Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 20

Bá A Ṣe Lè Pèsè Ìtùnú fún Àwọn Tí Wọ́n Bá Lò Pọ̀ Nígbà Tí Wọ́n Wà Lọ́mọdé

Bá A Ṣe Lè Pèsè Ìtùnú fún Àwọn Tí Wọ́n Bá Lò Pọ̀ Nígbà Tí Wọ́n Wà Lọ́mọdé

“Ọlọ́run ìtùnú gbogbo . . . ń tù wá nínú nínú gbogbo àdánwò wa.”​—2 KỌ́R. 1:3, 4.

ORIN 134 Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń fẹ́ káwọn míì tù wá nínú, káwa náà sì tù wọ́n nínú? (b) Ọgbẹ́ wo ni wọ́n ti dá sáwọn ọmọ kan lọ́kàn?

JÈHÓFÀ dá àwa èèyàn lọ́nà tó ń mú kó máa wù wá pé káwọn míì tù wá nínú, káwa náà sì tù wọ́n nínú. Bí àpẹẹrẹ, ọmọdé kan lè ṣubú níbi tó ti ń ṣeré kó sì fi orúnkún bó, kó wá sunkún lọ bá mọ́mì tàbí dádì ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ ò lè mú kí egbò náà jinná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, síbẹ̀ wọ́n máa tù ú nínú. Wọ́n lè béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ tàbí kí wọ́n rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. Wọ́n tiẹ̀ lè fọwọ́ ra á lórí kára lè tù ú, lẹ́yìn náà wọ́n lè bá a fi nǹkan sójú egbò náà tàbí kí wọ́n fi báńdéèjì wé e. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ọmọ náà tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré, tó bá sì yá egbò rẹ̀ á jinná.

2 Àmọ́ nígbà míì, ọgbẹ́ táwọn ọmọdé kan ní máa ń burú ju èyí lọ. Ìdí sì ni pé wọ́n ti bá wọn ṣèṣekúṣe. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan péré ni ìwà burúkú yìí wáyé tàbí kó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Èyí ó wù kó jẹ́, ọgbẹ́ ọkàn tí èyí máa ń fà fún àwọn ọmọ náà kì í ṣe kékeré, ọgbẹ́ náà sì lè má jinná fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà míì, ọwọ́ pálábá ọ̀daràn náà lè ségi kí wọ́n sì fìyà tó tọ́ jẹ ẹ́, nígbà míì sì rèé, ó lè dà bíi pé ó mú un jẹ. Ká tiẹ̀ sọ pé wọ́n mú onítọ̀hún tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́, ọgbẹ́ tó ti dá sọ́mọ náà lọ́kàn lè má jinná títí táá fi dàgbà.

3. Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4, kí ni Jèhófà fẹ́, àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn?

3 Tí Kristẹni kan tó ti dàgbà bá ṣì ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí pé wọ́n bá a ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọdé, kí ló lè ràn án lọ́wọ́? (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4.) Ó ṣe kedere pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn àgùntàn rẹ̀ ọ̀wọ́n rí ìfẹ́ àti ìtùnú tí wọ́n nílò. Torí náà, ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Kí nìdí táwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé fi nílò ìtùnú? (2) Àwọn wo ló lè tù wọ́n nínú? (3) Báwo la ṣe lè tù wọ́n nínú?

ÌDÍ TÍ WỌ́N FI NÍLÒ ÌTÙNÚ

4-5. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká fi sọ́kàn pé bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ọmọdé yàtọ̀ sí ti àgbàlagbà? (b) Tí wọ́n bá bọ́mọdé kan ṣèṣekúṣe, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí i?

4 Àwọn kan tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé ṣì nílò ìtùnú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ká lè lóye kókó yìí, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ọmọdé yàtọ̀ sí ti àgbàlagbà. Bákan náà, ipa tí ìwà ìkà yìí máa ń ní lórí ọmọdé yàtọ̀ sí bó ṣe máa ń rí lára àgbàlagbà. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan.

5 Àwọn ọmọdé máa ń sún mọ́ àwọn tó ń tọ́jú wọn, wọ́n sì máa ń fọkàn tán wọn. Èyí máa ń jẹ́ kọ́kàn àwọn ọmọ náà balẹ̀, kí wọ́n sì fọkàn tán àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wọn. (Sm. 22:9) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn tó sún mọ́ àwọn ọmọ náà ló sábà máa ń bá wọn ṣèṣekúṣe, bíi mọ̀lẹ́bí, aládùúgbò tàbí òbí pàápàá. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń dá ọgbẹ́ ńlá sọ́kàn àwọn ọmọdé, ó sì máa ń mú kó ṣòro fún wọn láti fọkàn tán ẹnikẹ́ni, kódà fún ọ̀pọ̀ ọdún.

