Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 13

Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

“Àánú wọn sì ṣe é . . . Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.”​—MÁÀKÙ 6:34.

ORIN 70 Ẹ Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Jésù tó ta yọ jù lọ? Kí ló mú kó o gbà bẹ́ẹ̀?

Ọ̀KAN lára àwọn ànímọ́ Jésù tó ta yọ jù lọ ni pé ó lóye bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn aláìpé. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó máa ń “yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀,” ó sì máa ń “sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn àádọ́rin (70) ọmọlẹ́yìn pa dà dé láti ibi tí wọ́n ti lọ wàásù, inú wọn dùn torí pé iṣẹ́ náà sèso rere, èyí sì mú kí Jésù “yọ̀ gidigidi nínú ẹ̀mí mímọ́.” (Lúùkù 10:17-21) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jésù rí bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣọ̀fọ̀ Lásárù, Bíbélì sọ pé “ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi, ìdààmú sì bá a.”​—Jòh. 11:33.

2. Kí ló mú kí Jésù lẹ́mìí ìgbatẹnirò?

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, ó máa ń ṣàánú àwọn èèyàn aláìpé, ó sì máa ń gba tiwọn rò. Kí nìdí? Ìdí pàtàkì kan ni pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó “fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” (Òwe 8:31) Ìfẹ́ yìí máa ń mú kó lóye báwa èèyàn ṣe ń ronú. Kódà, àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ó mọ ohun tó wà nínú èèyàn.” (Jòh. 2:25) Kò sí àní-àní pé àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe Jésù ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń tẹ́tí sí i. Táwa náà bá ń gba tàwọn èèyàn rò, ó dájú pé wọ́n á túbọ̀ máa tẹ́tí sí wa.​—2 Tím. 4:5.

3-4. (a) Irú ojú wo ló yẹ ká fi máa wo iṣẹ́ ìwàásù wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti wàásù, bó sì ṣe rí fáwa náà nìyẹn. (1 Kọ́r. 9:16) Àmọ́ tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tá a sì ń gba tiwọn rò, a ò ní ka iṣẹ́ ìwàásù sí ojúṣe lásán. Àá fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́ àti pé a fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. A mọ̀ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Tó bá jẹ́ irú ojú tá a fi ń wo iṣẹ́ ìwàásù wa nìyẹn, àá túbọ̀ gbádùn ẹ̀ gan-an.

4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àá rí bá a ṣe lè máa gba tàwọn èèyàn rò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àá kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe fàánú hàn sáwọn èèyàn. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.​—1 Pét. 2:21.

JÉSÙ GBA TÀWỌN ÈÈYÀN RÒ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Àánú mú kí Jésù sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn èèyàn (Wo ìpínrọ̀ 5 àti 6)

5-6. (a) Àwọn wo ni Jésù fẹ̀mí ìgbatẹnirò hàn sí? (b) Bí Àìsáyà 61:1, 2 ṣe sọ, kí nìdí tí Jésù fi káàánú àwọn tó wàásù fún?

5 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nípa bí Jésù ṣe gba tàwọn èèyàn rò. Nígbà kan, Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wàásù débi pé ó rẹ̀ wọ́n gan-an. “Kódà, wọn ò ráyè jẹun.” Torí náà, Jésù mú wọn ‘lọ síbi tó dá, tí àwọn nìkan máa wà, kí wọ́n lè sinmi díẹ̀.’ Àmọ́, èrò rẹpẹtẹ ti sáré lọ síbi tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń lọ. Nígbà tí Jésù débẹ̀ tó sì rí àwọn èèyàn náà, kí ló ṣe? Bíbélì sọ pé: “Àánú * wọn sì ṣe é, torí wọ́n dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.”​—Máàkù 6:30-34.

6 Kí nìdí tí àánú àwọn èèyàn náà fi ṣe Jésù? Ó kíyè sí i pé wọ́n “dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Bóyá Jésù rí àwọn kan lára wọn tó jẹ́ mẹ̀kúnnù tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ bí aago kí wọ́n lè pèsè fún ìdílé wọn. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn míì nínú wọn ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó kú. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wọn máa yé Jésù dáadáa. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó ṣeé ṣe kí Jésù náà ti kojú irú àwọn ìṣòro yìí rí. Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ àwọn míì máa ń jẹ Jésù lọ́kàn, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn.​—Ka Àìsáyà 61:1, 2.

7. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

7 Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù? Bíi ti Jésù, ọ̀pọ̀ àwọn tó yí wa ká ló dà bí “àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn,” onírúurú ìṣòro làwọn míì sì ń bá yí. Àmọ́, a ní ohun kan tó lè tù wọ́n nínú, ìyẹn sì ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Ìfi. 14:6) Torí náà bíi ti Ọ̀gá wa, à ń wàásù ìhìn rere torí pé ‘àánú àwọn aláìní àtàwọn tálákà’ máa ń ṣe wá. (Sm. 72:13) Ìdí nìyẹn tá a fi ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

BÁWO LA ṢE LÈ MÁA GBA TÀWỌN ÈÈYÀN RÒ?

Mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nílò (Wo ìpínrọ̀ 8 àti 9)

8. Kí lohun àkọ́kọ́ tá a lè ṣe láti fi ẹ̀mí ìgbatẹnirò hàn sáwọn tá à ń wàásù fún? Ṣàpèjúwe.

8 Kí ló máa jẹ́ ká lẹ́mìí ìgbatẹnirò fáwọn tá à ń wàásù fún? Ó yẹ ká fi ara wa sípò wọn, ká sì ṣe ohun tá a máa fẹ́ káwọn náà ṣe sí wa. * (Mát. 7:12) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́rin tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ronú nípa ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan nílò. A lè fi iṣẹ́ ìwàásù wa wé iṣẹ́ àwọn dókítà. Dókítà tó bá mọṣẹ́ dáadáa máa ń ronú nípa ohun tí aláìsàn kọ̀ọ̀kan nílò. Bí àpẹẹrẹ, á béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ ẹni tó ń ṣàìsàn, á sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí i bó ṣe ń ṣàlàyé ohun tó ń ṣe é. Dípò táá fi fún aláìsàn náà ní oògùn tó bá kọ́kọ́ sọ sí i lọ́kàn, ó lè ṣe àwọn àyẹ̀wò kan kó lè mọ irú àìsàn tó ń ṣe é gan-an. Lẹ́yìn náà lá wá fún un ní oògùn táá wò ó sàn. Lọ́nà kan náà, kò yẹ kó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan náà làá máa sọ fún gbogbo ẹni tá a bá pàdé lóde ẹ̀rí. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fara balẹ̀ kíyè sí ipò wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ ká lè mọ ohun tá a máa sọ.

9. Irú èrò wo ni kò yẹ ká ní tá a bá wà lóde ẹ̀rí? Ṣàlàyé.

9 Tó o bá pàdé ẹnì kan lóde ẹ̀rí, má ṣe ronú pé o ti mọ ohun tẹ́ni náà ń kojú àtohun tó gbà gbọ́. (Òwe 18:13) Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè fọgbọ́n lo àwọn ìbéèrè táá mú kó sọ èrò ẹ̀. (Òwe 20:5) O lè bi ẹni náà nípa iṣẹ́ rẹ̀, ìdílé rẹ̀ àtohun tó gbà gbọ́ tó bá jẹ́ pé wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lágbègbè yín. Tá a bá jẹ́ kí wọ́n sọ tọkàn wọn, ìyẹn á jẹ́ ká mọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn àtohun tí wọ́n nílò gan-an. Tá a bá sì ti mọ̀ ọ́n, ó yẹ ká sọ ohun tó máa tù wọ́n nínú bí Jésù náà ti ṣe.​—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 9:19-23.

Ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kẹ́ni tó ò ń wàásù fún máa bá yí (Wo ìpínrọ̀ 10 àti 11)

10-11. Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 4:7, 8, kí ni ọ̀nà kejì tá a lè gbà fi ìgbatẹnirò hàn? Sọ àpẹẹrẹ kan.

10 Ìkejì, fojú inú wo ohun tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa bá yí. Nígbà míì, ó ṣeé ṣe kí ohun tó ń ṣe wọ́n ti ṣe àwa náà rí. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tí kì í níṣòro torí pé aláìpé ni gbogbo wa. (1 Kọ́r. 10:13) A mọ̀ pé nǹkan ò rọrùn nínú ayé Sátánì, ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà lára wa. (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:7, 8.) Àmọ́ ẹ jẹ́ ká ronú nípa bó ṣe máa ṣòro tó fáwọn tí kò mọ Jèhófà láti fara da àwọn ìṣòro tó kúnnú ayé yìí. Bíi ti Jésù, àánú wọn máa ń ṣe wá, ìdí nìyẹn tá a fi ń ‘mú ìhìn rere nípa ohun tó sàn’ lọ fún wọn.​—Àìsá. 52:7.

