Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 11

Fetí sí Ohùn Jèhófà

Fetí sí Ohùn Jèhófà

“Èyí ni Ọmọ mi . . . Ẹ fetí sí i.”​—MÁT. 17:5.

ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

JÈHÓFÀ fẹ́ràn àtimáa bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀. Láyé àtijọ́, ó lo àwọn wòlíì, àwọn áńgẹ́lì àti Jésù Kristi ọmọ rẹ̀ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. (Émọ́sì 3:7; Gál. 3:19; Ìfi. 1:1) Àmọ́ lónìí, Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó fún wa ní Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun ká sì mọ àwọn ìlànà òun.

2 Nígbà tí Jésù wà láyé, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run. Ní báyìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ àti ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́. Àá tún jíròrò ohun tá a lè ṣe ká lè jàǹfààní nínú ohun tó sọ.

“ÌWỌ NI ỌMỌ MI, ÀYÀNFẸ́”

3. Bó ṣe wà nínú Máàkù 1:9-11, kí ni Jèhófà sọ nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́ta wo ló sì ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ náà?

3 Máàkù 1:9-11 ròyìn ìgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run. (Kà á.) Jèhófà sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.” Ẹ wo bí inú Jésù ti máa dùn tó nígbà tó gbọ́ bí Baba rẹ̀ ṣe fi í lọ́kàn balẹ̀, tó sì fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀! Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Jésù. Àkọ́kọ́, Ọmọ òun ni Jésù. Ìkejì, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Ẹ̀kẹta sì ni pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gbà á. Ẹ jẹ́ ká wá yàn-nà-ná ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn báyìí.

4. Àjọṣe tuntun wo ni Jésù ní pẹ̀lú Ọlọ́run nígbà tó ṣèrìbọmi?

4 “Ìwọ ni Ọmọ mi.” Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí fi hàn pé Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ àjọṣe tuntun pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run. Kò sí àní-àní pé ọmọ Ọlọ́run ni Jésù nígbà tó wà lọ́run. Àmọ́ nígbà tó ṣèrìbọmi, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án. Ọlọ́run tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Ọmọ tí òun fi ẹ̀mí yàn ni Jésù, èyí sì fi hàn pé Jésù nírètí láti pa dà sí ọ̀run kó sì di Ọba àti Àlùfáà Àgbà tí Ọlọ́run yàn. (Lúùkù 1:31-33; Héb. 1:8, 9; 2:17) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ nígbà ìrìbọmi Jésù pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi.”​—Lúùkù 3:22.

Orí wa máa ń wú táwọn èèyàn bá gbóríyìn fún wa tí wọ́n sì fún wa níṣìírí (Wo ìpínrọ̀ 5) *

5. Báwo la ṣe lè máa fìfẹ́ hàn, ká sì máa gbóríyìn fáwọn míì bíi ti Jèhófà?

5 ‘Ìwọ ni àyànfẹ́.’ Àpẹẹrẹ gidi ni Jèhófà fi lélẹ̀ tó bá di pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn ká sì máa gbóríyìn fún wọn. (Jòh. 5:20) Orí wa máa ń wú táwọn tó sún mọ́ wa bá fìfẹ́ hàn sí wa tí wọ́n sì yìn wá fún nǹkan rere tá a ṣe. Bákan náà, inú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin àtàwọn ìdílé wa máa dùn tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn tá a sì ń fún wọn níṣìírí. Tá a bá ń gbóríyìn fáwọn èèyàn, á mú kí wọ́n túbọ̀ fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Jèhófà, ìgbàgbọ́ wọn á sì lágbára sí i. Ó ṣe pàtàkì káwọn òbí máa gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn. Tẹ́yin òbí bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn, tẹ́ ẹ sì ń fìfẹ́ hàn sí wọn, wọ́n á túbọ̀ máa ṣe dáadáa.

