Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Fi Inú Rere Hàn sí Wa

Jèhófà Fi Inú Rere Hàn sí Wa

LÁWỌN ọdún 1970, èmi àti Danièle ìyàwó mi lọ sórílẹ̀-èdè Gabon lásìkò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Nígbà tá a wọnú òtẹ́ẹ̀lì tá a máa dé sí, olùgbàlejò òtẹ́ẹ̀lì náà sọ fún mi pé, “Ẹ jọ̀ọ́ sà, á dáa kẹ́ ẹ pe àwọn ọlọ́pàá aṣọ́bodè.”

Torí pé ìyàwó mi máa ń tètè kíyè sí nǹkan, ṣe ló fẹnu kò mí létí pé, “Ẹ má wulẹ̀ pe àwọn ọlọ́pàá, wọ́n ti dé!” Nígbà tá a bojú wẹ̀yìn, a rí i tí ọkọ̀ àwọn sójà páàkì síwájú òtẹ́ẹ̀lì náà. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, wọ́n ti fàṣẹ ọba mú wa. Àmọ́ mo dúpẹ́ pé ìyàwó mi tètè ta mí lólobó, ìyẹn ló jẹ́ kí n yára kó àwọn ìwé pàtàkì tó wà lọ́wọ́ mi fún arákùnrin míì.

Bí wọ́n ṣe ń mú wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, ṣe ni mò ń dúpẹ́ lọ́kàn mi pé Jèhófà fún mi ní aya rere tó nígboyà, tó sì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà bí irú èyí ni èmi àti Danièle máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó gbé wa dé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa.

JÈHÓFÀ JẸ́ KÍ N RÍ ÒTÍTỌ́

Ọdún 1930 ni wọ́n bí mi nílùú kékeré kan tó ń jẹ́ Croix, lórílẹ̀-èdè Faransé. Kátólíìkì paraku làwọn òbí mi, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sì ni ìdílé wa máa ń lọ sí Máàsì, kódà gbogbo ara ni bàbá mi fi ń ṣiṣẹ́ fún ṣọ́ọ̀ṣì wa. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14) tó jẹ́ kí n rí ìwà àgàbàgebè táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń hù.

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, abẹ́ ìjọba Jámánì ni ilẹ̀ Faransé wà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wa sì máa ń ṣe ìwàásù pé ká kọ́wọ́ ti ìjọba ilẹ̀ Jámánì. Ọ̀rọ̀ tó ń sọ yẹn máa ń bí wa nínú gan-an. Àmọ́ ní gbogbo àsìkò tá à ń sọ yìí, a máa ń yọ́ gbọ́ bí nǹkan ṣe ń lọ lórí rédíò BBC, pàápàá ìròyìn nípa bí àwọn ọmọ ogun tó ń bá ilẹ̀ Jámánì jà ṣe ń mókè nínú ogun náà. Nígbà tó di September 1944, ṣe ni ọwọ́ àwọn ọmọ ogun yìí túbọ̀ ń mókè nínú ìjà náà. Ká tó mọ̀, àlùfáà wa ti yíhùn pa dà, ó sọ fún wa pé a máa ṣayẹyẹ ìṣẹ́gun fún àwọn ọmọ ogun tó ń bá ilẹ̀ Jámánì jà. Èyí jẹ́ kí n rí i pé alábòsí gbáà làwọn aṣáájú ẹ̀sìn wa, mi ò sì fọkàn tán wọn mọ́.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tógun yẹn parí ni bàbá mi kú. Ẹ̀gbọ́n mi ti lọ sílé ọkọ, orílẹ̀-èdè Belgium sì lòun àtọkọ rẹ̀ ń gbé. Torí náà, ọrùn mi ni bùkátà màmá mi já lé. Nígbà tó yá, mo ríṣẹ́ sí iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe aṣọ. Kátólíìkì paraku ni ọ̀gá mi àtàwọn ọmọ rẹ̀. Bí nǹkan ṣe ń lọ nílé iṣẹ́ yẹn, ó jọ pé màá rọ́wọ́ mú níbẹ̀, àmọ́ àdánwò kan wà tí màá tó kojú.

