Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 28

Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Wọ́n Bá Tiẹ̀ Fòfin De Iṣẹ́ Wa

Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Wọ́n Bá Tiẹ̀ Fòfin De Iṣẹ́ Wa

“A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.”​—ÌṢE 4:​19, 20.

ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

LỌ́DÚN 2018, àwọn akéde tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́tàlélógún (223,000) ló wà láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de ìjọsìn wa, ìyẹn ò sì yà wá lẹ́nu rárá. Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé a máa kojú inúnibíni. (2 Tím. 3:12) Ibi yòówù ká máa gbé, ìgbàkigbà ni ìjọba lè ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́ mọ́, ó sì lè bá wa lójijì.

2 Tí ìjọba orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé bá fòfin de ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó o máa bi ara rẹ pé: ‘Ṣé inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wa fi hàn pé Jèhófà ń bínú sí wa ni? Ṣé ó túmọ̀ sí pé a máa pa ìjọsìn Jèhófà tì torí pé wọ́n fòfin dè wá? Ṣé kí n ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì tí màá ti lè sin Jèhófà bí mo ṣe fẹ́?’ A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa jíròrò bá a ṣe lè máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó tí wọ́n bá tiẹ̀ fòfin de iṣẹ́ wa, àá sì rí àwọn nǹkan tó yẹ ká yẹra fún.

ṢÉ INÚNIBÍNI TÍ WỌ́N Ń ṢE SÍ WA FI HÀN PÉ JÈHÓFÀ Ń BÍNÚ SÍ WA?

3. Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 11:​23-27, àwọn ìṣòro wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kojú, kí la sì rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ rẹ̀?

3 Tí ìjọba bá fòfin de ìjọsìn wa, a lè máa ronú pé bóyá Jèhófà ló ń bínú sí wa. Àmọ́ ohun kan wà tó yẹ ká fi sọ́kàn: Kì í ṣe torí pé Jèhófà ń bínú sáwa èèyàn rẹ̀ ló mú kó fàyè gba inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wa. Àpẹẹrẹ kan tó mú kó túbọ̀ dá wa lójú ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Kò sí àní-àní pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an. Jèhófà mí sí i láti kọ mẹ́rìnlá (14) lára Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó sì tún jẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Síbẹ̀, ó dojú kọ inúnibíni tó gbóná janjan. (Ka 2 Kọ́ríńtì 11:​23-27.) Àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń fàyè gbà á pé káwọn ọ̀tá ṣenúnibíni sáwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín.

4. Kí nìdí táwọn èèyàn ayé fi kórìíra wa?

4 Jésù ṣàlàyé ìdí táwọn èèyàn fi máa ṣenúnibíni sí wa. Ó sọ pé àwọn èèyàn máa kórìíra wa torí pé a kì í ṣe apá kan ayé. (Jòh. 15:​18, 19) Torí náà, ti pé wọ́n ń ṣenúnibíni sí wa kò túmọ̀ sí pé Jèhófà kẹ̀yìn sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí ló jẹ́ pé ohun tó tọ́ là ń ṣe!

ṢÉ A MÁA PA ÌJỌSÌN JÈHÓFÀ TÌ TÍ WỌ́N BÁ FÒFIN DE IṢẸ́ WA?

5. Ṣé àwọn èèyàn lásánlàsàn lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró? Ṣàlàyé.

5 Ńṣe lọ̀rọ̀ àwọn tó ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà dà bí ewúrẹ́ tó ń bínú, tó wá ń fẹsẹ̀ halẹ̀. Ẹ gbọ́ ná, kí lá fi olówó ẹ̀ ṣe? Kí èèyàn lásánlàsàn máa lérí pé òun á pa ìjọsìn Ọlọ́run Olódùmarè rẹ́! Àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ níjọ̀ọ́sí dà? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ń ṣenúnibíni tó gbóná janjan sáwa èèyàn Jèhófà. Wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lásìkò ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì, kódà wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, Kánádà àtàwọn ilẹ̀ míì. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Lọ́dún 1939 tí ogun yẹn bẹ̀rẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́rin àtààbọ̀ (72,475) làwọn akéde tó wà kárí ayé. Àmọ́ lẹ́yìn tí ogun náà parí lọ́dún 1945, àwọn akéde ti ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ lọ (156,299). Àbẹ́ ò rí nǹkan, láìka gbogbo àtakò wọn sí, ṣe làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run pọ̀ sí i, kódà wọ́n lé ní ìlọ́po méjì!