6. Kí nìdí tí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe fi jẹ́ ìwà ìkà tó burú jáì?

6 Àwọn ọmọdé ò dákan mọ̀, wọn ò sì lè dáàbò bo ara wọn torí náà ìwà ìkà gbáà ni tẹ́nì kan bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Tẹ́nì kan bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, ọṣẹ́ ńlá ló ṣe ọmọ náà. Ìdí ni pé ọmọ náà ò tíì dàgbà tó ẹni tó ń ní ìbálòpọ̀, kò sì dákan mọ̀. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ ọdún ṣì máa kọjá kí ọmọ náà tó dàgbà tó láti ṣègbéyàwó táá fi lè ní ìbálòpọ̀. Ìwà burúkú yìí lè mú kó ní èrò tí kò tọ́ nípa ìbálòpọ̀, ó lè mú kó máa wo ara ẹ̀ bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan, ó sì lè má fọkàn tán ẹnikẹ́ni mọ́.

7. (a) Kí nìdí tó fi rọrùn fáwọn èèyànkéèyàn láti tan àwọn ọmọdé jẹ, àwọn irọ́ wo ni wọ́n sì máa ń pa? (b) Àkóbá wo làwọn irọ́ yìí máa ń ṣe fáwọn ọmọ náà?

7 Àwọn ọmọdé ò tíì gbọ́n, wọn ò sì lè ronú jinlẹ̀ débi tí wọ́n á fi mọ ohun tó lè wu wọ́n léwu tàbí bí wọ́n ṣe lè yẹra fún un. (1 Kọ́r. 13:11) Torí náà, ó rọrùn gan-an fáwọn èèyànkéèyàn láti tan àwọn ọmọdé jẹ. Oríṣiríṣi irọ́ burúkú làwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe máa ń pa fún wọn. Wọ́n lè sọ pé ẹ̀bi ọmọ náà lohun tó ṣẹlẹ̀ tàbí pé kò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni torí tó bá sọ, kò sẹ́ni tó máa gbà á gbọ́. Wọ́n tún lè parọ́ fún un pé ọ̀nà tí àgbàlagbà máa ń gbà fìfẹ́ hàn sọ́mọdé nìyẹn. Irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ káwọn ọmọdé ní èrò òdì, ó sì lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó mọ̀ pé irọ́ ni gbogbo ohun tẹ́ni náà sọ. Bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, ó lè máa ronú pé ayé òun ti bà jẹ́, òun ò wúlò, kò sẹ́ni tó máa fìfẹ́ hàn sóun, òun ò sì lè rí ìtùnú.

8. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà lè tu àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú?

8 Ó ṣe kedere pé ọgbẹ́ ọkàn tí kì í jinná bọ̀rọ̀ làwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé máa ń ní. Ìwà ọ̀daràn ni ìwà yìí, ìwà ìkà burúkú sì ni! Bí ìwà burúkú yìí ṣe gbòde kan jẹ́ kó hàn gbangba pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà, ìyẹn àsìkò tí ọ̀pọ̀ “kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni,” tí ‘àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà sì ń burú sí i.’ (2 Tím. 3:​1-5, 13) Ìkà ẹ̀dá ni Sátánì, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sì burú gan-an. Ó yani lẹ́nu pé àwọn kan ń hùwà tó ń múnú Sátánì dùn, èyí sì bani nínú jẹ́ gan-an. Àmọ́ ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà lágbára ju Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ lọ fíìfíì. Gbogbo ohun tí Sátánì ń ṣe pátápátá ni Jèhófà ń rí, ó sì dá wa lójú pé gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wa ló mọ̀, á sì tù wá nínú. A mà dúpẹ́ o pé Ọlọ́run tá à ń sìn jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tó ń tù wá nínú nínú gbogbo àdánwò wa, kí a lè fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ tu àwọn míì nínú lábẹ́ àdánwò èyíkéyìí tí wọ́n bá wà.” (2 Kọ́r. 1:​3, 4) Àmọ́, àwọn wo ni Jèhófà máa ń lò láti tuni nínú?

ÀWỌN WO LÓ LÈ TUNI NÍNÚ?

