Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 6

Máa Hùwà Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

Máa Hùwà Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

“Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”​—JÓÒBÙ 27:5.

ORIN 34 Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta tá a sọ̀rọ̀ wọn ní ìpínrọ̀ yìí ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?

FOJÚ inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta kan. Ọ̀dọ́bìnrin lẹni àkọ́kọ́, ọmọléèwé sì ni. Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ rẹ̀ sọ pé kí òun àtàwọn tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì ṣe ayẹyẹ kan, àmọ́ ọ̀dọ́bìnrin náà fìrẹ̀lẹ̀ sọ fún wọn pé ayẹyẹ náà kò bá Bíbélì mu, torí náà òun ò ní lọ́wọ́ sí i. Ẹnì kejì ni ọ̀dọ́kùnrin kan tó máa ń tijú gan-an. Lọ́jọ́ kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé, ó kíyè sí i pé ọmọléèwé rẹ̀ kan tó máa ń fi àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́ ló ń gbé nílé tó kàn. Síbẹ̀, ó wàásù ní ilé náà. Baálé ilé ni arákùnrin kẹta, kò sì fiṣẹ́ ṣeré. Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé kó ṣe ohun kan tí kò tọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ tí kò bá ṣe ohun tí ọ̀gá náà sọ, síbẹ̀ ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé òun ò ní ṣe é torí pé inú Ọlọ́run ò dùn sí ìwà bẹ́ẹ̀.​—Róòmù 13:1-4; Héb. 13:18.

2. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò, kí sì nìdí?

2 Ànímọ́ wo ni wàá sọ pé àwọn ará yẹn ní? Ó ṣeé ṣe kó o kíyè sí i pé wọ́n jẹ́ onígboyà àti olóòótọ́. Àmọ́ ohun kan ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn sì ni pé wọn ò fi àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà ṣeré, wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló fi hàn pé ìlànà Jèhófà làwọn ń tẹ̀ lé. Kò sí àní-àní pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì dájú pé inú Jèhófà dùn sí wọn gan-an, kódà àmúyangàn ni wọ́n jẹ́ fún un. Àwa náà máa fẹ́ jẹ́ àmúyangàn fún Jèhófà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Fún ìdí yìí, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ oníwà títọ́? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa hùwà tó tọ́? Kí lá jẹ́ ká dúró lórí ìpinnu wa pé àá máa ṣe ohun tó tọ́ láìka ìṣòro yòówù kó dé bá wa sí?

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI JẸ́ ONÍWÀ TÍTỌ́

3. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ oníwà títọ́? (b) Àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ ohun tí ìwà títọ́ túmọ̀ sí?

3 Ká tó lè sọ pé ẹnì kan jẹ́ oníwà títọ́, ó gbọ́dọ̀ máa hàn nínú ìwà tó ń hù lójoojúmọ́ pé ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ ẹ́ lógún jù lọ, pé òun ló ń fayé rẹ̀ sìn àti pé àwọn nǹkan tí Jèhófà kà sí pàtàkì lòun náà kà sí pàtàkì. Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ìwà títọ́” nínú Bíbélì túmọ̀ sí pé kí nǹkan pé, kí ara ẹ̀ dá ṣáṣá, kó má sì ní àbùkù. Bí àpẹẹrẹ, Òfin Mósè sọ pé táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá máa fi ẹran rúbọ sí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá. * (Léf. 22:21, 22) Òfin náà kò gbà wọ́n láyè láti fi ẹran tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kán, tí etí rẹ̀ re, tí ojú rẹ̀ fọ́ tàbí tó ń ṣàìsàn rúbọ. Ó ṣe pàtàkì kí ẹran tí wọ́n máa fi rúbọ sí Jèhófà dá ṣáṣá, kó má sì lábùkù, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà kò ní tẹ́wọ́ gbà á. (Mál. 1:6-9) Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ohun tí kò lábùkù ni Jèhófà fẹ́. Ká sọ pé àwa náà bá fẹ́ ra èso, ìwé tàbí ohun èlò míì, ó dájú pé a ò ní gba èyí tó níhò tàbí tí apá kan nínú rẹ̀ ti bà jẹ́. Èyí tó pé tí kò sì lábùkù la máa gbà. Lọ́nà kan náà, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ látọkàn wá, kò sì yẹ ká máa ṣe ẹsẹ̀ kan ilé ẹsẹ̀ kan òde.