Ní gbogbo ìgbà yẹn, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Simone ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì wá kí wa lọ́dún 1953. Nígbà tá a jọ ń sọ̀rọ̀, ó fi Bíbélì túdìí àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń gbé lárugẹ, irú bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn àti ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì. Mo kọ́kọ́ bá a jiyàn torí pé kì í ṣe Bíbélì Kátólíìkì ló ń lò, àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi rí i pé òótọ́ ló ń sọ fún mi. Nígbà tó yá, ó kó àwọn Ilé Ìṣọ́ kan tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ wá fún mi, alẹ́ mọ́jú ọjọ́ kejì sì ni mo kà á tán nínú yàrá mi. Ohun tí mo kà yẹn jẹ́ kí n rí i pé òtítọ́ gan-an nìyí, síbẹ̀ ẹ̀rù ń bà mí pé tí mo bá ṣe ìsìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ mi.

Fún bí oṣù mélòó kan, mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ láyè ara mi. Àmọ́ nígbà tó yá, mo pinnu láti lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tí mo débẹ̀, àwọn tó wà níbẹ̀ yọ̀ mọ́ mi, wọ́n sì fìfẹ́ hàn sí mi, mi ò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn. Lẹ́yìn tí arákùnrin kan tó nírìírí kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún oṣù mẹ́fà, mo ṣèrìbọmi ní September 1954. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni màmá mi àti àbúrò mi obìnrin náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí sì múnú mi dùn gan-an.

A GBÁRA LÉ JÈHÓFÀ LẸ́NU IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN

Màámi kú ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú àpéjọ àgbáyé tá a ṣe nílùú New York lọ́dún 1958, ó sì dùn mí gan-an, síbẹ̀ mo lọ sí àpéjọ yẹn. Ní báyìí tí màámi ti kú, mi ò ní bùkátà kankan tí mò ń gbé mọ́. Torí náà, nígbà tí mo pa dà dé láti àpéjọ náà, mo fiṣẹ́ sílẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, mo pàdé arábìnrin kan, Danièle Delie lorúkọ rẹ̀, aṣáájú-ọ̀nà ni, ó sì nítara gan-an. A bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà, nígbà tó sì di May 1959, a ṣègbéyàwó.

Ìgbèríko ìlú Brittany ni Danièle ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ibẹ̀ sì jìnnà gan-an sílé rẹ̀. Ó gba pé kó ní ìgboyà kó tó lè wàásù torí pé Kátólíìkì lọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní ìgbèríko yẹn, yàtọ̀ síyẹn kẹ̀kẹ́ ló máa ń gùn lọ síbẹ̀. Bíi tèmi, òun náà gbà pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú torí a ò mọ bí òpin ṣe sún mọ́lé tó. (Mát. 25:13) Danièle máa ń múra tán láti yááfì ohunkóhun, ìyẹn sì jẹ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro tá a kojú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa.

Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó ni ètò Ọlọ́run sọ mí di alábòójútó àyíká. Ìyẹn gba pé ká máa gbé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ. Akéde mẹ́rìnlá (14) ló wà níjọ tá a kọ́kọ́ bẹ̀ wò, wọn ò sì nílé tí wọ́n lè fi wá sí. Torí náà, orí pèpéle Gbọ̀ngàn Ìjọba la gbé ibùsùn wa sí. Kí n sòótọ́, kò rọ̀ wá lọ́rùn, àmọ́ gbogbo ohun tágbára àwọn ará yẹn gbé nìyẹn àti pé a ríbi na ẹ̀yìn wa!

A máa ń gbé mọ́tò wa lọ sáwọn ìjọ tá à ń bẹ̀ wò

Láìka bọ́wọ́ wa ṣe máa ń dí tó nígbà yẹn, ìyàwó mi mú ara ẹ̀ bá iṣẹ́ wa mu. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń dúró dè mí nínú ọkọ̀ wa tó bá di pé kí n foríkorí pẹ̀lú àwọn alàgbà tó wá rí mi láìròtẹ́lẹ̀, síbẹ̀ kì í ráhùn. Ọdún méjì la lò lẹ́nu iṣẹ́ yìí, a sì gbádùn ẹ̀ gan-an torí ó jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú kí tọkọtaya máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí wọ́n sì máa finú han ara wọn.​—Oníw. 4:9.

A BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN MÍÌ

Lọ́dún 1962, ètò Ọlọ́run pè wá sí kíláàsì kẹtàdínlógójì (37) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nílùú Brooklyn. Oṣù mẹ́wàá gbáko la lò ní ilé ẹ̀kọ́ yẹn. Nínú ọgọ́rùn-ún (100) èèyàn tí wọ́n pè sí ilé ẹ̀kọ́ náà, àwa mẹ́tàlá (13) péré la jẹ́ tọkọtaya, torí náà inú èmi àtìyàwó mi dùn gan-an. Mo ṣì máa ń rántí àwọn ẹni ìgbàgbọ́ tá a pàdé ní Brooklyn, àwọn bíi Frederick Franz, Ulysses Glass àti Alexander H. Macmillan.

Inú wa dùn gan-an pé a jọ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Nílé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sọ fún wa pé ká kọ́ béèyàn ṣe ń lákìíyèsí. Lẹ́yìn tá a bá parí kíláàsì láwọn ọ̀sán Sátidé kan, wọ́n máa ń mú wa lọ sígboro New York City ká lè fojú lóúnjẹ. Tó bá di Monday, a máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tá a rí àti ẹ̀kọ́ tá a kọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ti máa ń rẹ̀ wá tẹnutẹnu tá a bá fi máa pa dà dé. Lẹ́yìn tá a bá dé, ẹni tó mú wa kiri ìgboro máa béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ wa, ká lè rántí àwọn ohun tá a rí àtàwọn nǹkan tá a kọ́. Mo rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Sátidé kan, a rìn kiri ìgboro, kódà a dé ibì kan tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn òkúta meteors àti meteorites. Nígbà tá a tún lọ sí ibi tí wọ́n kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí, ìyẹn American Museum of Natural History, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín àlégbà àti ọ̀nì. Nígbà tá a délé, ẹni tó mú wa kiri ìgboro bi wá pé, “Ó yá o, kí ni ìyàtọ̀ láàárín òkúta meteors àti meteorites?” Ó ti rẹ ìyàwó mi tẹnutẹnu, ló bá dáhùn pé, “Òkúta meteorites máa ń léyín gígùn!”

A máa ń gbádùn bá a ṣe ń bẹ àwọn ará wò nílẹ̀ Áfíríkà

Lẹ́yìn tá a parí ilé ẹ̀kọ́ yẹn, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílẹ̀ Faransé ni wọ́n rán wa lọ, a sì sìn níbẹ̀ fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta (53). Lọ́dún 1976, ètò Ọlọ́run sọ mí di olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, mo sì tún láǹfààní àtimáa ṣèbẹ̀wò sáwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Áfíríkà àti Éṣíà níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Ohun tó gbé wa dé orílẹ̀-èdè Gabon tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Kí n má parọ́, àwọn ìgbà kan wà tí iṣẹ́ yẹn kà mí láyà, ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò ní lè ṣe é. Àmọ́ ìyàwó mi dúró tì mí, ìyẹn ló jẹ́ kí n lè ṣe àwọn iṣẹ́ yìí láṣeyọrí.

