Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn Láìka Ìyípadà Èyíkéyìí Sí

Bó O Ṣe Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn Láìka Ìyípadà Èyíkéyìí Sí

“Mo ti tu ọkàn mi lára pẹ̀sẹ̀, mo sì ti mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́.”​—SM. 131:2.

ORIN: 128, 129

1, 2. (a) Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí nǹkan bá ṣàdédé yí pa dà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Bí Sáàmù 131 ṣe sọ, kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀?

LLOYD àti Alexandra ti lo ohun tó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ìyípadà tó ń wáyé máa gba pé kí wọ́n fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀, inú wọn bà jẹ́ gan-an. Lloyd sọ pé: “Mo gbádùn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì gan-an, kódà ó ń ṣe mí bíi pé kò sí nǹkan míì tí mo lè ṣe àfi iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì nìkan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ ìdí tí ètò Ọlọ́run fi ṣe ìyípadà yìí, síbẹ̀ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan. Kò rọrùn fún wa rárá. Nígbà míì, mi ò kì í rí i rò, àmọ́ ká tó ṣẹ́jú pẹ́, màá tún ti gbé e sọ́kàn.”

2 Nígbà tí nǹkan bá ṣàdédé yí pa dà fún wa, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn, kíyẹn sì fa ìdààmú ọkàn. (Òwe 12:25) Ó tiẹ̀ lè ṣòro láti gbà pé òótọ́ lohun tó ṣẹlẹ̀. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀? (Ka Sáàmù 131:​1-3.) Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé ìgbàanì àtàwọn ìránṣẹ́ Jèhófà míì lóde òní. A máa rí ohun tó mú kí ọkàn wọn balẹ̀ láìka àwọn ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ sí wọn.

BÍ “ÀLÀÁFÍÀ ỌLỌ́RUN” ṢE Ń RÀN WÁ LỌ́WỌ́

3. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù?

3 Jósẹ́fù ni Jékọ́bù fẹ́ràn jù nínú gbogbo ọmọ tó bí. Àmọ́ nígbà tí Jósẹ́fù wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà á sóko ẹrú torí pé wọ́n ń jowú rẹ̀. (Jẹ́n. 37:​2-4, 23-28) Nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá (13) ni Jósẹ́fù fi jẹ palaba ìyà. Ẹrú ni ní Íjíbítì, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi jù ú sẹ́wọ̀n. Ní gbogbo àsìkò yìí, kò fojú kan bàbá rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ gan-an. Kí ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ tí kò fi kárísọ, tí kò sì sọ̀rètí nù?

4. (a) Kí ni Jósẹ́fù ń ṣe nígbà tó wà lẹ́wọ̀n? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà rẹ̀?

4 Nígbà tí Jósẹ́fù ń jìyà lẹ́wọ̀n, ó ṣeé ṣe kó máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ran òun lọ́wọ́. (Jẹ́n. 39:21; Sm. 105:​17-19) Ó tún ṣeé ṣe kó máa rántí àlá tó lá nígbà tó wà ní kékeré, kíyẹn sì jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. (Jẹ́n. 37:​5-11) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló tú ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde fún Jèhófà. (Sm. 145:18) Jèhófà dáhùn àdúrà Jósẹ́fù, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun máa “wà pẹ̀lú rẹ̀” láìka gbogbo ìṣòro tó ń kojú sí.​—Ìṣe 7:​9, 10. *

5. Báwo ni “àlàáfíà Ọlọ́run” ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?

5 Láìka ìṣòro yòówù ká máa kojú, a lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run” tó ń tuni lára, tó sì ń dáàbò bo agbára èrò orí wa. (Ka Fílípì 4:​6, 7.) Torí náà, tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà nígbàkigbà tí àníyàn bá fẹ́ bò wá mọ́lẹ̀, àlàáfíà Ọlọ́run máa fún wa lókun táá jẹ́ ká máa bá iṣẹ́ ìsìn wa nìṣó láì sọ̀rètí nù. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ òde òní táá jẹ́ ká rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí.

GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ KÓ O LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

6, 7. Tá a bá sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn ní pàtó fún Jèhófà, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá? Sọ àpẹẹrẹ kan.

