Lila ìyàwó mi ṣì ń báṣẹ́ ìsìn wa lọ ní Bẹ́tẹ́lì, a sì ń gbádùn iṣẹ́ náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti lé lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84). Ní báyìí, ẹ̀ka tó ń gba lẹ́tà tó sì ń bójú tó o ni mo ti ń ṣiṣẹ́.

Èmi àti Lila rèé lónìí

Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ pé a wà nínú ètò tí Jèhófà ń darí, èyí ti jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ láàárín àwọn tó ń sin Jèhófà àtàwọn tí kò sìn ín. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Málákì 3:18 wá túbọ̀ ṣe kedere pé: “Dájúdájú, ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ṣe ni nǹkan túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé Sátánì, ọ̀pọ̀ èèyàn ò sì nírètí débi pé wọ́n á láyọ̀. Àmọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ń láyọ̀, wọ́n sì nírètí bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé tí nǹkan ti nira ni wọ́n ń gbé. A mà dúpẹ́ o pé a wà lára àwọn tó ń polongo ìhìn rere Ìjọba náà! (Mát. 24:14) A mọ̀ pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ayé búburú yìí, àá sì gbádùn àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí. Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo èèyàn máa ní ìlera pípé, àá sì wà láàyè títí láé. Ó dájú pé ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ náà máa jẹ́!