Mò ń túmọ̀ àsọyé tí Arákùnrin Theodore Jaracz sọ ní àpéjọ àgbègbè “Idajọ Ododo Atọrunwa” tó wáyé ní Paris, lọ́dún 1988

A JỌ KOJÚ ÌṢÒRO KAN TÓ LÁGBÁRA

Oṣù márùn-ún ká tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ni ìyàwó mi ti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó wá di ọ̀jáfáfá nídìí iṣẹ́ atúmọ̀ èdè. Àtìbẹ̀rẹ̀ la ti fẹ́ràn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, a sì gbádùn iṣẹ́ náà gan-an, àmọ́ ayọ̀ tá à ń rí bá a ṣe ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ ò lẹ́gbẹ́ rárá. Mo máa ń rántí àwọn ìgbà témi àtìyàwó mi máa ń lọ sóde ẹ̀rí, tá a sì máa ń wọ ọkọ̀ ojú irin pa dà sílé lọ́wọ́ alẹ́. Á ti rẹ̀ wá, àmọ́ inú wa máa ń dùn pé a darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú. Nígbà tó yá, ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, èyí bà mí nínú jẹ́ torí pé àìlera náà ò jẹ́ kó lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

Lọ́dún 1993 táwọn dókítà ṣàyẹ̀wò ìyàwó mi, wọ́n rí i pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú. Ìtọ́jú tó gbà ò rọrùn rárá, lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ abẹ, ó gba ìtọ́jú kan tí wọ́n ń pè ní chemotherapy. Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n tún sọ pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ míì tó burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Síbẹ̀, ìyàwó mi ò fi àìsàn yẹn kẹ́wọ́, kí ni ara ẹ̀ yá díẹ̀ sí, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pa dà.

Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé gbogbo bí àìlera ìyàwó mi ṣe burú tó, a ò fìgbà kan ronú àtifi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀ rárá. Àmọ́ ká sòótọ́, kì í rọrùn téèyàn bá ń ṣàìsàn ní Bẹ́tẹ́lì, pàápàá táwọn míì ò bá mọ bí ìṣòro náà ṣe burú tó. (Òwe 14:13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rin (80) ọdún, kò gbé ìṣòro ẹ̀ karí láìka ohun tójú ẹ̀ rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú rẹ̀ máa ń fani mọ́ra. Kì í kárísọ rárá, ṣe ló tún máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì tó níṣòro, táá sì wọ́nà àtiràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 17:17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó mi kì í ṣe agbani-nímọ̀ràn, síbẹ̀ ó máa ń lo ìrírí tó ní láti fi àwọn arábìnrin míì lọ́kàn balẹ̀ pé kí wọ́n má bẹ̀rù bí wọ́n tiẹ̀ lárùn jẹjẹrẹ.

Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn ìṣòro míì tún bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú. Ipò nǹkan le débi pé ìyàwó mi ò lè ṣiṣẹ́ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, ó wá pinnu pé òun á máa ràn mí lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń ṣe kí nǹkan lè rọ̀ mí lọ́rùn, ìyẹn ló sì jẹ́ kí n lè máa báṣẹ́ olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tí mò ń ṣe lọ fún ọdún mẹ́tàdínlógójì (37). Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń rí i dájú pé òun ṣètò ohun tá a máa jẹ lọ́sàn-án, ká lè jọ jẹun pa pọ̀ nínú yàrá, ká sì jọ sinmi díẹ̀.​—Òwe 18:22.