6 Nígbà tí ètò Ọlọ́run sọ fún Ryan àti Juliette pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe onígbà díẹ̀ tí wọ́n ń ṣe máa wá sópin, wọ́n sọ pé ìrònú bá àwọn. Ryan sọ pé: “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la gbàdúrà sí Jèhófà. A mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lásìkò yẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nínú ìjọ wa ló jẹ́ ẹni tuntun, torí náà a gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó ta yọ fún wọn.”

7 Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wọn? Ryan sọ pé: “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tá a gbàdúrà tán báyìí, ṣe lara tù wá pẹ̀sẹ̀, ìbẹ̀rù tó wà lọ́kàn wa tẹ́lẹ̀ sì pòórá. A rí i pé àlàáfíà Ọlọ́run ń ṣọ́ ọkàn wa àti agbára èrò orí wa. Yàtọ̀ síyẹn, a mọ̀ pé a ṣì máa wúlò fún Jèhófà tá a bá ní èrò tó tọ́.”

8-10. (a) Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè jẹ́ ká borí àníyàn? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá gbájú mọ́ nǹkan tẹ̀mí?

8 Yàtọ̀ sí pé ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ó tún máa ń jẹ́ ká rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. (Ka Jòhánù 14:​26, 27.) Bí àpẹẹrẹ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tí tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Philip àti Mary lò ní Bẹ́tẹ́lì. Láàárín oṣù mẹ́rin, àwọn méjèèjì pàdánù ìyá wọn, kò pẹ́ sígbà yẹn ni mọ̀lẹ́bí Philip kan tún kú. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń tọ́jú bàbá Mary tó ti ń ṣarán.

9 Philip sọ pé: “Mo rò pé kò sóhun tó yẹ kí n ṣe tí mi ò tíì ṣe, àmọ́ mi ò tíì ṣe tó. Lọ́jọ́ kan, mo ka Kólósè 1:11 nínú àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ kan. Lóòótọ́, mò ń fara da ohun tó ṣẹlẹ̀, àmọ́ mi ò tíì fara dà á tó. Mo rí i pé ó yẹ kí n túbọ̀ ‘fara dà á ní kíkún, kí n sì ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’ Ẹsẹ Bíbélì yìí rán mi létí pé kì í ṣe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí mi ló yẹ kó pinnu bóyá màá láyọ̀ tàbí mi ò ní láyọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, màá láyọ̀ tí mo bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí mi.”

10 Torí pé àwọn méjèèjì gbájú mọ́ nǹkan tẹ̀mí, Jèhófà bù kún wọn lónírúurú ọ̀nà. Kò pẹ́ tí wọ́n kúrò ní Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n rí àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà àwọn kan lára wọn sọ pé àwọn fẹ́ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mejì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́sẹ̀. Mary wá sọ pé: “Inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí i táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń tẹ̀ síwájú, ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún wa pé ká fọkàn balẹ̀, nǹkan máa dáa.”

ṢE IPA TÌRẸ KÓ O SÌ FI ÌYÓKÙ SÍLẸ̀ FÚN JÈHÓFÀ

Báwo la ṣe lè fara wé Jósẹ́fù nínú ipò èyíkéyìí tá a bá wà? (Wo ìpínrọ̀ 11 sí 13)

11, 12. (a) Kí ni Jósẹ́fù ṣe tí Jèhófà fi bù kún rẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe san Jósẹ́fù lẹ́san?

11 Nígbà tí nǹkan bá ṣàdédé yí pa dà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn débi pé a ò ní rí nǹkan míì rò ju àwọn ìṣòro wa lọ. Nígbà tí Jósẹ́fù kojú ìṣòro, kò kárísọ débi tí ìrẹ̀wẹ̀sì á fi bò ó mọ́lẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ó sì fi ìyókù sílẹ̀ fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣiṣẹ́ kára nígbà tó wà lọ́dọ̀ Pọ́tífárì, ohun tó sì ṣe náà nìyẹn nígbà tó wà lẹ́wọ̀n. Gbogbo ohun tí ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀wọ̀n bá ní kó ṣe ló máa ń ṣe.​—Jẹ́n. 39:​21-23.

