Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 10

Kí Ló Ń Dá Mi Dúró Láti Ṣèrìbọmi?

Kí Ló Ń Dá Mi Dúró Láti Ṣèrìbọmi?

‘Fílípì àti ìwẹ̀fà náà wọ inú omi, Fílípì sì ṣèrìbọmi fún un.’​—ÌṢE 8:38.

ORIN 52 Ìyàsímímọ́ Kristẹni

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Ádámù àti Éfà pàdánù, kí lèyí sì yọrí sí?

TA LO rò pé ó yẹ kó máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fáwa èèyàn? Ó dájú pé Jèhófà ni. Àmọ́, nígbà tí Ádámù àti Éfà jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, ṣe ni wọ́n jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn ò fẹ́ kí Jèhófà máa ṣàkóso àwọn àti pé àwọn á máa fúnra àwọn pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Jẹ́n. 3:22) Àmọ́, ẹ wo adúrú nǹkan tí wọ́n pàdánù torí ìpinnu tí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n pàdánù àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà. Wọ́n tún pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn sì tipa bẹ́ẹ̀ jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12) Kò sí àní-àní pé àjálù gbáà ni ìpinnu tí Ádámù àti Éfà ṣe yọrí sí.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí ìwẹ̀fà ará Etiópíà gba Jésù gbọ́ ló ṣèrìbọmi (Wo ìpínrọ̀ 2 àti 3)

2-3. (a) Kí ni ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan ṣe nígbà tí Fílípì wàásù fún un? (b) Àwọn ìbùkún wo là ń rí torí pé a ṣèrìbọmi, àwọn ìbéèrè wo la sì máa jíròrò?

2 Ohun tí ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan ṣe nígbà tí Fílípì wàásù fún un yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe. Ìwẹ̀fà náà mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún un débi pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣèrìbọmi. (Ìṣe 8:34-38) Táwa náà bá ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, tá a sì ṣèrìbọmi bíi ti ìwẹ̀fà yẹn, ṣe là ń jẹ́ kó hàn kedere pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa. A tún ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a sì gbà pé òun ló yẹ kó máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fún wa.

3 Mélòó la fẹ́ kà nínú àwọn ìbùkún tá à ń gbádùn báyìí àtèyí tá a máa gbádùn torí pé à ń sin Jèhófà! Bí àpẹẹrẹ, a láǹfààní láti gbádùn gbogbo ohun tí Ádámù àti Éfà pàdánù, títí kan ìyè àìnípẹ̀kun. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà máa ń dárí jì wá torí pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, ó sì ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Mát. 20:28; Ìṣe 10:43) Bákan náà, a tún wà lára ìdílé Ọlọ́run tó máa gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 10:14-16; Róòmù 8:20, 21) Láìfi gbogbo nǹkan yìí pè, àwọn kan wà tó ti mọ Jèhófà síbẹ̀ tí wọ́n ń fà sẹ́yìn láti ya ara wọn sí mímọ́ fún un. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kẹ́nì kan máa fà sẹ́yìn láti ṣèrìbọmi? Kí ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì lè ṣe láti borí àwọn ìṣòro náà?

OHUN TÓ Ń MÚ KÁWỌN KAN FÀ SẸ́YÌN LÁTI ṢÈRÌBỌMI

Ìṣòro táwọn kan kojú kí wọ́n tó pinnu láti ṣèrìbọmi

Kéèyàn Máa Ṣiyèméjì Pé Òun Ò Tóótun (Wo ìpínrọ̀ 4 àti 5) *

4-5. Ìṣòro wo ni Avery àti Hannah ní?

4 Kéèyàn máa ṣiyèméjì pé òun ò tóótun. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Avery. Alàgbà ni bàbá rẹ̀, bàbá yìí fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe rẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an. Síbẹ̀, ẹrù ń ba Avery láti ṣèrìbọmi. Kí nìdí? Avery sọ pé: “Mo máa ń ronú pé mi ò lè dà bíi dádì mi.” Avery ò gbà pé òun á lè ṣe àwọn ojúṣe téèyàn máa ń ní lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi. Ó sọ pé: “Mi ò rò pé màá lè máa ṣáájú àwọn ará nínú àdúrà, ká má tíì sọ pé kí n sọ àsọyé tàbí kí n kó àwọn ará lọ sóde ẹ̀rí.”

5 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Hannah, àmọ́ ó gbà pé òun ò wúlò rárá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí tó tọ́ ọ dàgbà, síbẹ̀ ó máa ń ronú pé bóyá lòun á lè ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́. Kí nìdí? Hannah máa ń ro ara ẹ̀ pin, kódà nígbà míì ó máa ń dìídì ṣe ara ẹ̀ léṣe, ìyẹn sì máa ń mú kí ìṣòro náà burú sí i. Hannah sọ pé: “Mi ò sọ ohun tí mo máa ń ṣe fún ẹnikẹ́ni rí, títí kan àwọn òbí mi. Mo sì máa ń ronú pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ mi láé torí ohun tí mò ń ṣe síra mi.”