11 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Sergey. Kí Sergey tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó máa ń tijú gan-an, kódà kì í rọrùn fún un láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sergey sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ, mo rí i pé, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn. Èrò mi ni pé mi ò ní lè ṣe é láé.” Àmọ́ bó ṣe ń ronú nípa àwọn tí ò tíì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó rí i pé àfi kí wọ́n mọ Jèhófà káyé wọn tó lè nítumọ̀. Ó tún sọ pé: “Àwọn ohun tuntun tí mò ń kọ́ ń fún mi láyọ̀, ó sì ń jẹ́ kí n ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Mo mọ̀ pé ó yẹ káwọn míì náà mọ̀ nípa òtítọ́ yìí.” Bí ire àwọn míì ṣe túbọ̀ ń jẹ Sergey lọ́kàn, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń nígboyà láti wàásù. Sergey wá fi kún un pé: “Sí ìyàlẹ́nu mi, ṣe ni mo túbọ̀ ń ní ìgboyà bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn. Ó tún jẹ́ kí àwọn ohun tuntun tí mò ń kọ́ yìí fẹsẹ̀ múlẹ̀ lọ́kàn mi.” *

Ó lè gba àkókò díẹ̀ káwọn kan tó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí (Wo ìpínrọ̀ 12 àti 13)

12-13. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní sùúrù fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? Ṣàpèjúwe.

12 Ìkẹta, máa ní sùúrù fáwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Ká rántí pé àwa la lóye àwọn òtítọ́ Bíbélì yìí, àmọ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè má gbọ́ àwọn òtítọ́ yẹn rí. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ti jingíri lọ́kàn wọn. Bákan náà, ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé ẹ̀sìn táwọn ń ṣe ló jẹ́ káwọn wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ìdílé wọn, kí àárín àwọn àtàwọn aládùúgbò wọn sì gún. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀sìn yẹn lè ti di ara àṣà ìbílẹ̀ wọn. Torí náà, báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

13 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí: Ká sọ pé afárá kan ti di àwókù, ó sì ti di ẹgẹrẹmìtì, ó dájú pé wọ́n máa ní láti kọ́ afárá tuntun. Àmọ́ lásìkò tí wọ́n ń kọ́ tuntun yẹn, wọ́n á ṣì máa lo èyí tó ti di àwókù náà. Ó dìgbà tí wọ́n bá parí tuntun yẹn kí wọ́n tó wó ti tẹ́lẹ̀. Lọ́nà kan náà, ká tó sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n pa ìgbàgbọ́ wọn àtijọ́ tì, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ kí wọ́n lóye òtítọ́ Bíbélì dáadáa kí wọ́n sì mọyì rẹ̀. Ìgbà yẹn ló máa tó rọrùn fún wọn láti pa ìgbàgbọ́ wọn àtijọ́ tì. Ká sòótọ́, ó lè gba àkókò káwọn èèyàn tó lè ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀.​—Róòmù 12:2.

14-15. Tá a bá pàdé àwọn tí kò mọ̀ pé àwa èèyàn máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.

14 Tá a bá ń mú sùúrù fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, a ò ní retí pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n á fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká gba tiwọn rò, ká sì fi sùúrù lo Ìwé Mímọ́ láti ṣàlàyé òtítọ́ fún wọn, èyí sì lè gba àkókò díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè ṣàlàyé fún ẹnì kan pé àwa èèyàn máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ òtítọ́ yìí, wọ́n lè rò pé téèyàn bá ti kú, ó parí nìyẹn. Àwọn míì sì rò pé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sọ́run. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

15 Arákùnrin kan sọ bó ṣe máa ń lo Ìwé Mímọ́ láti ṣàlàyé kókó yìí. Á kọ́kọ́ ka Jẹ́nẹ́sísì 1:28, á wá bi onílé pé ibo ni Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn máa gbé, báwo ló sì ṣe fẹ́ kí ìgbésí ayé wa rí. Ọ̀pọ̀ máa ń sọ pé, “Ó fẹ́ ká máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn ìyẹn, arákùnrin náà á ka Àìsáyà 55:11, á wá bi onílé bóyá ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ti yí pa dà. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á dáhùn pé rárá. Paríparí ẹ̀, arákùnrin náà á ka Sáàmù 37:10, 11, á sì bi onílé pé báwo ni nǹkan ṣe máa rí fáwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Bó ṣe ń lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà yìí ti mú kó ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti rí i pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn rere gbádùn títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

Ohun tó dà bíi pé kò jọjú tá a bá ṣe lè sèso rere, irú bíi ká fi lẹ́tà ránṣẹ́ sẹ́ni tó nílò ìtùnú (Wo ìpínrọ̀ 16 àti 17)

16-17. Òwe 3:27 ṣe sọ, àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé a gba tàwọn èèyàn rò? Sọ àpẹẹrẹ kan.