6. Kí nìdí tá a fi lè fọkàn tán Jésù Kristi?

6 “Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.” Gbólóhùn yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà fọkàn tán Jésù pé ó máa ṣe ìfẹ́ òun láìbọ́hùn. Torí pé Jèhófà fọkàn tán Ọmọ rẹ̀, ó yẹ káwa náà fọkàn tán Jésù láìsí iyèméjì pé ó máa mú gbogbo ìlérí Jèhófà ṣẹ. (2 Kọ́r. 1:20) Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, àá túbọ̀ pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀ ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà fọkàn tán Jésù, ó tún fọkàn tán àwa èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ pé a ò ní yẹsẹ̀ bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọmọ òun.​—1 Pét. 2:21.

“Ẹ FETÍ SÍ I”

7. Bó ṣe wà nínú Mátíù 17:1-5, ìgbà míì wo ni Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run, kí sì lohun tó sọ?

7 Ka Mátíù 17:​1-5. Ìgbà tí Jésù ‘yí pa dà di ológo’ ni ìgbà kejì tí Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run. Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tó lọ sórí òkè ńlá kan. Ibẹ̀ ni wọ́n wà nígbà tí wọ́n rí ìran kan tó kàmàmà. Wọ́n rí i tí ojú Jésù ń tàn yanran, tí aṣọ rẹ̀ sì ń kọ mànà. Wọ́n tún kíyè sí àwọn méjì kan tó ṣàpẹẹrẹ Mósè àti Èlíjà tí wọ́n ń bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa ikú àti àjíǹde rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “oorun ń kun” àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta náà gidigidi, nígbà tí oorun dá lójú wọn, wọ́n rí ìran àgbàyanu náà. (Lúùkù 9:29-32) Lẹ́yìn ìyẹn, ìkùukùu tó mọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, wọ́n sì gbọ́ ohùn Ọlọ́run fúnra rẹ̀! Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, Jèhófà sọ pé òun tẹ́wọ́ gba Ọmọ òun àti pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Jèhófà fi kún un pé: “Ẹ fetí sí i.”

8. Àǹfààní wo ni ìran yẹn ṣe Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

8 Ìran yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé ògo àti agbára Jésù máa kàmàmà nígbà tó bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Kò sí àní-àní pé ìran yẹn fún Jésù lókun, ó sì mú kó gbára dì fún ikú oró tó máa kú. Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ túbọ̀ lágbára, ó sì fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè fara da àdánwò, kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣeyọrí. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa ìran ológo yẹn, ìyẹn sì fi hàn pé ìran náà ṣì wà lọ́kàn rẹ̀ digbí, kò gbàgbé rárá.​—2 Pét. 1:16-18.

9. Àwọn ìmọ̀ràn wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

9 “Ẹ fetí sí i.” Ó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ ká máa fetí sí Ọmọ òun, ká sì máa ṣègbọràn sí i. Àwọn nǹkan wo ni Jésù sọ nígbà tó wà láyé? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sọ tó yẹ ká fetí sí. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, léraléra ló sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wà lójúfò. (Mát. 24:42; 28:19, 20) Ó tún gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa sa gbogbo ipá wọn, kí wọ́n má sì jẹ́ kó sú wọn. (Lúùkù 13:24) Jésù tẹnu mọ́ ọn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n ṣera wọn lọ́kan, kí wọ́n sì máa pa àṣẹ òun mọ́. (Jòh. 15:10, 12, 13) Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wúlò gan-an! Bó ṣe wúlò nígbà yẹn náà ló ṣe wúlò títí dòní.

10-11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fetí sí Jésù?

10 Jésù sọ pé: “Gbogbo ẹni tó bá fara mọ́ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.” (Jòh. 18:37) A lè fi hàn pé à ń fetí sí ohùn Jésù tá a bá ń ‘fara dà á fún ara wa, tá a sì ń dárí ji ara wa fàlàlà.’ (Kól. 3:13; Lúùkù 17:3, 4) Ọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé à ń fetí sí Jésù ni pé ká máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní àkókò tó rọrùn àti ní àkókò tí kò rọrùn.”​—2 Tím. 4:2.