Àwọn Téèyàn Ń Bá Ṣọ̀rẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 6) *

6. Kí ló mú kó ṣòro fún Vanessa láti ṣèrìbọmi?

6 Àwọn téèyàn ń bá ṣọ̀rẹ́. Ọmọ ọdún méjìlélógún (22) ni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Vanessa. Ó sọ pé: “Mo ní ọ̀rẹ́ kan tá a ti mọra fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ wa sì wọ̀ gan-an.” Àmọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí ò fẹ́ kó ṣèrìbọmi, ìyẹn ò sì dùn mọ́ Vanessa nínú. Ó wá sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti bá àwọn míì ṣọ̀rẹ́, ẹ̀rù sì ń bà mí pé tí àárín wa bá dàrú, mi ò ní rẹ́ni fojú jọ mọ́.”

Ìbẹ̀rù Pé Èèyàn Lè Ṣàṣìṣe (Wo ìpínrọ̀ 7) *

7. Kí ló ń ba Makayla lẹ́rù, kí sì nìdí?

7 Ìbẹ̀rù pé èèyàn lè ṣàṣìṣe. Ọmọ ọdún márùn-ún ni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Makayla nígbà tí wọ́n yọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́gbẹ́. Bó ṣe ń dàgbà, ó rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ba àwọn òbí wọn nínú jẹ́ gan-an. Makayla sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà mí pé tí mo bá ṣèrìbọmi, mo lè ṣàṣìṣe táá mú kí wọ́n yọ mí lẹ́gbẹ́, ìbànújẹ́ tí èyí sì máa fà fáwọn òbí mi á kọjá àfẹnusọ.”

Ìbẹ̀rù Inúnibíni (Wo ìpínrọ̀ 8) *

8. Kí ló ba Miles lẹ́rù?

8 Ìbẹ̀rù inúnibíni. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni bàbá Miles àmọ́ ìyá rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ti kọ ara wọn sílẹ̀. Miles wá sọ pé: “Ọdún méjìdínlógún (18) ni mo fi gbé lọ́dọ̀ ìyá mi, àyà mi sì ń já láti sọ fún wọn pé mo fẹ́ ṣèrìbọmi. Mo rántí ohun tí wọ́n fojú bàbá mi rí nígbà tí wọ́n di Ẹlẹ́rìí. Ẹ̀rù sì ń bà mí pé wọ́n á fojú èmi náà rí màbo.”

BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN ÌṢÒRO NÁÀ

9. Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ onísùúrù àti Ọlọ́run ìfẹ́, kí nìyẹn máa mú kó o ṣe?

9 Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà torí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú. Síbẹ̀, Jèhófà gbà wọ́n láyè láti bímọ kí wọ́n sì fúnra wọn pinnu bí wọ́n á ṣe tọ́ àwọn ọmọ wọn. Àmọ́ kò pẹ́ tó fi hàn pé ìwà agọ̀ gbáà ni wọ́n hù bí wọ́n ṣe kẹ̀yìn sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àkọ́bí wọn pa àbúrò rẹ̀, nígbà tó sì yá, ìwà ipá àti ìmọtara-ẹni-nìkan gbilẹ̀ láyé. (Jẹ́n. 4:8; 6:11-13) Bó ti wù kó rí, Jèhófà ti ṣètò ọ̀nà àbáyọ fún àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó bá jọ́sìn òun. (Jòh. 6:38-40, 57, 58) Bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ onísùúrù àti Ọlọ́run ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ. Ìyẹn á sì mú kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà dípò ko o kẹ̀yìn sí i bíi ti Ádámù àti Éfà.

Bó o ṣe lè borí àwọn ìṣòro náà

(Wo ìpínrọ̀ 9 àti 10) *

10. Tó o bá ṣàṣàrò lórí Sáàmù 19:7, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó o pinnu láti sin Jèhófà?

10 Túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ dá ẹ lójú pé o lè sìn ín láìyẹsẹ̀. Avery tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí mo ka ìlérí tó wà nínú Sáàmù 19:7, tí mo sì ṣàṣàrò lórí rẹ̀, ó dá mi lójú pé èmi náà á lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.” (Kà á.) Nígbà tí Avery rí bí Jèhófà ṣe mú ìlérí inú Sáàmù yẹn ṣẹ, ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀. Téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á túbọ̀ nígboyà, á sì jẹ́ kó pinnu láti fayé rẹ̀ sìn ín. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú Hannah tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, ó ní: “Bí mo ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ kí n rí i pé ó máa ń dun Jèhófà bí mo ṣe ń ṣe ara mi léṣe.” (1 Pét. 5:7) Nígbà tó yá, Hannah bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tó ń kọ́ sílò. (Jém. 1:22) Kí wá ló yọrí sí? Ó ní: “Àǹfààní tí mò ń rí bí mo ṣe ń ṣègbọràn sí Jèhófà mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ní báyìí, ó dá mi lójú pé Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́ nígbàkigbà tí mo bá nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀.” Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Hannah jáwọ́ nínú ṣíṣe ara ẹ̀ léṣe, ó ya ara ẹ̀ sí mímọ́, ó sì ṣèrìbọmi.

