Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Nǹkan Wo Ni Ọlọ́run Máa Ṣe?

Àwọn Nǹkan Wo Ni Ọlọ́run Máa Ṣe?

Tó o bá ní ìṣòro, ó máa wù ẹ́ pé kí ọ̀rẹ́ rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó ṣe tán, ìgbà ìpọ́njú là ń mọ ọ̀rẹ́. Ohun tí àwọn kan rò nìyẹn tí wọ́n fi sọ pé Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rẹ́ àwọn, torí wọ́n gbà pé Ọlọ́run kò ṣe nǹkan kan sí ìṣòro àwọn. Àmọ́ ká sọ̀rọ̀ síbi tí ọ̀rọ̀ wà, Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi fún wa. Ó sì máa tó mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, tí á sì fì òpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe?

Ó MÁA MÚ GBOGBO ÌWÀ IBI KÚRÒ

Bí Ọlọ́run ṣe máa fì òpin sí ìwà ibi ni pé ó máa pa olórí àwọn ẹni ibi run. Bíbélì jẹ́ ká mọ onítọ̀hún nígbà tó sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Sátánì Èṣù ni “ẹni burúkú náà.” Òun ni Jésù pè ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31) Ọ̀dọ̀ Sátánì gangan ni ìwà ibi ti bẹ̀rẹ̀, òun ló fojú pa mọ́ tó ń da wàhálà sí ọmọ aráyé lágbada. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe?

Jèhófà Ọlọ́run máa lo Jésù Kristi láti “sọ ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá di asán, èyíinì ni, Èṣù.” (Hébérù 2:14; 1 Jòhánù 3:8) Kódà, Bíbélì fi hàn pé Èṣù fúnra rẹ̀ mọ̀ pé “sáà àkókò kúkúrú ni òun ní” kí òun tó pa run. (Ìṣípayá 12:12) Ọlọ́run tún máa pa gbogbo àwọn tó ń hùwà burúkú run pátápátá.​—Sáàmù 37:9; Òwe 2:22.

Ó MÁA SỌ AYÉ DI PÁRÁDÍSÈ

Lẹ́yìn tí gbogbo ìwà ibi bá dópin tí àwọn ẹni ibi sì pa run, Ẹlẹ́dàá wa máa rí i dájú pé àwọn èèyàn rere nìkan ló ṣẹ́ kù sáyé, ayé sì máa di Párádísè bó ṣe fẹ́ kó rí ní ìbẹ̀rẹ̀. Kí ni ká máa fojú sọ́nà fún?

Àlàáfíà àti ààbò máa gbilẹ̀ títí láé. “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”​—Sáàmù 37:11.

Oúnjẹ aṣaralóore á pọ̀ yanturu. “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀, àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”​—Sáàmù 72:16.

A máa ní ilé tó dára àti iṣẹ́ tó ń tẹ́ni lọ́rùn. “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. . . . Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ.”​—Aísáyà 65:​21, 22.

Ṣé ó wù ẹ́ kí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ lójú ẹ̀mí rẹ? Láìpẹ́, àwọn ohun tí a ó máa gbádùn lójoojúmọ́ ayé wa nìyẹn.

Ó MÁA MÚ ÀÌSÀN ÀTI IKÚ KÚRÒ

Ọmọ aráyé ti kàgbákò àìsàn àti ikú. Àmọ́ láìpẹ́, ìyẹn máa di ohun ìgbàgbé. Ọlọ́run máa wo ọlá ikú ìrúbọ tí Jésù kú láti ra aráyé pa dà, kí “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀?

Àìsàn kò ní sí mọ́. “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.”​—Aísáyà 33:24.

Ikú ò ní máa pọ́n ọmọ aráyé lójú mọ́. “Òun yóò gbé ikú mì títí láé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”​—Aísáyà 25:8.

Àwọn èèyàn máa wà láàyè títí láé. “Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”​—Róòmù 6:23.

Àwọn tó ti kú máa jíǹde. “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ìràpadà Jésù máa mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó ti kú láti jíǹde.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe gbogbo nǹkan yìí?

Ó MÁA MÚ KÍ ÌJỌBA PÍPÉ ṢÀKÓSO AYÉ

Ọlọ́run máa lo ìjọba rẹ̀ ọrun lábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ fún ayé yìí àti àwa èèyàn. (Sáàmù 110:​1, 2) Ìjọba yẹn ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún nígbà tó sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, . . . kí ìjọba rẹ dé.”​—Mátíù 6:​9, 10.

Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé, á sì mú gbogbo wàhálà àti ìyà kúrò. Ìjọba yìí ló máa jẹ́ ìjọba tó dára jù fún aráyé! Ìdí nìyẹn tí Jésù ṣe fi ara rẹ̀ jìn fún iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere Ìjọba náà” nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀.​—Mátíù 4:23; 24:14.

Torí pé Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn ló ṣe ṣèlérí pé òun máa ṣe gbogbo àwọn ohun àgbàyanu yìí fún wa. Ṣé ó wù ẹ́ láti mọ Ọlọ́run yìí, kó o sì sún mọ́ ọn? To o bá sún mọ́ Ọlọ́run, àǹfààní wo ló máa ṣe fún ẹ? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé.

ÀWỌN NǸKAN WO NI ỌLỌ́RUN MÁA ṢE? Ọlọ́run máa mú àìsàn àti ikú kúrò, ó máa lo Ìjọba rẹ̀ láti mú kí aráyé wà ní ìṣọ̀kan, ó sì máa sọ ayé di Párádísè