6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni lè dẹ́rù bani, àǹfààní wo ló ń ṣe wá? Sọ àpẹẹrẹ kan.

6 Lóòótọ́, inúnibíni lè dẹ́rù bani, àmọ́ ó tún lè ṣe wá láǹfààní. Lọ́nà wo? Ó lè mú ká túbọ̀ máa fìtara jọ́sìn Jèhófà ká sì pinnu pé a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tó ní ọmọkùnrin kan ń gbé lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Dípò kí wọ́n dẹwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà nítorí ìbẹ̀rù, ńṣe ni tọkọtaya náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ìyàwó náà tiẹ̀ fi iṣẹ́ olówó ńlá tó ń ṣe sílẹ̀. Ọkọ rẹ̀ sọ pé ìfòfindè yẹn mú káwọn èèyàn máa béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn sì mú kó rọrùn fún òun láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Kì í ṣe àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan lọ̀rọ̀ yìí ṣe láǹfààní. Alàgbà kan lórílẹ̀-èdè yẹn sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé tí wọ́n sì ń wàásù.

7. (a) Kí la rí kọ́ nínú Léfítíkù 26:​36, 37? (b) Kí ni wàá ṣe tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa?

7 Ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọ̀tá wa ni pé táwọn bá fòfin de ìjọsìn wa, ẹ̀rù á bà wá, a ò sì ní jọ́sìn Jèhófà mọ́. Láfikún sí ìfòfindè, wọ́n tún lè tan irọ́ kálẹ̀ nípa wa, kí wọ́n rán àwọn agbófinró láti wá gbọn ilé wa yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́, wọ́n lè fẹ̀sùn kàn wá kí wọ́n sì gbé wa lọ sílé ẹjọ́. Kódà wọ́n lè ju àwọn kan lára wa sẹ́wọ̀n. Èrò wọn ni pé báwọn ṣe ju díẹ̀ lára wa sẹ́wọ̀n yẹn máa mú kí ẹ̀rù ba àwa tó kù. Tá a bá jẹ́ kí wọ́n kó wa láyà jẹ, a lè fọwọ́ ara wa dá ìjọsìn Jèhófà dúró. Ó sì dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí àwọn tí Bíbélì sọ nínú Léfítíkù 26:​36, 37. (Kà á.) Torí náà, ká má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú ká dẹwọ́ tàbí ṣíwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà. Ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá ká má sì gbọ̀n jìnnìjìnnì. (Àìsá. 28:16) Ká bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn rẹ̀, kò sí ìjọba náà láyé yìí táá mú ká ṣíwọ́ sísin Jèhófà, bó ti wù kí ìjọba náà lágbára tó.​—Héb. 13:6.

ṢÉ KÍ N ṢÍ LỌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ MÍÌ?

8-9. (a) Ìpinnu wo ni olórí ìdílé tàbí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ṣe tọ́rọ̀ bá dójú ẹ̀? (b) Kí lá ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu?

8 Tí ìjọba bá fòfin de ìjọsìn wa lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé, o lè máa ronú pé kó o ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì níbi tí wàá ti lè jọ́sìn Jèhófà bó o ṣe fẹ́. Ìwọ fúnra rẹ lo máa pinnu bóyá kó o ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí kó o má ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn kan lè ronú nípa ohun táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn táwọn alátakò sọ̀kò pa Sítéfánù, ńṣe làwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣí lọ sáwọn agbègbè Jùdíà àti Samáríà. Kódà, àwọn kan lọ sí Foníṣíà, Sápírọ́sì àti Áńtíókù. (Mát. 10:23; Ìṣe 8:1; 11:19) Àwọn míì sì lè ronú nípa àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni lẹ́yìn ìgbà yẹn. Pọ́ọ̀lù pinnu láti dúró lágbègbè tí wọ́n ti ń ṣenúnibíni yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn léwu, síbẹ̀ ó dúró kó lè wàásù ìhìn rere kó sì lè fún àwọn ará tó ń kojú inúnibíni lágbègbè yẹn lókun.​—Ìṣe 14:​19-23.

9 Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ méjèèjì yìí? Ẹ̀kọ́ náà ni pé olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tí ìdílé rẹ̀ máa ṣe. Kó tó ṣèpinnu bóyá káwọn lọ síbòmíì tàbí káwọn dúró, ó ṣe pàtàkì kó gbàdúrà, kó sì fara balẹ̀ gbé ipò ìdílé rẹ̀ yẹ̀ wò. Á dáa kó ronú nípa àǹfààní tí ṣíṣí lọ máa ṣe wọ́n àti ewu tó lè fà fún wọn. Nírú ipò bẹ́ẹ̀, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa “ru ẹrù ara rẹ̀.” (Gál. 6:5) A ò gbọ́dọ̀ dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́ fún ìpinnu èyíkéyìí tó bá ṣe.