(Wo ìpínrọ̀ 11) *

11. Kí ni Vanessa ṣe kó tó lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, kí nìyẹn sì kọ́ wa?

11 Fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nígbà tí Vanessa tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rí i pé ọ̀rẹ́ òun ni ò jẹ́ kó rọrùn fún òun láti sin Jèhófà, ṣe ló fi ọ̀rẹ́ yẹn sílẹ̀. Àmọ́ kò fi mọ síbẹ̀, ó tún sapá láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun nínú ìjọ. Ó sọ pé àpẹẹrẹ Nóà àti ìdílé rẹ̀ ló ran òun lọ́wọ́. Ó ní: “Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣera wọn lọ́kan, wọn ò sì bá àwọn ẹni ibi tó yí wọn ká ṣọ̀rẹ́.” Lẹ́yìn tí Vanessa ṣèrìbọmi, ó di aṣáájú-ọ̀nà. Ó wá sọ pé: “Iṣẹ́ yìí ti jẹ́ kí n láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ nínú ìjọ mi àti láwọn ìjọ míì pẹ̀lú.” Tíwọ náà bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa, ó dájú pé wàá ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́.​—Mát. 24:14.

(Wo ìpínrọ̀ 12 sí 15) *

12. Ìbẹ̀rù wo ni Ádámù àti Éfà kò ní, kí lèyí sì yọrí sí?

12 Máa ní ìbẹ̀rù tó tọ́. Ìbẹ̀rù máa ń ṣe wá láǹfààní nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá bẹ̀rù Jèhófà, a ò ní ṣe ohun tí kò nífẹ̀ẹ́ sí. (Sm. 111:10) Ká sọ pé Ádámù àti Éfà bẹ̀rù Ọlọ́run ni, wọn ò ní ṣọ̀tẹ̀ sí i. Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá rí i pé àwọn ti ṣẹ̀. Torí náà, kò sí nǹkan míì táwọn ọmọ wọn lè jogún lára wọn ju ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú lọ. Nígbà tó ṣe kedere sí wọn pé àwọn ti ṣẹ̀ sí Jèhófà, ojú tì wọ́n débi pé ṣe ni wọ́n wá nǹkan fi bo ìhòòhò wọn.​—Jẹ́n. 3:7, 21.

13-14. (a) Bí 1 Pétérù 3:21 ṣe sọ, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù ikú? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

13 Ó ṣe pàtàkì pé ká bẹ̀rù Ọlọ́run, àmọ́ kò sídìí kankan tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù ikú. Ìdí ni pé Jèhófà ti ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun fún wa. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa dárí jì wá torí pé a nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a nígbàgbọ́ ni pé ká ya ara wa sí mímọ́, ká sì ṣèrìbọmi.​—Ka 1 Pétérù 3:21.

14 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ṣe fún wa tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ń fún wa lọ́pọ̀ nǹkan tá à ń gbádùn lójoojúmọ́, ó sì jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa òun àtohun tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 8:​31, 32) Ó tún ṣètò ìjọ Kristẹni ká lè máa rí ìtọ́sọ́nà àti ìrànwọ́ gbà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń bá wa gbé àwọn ìṣòro wa, ó sì ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun fún wa lọ́jọ́ iwájú. (Sm. 68:19; Ìfi. 21:3, 4) Tá a bá ń ronú lórí gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, àwa náà á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ ká bẹ̀rù rẹ̀, a ò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa dùn ún.

15. Kí ló mú kí Makayla borí ìbẹ̀rù tó ní pé òun lè ṣàṣìṣe?

15 Makayla tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan borí ìbẹ̀rù tó ní pé òun lè ṣàṣìṣe nígbà tó ronú nípa bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini. Ó ní: “Mo mọ̀ pé gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe torí pé aláìpé ni wá. Àmọ́ mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ṣe tán láti dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù.” Ìfẹ́ tí Makayla ní fún Jèhófà mú kó ya ara ẹ̀ sí mímọ́ kó sì ṣèrìbọmi.