11 Jésù sọ pé: “Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi.” (Jòh. 10:27) Kì í ṣe pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń fetí sí ohùn rẹ̀ nìkan ni, wọ́n tún ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò. Wọn kì í jẹ́ kí “àníyàn ìgbésí ayé” gbà wọ́n lọ́kàn. (Lúùkù 21:34) Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe máa pa àṣẹ Jésù mọ́ ló jẹ wọ́n lógún kódà lásìkò tí nǹkan nira. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fara da àdánwò tó lékenkà, irú bí àtakò tó gbóná janjan, ipò òṣì àti àjálù. Síbẹ̀, wọ́n gbà pé bíná ń jó bíjì ń jà, ìfẹ́ Jèhófà làwọn máa ṣe. Jésù fi àwọn ará wa yìí lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní àwọn àṣẹ mi, tó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi. Lọ́wọ́ kejì, ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ mi, Baba mi máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”​—Jòh. 14:21.

Iṣẹ́ ìwàásù ń mú ká máa fetí sí ohùn Jésù (Wo ìpínrọ̀ 12) *

12. Kí lohun míì tá a lè ṣe láti fi hàn pé à ń fetí sí Jésù?

12 Ohun míì tá a lè ṣe láti fi hàn pé à ń fetí sí Jésù ni pé ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń múpò iwájú. (Héb. 13:7, 17) Onírúurú àtúnṣe ni ètò Ọlọ́run ti ṣe láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣàtúnṣe sí àwọn ohun tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àtọ̀nà tá à ń gbà wàásù. Bákan náà, wọ́n ṣàtúnṣe sí bá a ṣe ń ṣe ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa àti bá a ṣe ń bójú tó wọn. A mà dúpẹ́ o fún àwọn ìtọ́ni tó bọ́gbọ́n mu tó sì fìfẹ́ hàn yẹn! Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa gan-an tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò rẹ̀ ń fún wa.

13. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fetí sí Jésù?

13 Àá jàǹfààní gan-an tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ Jésù sílò. Jésù fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa tù wọ́n lára. Ó ní: “Ara sì máa tù yín. Torí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:28-30) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ apá kan rẹ̀ ń tù wá lára. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń sọ agbára wa dọ̀tun, ó sì ń mú ká di ọlọ́gbọ́n. (Sm. 19:7; 23:3) Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”​—Lúùkù 11:28.

‘MÀÁ ṢE ORÚKỌ MI LÓGO’

14-15. (a) Bó ṣe wà nínú Jòhánù 12:27, 28, ìgbà wo ni ẹ̀ẹ̀kẹta tí Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run? (b) Kí ló jẹ́ ká gbà pé ọ̀rọ̀ yẹn máa tu Jésù nínú, á sì fún un lókun?

14 Ka Jòhánù 12:27, 28. Ìhìn Rere Jòhánù ròyìn ìgbà kẹta tí Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run. Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ mélòó kan ṣáájú ikú rẹ̀ kó lè ṣàjọyọ̀ Ìrékọjá fúngbà ìkẹyìn. Níbẹ̀, ó sọ pé: “Ìdààmú bá mi.” Ẹ̀yìn náà ló gbàdúrà pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Jèhófà sì dá a lóhùn látọ̀run pé: “Mo ti ṣe é lógo, màá sì tún ṣe é lógo.”

15 Kí nìdí tí Jésù fi ní ìdààmú ọkàn? Ó mọ̀ pé wọ́n máa tó fìyà burúkú jẹ òun, wọ́n á sì pa òun ní ìpa ìka. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òun gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. (Mát. 26:38) Àmọ́ ohun tó jẹ ẹ́ lọ́kàn jù ni bó ṣe máa ṣe orúkọ Baba rẹ̀ lógo. Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, Jésù sì ronú pé tí wọ́n bá pa òun lórí ẹ̀sùn yìí, ó ṣeé ṣe kíyẹn kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Àmọ́ Jèhófà fi í lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ẹ wo bọ́rọ̀ yẹn ṣe máa múnú Jésù dùn tó! Jèhófà mú kó dá a lójú pé dípò tí ikú rẹ̀ á fi kó ẹ̀gàn bá orúkọ òun, ṣe ló máa ṣe orúkọ òun lógo. Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ yẹn máa tu Jésù nínú gan-an, á sì fún un lókun láti fara da ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù nìkan ló lóye ọ̀rọ̀ tí Baba rẹ̀ sọ nígbà yẹn, síbẹ̀ Jèhófà rí i dájú pé ọ̀rọ̀ náà wà lákọọ́lẹ̀ fún wa.​—Jòh. 12:29, 30.