4. (a) Kí nìdí tá a fi gbà pé èèyàn aláìpé lè jẹ́ oníwà títọ́? (b) Bí Sáàmù 103:12-14 ṣe sọ, kí ni Jèhófà ò retí pé ká ṣe?

4 Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ pípé ká tó lè jẹ́ oníwà títọ́? Rárá, ó ṣe tán aláìpé ni wá, a sì máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Síbẹ̀, kò yẹ ká ronú pé a ò ní lè sin Jèhófà bó ṣe fẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, kì í ṣe àṣìṣe wa ni Jèhófà ń wò. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sm. 130:3) Ó mọ̀ pé aláìpé ni wá, a sì máa ń dẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń dárí jì wá fàlàlà. (Sm. 86:5) Ìdí kejì ni pé Jèhófà mọ ibi tágbára wa mọ, torí náà kò retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. (Ka Sáàmù 103:12-14.) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lá jẹ́ kí Jèhófà gbà pé ìfẹ́ tá a ní fún òun tàbí pé ìjọsìn wa kò lábùkù?

5. Kí nìdí táwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ ká tó lè jẹ́ oníwà títọ́?

5 Ó ṣe pàtàkì ká ní ìfẹ́ ká tó lè jẹ́ oníwà títọ́. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ tọkàntọkàn, kò sì gbọ́dọ̀ ní àbùkù. Tá a bá fi gbogbo ọkàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pàápàá lójú àdánwò, a jẹ́ pé ìwà tó tọ́ là ń hù yẹn. (1 Kíró. 28:9; Mát. 22:37) Ẹ jẹ́ ká pa dà sọ́dọ̀ àwọn mẹ́ta tá a sọ níbẹ̀rẹ̀. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣèpinnu tí wọ́n ṣe yẹn? Ṣé torí pé kò wu ọ̀dọ́bìnrin yẹn kó gbádùn ara ẹ̀ ni? Ṣé ọ̀dọ́kùnrin yẹn fẹ́ kí ọmọléèwé òun fi òun ṣe yẹ̀yẹ́ ló mú kó lọ wàásù níbẹ̀, àbí torí pé baálé ilé yẹn fẹ́ kíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ òun? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n gbà pé ohun tó tọ́ làwọn ṣe. Ohun tó gbà wọ́n lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa múnú Baba wọn ọ̀run dùn. Torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èrò rẹ̀ ló máa ń darí wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu. Torí náà, ìpinnu tí wọ́n ṣe yẹn fi hàn pé wọ́n jẹ́ oníwà títọ́.

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ JẸ́ ONÍWÀ TÍTỌ́

6. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ oníwà títọ́? (b) Kí ló fà á tí Ádámù àti Éfà fi di aláìṣòótọ́?

6 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ oníwà títọ́? Ìdí kan ni pé Sátánì parọ́ mọ́ Jèhófà, ó sì tún fẹ̀sùn kan àwa náà. Inú ọgbà Édẹ́nì ni áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí ti sọ ara rẹ̀ di Sátánì tàbí “Alátakò.” Ó ba Jèhófà lórúkọ jẹ́, ó ní ìkà ni Jèhófà, onímọtara-ẹni-nìkan ni àti pé Alákòóso tí kì í sòótọ́ ni. Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà gba ohun tí Sátánì sọ gbọ́, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. (Jẹ́n. 3:1-6) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ àǹfààní làwọn tọkọtaya yìí ní láti mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà túbọ̀ lágbára. Àmọ́ nígbà tí Sátánì dán wọn wò, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà ti dín kù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jinlẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn wá gbé ìbéèrè kan dìde: Ǹjẹ́ ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí á lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà débi pé á jẹ́ adúróṣinṣin sí i lójú àdánwò? Lédè míì, ṣé àwa èèyàn lè jẹ́ oníwà títọ́? Ìbéèrè yìí ló jẹ yọ nígbà tí Jóòbù kojú àdánwò.

7. Bó ṣe wà nínú Jóòbù 1:8-11, ojú wo ni Jèhófà àti Sátánì fi wo ìwà títọ́ Jóòbù?

7 Ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní Íjíbítì ni Jóòbù gbáyé, ìwà títọ́ rẹ̀ sì jọni lójú. Aláìpé bíi tiwa ni, òun náà sì ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ torí pé ó máa ń hu ìwà tó tọ́. Ó jọ pé Sátánì ti gan Jèhófà pé kò sẹ́ni tó lè jẹ́ adúróṣinṣin sí i, torí náà Jèhófà fi Jóòbù yangàn lójú Sátánì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù àtohun tó ṣe fi hàn pé òpùrọ́ paraku ni Sátánì. Sátánì wá ní kí Jèhófà jẹ́ kóun dán Jóòbù wò. Jèhófà gbà á láyè pé kó ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó mọ̀ pé Jóòbù ọ̀rẹ́ òun máa jẹ́ adúróṣinṣin.​—Ka Jóòbù 1:8-11.