BÁWO LÀÁ ṢE MÁA JỌ́SÌN TÍ WỌ́N BÁ FÒFIN DE IṢẸ́ WA?

10. Ìtọ́sọ́nà wo ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn alàgbà máa fún wa?

10 Báwo ni wàá ṣe máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa? Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa fún àwọn alàgbà ìjọ ní ìtọ́sọ́nà, wọ́n á sì fún wọn láwọn àbá nípa bá a ṣe lè máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà, bá a ṣe lè máa pàdé pọ̀ láti jọ́sìn Jèhófà àti bá a ṣe lè máa wàásù ìhìn rere. Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ̀ka ọ́fíìsì láti kàn sí àwọn alàgbà, àwọn alàgbà máa ṣèrànwọ́ tó yẹ fún ìwọ àti gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ kẹ́ ẹ lè máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó. Wọ́n á lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtọ́ni tó wà nínú ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run láti tọ́ yín sọ́nà.​—Mát. 28:​19, 20; Ìṣe 5:29; Héb. 10:​24, 25.

11. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé a máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà bó ti wù kí nǹkan nira tó, kí lo sì lè ṣe láti dáàbò bo Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde rẹ?

11 Jèhófà ṣèlérí pé ìgbà gbogbo làwọn ìránṣẹ́ òun á máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà. (Àìsá. 65:​13, 14; Lúùkù 12:​42-44) Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ètò Ọlọ́run á ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kó o lè rí ìtìlẹ́yìn nípa tẹ̀mí gbà. Àmọ́ ohun kan wà tó yẹ kí ìwọ náà ṣe. Kí lohun náà? Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, rí i pé o wá ibi tó pa mọ́ dáadáa tó o lè tọ́jú Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde rẹ sí. Rí i dájú pé o ò kó àwọn nǹkan tó ṣeyebíye yìí síbi tí àwọn míì ti lè rí i, yálà èyí tí wọ́n tẹ̀ sórí ìwé tàbí èyí tó wà lórí ẹ̀rọ. Ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti rí i pé ìgbàgbọ́ òun lágbára.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè máa pàdé pọ̀ láti jọ́sìn láìbẹ̀rù (Wo ìpínrọ̀ 12) *

12. Kí làwọn alàgbà lè ṣe táwọn ará á fi máa ṣèpàdé láìjẹ́ káwọn èèyàn fura?

12 Ọgbọ́n wo la máa dá tí àá fi máa ṣèpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Àwọn alàgbà máa ṣètò bí àá ṣe máa ṣèpàdé láìjẹ́ káwọn èèyàn fura sí wa. Wọ́n lè ṣètò yín sí àwùjọ kéréje láti máa ṣèpàdé, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa yí ibi tẹ́ ẹ ti ń ṣèpàdé àti àsìkò tẹ́ ẹ̀ ń ṣe é pa dà látìgbàdégbà. Ṣe ipa tìrẹ láti dáàbò bo àwọn ará tẹ́ ẹ jọ ń ṣèpàdé, rí i pé o ò pariwo nígbà tó o bá ń lọ sípàdé àti nígbà tó o bá ń kúrò níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè gba pé kó o múra lọ́nà tó yàtọ̀ sí bá a ṣe máa ń múra lọ sípàdé.

A ò ní ṣíwọ́ àtimáa wàásù bí ìjọba bá tiẹ̀ fòfin de iṣẹ́ wa (Wo ìpínrọ̀ 13) *

13. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ àwọn ará wa tó gbé lábẹ́ ìjọba Soviet Union àtijọ́?

