Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 34

Bó O Ṣe Lè Láyọ̀ Tí Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Bá Yí Pa Dà

Bó O Ṣe Lè Láyọ̀ Tí Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Bá Yí Pa Dà

“Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”​—HÉB. 6:10.

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-3. Sọ díẹ̀ lára ohun tó lè mú káwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fi iṣẹ́ náà sílẹ̀.

TỌKỌTAYA ni Robert àti Mary Jo, wọ́n sì ti lo ọdún mọ́kànlélógún (21) lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí wọ́n kúrò lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ẹ gbọ́ ohun tí wọ́n sọ: “Àwọn òbí wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló ń ṣàìsàn, ìyẹn sì gba pé ká pa dà sílé lọ bójú tó wọn. A láyọ̀ pé à ń bójú tó wọn, àmọ́ ó dùn wá pé a fi ibi tá a nífẹ̀ẹ́ sí gan-an sílẹ̀.”

2 Tọkọtaya míì tó ń jẹ́ William àti Terrie náà sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn, wọ́n ní: “Nígbà tá a gbọ́ pé a ò ní lè pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa mọ́ torí àìlera, ó dùn wá gan-an, kódà ṣe la bú sẹ́kún. Ó wá ṣe kedere pé gbogbo èrò wa pé àá máa bá iṣẹ́ wa nìṣó nílẹ̀ òkèèrè ti já sófo.”

3 Arákùnrin Aleksey tó sìn ní Bẹ́tẹ́lì sọ pé: “A mọ̀ pé àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa ti ń wọ́nà bí wọ́n ṣe máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa pa. Síbẹ̀, ṣe ló dà bí àlá nígbà tí wọ́n ti ọ́fíìsì náà pa, ìyẹn sì gba pé kí gbogbo wa fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀.”

4. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Yàtọ̀ sí tàwọn tá a sọ tán yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míì ni iṣẹ́ ìsìn wọn ti yí pa dà. * Kò rọrùn rárá fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin olóòótọ́ yìí láti fi iṣẹ́ tí wọ́n gbádùn gan-an sílẹ̀. Kí lá jẹ́ kó rọrùn fún wọn nínú ipò tuntun tí wọ́n bára wọn? Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ káwa náà mọ ohun tá a lè ṣe tí nǹkan bá yí pa dà fún wa.

OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ NǸKAN BÁ YÍ PA DÀ

Kí nìdí tọ́kàn àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fi máa ń gbọgbẹ́ tí wọ́n bá ń fi iṣẹ́ ìsìn wọn sílẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 5) *

5. Báwo ló ṣe máa ń rí tí iṣẹ́ ìsìn wa bá yí pa dà?

5 Yálà Bẹ́tẹ́lì la ti ń sìn tàbí pápá, a máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn tó yí wa ká, ara wa sì máa ń mọlé níbi tá a ti ń sìn. Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé iṣẹ́ wa yí pa dà tó sì gba pé ká fibẹ̀ sílẹ̀, ọkàn wa máa ń gbọgbẹ́. A lè máa ṣàárò àwọn tá a fi sílẹ̀, a sì lè máa ṣàníyàn nípa wọn, pàápàá tó bá jẹ́ pé inúnibíni ló mú ká kúrò níbẹ̀. (Mát. 10:23; 2 Kọ́r. 11:28, 29) Yàtọ̀ síyẹn, ṣe lèèyàn máa ń dà bí àjèjì níbi tuntun tó bá lọ, kódà kó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ló pa dà sí. Robert àti Mary Jo tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ṣe la dà bí àlejò láàárín àwọn èèyàn wa, kódà kò rọrùn fún wa láti fi èdè wa wàásù. Ó ṣe wá bíi pé a ò rẹ́ni fojú jọ.” Àwọn tí iṣẹ́ ìsìn wọn yí pa dà lè níṣòro ìṣúnná owó. Nǹkan lè tojú sú wọn, ọkàn wọn lè dàrú, wọ́n sì lè rẹ̀wẹ̀sì. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni wọ́n lè ṣe?

Ó ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e (Wo ìpínrọ̀ 6 àti 7) *

6. Báwo la ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

6 Túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jém. 4:8) Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Sáàmù 62:8 sọ pé, “Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.” Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà “lè ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn.” (Éfé. 3:20) Kì í ṣe àwọn nǹkan tá a dìídì béèrè nínú àdúrà wa nìkan ni Jèhófà máa ń ṣe. Ó máa ń ṣe kọjá ohun tá a retí àtohun tá a lérò láti yanjú ìṣòro wa.

7. (a) Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? (b) Bó ṣe wà nínú Hébérù 6:10-12, kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín nìṣó?