8. Báwo ni Sátánì ṣe dán Jóòbù wò?

8 Òǹrorò ni Sátánì, apààyàn sì ni. Ó run gbogbo ọrọ̀ àti ohun ìní Jóòbù, ó pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó bà á lórúkọ jẹ́ ládùúgbò, ó sì tún pa ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Kò tán síbẹ̀ o, ó fi àìsàn kọ lù ú, ó jẹ́ kó ní eéwo látorí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́, nígbà tọ́rọ̀ náà dójú ẹ̀ fún ìyàwó Jóòbù, ó ní kí Jóòbù bú Ọlọ́run kó sì kú. Jóòbù fúnra ẹ̀ bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kóun kú. Nígbà tí Sátánì rí i pé Jóòbù ò bọ́hùn, ó dọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ míì, àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta ló sì lò. Ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n lò pẹ̀lú rẹ̀, kàkà kí wọ́n sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un, ọ̀rọ̀ kòbákùngbé ni wọ́n ń sọ sí i, wọ́n sì ń dá a lẹ́bi ṣáá. Wọ́n ní Ọlọ́run ló fa gbogbo àjálù tó dé bá a àti pé ìdúróṣinṣin rẹ̀ kò nítumọ̀ lójú Ọlọ́run. Kódà, wọ́n fẹ̀sùn kan Jóòbù pé èèyàn burúkú ni àti pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ ló ń jẹ.​—Jóòbù 1:13-22; 2:7-11; 15:4, 5; 22:3-6; 25:4-6.

9. Kí ni Jóòbù ò ṣe kódà nígbà tí àdánwò ẹ̀ le gan-an?

9 Kí ni Jóòbù wá ṣe sí gbogbo àjálù tó dé bá a yìí? Kì í kúkú ṣe ẹni pípé, torí náà ṣe ló fìbínú bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí, òun náà sì gbà pé ọ̀rọ̀ ẹhànnà lòun sọ. Lọ́pọ̀ ìgbà òdodo tiẹ̀ ló ń tẹnu mọ́ dípò òdodo Ọlọ́run. (Jóòbù 6:3; 13:4, 5; 32:2; 34:5) Síbẹ̀, Jóòbù ò bọ́hùn kò sì fi Jèhófà sílẹ̀ kódà nígbà tí àdánwò náà dójú ẹ̀ gan-an. Ó gbà pé irọ́ gbuu làwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta yẹn pa mọ́ Ọlọ́run. Ó ní: “Kò ṣé e ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi pé èmi yóò polongo yín ní olódodo! Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!” (Jóòbù 27:5) Ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Jóòbù sọ yìí fi hàn pé ó ti pinnu pé òun máa jẹ́ oníwà títọ́. Jóòbù ò juwọ́ sílẹ̀, àwa náà ò sì gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀.

10. Báwo ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jóòbù ṣe kàn ẹ́?

10 Ẹ̀sùn kan náà ni Sátánì fi ń kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lónìí. Ó sọ pé o ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, pé tó o bá kojú àdánwò, wàá pa òfin Jèhófà tì kó o lè yọ ara rẹ nínú wàhálà, ó tún sọ pé ojú ayé lásán ni gbogbo bó o ṣe ń jọ́sìn Jèhófà. (Jóòbù 2:4, 5; Ìṣí. 12:10) Báwo làwọn ẹ̀sùn yẹn ṣe rí lára rẹ? Ó ń ká ẹ lára, àbí? Àmọ́, wò ó báyìí ná, Jèhófà fọkàn tán ẹ pé wàá jẹ́ adúróṣinṣin, ó sì gbà kí Sátánì dán ẹ wò. Àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́ fún ẹ láti fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú àti pé òpùrọ́ burúkú ni Sátánì. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Héb. 13:6) Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní pé Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run fọkàn tán wa! Ṣé o ti wá rí ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ oníwà títọ́? Èyí á jẹ́ ká lè fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa ká sì buyì kún orúkọ Jèhófà, á sì tún fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀. Kí lá jẹ́ ká máa hùwà tó tọ́ nígbà gbogbo?