16 Ìkẹrin, ṣe àwọn nǹkan táá fi hàn pé o gba tàwọn èèyàn rò. Bí àpẹẹrẹ, a lè dé ọ̀dọ̀ ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ká sì rí i pé ó ń sùn tàbí pé ọwọ́ rẹ̀ dí. A lè sọ pé kó má bínú pé a wá lásìkò tí kò rọrùn fún un, ká sì ṣètò láti pa dà wá. Yàtọ̀ síyẹn, ẹni náà lè máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan lọ́wọ́, kó sì nílò ìrànlọ́wọ́. Ó sì lè jẹ́ pé ṣe lara ẹ̀ ò yá, kó sì máa wá ẹni táá rán níṣẹ́. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, a lè ran ẹni náà lọ́wọ́.​—Ka Òwe 3:27.

17 Arábìnrin kan ṣe ohun tó dà bíi pé kò jọjú àmọ́ tó sèso rere. Nígbà tó gbọ́ pé ìdílé kan pàdánù ọmọ wọn, àánú wọn ṣe é, ó sì kọ lẹ́tà sí wọn. Nínú lẹ́tà yẹn, ó kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táá tù wọ́n nínú síbẹ̀. Báwo ni lẹ́tà yẹn ṣe rí lára ìdílé náà? Ìyá ọmọ tó kú náà sọ pé: “Ọkàn mi gbọgbẹ́ gan-an lánàá. Àmọ́ nígbà tá a ka lẹ́tà yẹn, ó tù wá nínú gan-an, kódà a ò lè ṣàlàyé bó ṣe tù wá nínú tó. Mi ò mọ bí mo ṣe lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, àkàtúnkà ni mo kà á lánàá, kódà á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún (20) ìgbà. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ tù mí lára gan-an, ó sì jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀. A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ rẹ.” Kò sí àní-àní pé, táwa náà bá ń fi ara wa sípò àwọn tó ń jìyà tá a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ìsapá wa á sèso rere.

ṢE IPA TÌRẸ, KÓ O SÌ NÍ ÈRÒ TÓ TỌ́

18. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?

18 Ká fi sọ́kàn pé àwa kọ́ la máa pinnu bóyá ẹnì kan máa wá sínú òtítọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. A lè ṣe ipa tiwa láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, àmọ́ Jèhófà ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù. (Ka 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.) Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jòh. 6:44) Láìka gbogbo ìsapá wa, ohun tó wà lọ́kàn kálukú ló máa pinnu bóyá ó máa sin Jèhófà tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 13:4-8) Ká má gbàgbé pé Jésù ni Olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ jù, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ni kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Torí náà, kò yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn tá à ń wàásù fún bá kọtí ikún sọ́rọ̀ wa.

19. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gba tàwọn èèyàn rò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

19 Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú ká máa gba tàwọn èèyàn rò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Lára ẹ̀ ni pé àwa fúnra wa máa túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ náà, àá sì rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni. Yàtọ̀ síyẹn, á túbọ̀ rọrùn fáwọn “olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ìṣe 13:48) Torí náà, “nígbà tí a bá ti láǹfààní rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ṣe rere fún gbogbo èèyàn.” (Gál. 6:10) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa láyọ̀ bá a ṣe ń mú ìyìn bá Jèhófà Baba wa ọ̀run.​—Mát. 5:16.

ORIN 64 À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà

^ ìpínrọ̀ 5 Tá a bá ń gba tàwọn míì rò, a máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, iṣẹ́ wa á sì sèso rere. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù, a sì tún máa jíròrò ohun mẹ́rin tá a lè ṣe táá fi hàn pé à ń gba tàwọn èèyàn rò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

^ ìpínrọ̀ 5 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Bí wọ́n ṣe lo àánú nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ìmọ̀lára fún ẹnì kan tó ń jìyà tàbí tí wọ́n ti fojú ẹ̀ rí màbo. Irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 8 Wo àpilẹ̀kọ náà “Máa Fi Ìlànà Pàtàkì Náà Sílò Lóde Ẹ̀rí” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2014.