7 Kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. Arákùnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé, kó o sì máa múra ìpàdé sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ bó o ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀.” Bákan náà, máa wàásù déédéé ní ìjọ tuntun tó o wà. Fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í gbàgbé àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín láìka ìyípadà tó dé bá wọn bí wọn ò bá tiẹ̀ lè ṣe tó bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.—Ka Hébérù 6:10-12.

8. Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Jòhánù 2:15-17 ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bó o ti mọ?

8 Ṣe bó o ti mọ. Má ṣe jẹ́ kí àníyàn ayé Sátánì yìí paná ìtara tó o ní fún ìjọsìn Jèhófà. (Mát. 13:22) Má ṣe jẹ́ kí ohun táyé Sátánì ń gbé lárugẹ àtohun táwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí ń sọ mú kó o máa lé owó. (Ka 1 Jòhánù 2:15-17.) Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó ṣèlérí pé òun máa fún ẹ lókun, òun máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, òun á sì pèsè ohun tó o nílò “ní àkókò tó tọ́.”—Héb. 4:16; 13:5, 6.

9. Bó ṣe wà nínú Òwe 22:3, 7, kí nìdí tí kò fi yẹ kó o tọrùn bọ gbèsè? Kí lá mú kó o ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu?

9 Má ṣe tọrùn bọ gbèsè. (Ka Òwe 22:3, 7.) Ó máa ń náni lówó gan-an téèyàn bá ṣípò pa dà, téèyàn ò bá sì ṣọ́ra ó lè tọrùn bọ gbèsè. Tó ò bá fẹ́ tọrùn bọ gbèsè, má ṣe jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ra nǹkan àwìn, má sì yáwó láìnídìí. Tí ìṣòro bá yọjú, bóyá tẹ́nì kan nínú ìdílé rẹ ń ṣàìsàn, ẹ lè má mọ iye tẹ́ ẹ máa yá lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ yíjú sí Jèhófà, kẹ́ ẹ gbàdúrà, kẹ́ ẹ sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i pé kó ràn yín lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Jèhófà máa gbọ́ àdúrà yín, á mú kẹ́ ẹ ní àlàáfíà tó máa “ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín,” èyí á sì jẹ́ kẹ́ ẹ lè fara balẹ̀ ronú kẹ́ ẹ tó ṣèpinnu èyíkéyìí.—Fílí. 4:6, 7; 1 Pét. 5:7.

10. Báwo la ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun?

10 Má ṣe fàwọn ọ̀rẹ́ gidi sílẹ̀. Sọ ìrírí rẹ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ, pàápàá àwọn tẹ́ ẹ ti jọ ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rí. Torí pé ipò yín jọra, ẹ̀ẹ́ lè jọ fún ara yín níṣìírí. (Oníw. 4:9, 10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣì ń bá àwọn tó wà níbi tó o fi sílẹ̀ ṣọ̀rẹ́, á dáa kó o láwọn ọ̀rẹ́ tuntun níbi tó o wà báyìí. Rántí pé tó o bá fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́, ó yẹ kára tìẹ náà yá mọ́ọ̀yàn. Báwo lo ṣe lè láwọn ọ̀rẹ́ tuntun? Jẹ́ káwọn ará mọ àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ, kí wọ́n lè rí i pé o gbádùn iṣẹ́ ìsìn yẹn gan-an. Táwọn kan nínú ìjọ ò bá tiẹ̀ mọyì bó o ṣe lo ara rẹ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àpẹẹrẹ rẹ máa wú àwọn míì lórí, wọ́n á sì mú ẹ lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́ o, má ṣe máa sọ̀rọ̀ ṣáá nípa àwọn nǹkan tó o ti gbé ṣe, má sì máa ránnu mọ́ àwọn ìṣòro tó o ní báyìí.

11. Báwo lo ṣe lè mú kí àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ gún régé?

11 Tó bá jẹ́ pé àìsàn ọkọ tàbí ìyàwó rẹ ló mú kẹ́ ẹ fiṣẹ́ ìsìn sílẹ̀, má ṣe dá a lẹ́bi. Tó bá sì jẹ́ pé àìlera tìẹ ló mú kẹ́ ẹ fiṣẹ́ náà sílẹ̀, má ṣe máa dá ara ẹ lẹ́bi, má sì ronú pé ìwọ lo fi tìẹ kó bá ẹnì kejì rẹ. Rántí pé “ara kan” ni yín, ẹ sì ti ṣèlérí níwájú Jèhófà pé èkùrọ̀ ni alábàákú ẹ̀wà, pé lábẹ́ dídùn lábẹ́ kíkan, ẹ̀ẹ́ wà fúnra yín. (Mát. 19:5, 6) Tó bá jẹ́ pé oyún ló gbé yín kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn, ẹ jẹ́ kí ọmọ yín mọ̀ pé ẹ mọyì rẹ̀ ju iṣẹ́ ìsìn yín lọ. Ẹ máa fi dá ọmọ náà lójú nígbà gbogbo pé ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni. (Sm. 127:3-5) Bákan náà, ẹ máa sọ àwọn ìrírí alárinrin tẹ́ ẹ ní nígbà tẹ́ ẹ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún un. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kó máa wu ọmọ yín láti fayé rẹ̀ sin Jèhófà bẹ́yin náà ti ṣe.

