Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Ọlọ́run?

Ta Ni Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́. Ṣùgbọ́n tó o bá bi wọ́n pé ta ni Ọlọ́run, oríṣiríṣi ìdáhùn ni wọ́n á fún ẹ. Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run jẹ́ adájọ́ tó burú tí kò mọ̀ ju kó máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹni. Àmọ́, àwọn míì kà á sí ẹlẹ́yinjú àánú tó kàn ṣáà máa ń dárí jini láìka ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn bá dá sí. Síbẹ̀ àwọn míì gbà pé Ọlọ́run jìnnà sí wa, kò sì rí tiwa rò. Pẹ̀lú oríṣiríṣi èrò tí àwọn èèyàn ní yìí, ọ̀pọ̀ gbà pé kò ṣeé ṣe láti mọ Ọlọ́run.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ Ọlọ́run? Ìdí ni pé tó o bá mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, á jẹ́ kí ìgbé ayé rẹ túbọ̀ dára, wàá sì ní ìrètí. (Ìṣe 17:​26-28) Bó o bá ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ ni òun náà á ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Jákọ́bù 4:8) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run máa jẹ́ kó o ní ìyè ayérayé.​—Jòhánù 17:3.

Báwo lo ṣe lè mọ Ọlọ́run? Ronú nípa ẹnì kan tó o mọ̀ dáadáa, bóyá ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan. Báwo lẹ ṣe di ọ̀rẹ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orúkọ rẹ̀ lo kọ́kọ́ mọ̀, lẹ́yìn náà o bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ìwà rẹ̀, ohun tó fẹ́, ohun tí kò fẹ́, ohun tó ti gbé ṣe, àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lọ́rọ̀ kan, ohun tó jẹ́ kó o sún mọ́ ọn ni pé, o mọ irú ẹni tó jẹ́.

Bákan náà, a lè mọ Ọlọ́run tá a bá wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí:

A dìídì ṣe ìwé ìròyìn yìí kó o lè rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti àǹfààní tí wàá rí tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run.