9. Bí Ọba Dáfídì ṣe sọ nínú Sáàmù 27:​10, kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn tí òbí wọn pa tì?

9 Àwọn tí òbí ti pa tì àtàwọn tí mọ̀lẹ́bí tàbí ẹlòmíì ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé máa ń nílò ìtùnú gan-an. Onísáàmù náà Dáfídì mọ̀ pé kò sẹ́ni tó lè tuni nínú bíi Jèhófà. (Ka Sáàmù 27:10.) Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà máa ń bójú tó gbogbo àwọn táwọn èèyàn wọn pa tì. Ọ̀nà wo ni Jèhófà máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ó máa ń lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, ó ṣe tán ìdílé kan ni gbogbo àwa tá à ń sin Jèhófà. Jésù jẹ́ kí èyí ṣe kedere nígbà tó pe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní arákùnrin, arábìnrin àti ìyá rẹ̀.​—Mát. 12:​48-50.

10. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ojúṣe rẹ̀ bí alàgbà?

10 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bí ìjọ Kristẹni ṣe dà bí ìdílé kan. Alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, olóòótọ́ ni, ó sì fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀. Kódà lábẹ́ ìmísí, ó rọ àwọn míì pé kí wọ́n fara wé òun bí òun náà ṣe fara wé Kristi. (1 Kọ́r. 11:1) Ẹ wo bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé irú ọwọ́ tó fi mú àwọn ará nínú ìjọ, ó ní: “A di ẹni jẹ́jẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.” (1 Tẹs. 2:7) Lọ́nà kan náà, ó yẹ káwọn alàgbà máa lo ọ̀rọ̀ tútù tó ń mára tuni bí wọ́n ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú.

Àwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn mọ bá a ṣe ń tu àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú (Wo ìpínrọ̀ 11) *

11. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn alàgbà nìkan kọ́ ló lè tu àwọn míì nínú?

11 Ṣé àwọn alàgbà nìkan ló lè pèsè ìtùnú fáwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé? Rárá o. Ìdí ni pé ojúṣe gbogbo wa ni láti máa ‘tu ara wa nínú.’ (1 Tẹs. 4:18) Ó ṣàǹfààní gan-an táwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn bá lè tu àwọn arábìnrin míì nínú. Ó ṣe tán, Jèhófà fi ara rẹ̀ wé abiyamọ tó ń tu ọmọ rẹ̀ nínú. (Àìsá. 66:13) Bíbélì tiẹ̀ mẹ́nu kan àwọn obìnrin tó tu àwọn míì tó ní ìdààmú ọkàn nínú. (Jóòbù 42:11) Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà ń dùn bó ṣe ń rí àwọn arábìnrin tó ń pèsè ìtùnú fáwọn arábìnrin míì tó ní ìdààmú ọkàn! Nígbà míì, alàgbà kan tàbí méjì lè fọgbọ́n sọ fún arábìnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ pé kó sún mọ́ arábìnrin kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn, kó sì tù ú nínú. *

BÁWO LA ṢE LÈ TÙ WỌ́N NÍNÚ?

12. Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún?

12 Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ tojú bọ ọ̀rọ̀ tí Kristẹni kan ò ní fẹ́ káwọn míì mọ̀. (1 Tẹs. 4:11) Báwo la ṣe lè ran àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn lọ́wọ́, ká sì tù wọ́n nínú? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà márùn-ún tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

13. Bó ṣe wà nínú 1 Àwọn Ọba 19:​5-8, kí ni áńgẹ́lì Jèhófà ṣe fún Èlíjà, báwo la ṣe lè fara wé áńgẹ́lì náà?

13 Ṣe ohun pàtó láti ran ẹni náà lọ́wọ́. Nígbà tí wòlíì Èlíjà gbọ́ pé wọ́n fẹ́ pa òun, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá a, ó sì sá lọ kódà ó ronú pé á dáa kóun kú. Jèhófà wá rán áńgẹ́lì alágbára kan láti tù ú nínú, áńgẹ́lì náà sì pèsè ohun tí Èlíjà nílò. Ó gbé oúnjẹ tó gbóná fẹlifẹli wá fún Èlíjà, ó sì rọ̀ ọ́ pé kó jẹun. (Ka 1 Àwọn Ọba 19:​5-8.) Àkọsílẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ òótọ́ pàtàkì kan: Ìyẹn ni pé kò dìgbà tá a bá ṣe nǹkan ńlá fún ẹnì kan ká tó lè tù ú nínú. Nígbà míì, ó lè jẹ́ ohun kékeré kan tá a ṣe ló máa ṣe ẹni náà láǹfààní. A lè se oúnjẹ fún un, ká fún un lẹ́bùn kan, ká fi káàdì ránṣẹ́ sí i tàbí ká bá a ṣiṣẹ́ ilé, èyí á jẹ́ kó mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun, ọ̀rọ̀ òun sì jẹ wá lógún. Tá ò bá tiẹ̀ mọ ohun tá a lè sọ láti tu ẹni náà nínú, ó dájú pé a lè ràn án lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà yìí.

14. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà?

14 Mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀, kó o sì mú kára tù ú. Ẹ̀kọ́ míì wà tá a lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà. Jèhófà fún wòlíì náà lókun lọ́nà ìyanu kó lè rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn títí dé Òkè Hórébù. Ó ṣeé ṣe kára tu Èlíjà nígbà tó dé òkè yẹn torí pé ibẹ̀ ni Jèhófà ti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ọkàn ẹ̀ balẹ̀ níbẹ̀ torí ó gbà pé àwọn tó fẹ́ gbẹ̀mí òun kò ní lè rí òun mú níbẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú èyí? Tá a bá fẹ́ pèsè ìtùnú fún ẹni tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé, ó yẹ ká kọ́kọ́ mára tù ú, ká sì fi í lọ́kàn balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè rọrùn fún arábìnrin kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn láti bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀ nílé rẹ̀ níbi tára ti máa tù ú dípò inú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó sì lè jẹ́ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lara ti máa tu ẹlòmíì.

A lè tu ẹnì kan nínú tá a bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, tá a gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀, tá a sì lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára (Wo ìpínrọ̀ 15-20) *

15-16. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì?

15 Máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀.” (Jém. 1:19) Ṣé àwa náà máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì? Kéèyàn fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì kọjá pé ká máa wò wọ́n bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, ká má sì sọ ohunkóhun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó dójú ẹ̀ fún Èlíjà, ó tú ọkàn ẹ̀ jáde, ó sọ gbogbo ohun tó ń dùn ún fún Jèhófà, Jèhófà sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Jèhófà kíyè sí i pé ẹ̀rù ń ba Èlíjà, ó ń ronú pé òun ò rẹ́ni fojú jọ àti pé gbogbo làálàá òun ti já sásán. Jèhófà wá fi í lọ́kàn balẹ̀, ó sì fìfẹ́ yanjú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Èyí fi hàn pé Jèhófà fara balẹ̀ tẹ́tí sí Èlíjà.​—1 Ọba 19:9-11, 15-18.

16 Tá a bá ń tẹ́tí sí ẹnì kan, báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé a gba tiẹ̀ rò? Nígbà míì, a lè sọ ohun tó máa jẹ́ kẹ́ni náà mọ bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára wa. A lè sọ pé: “Ó dùn mí gan-an pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ! Ìkà burúkú lẹni tó hu irú ìwà yìí sọ́mọdé!” O sì lè fọgbọ́n bi í láwọn ìbéèrè kan kí ohun tó ń sọ lè yé ẹ dáadáa. O lè bi í pé, “Ṣé o lè tún àlàyé yẹn ṣe kí n lè mọ̀ bóyá mo gbọ́ ẹ dáadáa?” tàbí “Ṣé ohun tó ò ń sọ ni pé . . . Ṣé bẹ́ẹ̀ ni?” Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé lóòótọ́ là ń tẹ́tí sí òun ká lè lóye ọ̀rọ̀ òun.​—1 Kọ́r. 13:​4, 7.

17. Kí nìdí tó fi yẹ ká mú sùúrù ká sì “lọ́ra láti sọ̀rọ̀”?

17 Ó tún ṣe pàtàkì pé ká “lọ́ra láti sọ̀rọ̀.” Má ṣe já lu ọ̀rọ̀ ẹni náà torí pé o fẹ́ fún un nímọ̀ràn tàbí pé o fẹ́ tún èrò rẹ̀ ṣe. Rí i dájú pé o mú sùúrù fún un! Nígbà tí Èlíjà ń tú ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde fún Jèhófà, kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá. Kódà lẹ́yìn tí Jèhófà tù ú nínú tó sì fún un lókun, Èlíjà tún sọ ohun kan náà láìfi ọ̀kan pe méjì. (1 Ọba 19:​9, 10, 13, 14) Kí lèyí kọ́ wa? Nígbà míì, ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn lè máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ lásọtúnsọ. Bíi ti Jèhófà, ó yẹ káwa náà fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, ká sì mú sùúrù fún un. Dípò ká máa ronú ohun tá a máa sọ láti yanjú ìṣòro ẹ̀, á dáa ká jẹ́ kó mọ̀ pé a ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i dùn wá.​—1 Pét. 3:8.

