Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀bùn Wo La Lè Fún Jèhófà?

Ẹ̀bùn Wo La Lè Fún Jèhófà?

JÉSÙ sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn tó bá kan àwọn ohun tá à ń fún Jèhófà. Kí nìdí? Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti fún wa tó ń jẹ́ ká láyọ̀, àmọ́ ayọ̀ wa máa pọ̀ sí i tá a bá ń fún Jèhófà náà ní nǹkan. Ẹ̀bùn wo la lè fún Jèhófà? Òwe 3:9 sọ pé: “Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.” Lára ‘àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí’ ni àkókò wa, ẹ̀bùn àbínibí wa, okun wa àtàwọn nǹkan tara tá a ní. Tá a bá ń lo àwọn ohun tá a ní yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, à ń fún Jèhófà lẹ́bùn nìyẹn, ó sì dájú pé a máa ní ayọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n.

Kí ló máa jẹ́ ká máa fún Jèhófà láwọn ohun ìní wa fàlàlà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n “ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe” tí wọ́n á fi ṣe ìtọrẹ. (1 Kọ́r. 16:2) Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè ṣètọrẹ ní àgbègbè rẹ, wo àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè lèèyàn ti lè ṣètọrẹ lórí ìkànnì. Àmọ́, ní abala donate.pr418.com, ẹ̀ẹ́ rí àlàyé tá a ṣe nípa àwọn ọ̀nà míì téèyàn lè gbà ṣètọrẹ. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, a ní abala kan lórí ìkànnì wa tó dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa béèyàn ṣe lè ṣètọrẹ.