BÁWỌN MÍÌ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́

12. (a) Kí la lè ṣe táwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún á fi máa bá iṣẹ́ náà lọ? (b) Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ bí nǹkan bá yí pa dà fún wọn?

12 Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ìjọ àtàwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń ṣe bẹbẹ tó bá di pé kí wọ́n ran àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n má fiṣẹ́ náà sílẹ̀, wọ́n sì máa ń fowó àtàwọn nǹkan míì ránṣẹ́ sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan máa ń bá wọn bójú tó òbí wọn tó wà nílé. (Gál. 6:2) Tí nǹkan bá yí pa dà fáwọn tó wà nínú iṣẹ́ alákòókò kíkún tí wọ́n sì kó wá sí ìjọ yín, ẹ má ṣe fojú burúkú wò wọ́n bíi pé ṣe ni ètò Ọlọ́run bá wọn wí tàbí pé wọ́n gbaṣẹ́ lọ́wọ́ wọn. * Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti mú kára tù wọ́n. Ẹ gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, ẹ gbóríyìn fún wọn torí iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ti ṣe kódà tí àìlera ò bá jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ẹ sún mọ́ wọn kẹ́ ẹ lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n. Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn torí pé ọ̀pọ̀ ìrírí ni wọ́n ní, ètò Ọlọ́run sì ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ gan-an.

13. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí iṣẹ́ ìsìn wọn yí pa dà?

13 Níbẹ̀rẹ̀, ó máa gba pé kẹ́ ẹ ṣèrànwọ́ fáwọn tí iṣẹ́ ìsìn wọn yí pa dà, bóyá kẹ́ ẹ bá wọn wá ilé tàbí iṣẹ́. Ó sì lè gba pé kẹ́ ẹ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń wọkọ̀ ládùúgbò yín àti bí wọ́n ṣe lè ra nǹkan. A lè sọ bí wọ́n ṣe lè sanwó iná àtàwọn nǹkan míì, ká sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè rí àwọn nǹkan tí wọ́n nílò lójoojúmọ́. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká lóye wọn, ká sì gba tiwọn rò, kì í ṣe pé ká kàn máa káàánú wọn lásán. Ó ṣeé ṣe kí àwọn fúnra wọn máa ṣàìsàn tàbí kí wọ́n máa tọ́jú mọ̀lẹ́bí wọn kan tó ń ṣàìsàn. Wọ́n sì lè máa ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó kú. * Bákan náà, wọ́n lè máa ṣàárò àwọn ará tí wọ́n fi sílẹ̀ níbi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, bí ò tiẹ̀ hàn lójú wọn. Ó máa ń pẹ́ kéèyàn tó lè gbọ́kàn kúrò nínú àwọn nǹkan yìí.

14. Báwo làwọn akéde ìjọ tuntun tí arábìnrin kan wà ṣe mú kára ẹ̀ mọlé?

14 Ní báyìí ná, àpẹẹrẹ yín àti bẹ́ ẹ ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ máa mú kára wọn mọlé. Arábìnrin kan tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn nílẹ̀ òkèèrè sọ pé: “Níbi tí mo ti ń sìn tẹ́lẹ̀, ojoojúmọ́ ni mo máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ látìgbà tí mo ti débí, mi ò réèyàn bá sọ̀rọ̀ ká má tíì sọ pé màá ka Bíbélì tàbí fi fídíò hàn wọ́n. Bó ti wù kó rí, àwọn akéde ìjọ náà máa ń mú mi lọ sí ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn. Bí mo ṣe ń rí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin onítara yẹn tí wọ́n ń fìgboyà wàásù tí wọ́n sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mú kó dá mi lójú pé èmi náà ṣì máa ní ìkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, mo mọ bí mo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò níbi tí mo wà báyìí. Èyí sì mú kí n pa dà láyọ̀.”

MÁA FAYỌ̀ SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ

Máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ níbi tó o wà báyìí (Wo ìpínrọ̀ 15 àti 16) *

15. Kí lá jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí bí iṣẹ́ ìsìn rẹ bá yí pa dà?

15 O lè ṣàṣeyọrí bíṣẹ́ ìsìn rẹ bá tiẹ̀ yí pa dà. Má ṣe wo ara rẹ bí aláìmọ̀-ọ́n-ṣe. Máa fiyè sí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, má sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Fara wé àwọn Kristẹni tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà lọ́gọ́rùn-ún ọdún kìíní. Bíbélì ròyìn pé “wọ́n ń kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà” ní gbogbo ibi tí wọ́n lọ. (Ìṣe 8:1, 4) Tó ò bá dẹwọ́, wàá rẹ́ni tó máa gbọ́rọ̀ rẹ, tí wàá sì máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lé àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan kúrò lórílẹ̀-èdè kan, wọ́n sì lọ sórílẹ̀-èdè míì láti wàásù fáwọn tó ń sọ èdè wọn níbẹ̀ torí àìní wà lágbègbè yẹn. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Jèhófà bù kún iṣẹ́ wọn, wọ́n sì dá àwùjọ mélòó kan sílẹ̀.

16. Kí lá jẹ́ kó o láyọ̀ níbi tó o wà báyìí?

16 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìdùnnú Jèhófà ni agbára” wa. (Neh. 8:10, àlàyé ìsàlẹ̀) Àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà ló ń fún wa láyọ̀, kì í ṣe irú iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe, bó ti wù ká gbádùn iṣẹ́ náà tó. Torí náà, túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, máa bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n, kó máa tọ́ ẹ sọ́nà, kó sì máa tì ẹ́ lẹ́yìn. Rántí pé ohun tó jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ ibi tó o wà tẹ́lẹ̀ ni pé gbogbo ọkàn lo fi ṣe iṣẹ́ náà. Torí náà, fi gbogbo ọkàn ẹ sí iṣẹ́ ìsìn tó ò ń ṣe báyìí, wàá sì rí bí Jèhófà ṣe máa mú kó o nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ náà.—Oníw. 7:10.

17. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe báyìí?

17 Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé títí ayé làá máa jọ́sìn Jèhófà, àmọ́ iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe báyìí máa dópin láìpẹ́. Nínú ayé tuntun, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iṣẹ́ gbogbo wa pátá ló máa yí pa dà. Arákùnrin Aleksey tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ gbà pé ńṣe làwọn ìyípadà yẹn ń múra òun sílẹ̀ de ayé tuntun. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà wà, àmọ́ mi ò rò pé mo sún mọ́ ọn tó. Bákan náà, mo mọ̀ pé ayé yìí máa di Párádísè, àmọ́ ó jọ pé ó ṣì máa pẹ́ kó tó dé. Ṣùgbọ́n ní báyìí, ṣe ló dà bíi pé mò ń wo Jèhófà níwájú mi àti pé ayé tuntun ti dé tán.” (Ìṣe 2:25) Iṣẹ́ ìsìn yòówù ká máa ṣe báyìí, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó dájú pé kò ní fi wá sílẹ̀ láé, kàkà bẹ́ẹ̀ á jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa níbi yòówù ká ti máa sìn.—Àìsá. 41:13.

ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú

^ ìpínrọ̀ 5 Nígbà míì, ó lè ṣẹlẹ̀ pé káwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ tàbí kí ètò Ọlọ́run fún wọn níṣẹ́ míì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ àwọn ìṣòro tí wọ́n máa ń kojú àtohun táá jẹ́ kó rọrùn fún wọn nínú ipò tuntun tí wọ́n bára wọn. Àá tún sọ báwọn míì ṣe lè fún wọn níṣìírí kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Bákan náà, a máa jíròrò àwọn ìlànà mélòó kan tó lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ tí nǹkan bá yí pa dà fún wa.

^ ìpínrọ̀ 4 Bákan náà, táwọn arákùnrin tó ní ojúṣe pàtàkì nínú ètò Ọlọ́run bá ti dé ọjọ́ orí kan, wọ́n máa ń fi ojúṣe náà sílẹ̀ fáwọn arákùnrin tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí. Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ̀yin Àgbàlagbà—Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Yín” nínú Ilé Ìṣọ́ September 2018, àti “Bó O Ṣe Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn Láìka Ìyípadà Èyíkéyìí Sí” nínú Ilé Ìṣọ́ October 2018.

^ ìpínrọ̀ 12 Kí àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n ti kúrò kọ lẹ́tà ìfinimọni ránṣẹ́ sí ìjọ tuntun tí wọ́n wà láìjáfara kí ìjọ tuntun náà lè tètè dámọ̀ràn wọn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà.

^ ìpínrọ̀ 13 Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀,” nínú Jí! No. 3, 2018.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí tọkọtaya kan tó ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè fiṣẹ́ náà sílẹ̀. Ọkàn wọn gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe ń dágbére fáwọn ará ìjọ wọn.

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Nígbà tí wọ́n pa dà sí ìlú wọn, wọn ò fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré, wọ́n máa ń bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wọn.

^ ìpínrọ̀ 61 ÀWÒRÁN: Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì pa dà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alákòókò kíkún. Wọ́n ń fi èdè tí wọ́n kọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì wàásù fún ẹnì kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ sìn.