BÁ A ṢE LÈ DÚRÓ LÓRÍ ÌPINNU WA PÉ ÀÁ JẸ́ ONÍWÀ TÍTỌ́

11. Kí la kọ́ lára Jóòbù?

11 Sátánì ti koná mọ́ àtakò tó ń ṣe sáwọn èèyàn Ọlọ́run ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2 Tím. 3:1) Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, báwo la ṣe lè dúró lórí ìpinnu wa pé àá jẹ́ oníwà títọ́? Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára Jóòbù. Tipẹ́tipẹ́ kí àjálù tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ló ti pinnu pé òun á jẹ́ oníwà títọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ mẹ́ta tá a lè kọ́ lára Jóòbù táá jẹ́ ká dúró lórí ìpinnu wa pé àá jẹ́ oníwà títọ́.

Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe ká lè dúró lórí ìpinnu wa pé àá máa hùwà tó tọ́? (Wo ìpínrọ̀ 12) *

12. (a) Bó ṣe wà nínú Jóòbù 26:7, 8, 14, kí ló mú kí Jóòbù ní ìbẹ̀rù àti ọ̀wọ̀ fún Jèhófà? (b) Báwo làwa náà ṣe lè ṣe bíi ti Jóòbù?

12 Bí Jóòbù ṣe ń kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà dá mú kó ní ọ̀wọ̀ fún un. Jóòbù máa ń kíyè sí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà dá, ó sì máa ń ronú jinlẹ̀ nípa wọn. (Ka Jóòbù 26:7, 8, 14.) Ẹnu yà á gan-an nígbà tó ń ronú nípa òfúrufú, kùrukùru, ààrá àti bí ilẹ̀ ayé ṣe rí. Síbẹ̀, ó gbà pé ohun tóun mọ̀ nípa àwọn nǹkan yẹn ò tó nǹkan. Ó tún mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ní: “Mo ti fi àsọjáde ẹnu rẹ̀ ṣúra.” (Jóòbù 23:12) Àwọn ohun tí Jèhófà ṣe mú kí Jóòbù bẹ̀rù Jèhófà kó sì bọ̀wọ̀ fún un. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ṣe ohun tó máa múnú rẹ̀ dùn. Ìyẹn wá jẹ́ kó pinnu pé ìwà tó tọ́ lòun á máa hù láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí, ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe gan-an nìyẹn. Lónìí, ohun tá a mọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ti pọ̀ fíìfíì ju ohun táwọn èèyàn mọ̀ nígbà ayé Jóòbù lọ. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ní odindi Bíbélì tó ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. Gbogbo ohun tá a mọ̀ yìí máa jẹ́ ká ní ìbẹ̀rù Jèhófà. Ìbẹ̀rù àti ọ̀wọ̀ tá a ní yìí á jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì ṣègbọràn sí i, ìyẹn lá sì jẹ́ ká dúró lórí ìpinnu wa pé àá jẹ́ oníwà títọ́.​—Jóòbù 28:28.

Àá máa hùwà tó tọ́ tá a bá ń yẹra fún àwòrán ìṣekúṣe (Wo ìpínrọ̀ 13) *

13, 14. (a) Bó ṣe wà nínú Jóòbù 31:1, kí ni Jóòbù ṣe tó mú kó jẹ́ onígbọràn? (b) Báwo làwa náà ṣe lè ṣe bíi tiẹ̀?

13 Jóòbù ń ṣègbọràn nígbà gbogbo, ìyẹn sì jẹ́ kó máa hùwà tó tọ́. Jóòbù mọ̀ pé téèyàn bá máa jẹ́ oníwà títọ́, àfi kó máa ṣègbọràn. Kódà, gbogbo ìgbà tá a bá ṣègbọràn là ń fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin. Jóòbù sapá gan-an kó lè máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run jálẹ̀ ayé rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kì í bá àwọn obìnrin tage, kì í sì í ṣẹ̀fẹ̀ rírùn. (Ka Jóòbù 31:1.) Ó mọ̀ pé òun ti gbéyàwó, torí náà kò dáa kóun máa tẹjú mọ́ obìnrin míì, bíi pé kóun bá a ṣe ìṣekúṣe. Lónìí, kò síbi téèyàn yíjú sí tí kò ní rí àwọn ohun tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè. Bíi ti Jóòbù, ṣé àwa náà kì í tẹjú mọ́ ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa? Ṣé a kì í wo àwòrán oníhòòhò tàbí ohunkóhun tó lè mú kó wù wá láti ṣèṣekúṣe? (Mát. 5:28) Tá a bá ń sapá láti kóra wa níjàánu lójoojúmọ́, ìyẹn á mú ká lè máa hùwà tó tọ́ nígbà gbogbo.