13 Tó bá dọ̀rọ̀ ìwàásù, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ọ̀nà tá a máa gbà wàásù níbì kan lè yàtọ̀ sí ti ibòmíì. Àmọ́ torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì gbádùn ká máa sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn, àá wá bá a ṣe máa wàásù fún wọn. (Lúùkù 8:1; Ìṣe 4:29) Nígbà tí òpìtàn kan tó ń jẹ́ Emily B. Baran ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará wa lábẹ́ ìjọba Soviet Union àtijọ́, ó sọ pé: “Nígbà tí ìjọba ṣòfin pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbọ́dọ̀ wàásù fáwọn míì, ńṣe ni wọ́n ń dọ́gbọ́n bá àwọn aládùúgbò wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn àtàwọn ará ibiṣẹ́ wọn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tọ́wọ́ àwọn aláṣẹ bá tẹ̀ wọ́n, tí wọ́n sì jù wọ́n sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí tún máa ń wàásù fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bá níbẹ̀.” Àbẹ́ ò rí nǹkan, láìka ìfòfindè sí, àwọn ará yẹn ò dẹ́kun wíwàásù fáwọn èèyàn. Torí náà, tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa níbi tó ò ń gbé, rántí àpẹẹrẹ àwọn ará yẹn, kó o sì fara wé wọn.

ÀWỌN NǸKAN WO NI KÒ YẸ KÁ ṢE

Mọ ìgbà tó yẹ kó o dákẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 14) *

14. Tá a bá fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 39:1 sọ́kàn, àṣìṣe wo la ò ní ṣe?

14 Rí i pé o pa àwọn ìsọfúnni tó jẹ́ àṣírí mọ́. Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, ó yẹ ká mọ “ìgbà dídákẹ́.” (Oníw. 3:7) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìsọfúnni tó yẹ ká pa mọ́ láṣìírí bọ́ sọ́wọ́ àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, orúkọ àwọn ará, àwọn ibi tá a ti ń ṣèpàdé, ọ̀nà tá à ń gbà wàásù àti bá a ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà. A ò ní fún aṣojú ìjọba èyíkéyìí láwọn ìsọfúnni yìí, bẹ́ẹ̀ sì la ò ní fún àwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa lórílẹ̀-èdè tá à ń gbé tàbí lórílẹ̀-èdè míì. Tá a bá jẹ́ káwọn ìsọfúnni yìí bọ́ sọ́wọ́ àwọn míì, ṣe là ń fi ẹ̀mí àwọn ará wa sínú ewu.​—Ka Sáàmù 39:1.

15. Kí ni Sátánì máa fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí wa, àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe?

15 Ká má ṣe jẹ́ kí èdèkòyédè tàbí àìgbọ́ra-ẹni-yé fa ìpínyà láàárín wa. Sátánì mọ̀ pé tí kò bá sí ìṣọ̀kan nínú ilé kan, ilé náà kò ní lè dúró. (Máàkù 3:​24, 25) Bó ṣe máa kẹ̀yìn wa síra ló ń wá, kò níṣẹ́ míì. Ó mọ̀ pé tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, dípò ká ṣe ara wa ní òṣùṣù ọwọ̀ ká sì kọjú ìjà sí òun ńṣe làá máa bá ara wa jà.

16. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Arábìnrin Gertrud Poetzinger?

16 Kódà, àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa gba èṣù láyè. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, ìyẹn Gertrud Poetzinger àti Elfriede Löhr. Ìjọba Násì sọ àwọn méjèèjì àtàwọn arábìnrin míì sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ó ṣẹlẹ̀ pé Arábìnrin Gertrud bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Arábìnrin Elfriede torí pé ó máa ń sọ àsọyé tó ń fún àwọn arábìnrin yòókù níṣìírí. Nígbà tó yá, Arábìnrin Gertrud tún inú rò, ó rí i pé ohun tí òun ṣe kù díẹ̀ káàtó, ó sì bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Ó wá sọ pé: “Ó yẹ kí inú wa máa dùn pé àwọn míì ní àwọn ẹ̀bùn táwa ò ní tàbí pé wọ́n láwọn àfikún ojúṣe tó ju tiwa lọ.” Kí ni Gertrud ṣe tí kò fi jowú ẹnì kejì rẹ̀ mọ́? Dípò kó máa wá ibi tí Elfriede kù sí, àwọn ànímọ́ dáadáa tó ní ló gbájú mọ́. Ìyẹn mú kó túbọ̀ mọyì Arábìnrin Elfriede, àárín wọn sì pa dà gún régé. Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, àwọn méjèèjì fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà títí wọ́n fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé. Torí náà, tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa, a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun da àárín wa rú, àá sì wà níṣọ̀kan.​—Kól. 3:​13, 14.

17. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra ká má bàa kọjá àyè wa?