À Ń FARA DA ÀWỌN ÌṢÒRO WA

Ìyàwó mi kì í kárísọ, ó sì dá a lójú pé nǹkan ṣì máa dáa. Ó máa yà yín lẹ́nu pé ó tún pa dà lárùn jẹjẹrẹ lẹ́ẹ̀kẹta. Gbogbo ẹ̀ tojú sú wa, pàápàá pẹ̀lú ìtọ́jú chemotherapy àti radiotherapy tó ń gbà. Ṣe nìtọ́jú yẹn máa ń tán an lókun, kì í jẹ́ kó lè rìn nígbà míì. Ìbànújẹ́ sorí mi kodò bí mo ṣe ń wo olólùfẹ́ mi ọ̀wọ́n tó jẹ́ ọ̀jáfáfá atúmọ̀ èdè tẹ́lẹ̀, tó wá dẹni tí ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa mọ́.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan tojú sú wa, a ò dákẹ́ àdúrà torí ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ ká kojú ìṣòro tó ju agbára wa lọ. (1 Kọ́r. 10:13) Jèhófà ò fi wá sílẹ̀ rárá, ìgbà gbogbo ló ń tù wá nínú, a sì mọyì ẹ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ó pèsè ìtùnú nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ará tó wà ní ẹ̀ka tó ń tọ́jú aláìsàn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Gbogbo ìgbà la máa ń bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, kó sì jẹ́ ká mọ irú ìtọ́jú tó yẹ ká gbà. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé a ò gba ìtọ́jú kankan. Ìdí ni pé ṣe ni ìyàwó mi máa ń dákú lọ gbọnrangandan tó bá ti gba ìtọ́jú chemotherapy. Kódà, dókítà tó ti ń tọ́jú ẹ̀ fún ọdún mẹ́tàlélógún (23) sọ pé òun ò mọ ìdí tó fi ń dákú lẹ́yìn tó bá gba ìtọ́jú náà, òun ò sì mọ ohun tá a lè ṣe sí i. A wá dà bí àlejò tó bára ẹ̀ ní ìkóríta mẹ́ta, a ò mọ ọ̀nà tá a lè gbà. Àmọ́ dókítà míì gbà láti tọ́jú ìyàwó mi, ṣe ló dà bíi pé Jèhófà ṣọ̀nà àbáyọ ká lè fara da àwọn ìṣòro wa.

A kọ́ bá a ṣe lè máa fara da àwọn ìṣòro wa láì jan àníyàn tòní mọ́ tọ̀la. Ó ṣe tán Jésù sọ pé, wàhálà “ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.” (Mát. 6:34) Bá ò ṣe sọ̀rètí nù tá a sì máa ń ṣàwàdà mú ká lè fara dà á. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí ìyàwó mi ò gba ìtọ́jú chemotherapy fún oṣù méjì, ó wá fi yẹ̀yẹ́ sọ pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé, ara mi ò yá tó yìí rí!” (Òwe 17:22) Pẹ̀lú bí ìrora ẹ̀ ṣe pọ̀ tó, ó gbádùn kó máa fayọ̀ kọ àwọn orin wa tuntun.

Ẹ̀mí tó dáa tí ìyàwó mi ní mú kó rọrùn fún mi láti ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi. Kí n sòótọ́, ìyàwó mi tọ́jú mi gan-an ní gbogbo ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) tá a fi wà pa pọ̀. Kódà, mi ò mọ bí wọ́n ṣe ń dín ẹyin lásán, àmọ́ nígbà tí àìsàn ẹ̀ dójú ẹ̀, mo kọ́ béèyàn ṣe ń dáná, bá a ṣe ń fọ abọ́ àti béèyàn ṣe ń fọṣọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwo mélòó kan fọ́ lọ́wọ́ mi, síbẹ̀ inú mi dùn pé mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti múnú ẹ̀ dùn. *

MO DÚPẸ́ PÉ JÈHÓFÀ FI INÚURE HÀN SÍ WA

Tí n bá ń rántí ohun tójú èmi àtìyàwó mi ti rí, àti bá a ṣe fara da àìsàn àti ọjọ́ ogbó, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo rí kọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kọ́wọ́ èèyàn dí jù débi tí ò fi ní ráyè fún ẹnì kejì rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbà tá a ṣì lókun ló yẹ ká ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé láti tọ́jú àwọn èèyàn wa. (Oníw. 9:9) Ìkejì, kò yẹ ká máa ṣàníyàn jù nípa àwọn ìṣòro tí ò tó nǹkan, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè má kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń bù kún wa lójoojúmọ́.​—Òwe 15:15.

Kò sígbà tí mo ronú nípa bá a ṣe fi gbogbo ayé wa sin Jèhófà tí inú mi kì í dùn, torí ó hàn kedere sí mi pé Jèhófà bù kún wa kọjá bẹ́ẹ̀. Bíi ti onísáàmù, èmi náà lè fi gbogbo ẹnu sọ pé Jèhófà ti fi inú rere hàn sí mi.​—Sm. 116:7.

^ ìpínrọ̀ 32 Arábìnrin Danièle Bockaert kú lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (78) nígbà tá à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí.