Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Pańpẹ́ Sátánì

Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Pańpẹ́ Sátánì

NÍGBÀ tó ku díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Odò Jọ́dánì sí ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí fún wọn, àwọn kan dé bá wọn lálejò. Obìnrin làwọn àlejò yìí, ilẹ̀ àjèjì ni wọ́n sì ti wá, wọ́n wá pe àwọn ọkùnrin ilẹ̀ Ísírẹ́lì sí àsè kan. Lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àǹfààní nìyẹn jẹ́, ó ṣe tán wọ́n á ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, wọ́n á jẹun, wọ́n á mu, wọ́n á jó, wọ́n á sì gbádùn ara wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà àti ìṣe àwọn obìnrin náà ta ko òfin Jèhófà, síbẹ̀ àwọn ọkùnrin náà lè máa ronú pé: ‘A mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì. Torí náà, kò sóhun tó máa ṣẹlẹ̀.’

Ṣé òótọ́ ni pé kò sóhun tó ṣẹlẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ròyìn pé: “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọbìnrin Móábù ṣe ìṣekúṣe.” Kódà, ṣe làwọn obìnrin yẹn fẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀! Abájọ tí ‘inú fi bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì.’​—Nọ́ń. 25:1-3.

Ọ̀nà méjì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn gbà tẹ òfin Ọlọ́run lójú: Àkọ́kọ́, wọ́n bọ̀rìṣà, èkejì wọ́n ṣe ìṣekúṣe. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló sì kú torí ohun tí wọ́n ṣe yẹn. (Ẹ́kís. 20:4, 5, 14; Diu. 13:6-9) Ohun míì tó mú kọ́rọ̀ náà burú ni àsìkò tó bọ́ sí. Ká sọ pé àwọn ọkùnrin náà kò rú òfin Ọlọ́run ni, gbogbo àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn ì bá sọdá Odò Jọ́dánì bọ́ sí Ilẹ̀ Ìlérí.​—Nọ́ń. 25:5, 9.

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ó ní: ‘Àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí wọn kí ó lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, wọ́n sì wà lákọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin ètò àwọn nǹkan dé bá.’ (1 Kọ́r. 10:7-11) Kò sí àní-àní pé inú Sátánì dùn bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ṣe dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọn ò sì dé Ilẹ̀ Ìlérí. Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, torí pé ohun tí Sátánì ń wá tó sì máa múnú ẹ̀ dùn jù ni pé kó gbé wa ṣubú ká má sì wọ inú ayé tuntun!

ÌDẸKÙN TÓ Ń ṢENI LỌ́ṢẸ́

Sátánì dájú sọ àwa Kristẹni, àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n tó fi ń mú ọ̀pọ̀ èèyàn balẹ̀ látọjọ́ yìí náà ló sì ń lò. Bá a ṣe sọ ṣáájú, ìṣekúṣe ló fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lónìí, ìṣekúṣe yìí kan náà ni pańpẹ́ tó fi ń mú ọ̀pọ̀ èèyàn. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó gbà ń mú káwọn èèyàn ṣèṣekúṣe ni wíwo àwòrán oníhòòhò.

Lóde òní, ó ti ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti máa wo ìwòkuwò láìsí pé ẹlòmíì mọ̀ sí i. Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ẹni bá máa wo ìwòkuwò máa ní láti lọ sí ilé sinimá tàbí kó lọ sílé ìtàwé láti ra àwọn ìwé tó ní ìwòkuwò nínú. Ìbẹ̀rù pé àwọn èèyàn á rí wọn nílé sinimá tàbí ilé ìtàwé bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ káwọn kan lọ síbẹ̀. Àmọ́ ní báyìí tí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti wà níbi gbogbo, ó ti ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti wo ìwòkuwò níbi iṣẹ́ tàbí nínú mọ́tò. Kódà ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, tọkùnrin tobìnrin ló lè wo ìwòkuwò láìkúrò nílé rárá.

Kò mọ síbẹ̀. Àwọn ẹ̀rọ alágbèéká ti mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti máa wo ìwòkuwò níbikíbi tí wọ́n bá wà. Yálà wọ́n ń rìn lọ́nà ni o tàbí wọ́n wà nínú mọ́tò tàbí nínú ọkọ̀ ojú irin, ó rọrùn fún wọn láti wo ìwòkuwò lórí fóònù.

Ní báyìí tó ti rọrùn fáwọn èèyàn láti wo ìwòkuwò láìjẹ́ kí ẹlòmíì mọ̀, àkóbá tí wíwo àwòrán oníhòòhò ń fà ti burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àìmọye èèyàn ni ìgbéyàwó wọn ti tú ká nítorí ìwòkuwò, ó ti mú kí wọ́n dẹni ẹ̀tẹ́, ẹ̀rí ọkàn wọn sì ń dá wọn lẹ́bi ṣáá. Èyí tó wá burú jù ni pé, tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá jáwọ́, wọ́n á pàdánù ojúure Jèhófà. Ó dájú pé wíwo àwòrán oníhòòhò máa ń ṣàkóbá fún àwọn tó ń wò ó. Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ni ìwòkuwò máa ń dá ọgbẹ́ tí kì í tètè jinná síni lọ́kàn. Ó dà bí ẹni tó ní ọgbẹ́ tí kì í jinná bọ̀rọ̀, àní tó bá tiẹ̀ jinná, ojú àpá kò lè dà bí ojú ara.

Bó ti wù kó rí, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà ń dáàbò bò wá ká má bàa kó sínú pańpẹ́ Sátánì yìí. Kí Jèhófà lè dáàbò bò wá, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun táwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yẹn kọ̀ láti ṣe, ìyẹn ni pé ká “ṣègbọràn sí ohùn [Jèhófà] délẹ̀délẹ̀.” (Ẹ́kís. 19:5) Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà kórìíra kéèyàn máa wo ìwòkuwò. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

KÓRÌÍRA RẸ̀ BÍI TI JÈHÓFÀ

Wò ó báyìí ná: Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ yàtọ̀ pátápátá sí òfin táwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń tẹ̀ lé. Òfin náà dà bí ògiri tó ń dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ìwà burúkú tó kún agbègbè yẹn má bàa ràn wọ́n. (Diu. 4:6-8) Òtítọ́ kan ṣe kedere nínú Òfin tí Ọlọ́run fún wọn, ìyẹn ni pé Jèhófà kórìíra ìṣekúṣe.

Lẹ́yìn tí Jèhófà ti mẹ́nu kan àwọn ìwàkiwà táwọn èèyàn agbègbè náà ń hù, ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe nílẹ̀ Kénáánì tí mò ń mú yín lọ. . . . Ilẹ̀ náà jẹ́ aláìmọ́, màá fìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́.” Lójú Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run mímọ́, ìṣe àti àṣà àwọn ọmọ Kénáánì burú débi pé ilẹ̀ wọn ti di aláìmọ́ lójú rẹ̀, ó sì ń kó o ní ìríra.​—Léf. 18:3, 25.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fìyà jẹ àwọn ọmọ Kénáánì, síbẹ̀ àwọn èèyàn ò yé ṣèṣekúṣe. Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) ọdún lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó ń gbé lásìkò yẹn pé àwọn èèyàn tó yí wọn ká ti “kọjá gbogbo òye ìwà rere.” Kódà ṣe ni “wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìnítìjú láti máa fi ojúkòkòrò hu oríṣiríṣi ìwà àìmọ́.” (Éfé. 4:17-19) Bíi tìgbà yẹn, àwọn èèyàn òde òní náà ò mọ̀ ju ìṣekúṣe lọ, kódà òun ni wọ́n fi ń ṣayọ̀. Torí náà, àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú àwòrán oníhòòhò.

Àwòrán oníhòòhò ń tàbùkù sí Ọlọ́run. Ó ṣe tán, nígbà tí Ọlọ́run máa dá wa, àwòrán ara rẹ̀ ló dá wa. A mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Bákan náà, ó fún wa ní òfin tó bá kan ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu. Ìdí ni pé àwọn tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló yọ̀ǹda fún pé kí wọ́n máa gbádùn ìbálòpọ̀. (Jẹ́n. 1:26-28; Òwe 5:18, 19) Àmọ́ kí la lè sọ nípa àwọn tó ń gbé ìwòkuwò jáde yálà nínú ìwé, orin, fíìmù tàbí géèmù? Ṣe ni wọ́n ń fọwọ́ rọ́ ìlànà Ọlọ́run tì. Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ńṣe làwọn tó ń gbé ìwòkuwò jáde ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ àwọn tó ń gbé àwòrán oníhòòhò jáde torí pé ńṣe ni wọ́n ń tẹ ìlànà rẹ̀ lójú, á sì fìyà jẹ wọ́n.​—Róòmù 1:24-27.

Àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ wo àwòrán oníhòòhò ńkọ́? Àwọn kan lè sọ pé àwọn kàn fi ń najú ni, kò sóhun tó fi ń ṣèèyàn. Àmọ́, ṣe nirú wọn ń ṣagbátẹrù àwọn tó ń tẹ ìlànà Jèhófà lójú. Lóòótọ́, wọ́n lè má nírú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wo ìwòkuwò, àmọ́ ohun tí kò dáa kò dáa. Bó ti wù kó rí, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ kórìíra ìwòkuwò tẹ̀gbintẹ̀gbin. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé: “Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun tó burú.”​—Sm. 97:10.

Ti pé èèyàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ò túmọ̀ sí pé ó máa rọrùn fún un láti yẹra fún ohun tí kò tọ́. Ìdí ni pé aláìpé ni wá, ó sì máa gba ìsapá gan-an ká má bàa ro èròkerò. Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn wa lè máa tàn wá pé kò sóhun tó burú nínú wíwo ìwòkuwò. (Jer. 17:9) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó di Kristẹni ló ti jà fitafita, tí wọ́n sì ti jáwọ́ nínú wíwo ìwòkuwò. Àpẹẹrẹ wọn jẹ́ kó ṣe kedere pé ìwọ náà lè ṣàṣeyọrí bó o ṣe ń sapá láti má ṣe lọ́wọ́ nínú àṣà burúkú yìí. Jẹ́ ká wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa kó sínú pańpẹ́ Sátánì yìí.

MÁ ṢE MÁA RO ÈRÒKERÒ

Bá a ṣe sọ ṣáájú, èròkerò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan gbà láyè ló mú kí wọ́n kàgbákò. Tá ò bá ṣọ́ra, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Jémíìsì tó jẹ́ àbúrò Jésù sọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa ro èròkerò, ó ní: “Àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ. Tí ìfẹ́ ọkàn náà bá ti gbilẹ̀, ó máa bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Jém. 1:14, 15) Tẹ́nì kan bá jẹ́ kí èrò ìṣekúṣe ta gbòǹgbò lọ́kàn òun, wẹ́rẹ́ báyìí ló máa dẹ́ṣẹ̀. Torí náà, dípò tá a fi máa gba èròkerò láyè, ṣe ló yẹ ká fà á tu kíá.

Tí èròkerò bá ń wá sí ẹ lọ́kàn ṣáá, ṣe ni kó o gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara. Jésù sọ pé: “Torí náà, tí ọwọ́ rẹ tàbí ẹsẹ̀ rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. . . . Bákan náà, tí ojú rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Mát. 18:8, 9) Àmọ́ ṣá o, Jésù ò sọ pé ká gé ẹ̀yà ara wa sọ nù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń ṣàpẹẹrẹ ohun tó yẹ ká ṣe ká má bàa kó sínú ẹ̀ṣẹ̀, ká sì tètè ṣe bẹ́ẹ̀ láìṣiyèméjì. Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò tó bá kan ọ̀rọ̀ wíwo àwòrán oníhòòhò?

Tírú àwòrán bẹ́ẹ̀ bá yọjú, má ṣe ronú pé, ‘Kò sóhun tó máa ṣẹlẹ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o gbójú kúrò níbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Pa tẹlifíṣọ̀n náà lójú ẹsẹ̀. Pa kọ̀ǹpútà tàbí fóònù rẹ láìjáfara. Ṣe ohun táá mú kó o máa ro ohun tó dáa. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, èròkerò kò ní ráyè gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ.

KÍ LA LÈ ṢE TÍ ÈRÒKERÒ BÁ Ń PA DÀ SÍ WA LỌ́KÀN?