12 Lọ́jọ́ kan, wọ́n ní kí Jósẹ́fù máa bójú tó àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n wà ní ipò pàtàkì láàfin Fáráò tẹ́lẹ̀. Jósẹ́fù fi inúure hàn sí wọn débi pé wọ́n sọ gbogbo ìṣòro tí wọ́n ní fún Jósẹ́fù títí kan àlá táwọn méjèèjì lá mọ́jú ọjọ́ náà. (Jẹ́n. 40:​5-8) Jósẹ́fù ò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ sọ lọ́jọ́ yẹn ló máa gbé òun kúrò lẹ́wọ̀n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì lo ọdún méjì sí i lẹ́wọ̀n, síbẹ̀ ọjọ́ tó jáde ló di igbá kejì Fáráò.​—Jẹ́n. 41:​1, 14-16, 39-41.

13. Kí ló yẹ ká ṣe kí Jèhófà lè bù kún wa nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro?

13 Bíi ti Jósẹ́fù, àwa náà lè bá ara wa láwọn ipò kan tó jẹ́ pé ìwọ̀nba lohun tá a lè ṣe sí i. Síbẹ̀, tá a bá ṣe sùúrù, tá a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, Jèhófà máa bù kún wa. (Sm. 37:5) Ká sòótọ́, ‘ọkàn wa lè dàrú’ nígbà míì, síbẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa dúró tì wá. (2 Kọ́r. 4:8) Ó dájú pé tá a bá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn wa, Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé!

PỌKÀN PỌ̀ SÓRÍ IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ

14-16. Kí ló fi hàn pé Fílípì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láìka àwọn ìyípadà tó dé bá a?

14 Àpẹẹrẹ ẹlòmíì tó gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìka ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ ni Fílípì ajíhìnrere. Lẹ́yìn táwọn alátakò pa Sítéfánù, inúnibíni tó gbóná janjan bẹ̀rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. * Nígbà yẹn, Fílípì ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Ìṣe 6:​1-6) Inúnibíni yìí mú káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, síbẹ̀ Fílípì ronú nípa bó ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Torí náà, ó lọ sí Samáríà kó lè wàásù torí pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ibẹ̀ ò tíì gbọ́ ìhìn rere.​—Mát. 10:5; Ìṣe 8:​1, 5.

15 Fílípì múra tán láti lọ síbikíbi tí ẹ̀mí mímọ́ bá darí rẹ̀ lọ, torí náà Jèhófà lò ó láti wàásù láwọn àgbègbè tí ìwàásù ò tíì dé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kórìíra àwọn ará Samáríà, síbẹ̀ Fílípì ò ṣojúsàájú, èyí sì mú kára tù wọ́n. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi tẹ́tí sí i “pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan.”​—Ìṣe 8:​6-8.

16 Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí Ọlọ́run darí Fílípì lọ sí ìlú Áṣídódì àti Kesaréà níbi táwọn tí kì í ṣe Júù pọ̀ sí. (Ìṣe 8:​39, 40) Nígbà tó yá, nǹkan yí pa dà fún Fílípì torí ó fẹ́ ìyàwó, ó sì bímọ. Síbẹ̀, ó gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, èyí sì mú kí Jèhófà bù kún òun àti ìdílé rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu.​—Ìṣe 21:​8, 9.

17, 18. Tá a bá pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lásìkò tí nǹkan yí pa dà, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá?

17 Ọ̀pọ̀ àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gbà pé téèyàn bá pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó máa láyọ̀ láìka ìyípadà èyíkéyìí tó bá wáyé. Bí àpẹẹrẹ, Bẹ́tẹ́lì tó wà ní South Africa ni tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Osborne àti Polite ti ń sìn tẹ́lẹ̀. Nígbà tí wọ́n kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n rò pé àwọn á tètè ríṣẹ́ tí kò ní gba gbogbo àkókò àwọn, àwọn á sì ríbi táwọn á máa gbé. Àmọ́ Osborne sọ pé: “A wáṣẹ́, wáṣẹ́, a ò ríṣẹ́.” Polite ìyàwó rẹ̀ náà sọ pé: “Oṣù mẹ́ta kọjá, a ò ríṣẹ́, a ò sì lówó kankan nípamọ́. Kí n sòótọ́, nǹkan ò rọrùn rárá.”

