Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ló mú kí ọkàn Sítéfánù balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí i?

SÍTÉFÁNÙ dúró níwájú àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tínú ń bí burúkú-burúkú. Mọ́kànléláàádọ́rin (71) làwọn adájọ́ yìí, àwọn ló sì para pọ̀ di ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, ìyẹn ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ní Ísírẹ́lì. Káyáfà tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ló pe ìpàdé náà, òun náà ló sì ṣe kòkárí ìgbìmọ̀ yẹn ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn nígbà tí wọ́n dájọ́ ikú fún Jésù. (Mát. 26:57, 59; Ìṣe 6:8-12) Bí àwọn ẹlẹ́rìí èké ṣe ń wá níkọ̀ọ̀kan tí wọ́n sì ń parọ́ mọ́ Sítéfánù, wọ́n kíyè sí ohun kan tó yà wọ́n lẹ́nu nípa rẹ̀, wọ́n rí i pé “ojú rẹ̀ rí bí ojú áńgẹ́lì.”​—Ìṣe 6:13-15.

Kí ló mú kí ọkàn Sítéfánù balẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ láìka inúnibíni tó gbóná janjan tí wọ́n ń ṣe sí i? Kó tó dìgbà tí wọ́n mú un wá síwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, kì í fi iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ṣeré torí ẹni tó kún fún ẹ̀mí mímọ́ ni. (Ìṣe 6:3-7) Abájọ tó fi jẹ́ pé lásìkò tó fi ń jẹ́jọ́, ẹ̀mí mímọ́ yìí kan náà ló ń tù ú nínú tó sì tún jẹ́ kó rántí àwọn ohun tó ti kọ́ tẹ́lẹ̀. (Jòh. 14:16) Ìṣe orí 7 fi hàn pé onígboyà ni àti pé ẹ̀mí mímọ́ ràn án lọ́wọ́ débi tó fi lè sọ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan lórí. Ó rántí ohun tó lé ní ogún (20) lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (Jòh. 14:26) Ṣùgbọ́n, ohun tó túbọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ Sítéfánù lágbára ni bó ṣe rí Jésù tó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run nínú ìran.​—Ìṣe 7:54-56, 59, 60.

Àwa náà lè bára wa láwọn ipò tó le koko bíi kí wọ́n halẹ̀ mọ́ wa tàbí kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wa. (Jòh. 15:20) Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo tá a sì ń lọ sí òde ẹ̀rí déédéé, ńṣe là ń jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà ṣiṣẹ́ lára wa. Ẹ̀mí yìí tún máa jẹ́ ká lókun ká lè fara da àtakò, ká sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn.​—1 Pét. 4:12-14.