Ká sọ pé o ti jáwọ́ pátápátá nínú wíwo ìwòkuwò, àmọ́ tí èrò burúkú náà tún ń wá sí ẹ lọ́kàn ńkọ́? Ká sòótọ́, àwọn àwòrán oníhòòhò tàbí èròkerò kì í tètè kúrò lọ́kàn ẹni. Ìgbàkigbà ni wọ́n lè pa dà síni lọ́kàn láìròtẹ́lẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó lè mú kó o ṣe ohun tí kò mọ́, bíi fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ. Torí náà, fi sọ́kàn pé èrò burúkú lè wá sí ẹ lọ́kàn, kó o sì ronú ohun tó o lè ṣe láti gbé e kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Túbọ̀ pinnu pé ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ni wàá máa rò, òun náà sì ni wàá máa ṣe. Fara wé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó máa ń ‘lu ara rẹ̀ kíkankíkan, tó sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.’ (1 Kọ́r. 9:27) Má ṣe jẹ́ kí èròkerò máa darí rẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò pé, “Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Máa rántí kókó yìí: Tó o bá ń ronú tó o sì ń hùwà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, wàá ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn ò lè ní tó bá ń wo ìwòkuwò tàbí ṣèṣekúṣe.

Tó o bá ń ronú tó o sì ń hùwà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, wàá ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn ò lè ní tó bá ń wo ìwòkuwò tàbí ṣèṣekúṣe

O lè há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí tí wàá máa rántí ní gbogbo ìgbà. Tí èròkerò bá sì wá sí ẹ lọ́kàn, sapá láti ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà. Lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o lè há sórí ni Sáàmù 119:37; Àìsáyà 52:11; Mátíù 5:28; Éfésù 5:3; Kólósè 3:5 àti 1 Tẹsalóníkà 4:4-8. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí á jẹ́ kó o máa rántí pé Jèhófà kórìíra àwòrán oníhòòhò, á sì jẹ́ kó o mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe.

Ká sọ pé ó ń wù ẹ́ gan-an pé kó o wo ìwòkuwò tàbí kó o ro èròkerò, kí lo lè ṣe? Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù fi lélẹ̀. (1 Pét. 2:21) Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, Sátánì dẹ ẹ́ wò léraléra. Kí wá ni Jésù ṣe? Gbogbo ìgbà tí Sátánì dẹ ẹ́ wò ló kọ̀ jálẹ̀. Ó lo onírúurú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ láti dènà gbogbo ìdẹwò tí èṣù gbé kò ó. Jésù sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” Sátánì náà sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Jésù ò jẹ́ kó sú òun láti kọjú ìjà sí Sátánì, ohun tó sì yẹ kíwọ náà ṣe nìyẹn. (Mát. 4:1-11) Sátánì àti ayé burúkú yìí á ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kó o máa ro èròkerò, àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ dẹra nù bó o ṣe ń sapá láti borí èròkerò. Ó dájú pé o lè jáwọ́ nínú wíwo ìwòkuwò. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, wàá borí ọ̀tá burúkú yìí.

GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ KÓ O SÌ MÁA ṢÈGBỌRÀN SÍ I

Máa gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 4:6, 7) Àlàáfíà Ọlọ́run máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ bá a ṣe ń sapá láti sá fún ẹ̀ṣẹ̀. Ó dájú pé tó o bá sún mọ́ Jèhófà, òun náà ‘á sún mọ́ ẹ.’​—Jém. 4:8.

Ààbò tó dáa jù tá a lè rí nínú ayé èṣù yìí ni pé ká sún mọ́ Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Jésù sọ pé: “Alákòóso ayé ń bọ̀ [Sátánì], kò sì ní agbára kankan lórí mi.” (Jòh. 14:30) Kí ló mú kí ọkàn Jésù balẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Ẹni tó rán mi wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì lémi nìkan, torí gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó wù ú.” (Jòh. 8:29) Tíwọ náà bá ń ṣe ohun tó wu Jèhófà, ó dájú pé kò ní pa ẹ́ tì. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti yẹra fún àwòrán oníhòòhò, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Sátánì ò ní rí ẹ mú láé.