18 Kí ló ran tọkọtaya yìí lọ́wọ́ lásìkò tí nǹkan nira yìí? Osborne sọ pé: “Bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú àwọn ará ìjọ jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. A pinnu pé dípò tá a fi máa káwọ́ gbera, ká wá máa ronú nípa ìṣòro wa, a máa túbọ̀ lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, èyí sì fún wa láyọ̀ gan-an. Bá a ṣe ń ṣèyẹn, bẹ́ẹ̀ là ń wáṣẹ́, Jèhófà sì ṣe é, a pa dà ríṣẹ́.”

ṢE SÙÚRÙ, KÓ O SÌ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

19-21. (a) Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ tíṣòro bá dé? (b) Àǹfààní wo ni ìyípadà lè ṣe wá?

19 Àwọn àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò yìí ti jẹ́ ká rí i pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá a sì ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé, a máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn. (Ka Míkà 7:7.) Kódà, a lè wá rí i pé àwọn ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ sí wa ti mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Polite tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan sọ ohun tó kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó ní: “Bá a ṣe kúrò ní Bẹ́tẹ́lì ti jẹ́ kí n túbọ̀ mọ ohun tó túmọ̀ sí láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pàápàá nígbà tí nǹkan bá ṣòro gan-an. Èyí sì ti mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.”

20 Mary tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣì ń tọ́jú bàbá rẹ̀, ó sì tún ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mary sọ pé: “Mo ti rí i pé tí àníyàn bá gbà mí lọ́kàn tàbí tí ìrònú ń dà mí lọ́kàn rú, á dáa kí n ṣe sùúrù, kí n gbàdúrà, kí n sì fọkàn balẹ̀. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù tí mo kọ́ ni pé kí n fa gbogbo ìṣòro mi lé Jèhófà lọ́wọ́, torí Jèhófà nìkan ló lè gbà wá nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.”

21 Lloyd àti Alexandra tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ sọ pé ìyípadà tó wáyé yẹn ti dán ìgbàgbọ́ àwọn wò lọ́nà táwọn ò rò tẹ́lẹ̀. Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ yìí jẹ́ ká mọ bí ìgbàgbọ́ wa ṣe lágbára tó, ó sì jẹ́ ká mọ̀ bóyá ìgbàgbọ́ wa máa dúró digbí débi tá ò fi ní rẹ̀wẹ̀sì nígbà táwọn ìṣòro míì bá dé. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti mú ká túbọ̀ lókun nípa tẹ̀mí.”

Àwọn ìyípadà tá ò rò tẹ́lẹ̀ máa ń jẹ́ ká rí àwọn ìbùkún tá ò lérò! (Wo ìpínrọ̀ 19 sí 21)

22. Tá a bá ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lábẹ́ ipò èyíkéyìí, kí ló dá wa lójú?

22 Ìgbàkigbà ni nǹkan lè yí pa dà fún wa nínú ayé yìí. Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní lè yí pa dà, ó sì lè jẹ́ àìsàn kan ló máa ṣàdédé yọjú tàbí kí nǹkan yí pa dà nínú ìdílé wa. Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ lásìkò tó o nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́. (Héb. 4:16; 1 Pét. 5:​6, 7) Àmọ́ ní báyìí ná, ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ gbé nínú ipò èyíkéyìí. Máa gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì fi gbogbo ohun tó kù sílẹ̀ fún Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní ìbàlẹ̀ ọkàn láìka ìyípadà èyíkéyìí tó lè wáyé nígbèésí ayé rẹ.

^ ìpínrọ̀ 4 Lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kúrò lẹ́wọ̀n, ó gbà pé Jèhófà ló fún òun ní ọmọkùnrin kan kó lè fi tu òun nínú. Ó sọ ọmọ náà ní Mánásè, ó sì sọ pé: “Ọlọ́run ti mú kí n gbàgbé gbogbo ìdààmú mi.”​—Jẹ́n. 41:51.

^ ìpínrọ̀ 14 Wo àpilẹ̀kọ náà “Ǹjẹ́ O Mọ̀?” nínú ìwé ìròyìn yìí.