Jèhófà máa ṣe orúkọ rẹ̀ lógo, á sì gba àwọn èèyàn rẹ̀ là (Wo ìpínrọ̀ 16) *

16. Kí làwọn èèyàn ń ṣe nípa orúkọ Ọlọ́run tó lè máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa?

16 Bíi ti Jésù, ó lè máa dun àwa náà pé àwọn èèyàn ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fojú pọ́n wa láìṣẹ̀ láìrò. Ó sì lè jẹ́ irọ́ táwọn alátakò ń pa mọ́ wa ló ń kó ìdààmú ọkàn bá wa. A lè máa ṣàníyàn pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ yìí máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà á sì tàbùkù sí ètò rẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún ọmọ rẹ̀ máa tù wá nínú gan-an. Tá a bá fi ohun tí Jèhófà sọ sọ́kàn, a ò ní jẹ́ káwọn nǹkan yẹn dà wá láàmú ju bó ti yẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ‘àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò máa ṣọ́ ọkàn wa àti agbára ìrònú wa nípasẹ̀ Kristi Jésù.’ (Fílí. 4:6, 7) Ohun kan tó dájú hán-ún ni pé Jèhófà máa ṣe orúkọ rẹ̀ lógo. Tó bá sì tó àsìkò, á lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣàtúnṣe gbogbo nǹkan tí Sátánì àti ayé yìí ti mú bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́.​—Sm. 94:22, 23; Àìsá. 65:17.

JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ JÈHÓFÀ MÁA ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ

17. Bó ṣe wà nínú Àìsáyà 30:21, báwo ni Jèhófà ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ lónìí?

17 Jèhófà ṣì ń bá wa sọ̀rọ̀ títí dòní olónìí. (Ka Àìsáyà 30:21.) Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ ní tààràtà látọ̀run. Àmọ́, ó ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bákan náà, Jèhófà ń fi ẹ̀mí mímọ́ darí “ìríjú olóòótọ́ náà” láti máa fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lóúnjẹ tẹ̀mí. (Lúùkù 12:42) Mélòó la fẹ́ kà nínú ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú yìí ń pèsè! Ṣé èyí tí wọ́n ń tẹ̀ sórí ìwé ni ká sọ ni, àbí èyí tó wà lórí ìkànnì, ká má tíì sọ tàwọn fídíò àtàwọn àtẹ́tísí lónírúurú.

18. Báwo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe lè mú kó o túbọ̀ nígbàgbọ́ àti ìgboyà?

18 Ẹ wo bó ṣe máa dáa tó tá a bá ń rántí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nígbà tí Jésù Ọmọ rẹ̀ wà láyé. Ǹjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì mú kó dá wa lójú pé kò sóhun tó kọjá agbára Jèhófà. Tó bá sì tó àsìkò, á ṣàtúnṣe sí gbogbo ohun tí Sátánì àti ayé yìí ti bà jẹ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa fetí sí ohùn Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè fara da ìṣòro yòówù ká máa kojú nísinsìnyí àtèyí tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì sọ pé: “Ẹ nílò ìfaradà, pé lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ lè rí ohun tí ó ṣèlérí náà gbà.”​—Héb. 10:36.

ORIN 4 “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”

^ ìpínrọ̀ 5 Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run nígbà tí Jésù wà láyé. Ìgbà kan wà nínú ìgbà mẹ́ta yẹn tí Jèhófà ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fetí sí Ọmọ òun. Lónìí, Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ Jésù. Bákan náà, ó ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa sọ àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń fetí sí Jèhófà àti Jésù.

^ ìpínrọ̀ 52 ÀWÒRÁN: Alàgbà kan kíyè sí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, tó sì ń bójú tó ìwé nípàdé. Alàgbà náà gbóríyìn fún arákùnrin yẹn gan-an.

^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Sierra Leone ń fún apẹja kan ní ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn sípàdé.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa ń ṣèpàdé nínú ilé ẹnì kan. Wọn ò múra bí ẹni tó ń lọ sípàdé káwọn èèyàn má bàa fura sí wọn.