(Wo ìpínrọ̀ 16) *

16. Kí ló mú kí Miles borí ìbẹ̀rù rẹ̀?

16 Miles tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ bá alábòójútó àyíká pé kó ran òun lọ́wọ́. Ó wá sọ pé: “Mo gbà pé ọ̀rọ̀ mi máa yé alábòójútó àyíká wa torí pé ìyá tiwọn náà kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ ohun tí màá sọ kí ìyá mi lè mọ̀ pé èmi fúnra mi ni mo pinnu pé màá ṣèrìbọmi kì í ṣe bàbá mi ló ń tì mí.” Bó ti wù kó rí, ọ̀rọ̀ yẹn ò bọ́ síbi tó dáa lára ìyá rẹ̀. Fún ìdí yìí, Miles fi ilé sílẹ̀ kó lè ṣèrìbọmi. Ó wá sọ pé: “Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣe fún mi, tí mo sì ń ronú nípa ìràpadà tí Jésù san jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi gan-an. Ìyẹn ló jẹ́ kí n ya ara mi sí mímọ́ kí n sì ṣèrìbọmi.”

DÚRÓ LÓRÍ ÌPINNU RẸ

A lè fi hàn pé a mọyì àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń ṣe fún wa (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Àǹfààní wo ni gbogbo wa ní?

17 Nígbà tí Éfà jẹ èso igi tí Ọlọ́run ní kí wọ́n má jẹ, ṣe ló kọ Jèhófà ní Baba. Nígbà tí Ádámù náà jẹ èso yẹn, ó fi hàn pé aláìmoore lòun, torí kò mọyì gbogbo nǹkan tí Jèhófà ṣe fún un. Ìbéèrè náà ni pé ṣé àwa ní tiwa máa fi hàn pé a moore àti pé a mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wa? Tá a bá ya ara wa sí mímọ́ tá a sì ṣèrìbọmi, ṣe là ń fi hàn pé a gba Jèhófà ní Ọba Aláṣẹ tó lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run, a sì fọkàn tán an.

18. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ ṣàṣeyọrí?

18 Lẹ́yìn tá a bá ṣèrìbọmi, ohun tó kàn ni pé ká máa sapá láti fi ìlànà Jèhófà sílò lójoojúmọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìbọ́hùn. Kó o lè ṣàṣeyọrí, o gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Bákan náà, máa wà pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kó o sì máa fìtara kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́. (Héb. 10:24, 25) Yàtọ̀ síyẹn, jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ ẹ sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ nígbàkigbà tó o bá fẹ́ ṣèpinnu. (Àìsá. 30:21) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá ṣàṣeyọrí.​—Òwe 16:3, 20.

19. Kí ló yẹ kó o máa kíyè sí, kí sì nìdí?

19 Tó o bá ń kíyè sí bí àwọn ìlànà Jèhófà ṣe ń ṣe ẹ́ láǹfààní, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ á túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí ètekéte Sátánì táá mú kó o fi Jèhófà sílẹ̀ láé. Wo bó ṣe máa rí lára rẹ ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan sí àkókò tá a wà yìí. Bó o ṣe ń ronú pa dà sẹ́yìn, ó dájú pé inú rẹ máa dùn pé o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o sì ṣèrìbọmi.

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

^ ìpínrọ̀ 5 O lè máa ronú pé ṣé kó o ṣèrìbọmi tàbí kó o má ṣèrìbọmi? Èyí ni ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o máa ṣe láyé rẹ. Kí ló mú kọ́rọ̀ yìí ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. A tún máa jíròrò àwọn nǹkan tó lè mú kẹ́nì kan máa fà sẹ́yìn láti ṣèrìbọmi, àá sì rí àwọn nǹkan táá mú kó borí àwọn ìṣòro náà.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Iyèméjì: Ẹ̀rù ń ba ọ̀dọ́kùnrin kan láti dáhùn nípàdé.

^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Àwọn Ọ̀rẹ́: Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan ń kó ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́, torí náà ojú tì í nígbà tó rí àwọn Ẹlẹ́rìí míì.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Àṣìṣe: Ọ̀dọ́bìnrin kan ń ronú pé òun ò ní lè sin Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n yọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́gbẹ́ tó sì fi ilé sílẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Inúnibíni: Ẹ̀rù ń ba ọ̀dọ́kùnrin kan láti gbàdúrà níwájú ìyá rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.

^ ìpínrọ̀ 65 ÀWÒRÁN: Iyèméjì: Ọ̀dọ́kùnrin kan jára mọ́ ìdákẹ́kọ̀ọ́.

^ ìpínrọ̀ 67 ÀWÒRÁN: Àwọn Ọ̀rẹ́: Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan ń fìgboyà wàásù.

^ ìpínrọ̀ 69 ÀWÒRÁN: Àṣìṣe: Ọ̀dọ́bìnrin kan túbọ̀ mọyì òtítọ́, ó sì ṣèrìbọmi

^ ìpínrọ̀ 71 ÀWÒRÁN: Inúnibíni: ọ̀dọ́kùnrin kan fìgboyà ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún ìyá rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.