17 Mọ̀wọ̀n ara rẹ, má ṣe kọjá àyè rẹ. Ó ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn arákùnrin tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n ń múpò iwájú. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní fa ìṣòro fún ara wa tàbí fún àwọn míì. (1 Pét. 5:5) Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn tó ń múpò iwájú sọ fún àwọn akéde pé kí wọ́n má ṣe fún àwọn èèyàn ní ìtẹ̀jáde wa tí wọ́n bá wàásù fún wọn. Síbẹ̀, arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan gbà pé òun gbọ́n jùyẹn lọ, kò sì fi ìtọ́ni náà sílò, ṣe ló ń fún àwọn èèyàn ní ìwé wa. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Kò pẹ́ tí òun àtàwọn míì parí wíwàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà làwọn ọlọ́pàá mú wọn tí wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Ó ṣeé ṣe káwọn aṣojú ìjọba ti máa ṣọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan síbòmíì, wọ́n sì gba gbogbo ìwé yẹn lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fún. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni, ká má ṣe ronú pé a gbọ́n ju àwọn tó ń múpò iwájú. Inú Jèhófà máa ń dùn bá a ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó yàn sípò.​—Héb. 13:​7, 17.

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣòfin máṣu mátọ̀?

18 Yẹra fún ṣíṣe òfin máṣu mátọ̀. Bí àwọn alàgbà bá ń gbé àwọn òfin tara wọn kalẹ̀ nínú ìjọ, nǹkan máa nira fún àwọn ará. Arákùnrin Juraj Kaminský rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè tó ń jẹ́ Czechoslovakia tẹ́lẹ̀, ó ní: “Lẹ́yìn tí wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run, àwọn alábòójútó kan nínú ìjọ àti ní àyíká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfin máṣu mátọ̀ fún àwọn ará.” Ká fi sọ́kàn pé Jèhófà kò fún ẹnikẹ́ni nínú wa láṣẹ láti ṣèpinnu fún àwọn míì. Ńṣe lẹni tó ń ṣe òfin máṣu mátọ̀ ń sọ ara ẹ̀ di ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ àwọn ará dípò kó dáàbò bò wọ́n.​—2 Kọ́r. 1:24.

MÁ ṢE FI JÈHÓFÀ SÍLẸ̀ LÁÉ!

19. Bó ṣe wà nínú 2 Kíróníkà 32:​7, 8, kí nìdí tí ẹ̀rù kò fi bà wá láìka ohun yòówù kí Sátánì ṣe sí?

19 Sátánì Èṣù tó jẹ́ olórí ọ̀tá wa kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. (1 Pét. 5:8; Ìfi. 2:10) Òun àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ máa wá gbogbo ọ̀nà láti mú ká ṣíwọ́ jíjọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ ẹ má ṣe jẹ́ ká bẹ̀rù! (Diu. 7:21) Jèhófà wà pẹ̀lú wa, kò sì ní fi wá sílẹ̀ láé kódà tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa.​—Ka 2 Kíróníkà 32:​7, 8.

20. Kí lo pinnu láti ṣe?

20 Ẹ jẹ́ káwa náà pinnu bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí wọ́n sọ fún àwọn aláṣẹ ìgbà yẹn pé: “Ẹ̀yin náà ẹ sọ, tó bá tọ́ lójú Ọlọ́run pé ká fetí sí yín dípò ká fetí sí Ọlọ́run. Àmọ́ ní tiwa, a ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.”​—Ìṣe 4:​19, 20.

ORIN 73 Fún Wa Ní Ìgboyà

^ ìpínrọ̀ 5 Kí ló yẹ ká ṣe tí ìjọba bá ṣòfin pé ká má ṣe jọ́sìn Jèhófà mọ́? Àpilẹ̀kọ yìí máa sọ àwọn ohun pàtó tá a lè ṣe àtàwọn ohun tó yẹ ká yẹra fún ká lè máa sin Jèhófà nìṣó.

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Gbogbo àwòrán inú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká rí bí nǹkan ṣe rí fáwọn ará wa láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Nínú àwòrán yìí, àwọn ará mélòó kan ń ṣèpàdé nínú yàrá ìkẹ́rùsí arákùnrin kan.

^ ìpínrọ̀ 61 ÀWÒRÁN: Arábìnrin tó wà lápá òsì yìí ń bá obìnrin kan sọ̀rọ̀, ó sì ń wá bó ṣe máa mú ọ̀rọ̀ Bíbélì wọnú ìjíròrò náà.

^ ìpínrọ̀ 63 ÀWÒRÁN: Àwọn ọlọ́pàá ń wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu arákùnrin kan, àmọ́ ó kọ̀ láti sọ ohunkóhun fún wọn nípa àwọn ará.