Àá máa hùwà tó tọ́ tá a bá ń fojú tó tọ́ wo àwọn ohun ìní tara (Wo ìpínrọ̀ 14) *

14 Jóòbù tún ṣègbọràn sí Jèhófà ní ti ojú tó fi ń wo àwọn ohun ìní tara. Jóòbù mọ̀ pé tó bá jẹ́ ohun ìní tara ni òun ń lé, òun máa ṣẹ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì lè fìyà jẹ òun. (Jóòbù 31:24, 25, 28) Lónìí, bí àwọn èèyàn ṣe máa kó ohun ìní tara jọ pelemọ ni wọ́n ń wá. Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo owó àtàwọn ohun ìní tara làwa náà fi ń wò ó, bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe rọ̀ wá pé ká ṣe, ìwà tó tọ́ làá máa hù nígbà gbogbo.​—Òwe 30:8, 9; Mát. 6:19-21.

Àá máa hùwà tó tọ́ tá a bá ń jẹ́ kí ìrètí wa túbọ̀ dá wa lójú (Wo ìpínrọ̀ 15) *

15. (a) Kí ló mú kí Jóòbù pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́? (b) Báwo ni ìrètí tá a ní ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

15 Jóòbù mọ̀ pé Ọlọ́run máa san òun lẹ́san, ìyẹn sì mú kó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. Ó mọ̀ pé inú Ọlọ́run ń dùn sí òun bí òun ṣe ń hùwà tó tọ́. (Jóòbù 31:6) Bí Jóòbù tiẹ̀ dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa san òun lẹ́san. Ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní yìí ló mú kó máa ṣe ohun tó tọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù jẹ́ aláìpé, síbẹ̀ kò bọ́hùn, ìyẹn sì mú kí inú Jèhófà dùn sí i, ó sì bù kún un jìngbìnnì. (Jóòbù 42:12-17; Ják. 5:11) Ó dájú pé Jèhófà tún máa san án lẹ́san tó jùyẹn lọ lọ́jọ́ iwájú. Ṣé ìwọ náà gbà pé Jèhófà máa bù kún ẹ tó o bá ń hùwà tó tọ́? Jèhófà ò tíì yí pa dà, torí náà, ó dájú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Mál. 3:6) Tá a bá ń fi sọ́kàn pé Jèhófà mọyì bá a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin, ìyẹn á jẹ́ kí ìrètí ọjọ́ iwájú túbọ̀ dá wa lójú.​—1 Tẹs. 5:8, 9.

16. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

16 Torí náà, pinnu pé wàá máa hùwà tó tọ́ nígbà gbogbo. Nígbà míì, ó lè dà bíi pé ìwọ nìkan lò ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, má jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́, ẹgbàágbèje àwọn olóòótọ́ kárí ayé bíi tìẹ ló ń hùwà tó tọ́. O tún máa wà lára àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin kódà lójú ikú. (Héb. 11:36-38; 12:1) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa náà pinnu bíi ti Jóòbù pé: “Èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!” Tá a bá ń hùwà tó tọ́ nígbà gbogbo, tá ò sì bọ́hùn, títí ayé làá máa múnú Jèhófà dùn!

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

^ ìpínrọ̀ 5 Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ oníwà títọ́? Kí nìdí tí Jèhófà fi mọyì pé káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa hùwà tó tọ́ nígbà gbogbo? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ olóòótọ́? A máa rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. Bákan náà, á jẹ́ ká rí bá a ṣe lè túbọ̀ pinnu pé àá máa hùwà tó tọ́ nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀.

^ ìpínrọ̀ 3 Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “dá ṣáṣá” nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹran jọra pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n máa ń lò fún kéèyàn jẹ́ oníwà títọ́ tàbí adúróṣinṣin.

^ ìpínrọ̀ 50 ÀWÒRÁN: Jóòbù ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá.

^ ìpínrọ̀ 52 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan kọ̀ láti wo àwòrán oníhòòhò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́.

^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan kọ̀ láti ra tẹlifíṣọ̀n ńlá tó wọ́n gan-an torí pé kò nílò rẹ̀, kò sì lówó rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan gbàdúrà, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Párádísè, ó sì ń ronú nípa ohun tó kà.