18. Báwo ni àdúrà wa ṣe lè tu ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú?

18 Gbàdúrà àtọkànwá pẹ̀lú ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn. Ó lè má rọrùn fáwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn láti gbàdúrà. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè máa ronú pé Jèhófà ò lè tẹ́tí sí èèyàn bíi tòun. Tá a bá wà pẹ̀lú ẹni náà, a lè gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀, ká sì dárúkọ rẹ̀ nínú àdúrà náà, ìyẹn á sì jẹ́ kára tù ú. Nínú àdúrà náà, a lè sọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó àti bí gbogbo àwọn ará ìjọ ṣe fẹ́ràn rẹ̀. A tún lè bẹ Jèhófà pé kó tu àgùntàn rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí nínú, kọ́kàn rẹ̀ lè balẹ̀. Ó dájú pé irú àdúrà bẹ́ẹ̀ máa tu ẹni náà nínú gan-an.​—Jém. 5:16.

19. Kí lo lè ṣe tó o bá fẹ́ tu ẹnì kan nínú?

19 Lo àwọn ọ̀rọ̀ táá fi ẹni náà lọ́kàn balẹ̀, táá sì mára tù ú. Ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Téèyàn bá sọ̀rọ̀ láìronú, ó lè dá kún ọgbẹ́ ọkàn ẹni náà, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mára tuni. (Òwe 12:18) Torí náà bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ ọ̀rọ̀ tó o lè lò táá mára tù ú, táá fi í lọ́kàn balẹ̀, táá sì múnú rẹ̀ dùn. Tún fi sọ́kàn pé kò sí ọ̀rọ̀ tó lè tuni nínú bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì.​—Héb. 4:12.

20. Irú èrò wo làwọn kan tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé máa ń ní, kí ló sì yẹ ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀?

20 Àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé lè máa ronú pé ayé àwọn ti bà jẹ́, pé àwọn ò wúlò àti pé kò sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ́. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Torí náà, á dáa kó o lo Ìwé Mímọ́ láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹni ọ̀wọ́n ni wọ́n jẹ́ lójú Jèhófà. (Wo àpótí náà “ Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Lè Tuni Nínú.”) Rántí bí Jèhófà ṣe lo áńgẹ́lì kan láti fún wòlíì Dáníẹ́lì lókun nígbà tó rẹ̀wẹ̀sì. Jèhófà fẹ́ kí Dáníẹ́lì mọ̀ pé ẹni ọ̀wọ́n ló jẹ́ lójú òun. (Dán. 10:​2, 11, 19) Lọ́nà kan náà, ẹni ọ̀wọ́n làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ní ẹ̀dùn ọkàn, wọ́n sì ṣeyebíye lójú Jèhófà!

21. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà, àmọ́ ní báyìí kí ló yẹ kí gbogbo wa ṣe?

21 Tá a bá ń tu àwọn míì nínú, ṣe là ń rán wọn létí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Ká má sì gbàgbé pé Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà. Kò sí ìwà burúkú tẹ́nì kan hù tó bò. Gbogbo ẹ̀ ni Jèhófà ń rí, kò sì ní ṣàìfi ìyà jẹ oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà. (Nọ́ń. 14:18) Àmọ́ ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa fìfẹ́ hàn sáwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé. Bó ti wù kó rí, láìpẹ́ Jèhófà máa mára tu gbogbo àwọn tí Sátánì àti ayé búburú rẹ̀ ti hàn léèmọ̀, ìyẹn sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo ohun tó ń fa ẹ̀dùn ọkàn fọ́mọ aráyé ò ní wá sọ́kàn mọ́.​—Àìsá. 65:17.

ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá

^ ìpínrọ̀ 5 Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé ṣì máa ń ní ọgbẹ́ ọkàn kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. A tún máa rí àwọn tó lè pèsè ìtùnú fún àwọn tírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò àwọn ọ̀nà tá a lè gbà tù wọ́n nínú.

^ ìpínrọ̀ 11 Ẹni tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé ló máa pinnu bóyá kóun lọ rí dókítà tó ń tọ́jú àwọn tó ní ìsoríkọ́ tàbí kóun má ṣe bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 76 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ ń tu arábìnrin míì tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú.

^ ìpínrọ̀ 78 ÀWÒRÁN: Àwọn alàgbà méjì ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arábìnrin kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn. Arábìnrin náà pe arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ yẹn pé kó wà níbẹ̀ pẹ̀lú òun.